Wá A Pẹ̀lú Gbogbo Ọkàn Rẹ
Bí Jésù Krístì bá wá àkokò ìdákẹ́jẹ́ láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ àti láti fún Un lókun, yíò bọ́gbọ́n mu fún wa láti ṣe bákannáà.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, èmi àti ìyàwó mi sìn gẹ́gẹ́bí olórí míṣọ̀n ní Tokyo, Japan. Nígbà ìbẹ̀wò míṣọ̀n wa nípasẹ̀ Alàgbà Russell M. Nelson nígbànáà, ọ̀kan lára àwọn ojíṣẹ́-ìhìnrere náà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó ṣe dára jù lọ láti fèsì nígbàtí ẹnì kan bá sọ fún wọn pé ọwọ́ wọn dí jù láti fetísílẹ̀ sí wọn. Pẹ̀lú ìlọ́ra díẹ̀, Alàgbà Nelson wí pe, “èmi yíò bèèrè bòyà iṣẹ́ wọn díwọ́ púpọ̀ láti jẹ oúnjẹ ọ̀san ní ọjọ́ náà nígbànáà kí ẹ sì kọ́ wọn pé wọ́n ní ara àti ẹ̀mí, àti gẹ́gẹ́bí ara wọn yíò ti kú tí a kò bá bọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí wọn yíò ṣe bí a kò bá bọ wọn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run.”
O jẹ iyanilenu lati ṣe akiyesi pe ọrọ Japanese fun “ọwọ́ dí jù,” isogashii, jẹ́ ohun kíkọ kan pẹ̀lú àwọn àmì méjì (忙). Èyí tí ó wà ní òsì túmọ̀ sí “ọkàn” tàbí “ẹ̀mí,” èyí tí ó wà ní apá ọ̀tún túmọ̀ sí “ikú”—bóyá ó ndá àbá, bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni, pé dídi ọwọ́ jù láti bọ́ àwọn ẹ̀mí wa lè mú wa kú nípa tẹ̀mí.
Olúwa mọ̀—nínú ayé yíyára yí, tí ó kún fún àwọn ìyọnu àti ninu ìdàrú-dàpọ—pé ṣíṣe àkokò dídára fún Un yíò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpèníjà nlá ọjọ́ wa. Sísọrọ nípasẹ̀ wòlíì Ìsàíàh, Ó pèsè àwọn ọ̀rọ̀ àmọ̀ràn àti ìṣọ́ra wọ̀nyí tí a lè fi wé àwọn ọjọ́ ìrúkèrúdò nínú èyí tí a ngbé:
“Ní pípadàbọ̀ àti ìsinmi li a ó gbà nyín; nínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ní ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára nyín yíò jẹ́: ẹ̀nyin kò sì fẹ́.
“Ṣùgbọ́n ẹ̀nyin wípé, Bẹ̃kọ́; nítorí àwa ó sá lórí àwọn ẹṣin; nítorínáà li ẹ̀nyin o ṣe sá: àtipé, Àwa o gùn ìyára; nítorínáà àwọn tí nlépa yín yíò yára.”
Ní ọ̀rọ̀ míràn, bíótilẹ̀jẹ́pé ìgbàlà wa dá lórí pípadàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nígbàgbogbo kí a sì sinmi kúrò ninu àwọn àníyàn ayé, a kò ṣeé. Àtipé bíótilẹ̀jẹ́pé ìgbẹ́kẹ̀lé wa yíò wá láti inú agbára kan tí a mú dàgbà ní àwọn àkokò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ní jíjókòó pẹ̀lú Olúwa nínu àṣàrò àti ìrònú, a kò ṣe. Kíló dé? Nítorípé a sọ pé, “Rárá o, ọwọ́ wa dí pẹ̀lú àwọn nkan míràn”—ní sísá lórí àwọn ẹṣin wa, kí a sọ bẹ́ẹ̀. Nítorínáà, a ó lọ síwájú àti síwájú síi kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run; a ó ta kú lórí lílọ ni yíyára àti yíyára síi; àtipé bí a bá ṣe yára kánkán sí, ni Sátánì yíò yára tẹ̀lé e.
Bóyá èyí ni ìdí tí Ààrẹ Nelson fi bẹ̀wá léraléra láti fi àkokò sílẹ̀ fún Olúwa nínú ìgbé ayé wa ní—”ọ̀kọ̀ọ̀kan àti ní gbogbo ọjọ́.” Ó ránwa létí pé “àkokò ìdákẹ́rọ́rọ́ jẹ́ àkokò mímọ́—àkokò tí yío ṣe okùnfà ìfihàn ti ara ẹni tí yío sì gbìn àláfíà.” Ṣùgbọ́n láti gbọ́ ohùn jẹ́jẹ́ Olúwa, ó gbani nímọ̀ràn, “ẹ̀yin pẹ̀lú gbọdọ̀ dúró jẹ́ẹ́.”
Dídúró jẹ́ẹ́, nbéèrè bákanáà, ju wíwá àkokò fún Olúwa nìkan lọ—ó nbéèrè pé kí a jáwọ́ nínú àwọn ìrònú ṣíṣe iyèméjì àti bíbẹ̀rù wa àti gbígbé ọkàn àti èrò inú wa lé E. Bí Alàgbà David A. Bednar ti kọ́ni, “Àmọ̀ràn Olúwa láti ‘dúró jẹ́ẹ́’ ní ohun púpọ̀ nínú ju kí a máṣe sọ̀rọ̀ tàbí rìn lásán lọ.” Lati dúró jẹ́ẹ́, ni ó dábàá, “lè jẹ́ ọ̀nà kan láti rán wa létí láti dojúkọ Olùgbàlà láìkùnà.”
Dídúró jẹ́ẹ́ jẹ́ ìṣe ìgbàgbọ́ ó sì nbèèrè akitiyan. Àwọn Ìkọ́ni lórí Ìgbàgbọ́ wípé, “Nígbàtí ènìyàn bá ṣiṣẹ́ nípa ìgbàgbọ́ ó ṣiṣẹ́ nípa agbára ọpọlọ.” Ààrẹ Nelson kéde pé: “Ìfojúsùn wa gbọ́dọ̀ jẹ́ síso mọ́ Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀. Ó jẹ́ iṣẹ́ líle fún ọpọlọ láti tiraka láti wò Ó nínú gbogbo èrò. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn iyèméjì àti ẹ̀rù wa yíò fò lọ.” Sísọ̀rọ̀ nípa ìnílò yí láti ṣe ìfojúsùn ọkàn wa, Ààrẹ David O. McKay wí pé: “Mo rò wípé a fi àkíyèsí tó kéréjù sí iye-orí àṣàrò, ìlànà ti ìfọkànsìn kan. … Àṣàrò jẹ́ ọ̀kan nínú … àwọn ilẹ̀kùn mímọ́ jùlọ èyítí a ngbà lọ síwájú Olúwa.”
Ọ̀rọ̀ kan wà ní Japanese, mui, wípé, fún èmi, èyi kápá èrò-orí aláròjinlẹ̀ tó kún fún ìgbàgbọ́ náà, ti ohun tó túmọ̀ sí láti dúró jẹ́ẹ́. Ó jẹ́ nínú àwọn ohun kíkọ méjì (無為). Ohun kíkọ tí ó wà ní apá òsì túmọ̀sí “kò sí ohunkóhun” tàbí “nkankan,” àti pé èyí tí ó wà ní apá ọ̀tún túmọ̀ sí “láti ṣe.” Àpapọ̀ wọ́n túmọ̀ sí “àì-máṣe.” Ní mímú bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an, a lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà lòdì láti túmọ̀ sí “láti má ṣe ohunkóhun” lọ́nà kannáà “láti dúró jẹ́ẹ́” ni a lè túmọ̀ lòdì sí “láì sọ̀rọ̀ tàbí mira. Síbẹ̀síbẹ̀, bíi gbólóhùn náà, “láti dúró jẹ́ẹ́,” ó ní ìtumọ̀ tí ó ga jù; fún mi ó jẹ́ ìránnilétí láti ṣe díẹ̀díẹ̀ àti láti gbé pẹ̀lú òye nlá ti ẹ̀mí.
Nígbàtí mo nsìn nínú Àjọ Ààrẹ Agbègbè Àríwá Asia pẹ̀lú Alàgbà Takashi Wada, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ìyàwó rẹ̀, Arábìnrin Naomi Wada, jẹ́ ògbóǹtarìgí ònkọ̀wé-àrà ní Japan. Mo bi Arábìnrin Wada bóyá yíò ya ohun kíkọ ti ará Japan fún mi fún ọ̀rọ̀ náà mui. Mo fẹ́ láti so àwòrán náà mọ́ ògiri mi gẹ́gẹ́bí ìránnilétí láti dúró jẹ́ẹ́ kí a sì fojúsun Olùgbàlà. Ó yà mí lẹ́nu nígbàtí kò fara mọ́ ìbéèrè tí ó dà bíi ẹnipé ó rọrùn yìí.
Ní ọjọ́ kejì, ní mímọ̀ pé ó ṣeéṣe kí èmi ti ṣe àìlóye ìlọ́ra rẹ̀, Alàgbà Wada ṣàlàyé pé kíkọ àwọn ohun kíkọ́ wọ̀nyẹn yíò gba ìtiraka pàtàkì. Yíò nílò láti ronú àti ṣàṣàrò lórí èrò àti àwọn ohun kíkọ́ títí yíò fi lóye ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ nínú ẹ̀mí rẹ̀ àtipé ó lè fi ìkọsílẹ̀ sí àwọn ìwúnilórí ọ̀kànkan wọ̀nyí pẹ̀lú ìkọlù kọ̀ọ̀kan ti ọwọ̀ rẹ̀. Ojú tì mí pé mo ti sọ fún un pé kó ṣe ohun kan tó pọn dandan. Mo sọ fún un pé kó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀ fún àìmọ̀kan mi, kó sì jẹ́ kó mọ̀ pé mò nfagilé ìbéèrè mi.
Ẹ lè fi ojú-inú wo ìyàlẹ́nu àti ìmoore mi nígbàtí mo kúrò ní Japan, tí Arábìnrin Wada, láì bẹ̀bẹ̀, fún mi ní ẹ̀bùn àkànṣe àwòrán rírẹwà yìí tí ó fi àwọn ohun kíkọ́ Japanese hàn fún ọ̀rọ̀ náà mui. Nísisìyí ó rọ̀ mọ́ ògiri ọ́fíìsì mi, ó nrán mi létí láti máa wá Olúwa lójoojúmọ́ àti láti sìn Ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ipá, iyè àti okun. Ó ti mú ìtumọ̀ mui, tàbí ìdákẹ́jẹ́ẹ́, sàn ju ọ̀rọ̀ èyíkéyìí lọ. Dípò kí ó máa fọkàn yàwòrán àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, ó sún mọ́ àwòrán ìkànnì rẹ̀ pẹ̀lú ète ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti ọkàn àti ète gidi.
Bákannáà, Ọlọ́run fẹ́ kí a sún mọ́ àkokò wa pẹ̀lú òun pẹ̀lú irú ìfọkànsìn àtọkànwá kannáà. Nígbàtí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìjọsìn wa máa nfihàn pé a nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.
Ó nfẹ́ kí á bá Òun sọ̀rọ̀. Ní àkokò kan, lẹ́hìn gbígba àdúrà ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ nínú ìpàdé pẹ̀lú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Ààrẹ Nelson yíjú sí mi ó sì wí pé, “Nígbàtí o ngbàdúrà, mo ronú bí Ọlọ́run ṣe gbọ́dọ̀ mọrírì tó nígbàtí a bá gba àkokò láti inú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọwọ́dídí wa láti jẹ́wọ́ Rẹ̀.” Ó jẹ́ ìránnilétí tí ó rọrùn síbẹ̀síbẹ̀ tí ó lágbára nípa iye tí ó gbọ́dọ̀ túmọ̀ sí fún Olúwa nígbàtí a bá dánu dúró láti bá A sọ̀rọ̀.
Bí Ó ti nfẹ́ wa, Òun kò ní fi agbára mú wa láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Sí àwọn ará Néfì ni Olúwa tí ó jíǹde wí pé, “Báwo ni èmi ìbá ti ràdọ̀ bo yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ̀ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ rẹ̀, àti ẹ̀yin kò sì fẹ́.” Ó tẹ̀lé ìyẹn pẹ̀lú ipè ìrètí tí ó kàn àwa náà lónìí: “Báwo ni èmi ìbá ti ràdọ̀ bò yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ̀ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà kí ẹ sì padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú èrèdí ọkàn-àyà kíkún.”
Ìhìnrere Jésù Krístì fún wa ní ààyè láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nígbàgbogbo. Àwọn ànfàní wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn àdúrà ojoojúmọ́, àṣàrò ìwé-mímọ́, ìlànà oúnjẹ Olúwa, ọjọ́ ìsimi, àti ìjọsìn tẹ́mpìlì. Kíni bí a bá mú àwọn ààyè mímọ́ wọ̀nyí kúrò nínú àwọn àtòkọ “láti-ṣe” kí á sì fi wọ́n sí àwọn àtòkọ “láti-máṣe” wa; ìtumọ̀ láti súnmọ́ wọn pẹ̀lú ọkàn kanáà àti ìdojúkọ pẹ̀lú èyítí Arábìnrin Wada súnmọ́ àwòràn rẹ̀?
Ẹ lè máa ronú pe, “Èmi kò ní àkokò fún ìyẹn.” Mo ti fi ìgbàkũgbà nímọ̀lára bákanáà. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ndábàá pé ohun tí a lè nílò kìí ṣe àkokò díẹ̀ síi ṣùgbọ́n àkíyèsí díẹ̀ síi àti ìfojúsun Ọlọ́run ní àwọn àkokò tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Un tẹ̀lẹ́.
Fún àpẹrẹ, nígbàtí a bá ngbàdúrà, kí ni bí a bá nlo àkokò díẹ̀ fún sísọ̀rọ̀ àti àkokò púpọ̀ síi ní wíwà pẹ̀lú Ọlọ́run; àti nígbàtí a bá ní láti sọ̀rọ̀, láti túbọ̀ fi ìmoore àti ìfẹ́ àtọkànwá hàn?
Ààrẹ Nelson ti gbani nímọ̀ràn pé kí a má kàn ka àwọn ìwé mímọ́ ṣùgbọ́n kí a gbádùn wọn. Ìyàtọ̀ wo ló máa jẹ́ tí a bá nkàwé díẹ̀ tí a sì ngbádùn ara wa?
Kíni bí a bá fẹ́ túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i láti múra ọkàn wa sílẹ̀ láti jẹ oúnjẹ Olúwa tí a sì nfi pẹ̀lú ayọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìbùkún Ètùtù ti Jésù Krístì lákòókò ìlànà mímọ́ yìí?
Ní Ọjọ́ Ìsinmi, èyí tí ó túmọ̀ sí “ìsinmi” ní èdè Hébérù, kí ni bí a bá ní láti sinmi kúrò nínú àwọn àníyàn míràn tí a sì wá àkokò láti jókòó ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú Olúwa láti san àwọn ìfọkànsìn wa fún Un?
Ní àkokò ìjọsìn tẹ́mpìlì wa, kíni bí a bá ní láti fún wa ní ìtọ́ni a ní láti túbọ̀ sapá tí ó ní ìbáwí àti àfiyèsí púpọ̀ sí i láti kíyè sí i tàbí kí a dúró díẹ̀ sí i nínú yàrá sẹ̀lẹ́stíà ní dídákẹ́ jẹ́ẹ́?
Nígbàtí ìdojúkọ wa kéré sí ṣíṣe àti díẹ̀ síi lóri mímú ìsopọ̀ májẹ̀mú wa lágbára pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì, mo jẹri pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àkokò mímọ́ wọ̀nyí yíò jẹ́ ọlọ́rọ̀, àti pé a ó gba ìtọ́sọ́nà tí a nílò nínú ìgbésí ayé ti ara ẹni wa. Àwa, bíi Màtá nínú àkọsílẹ̀ Lúkù, sábà máa “nṣọ́ra ká sì máa ṣàníyàn nípa ọ̀pọ̀ nkan.” Ṣùgbọ́n, bí a ti nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú Olúwa ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, Òun yío rànwá lọ́wọ́ láti mọ̀ ohun náà tí a nílò jùlọ.
Olùgbàlà pàápàá mú àkokò làti inú iṣẹ́-ìránṣẹ́ Rẹ̀ láti dúró jẹ́ẹ́. Àwọn ìwé-mímọ́ kún fún àpẹẹrẹ ti pípadà sẹ́hìn Olúwa sí ibì kan, òkè nlá, aginjù, ibi aginjù kan tàbí lọ “kúrò jìnnà díẹ̀” láti gbàdúrà sí Baba. Bí Jésù Krístì bá wá àkokò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ àti láti fún Un lókun, yóò bọ́gbọ́n mu fún wa láti ṣe bákan náà.
Bí a ṣe npa ọkàn ati iyè wa pọ̀ sórí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì tí a sì ntẹ́tí sí ohùn jẹ́ẹ́jẹ́, kékeré ti Ẹ̀mí Mímọ́ náà, a yíò ní ìmọ̀ kedere púpọ̀ síi nípa ohun tí a nílò jùlọ, mú ìyọ́nú jíjinlẹ̀ dàgbàsókè, a ó sì rí ìsinmi àti okun nínú Rẹ̀. Lọ́nà tí kò tọ́, ríran Ọlọ́run lọ́wọ́ kí ó yára fún iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga Rẹ̀ lè béèrè pé kí a falẹ̀. Fífi ìgbàgbogbo wà “ní lílọ kiri” lè máa fikún “ìdàrú-dàpọ̀” nínú ìgbésí ayé wa kí ó sì máa jàwá lólè àláfíà tí à nwá.
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ṣe npadà sọ́dọ̀ Olúwa léraléra pẹ̀lú erò ọkàn kíkún, a ó fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa láti mọ̀ Ọ̀ àti láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ àìlópin onímájẹ̀mú Rẹ̀ fún wa.
Olúwa ti ṣe ìlérí:
“Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi Èmi ó sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ yín; ẹ wá mi taratara ẹ̀yin yíò sì rí mi.”
“Ẹyin yío sì wá mi, ẹ ó sì rí mi, nígbàtí ẹ̀yin bá wá mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín.”
Mo jẹ́rĩ pé ìlérí yí jẹ́ òtítọ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.