Ayé-ikú Nṣiṣẹ́
Láìka àwọn ìpènijà tí a nkojú, olùfẹ́ni Baba wa Ọ̀run ti ṣe ètò ìdùnnú irú èyí tí a kò yàn wá mọ́ láti kùnà.
Fun Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún a yàn mi láti kọ́ arábìnrin àgbà kan nílé ní wọ́ọ̀dù mi. Òun kò ní ayé ìrọ̀rùn. Ó ní onírurú wàhálà ìlera ó sì ní ìrírí ìgbésí ayé ìrora nítorí ìjàmbá ìgbà-èwe kan lórí pápá-ìṣeré. Ó ní ìkọ̀sílẹ̀-ìgbéyàwó ní ọjọ́ orí ọdún méjìlélọ́gbọ̀n pẹ̀lú ọmọ mẹ́rin láti tọ́ àti láti pèsè fún, ó tún ìgbéyàwó ṣe ní ọjọ́ orí àádọ́ta ọdún. Ọkọ rẹ̀ kejì kọjá lọ nígbàtí ó wà ní ọjọ́ orí ọdún mẹ́rìndínláàdọ́rin (66), àti pé arábìnrin yí gbé àfikún ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) bí opó.
Láìka àwọn ìpènijà tó gba gbogbo igbésí ayé rẹ̀ sí, ó jẹ́ olotitọ sí àwọn májẹ̀mú rẹ̀ dé òpin. Arábìnrin yí jẹ́ onítara onítàn-ìdílé, ẹnití ó nlọ sí tẹ́mpìlì, àti ẹnití ó nkọ tí ó sì ngba àwọn ìwé-ìtàn ẹbí. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àdánwò tó ṣòro, àti láìsí ìbèèrè ó máà nní ìmọ̀lára ìbànújẹ́ àti àdánìkanwà nígbàmíràn, ó ní ìwò-ojú ọlọ́yàyà àti ìrínisí ìmoore àti dídùnmọ́ni.
Ní oṣù mẹ́sán lẹ́hìn ikú rẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ìrírí alámì nínú tẹ́mpìlì. Ó kẹkọ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ pé ìyá rẹ̀ ní ọ̀rọ̀ fún un. Ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa ìran tàbí àwọn ọ̀rọ̀ sísọjáde. Ọ̀rọ̀ àìní-àṣiṣe wọ̀nyí wá sí inú ọmọkùnrin náà láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀: “mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ayé-ikú nṣiṣẹ́, mo sì fẹ́ kí o mọ̀ pé mo ní òye nísisìyí ìdí tí ohun gbogbo fi ṣẹlẹ̀ [nínú ayé mi] ní ọ̀nà tí ó ṣe—àti pé gbogbo rẹ̀ DARA.”
Ọ̀rọ̀ yí ní gbogbo ọ̀nà jẹ́ alámì síi nígbàtí ẹnìkan bá yẹ ipò rẹ̀ wò àti àwọn ìṣòrò tí arábìnrin yí faradà tí ó sì borí.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ayé-ikú nṣiṣẹ́! Ó jẹ́ ṣíṣe láti ṣiṣẹ́! Láìka àwọn ìpènijà, ìrora-ọkàn, àti àwọn ìṣòrò tí gbogbo wa nkojú sí, olùfẹ́ni, ọlọ́gbọ́n, àti ẹni pípé Baba wa Ọ̀run ti ṣe ètò ìdùnnú irú èyí tí a kò yàn wá mọ́ láti kùnà. Ètò Rẹ̀ npèsè ọ̀nà kan fún wa láti dìde tayọ àwọn ìkùnà ayé-ikú wa. Olúwa ti wí pé, “Èyí ni iṣẹ́ mi àti ògo mi—láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ.”
Bíotilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, bí a bá níláti jẹ́ olùjẹ-ànfààní sí “iṣẹ́ àti … ògo,” àní “àìkú àti ìyè ayérayé,” a gbọ́dọ̀ retí láti gba ẹ̀kọ́ àti ìkọ́ni, àti láti kọjá nínú iná olùsọdọ̀tun—nígbàmíràn dé òpin wa pátápátá. Láti yẹra fún wàhálà, ìpènijà, àti àwọn ìṣòrò ti ayé yí pátápátá yio jẹ́ láti tẹ-ẹ̀gbẹ́ ètò tí ó ṣe dandan nítòótọ́ fún ayé-ikú láti ṣiṣẹ́.
Àti pé nítorínáà kò níláti yà wá lẹ́nu nígbàtí àwọn ìgbà líle bá wá sórí wa. A ó pàdé àwọn ipò tí yíò dán wa wò àti àwọn ènìyàn tí yíò mú wa ṣe àmúlò ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́ àti sùúrù tòótọ́. Ṣùgbọ́n a nílò láti gbéra sókè ní abẹ́ àwọn ìṣòro wa kí a sì rántí, bí Olúwa ti wí:
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ayé rẹ̀ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ mi, nítorí orúkọ mi, yíò rí i lẹ́ẹ̀kansi, àní ìyè ayérayé.
“Nítorínáà, ẹ máṣe bẹ̀rù àwọn ọ̀tá yín [tàbí àwọn wàhálà, ìpènijà, tàbí àdánwó ayé yí], nítorí mo ti pàṣẹ … , ni Olúwa wí, pé èmi ó dán yín wò nínú ohun gbogbo, bóyá ẹ ó gbé nínú májẹ̀mú mi … kí a lè kà yín yẹ.”
Nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára ìrora tàbí ìtara nípa àwọn wàhálà wa tàbí ní ìmọ̀lára pé a lè máa gba ju bí ó ti yẹ níti àwọn ìṣòrò ayé, a lè rántí ohun tí Olúwa wí fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì:
“Ẹ̀yin ó sì rántí [àwọn] ọ̀nà èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín fi darí yín ní ogójì ọdún wọ̀nyí nínú aginjù, láti mú yín ní ìrẹ̀lẹ̀, àti láti dán yín wò, láti mọ ohun [tí] ó wà nínú ọkàn yín, bóyá ẹ̀yin [yíò] pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, tàbí bẹ́ẹ̀kọ́.”
Bí Léhì ti kọ́ ọmọ rẹ̀ Jákọ́bù:
“Ìwọ ti jìyà àwọn ìpọ́njú àti ìkorò pupọ̀. … Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, … [Ọlọ́run] yíò ya ípọ́njú rẹ sí mímọ́ fun èrè rẹ. Nítorí-èyi, èmi mọ̀ pé a ti rà ọ́ padà, nítorí ti òdodo Olùràpadà rẹ.”
Nítorí ayé yí jẹ́ ibi ìdánwò tí “òkùnkùn ìkukù ti ìdàmú si rọ̀ lórí wa tí ó sì ndẹ́rù ba àláfíà wa láti parun,” ó ṣe ìranlọ́wọ́ láti rántí ìmọ̀ràn àti ìlérí yí tí a rí nínú Mosiah 23 ní ìbámu sí àwọn ìpènijà ayé: “Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀—ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú [Olúwa] ọ̀kannáà ni a ó gbé sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn.”
Gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́, èmì tìkálárami ní ìrírí ìrora ẹ̀dùn ọkàn nlá àti ìtìjú tí ó wá bí àbájáde àwọn ìṣe àìṣòdodo ti ẹlòmíràn, èyítí ó pa yíyẹ-araẹni àti èrò orí wíwà ní yíyẹ mi níwájú Olúwa lára fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Bíotilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, mo jẹ́ ẹ̀rí ti araẹni pé Olúwa lè fún wa lókun kí ó sì gbé wa sókè nínú eyikeyi àwọn ìṣòrò tí a pè wá láti ní ìrírí rẹ̀ nínú àtìpó wa nínú àfonífojì omijé yí.
A mọ ìrírí Páùlù dáadáa:
“Bí èmi tilẹ̀ di gbígbé sókè kọjá ìwọ̀n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ìfihàn [tí mo ti gbà], a ti fi ẹ̀gún fún mi nínú ara, ìránṣẹ́ Sátánì láti bò mí, kí èmi máa baà di gbígbé sókè kọjá ìwọ̀n.
“Fún ohun yí ni mo bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta, kí ó lè kúrò lọ́dọ̀ mi.
“Ó sì wí fún mi pé, Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún yín: nítorí okun mi ni a mu di pípé nínú àìlera. Nítorínáà, ní ìnúdídùn jùlọ ni èmi yíò ṣògo nínú àìlera mi, pé kí agbára Krístì lè bà lé mi.”
A kò mọ ohun tí “ẹ̀gún nínú ara” ti Páùlù jẹ́. Ó yan láti máṣe júwe bóyá ó jẹ́ àìlera ti-ara, àrùn ti ọpọlọ tàbí ẹ̀dùn ọkàn, tàbí àdánwò kan. Ṣùgbọ́n a kò nílò láti mọ̀ àlàyé náà láti mọ̀ pé ó làkàkà ó sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ìrànlọ́wọ́ àti pé nígbẹ̀hìn, okun àti agbára Olúwa ni ohun tí ó ràn án lọ́wọ́ láti la inú rẹ̀ kọjá.
Bíi ti Páùlù, ó jẹ́ nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo gba okun ní ti ẹ̀dùn ọkàn àti ti-ẹ̀mí nígbẹ̀hìn, àti ní òpin mo damọ̀ lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pé mo ti nfi ìgbàgbogbo jẹ́ ẹni iyì àti yíyẹ fún àwọn ìbùkún ìhìnrere. Olùgbàlà ràn mi lọ́wọ́ láti borí àwọn ìmọ̀lára mi nípa àìyẹ àti láti nawọ́ ìdáríjì àtinúwa sí ẹni tó ṣẹ̀. Ní òpin mo ní òye pé Ètùtù Olùgbàlà ni ẹ̀bùn araẹni fún mi àti pé Baba Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀ fẹ̀ràn me ní pípé. Nítorí Ètùtù Olùgbàlà, ayé-ikú nṣiṣẹ́.
Nígbàtí mo di alábùkún-fún nígbẹ̀hìn láti damọ̀ bí Olùgbàlà ṣe gbà mí là tí ó sì dúró lẹgbẹ mi nínú àwọn ìrírí wọnnì, mo ní òye kedere pé ipò àìdára ti àwọn ọdún-èwè mi jẹ́ ìrìnàjò àti ìrírí ti araẹni mi, ìpinnu èyí àti àbájáde ìgbẹ̀hìn tí a kò lè retí sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti jìyà tí wọ́n sì tẹ̀síwájú láti jìyà látinú ìwà àìṣòdodo ti àwọn ẹlòmírán.
Mo damọ̀ pé àwọn ìrírí ayé—rere àti búburú—lè kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. Mo mọ̀ nísisìyí mo sì jẹ́ ẹ̀rí pé ayé-ikú nṣiṣẹ́! Mo ní ìrètí pé bíi àbájáde àròpọ̀ àwọn ìrírí ìgbésí ayé mi—rere àti búburú—mo ní àánú fún àwọn aláímọ̀kan tí a palára nípa àwọn ìṣe ẹlòmíràn àti ìrọ́nú fún àwọn tí a ntẹ̀ mọ́lẹ̀.
Mo ní ìrètí lódodo pé bíi àbájáde àwọn ìrírí ìgbésí ayé mi—rere àti búburú—mo ní inú rere sí àwọn ẹlòmíràn síi, mo nṣe sí àwọn ẹlòmíràn bí Olùgbàlà yíò ti ṣe, mo sì ní òye títóbijù fún ẹlẹ́ṣẹ̀ àti pé mo ní ìwà ìṣòtítọ́ pípé. Bí a ti wá láti gbáralé oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà tí a sì npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, a lè dúró bí àpẹrẹ àbábọ̀ pípẹ́ ti Ètùtù Olùgbàlà.
Mo pín àpẹrẹ íparí pé ayé-ikú nṣiṣẹ́.
Àùntí Alàgbà Hales, Lois VandenBosch, àti ìyá rẹ̀, Klea VandenBosch.
Ìyá mi kò ní ìrìnàjò ìrọ̀rùn nínú ayé-ikú. Kò gba àwọn oríyìn tàbí iyì ti-ayé kò sì ní àwọn ànfàní ikẹkọ tayọ ilé-ìwé giga. Ó kó àrùn pólíò bí ọmọdé, tí ó yọrísí ìgbésí-ayé ìrora àti àìní-ìtura nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bí àgbàlagbà, ó ní ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòrò àti pípèníjà ti-ara àti ipò ìnáwó, ṣùgbọ́n ó jẹ́ olótítọ́ sí àwọn májẹ̀mú rẹ̀ ó sì fẹ́ràn Olúwa.
Nígbàtí ìyá mi jẹ́ ẹni ọdún márunléláàdọ́ta (55), arábìnrin mi àgbà tí mo tẹ̀lé kọjá lọ, ó fi ọmọdébìnrin kan sílẹ̀ ní ọmọ oṣù mẹ́jọ, níìsì mi, aláìníyàá. Fún onírurú àwọn èrèdí, ní púpọ̀jù Ìyá parí sí títọ́ níìsì mi fún ọdún mẹ́tàdínlógún tó tẹ̀le, nígbàkugbà lábẹ́ àwọn ipò ìgbìyànjú gidi. Síbẹ̀, láìka àwọn ìrírí wọ̀nyí sí, ó fi ìdùnnú àti pẹ̀lú ìfẹ́ sin ẹbí, aladugbo, àti àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ ó sì sìn bí òṣìṣẹ́ ìlànà nínú tẹ́mpìlì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọdún tó kẹ́hìn ní ayé rẹ̀, Ìyá jìyà nínú irú àrùn ìgbàgbé-ọpọlọ kan, nígbàkugbà ó máa nní ìdàmú, a sì fi sí ilé ìtọ́jú kan. Pẹ̀lú àbámọ̀, ó dánìkanwà nígbàtí ó kọjá lọ ní àìròtẹ́lẹ̀.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣù lẹ́hìn ikú rẹ̀, mo lá àlá kan tí èmi kò tíì gbàgbé rí. Nínú àlá mi, mo joko nínú ọ́físì mi ní Ilé Ìṣàkóso Ìjọ. Ìyá wọlé sínú ọ́físì náà. Mo mọ̀ pé ó wá láti ayé ẹ̀mí. Èmì yíò máa rántí ìmọ̀lára tí mo ní nígbà-gbogbo. Òun kò sọ ohun kankan, ṣùgbọ́n ó dán ìdán ẹ̀wà ti-ẹ̀mí tí èmi kò ní ìrírí rẹ̀ rí ṣaájú àti èyí tí mo ní ìṣòro ní jíjúwe rẹ̀.
Ìwò ojú àti wíwà rẹ̀ yanilẹ́nu nítòótọ́! Mo rántí tí mò nsọ fun pé, “Ìyá, o rẹwà gidi!,” ní títọ́ka sí agbára àti ẹ̀wà rẹ̀ ti-ẹ̀mí. Ó dá mi mọ̀—lẹ́ẹ̀kansi láìsọ ọ̀rọ̀. Mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ rẹ̀ fún mi, mo sì mọ̀ nígbànáà pé inú rẹ̀ dùn ó sì ti ní ìwòsàn kúrò nínú àwọn wàhálà àti ìpènijà rẹ̀ ti ayé ó sì ndúró pẹ̀lú ìtara de “àjínde ológo kan.” Mo mọ̀ pé fún Ìyá, ayé-ikú ṣiṣẹ́—àti pé ó nṣiṣẹ́ fún wa, bákannáà.
Iṣẹ́ àti ògo Ọlọ́run ní láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ. Àwọn ìrírí ayé-ikú jẹ́ ara ìrìnàjò tí ó fi àyè gbà wá láti dàgbà kí a sì tẹ̀síwájú sí ìhà ayé-ikú àti ìyè ayérayé náà. A kò rán wa wá sihin láti kùnà ṣùgbọ́n láti yege nínú ètò Ọlọ́run fún wa.
Ọba Benjamin kọ́ni pé: “Àti pẹ̀lúpẹ̀lù, mo fẹ́ kí ẹ ro ti ipò alábùkúnfún àti ayọ̀ ti àwọn tí wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Nítorí kíyèsíi, wọ́n jẹ́ alábùkúnfún nínú ohun gbogbo, níti-ara àti ti-ẹ̀mí; tí wọ́n bá sì forítĩ ní òtítọ́ dé òpin a ó gbà wọ́n sí ọ̀run, pé nípa èyí nã wọn ó le gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ipò inúdídùn tí kò nípẹ̀kun.” Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, ayé-ikú nṣiṣẹ́!
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ti ngba àwọn ìlànà ìhìnrere, tí a nwọlé sínú àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run àti nígbànáà tí a npa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́, tí a nronúpìwàdà, tí a nsin àwọn ẹlòmíràn, tí a sì nfaradà dé òpin, àwà bákannáà lè ní ìdánilójú àti ìgbẹ́kẹ̀lé pípé nínú Olúwa pé ayé-ikú nṣiṣẹ́! Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì àti pé ọjọ́-iwájú wa ológo pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run ni a mú ṣeéṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ àti Ètùtù Olùgbàlà. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.