Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọlọ́run Fẹ́ràn Gbogbo Àwọn Ọmọ Rẹ̀
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


9:36

Ọlọ́run Fẹ́ràn Gbogbo Àwọn Ọmọ Rẹ̀

Ó máa nfi ìgbà-gbogbo ké pè wa, Ó sì máa nlò wá, àwa ìránṣẹ́ Rẹ̀ lásán, láti ṣèrànwọ́ mú àwọn ọmọ Rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Kíni Baba wa Ọ̀run fẹ́ láti ọ̀dọ̀ yín? Njẹ́ ẹ ní òye pé nígbàtí ẹ wà ṣaájú-ayé-ikú, Baba Ọ̀run npèsè yín fún ìgbé ayé yín ní orí ilẹ̀ ayé? Ní sísọ̀rọ̀ sí àwọn ọ̀dọ́, Ààrẹ Nelson kọ́ni pé: “Baba Wa Ọrun ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí Rẹ̀ tó lọ́lá jùlọ pamọ́—bóyá … àwọn ikọ̀ Rẹ̀ tó dára jùlọ—fún ipele ìparí yi.” Nítorípé a ti pa wá mọ́ fún awọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí, ó ṣe pàtàkì fún wa láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì.

Olúwa Jésù Krístì ni Olùṣọ́-àgùtàn rere O sì mọ agbo Rẹ̀, agbo náà sì mọ Olùṣọ́-àgùtàn rẹ̀ nítorípé “ó npe àwọn àgùtàn tirẹ̀ ní orúkọ.” Ó máa nfi ìgbà-gbogbo ké sí wa, Ó sì máa nlò wá, àwa ìránṣẹ́ Rẹ̀ lásán, láti ṣèrànwọ́ mú àwọn ọmọ Rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Ní àìpẹ́ sẹ́hìn, ààrẹ èèkàn kan áti èmi nbẹ àwọn ọmọ Ìjọ wò ní àyíká agbègbè kan. Lẹ́hìn tí a ti parí àwọn àbẹ̀wò tí a ti là sílẹ̀, ààrẹ èèkàn náà bèèrè lọ́wọ́ mi bí a bá le lọ rí ẹbí kan síi. Ó ní ìtẹ̀mọ́ ímọ̀lára pé kí a bá wọn sọ̀rọ̀.

A kan ilẹ̀kùn, arábìnrin kan sì ṣí i. Ó wò mí, ṣùgbọ́n kò mọ ẹnití mo jẹ́, nítorínáà kò sọ ohun púpọ̀. Mo na ọwọ́ mi sí ìhà ọ̀dọ̀ ààrẹ èèkàn náà, ẹnití ó kí i nípasẹ̀ orúkọ. Bí ó ti gbọ́ tí ó sì rí i, inú rẹ̀ dùn. Ní dídúró síbẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà náà, àwọn méjèèjì gba ara wọn mọ́ra wọ́ sì sunkún papọ̀. Èyí ṣe ìpìlẹ̀ fún àbẹ̀wò wa. A kò mọ̀ pé arábìnrin náà ti gba ìtọ́jú kẹmotẹ́rápì ní ọjọ́ kan ṣaájú. Ó ní ìmọ̀lára àìlera púpọ̀jù láti le ṣe ìtọ́jú fún àgbàlagbà ọmọkùnrin rẹ̀. Nítorínáà mo ran ààrẹ èèkàn náà lọ́wọ́ láti múra fún ọmọkùnrin rẹ̀, a sì gbé e sí inú kẹ̀kẹ́-ìjóko-aláyíká rẹ̀. A bọ́ ọ pẹ̀lú oúnjẹ tí arábìnrin dídùn míràn láti wọ́ọ̀dù náà ti gbé wá ṣaáju, a sì ṣèrànwọ́ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ míràn. Kí a tó kúrò ní ilé wọn, a ti bùkún wọn.

Gbogbo ohun tó nkọjá lọ nínú ọkàn mi ní àkókò ìbẹ̀wò yí ni ìfẹsẹ̀múlẹ̀ pé Jésù Krístì fẹ́ràn wọn jinlẹ̀. Ó ní òye wọn ó sì tìkararẹ̀ mọ ìrora ti ipò ara-ọ̀tọ̀ wọn. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìbẹ̀wò náà ni ó ṣẹlẹ̀ ní ìdákẹ́jẹ́. Ní àkókò yí a kò fúnni ní ìwàásù nlá tàbí pín ìwé mímọ́ tí a fẹ́ràn jù, ṣùgbọ́n Olúwa bùkún wa pẹ̀lú Ẹ̀mí Rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

Ọ̀kan nínù àwọn èrèdí títóbi-jùlọ tí Baba yín Ọ̀run fi rán yín wá síhin ní àkókò yí ni kí ẹ lè mọ agbára-ìleṣe yín ní kíkún. Wàásù Ìhìnrere Mi kọ́ wa pé, bí ọmọ-ẹ̀hìn ti Krístì, a níláti yẹra fún ṣíṣe àfiwé ara wa ọ̀kan sí ẹlòmíràn. Àwọn ìleṣe yín ti ẹ̀mí jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀, ti araẹni, àti àbímọ́, Baba yín Ọ̀run sì fẹ́ láti ràn yín lọ́wọ́ mú wọn dàgbà. Nígbà-gbogbo ni ẹnìkan yio wà tí ẹ lè rànlọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ti Baba yín Ọ̀run. Agbára ìleṣe yín jẹ́ ti ọ̀run. Nígbàtí ó ṣe pàtàkì nítòótọ́ láti mùra ara yín sílẹ̀ láti ṣe àṣeyọrí nínú ayé ìdíje gidi yí, ọ̀kan nínú áwọn iṣẹ yín pàtàkì jákè-jádò ìgbésí ayé yín ni láti di ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì àti láti tẹ̀lé àwọn ìtẹ̀mọ́ra ti Ẹ̀mí. Bí ẹ ti nṣe èyí, Ọlọ́run yío bùkún ayé yín; Òun yío bùkún ẹbí yín ti ìsisìyí tàbí ti ọjọ́ iwájú; Òun yío sì bùkún ayé àwọn ọmọ Rẹ̀ tí ẹ bá bá pàdé.

À ngbé ní àkókò ànfàní nlá kan. Bíótilẹ̀jẹ́pé a nkojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣòro, mo mọ̀ pé wọ́n wà níbẹ̀ ní apákan láti fún wa ní àyè láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Baba wa Ọ̀run. Ààrẹ Nelson kọ́ni pé: “Ní àwọn ọjọ́ tí ó nbọ̀, a ó rí àwọn ìfarahàn títóbijùlọ tí agbára Olùgbàlà tí ayé kò rí rí ever seen.” A ní ànfàní láti ṣe olùṣọ́ lórí àwọn ènìyàn tí wọ́n nílò ọwọ́ tó nṣèrànwọ́, ìgbàmọ́ra, ìmọ̀lára ìtùnú, tàbí fún wa láti kàn wà pẹ̀lú wọn ní ìdákẹ́jẹ́. Bí a bá le ṣèrànwọ́ mú àwọn ẹrù wọn fúyẹ́, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nìkan, nígbànáà yío ṣeéṣe fúnwa láti rí ìfarahàn nlá ti agbára Olùgbàlà nínú ayé wọn.

Bí ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn le ṣe ìyàtọ̀ dáradára kan nínú ayé. A le pèsè èrò orí ti ayọ̀ kan tí ó hàn ninú ìwò ojú wa—ayọ̀ tí a pín pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àti àwọn ìṣe ti inúrere. Ẹ jẹ́kí a jẹ́ aládúgbò rere, agbani-síṣẹ rere, àti òṣìṣẹ́ rere. Ẹ jẹ́kí a gbìyànjú láti jẹ́ Krìstẹ́nì rere nígbà gbogbo.

Olúwa ti mú ìhìnrere Rẹ̀ padàbọ̀sípò pẹ̀lú àwọn ìlànà tí ó ṣe dandan kí àwọn ọmọ ti Baba Ọ̀run ó le ní gbogbo àwọn ìlérí tí ó so wá pọ̀ mọ́ Òun. Nípa ríran àwọn arábìnrin àti awọn arákùnrin wa lọ́wọ́ nínú awọn ìpèníja wọn ojojúmọ́, ẹ jẹ́kí a ránti bákannáà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ṣ̣e awọn ìlérí mímọ́ wọ̀nyí kí wọ́n sì pa wọ́n mọ́ pẹ̀lú Baba wọn Ọ̀run, kí Òun ní ìdàkejì le ṣ̣e ìlérí awọn ìbùkún dìdàrajùlọ fún wọn fún ayé yí ati fún ayérayé. Awọn ìlérí wọ̀nyí ni a mú ṣeéṣe nípasẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì ati awọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà Rẹ̀ nìkan.

Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, a le ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Àwọn kan ninu wa a máa yà kúrò ní ipa ọ̀nà náà lati àkókò dé àkókò, àti nitorínáà a gbọ́dọ̀ rántí pé fún Baba wa Ọ̀run, a nfi ìgbà gbogbo ní ànfàní ṣíṣeéṣe láti padà. Àní bí ipa ọ̀nà wa ko tilẹ̀ jẹ́ pípé jùlọ, Olùgbàlà nfi ìgbà gbogbo ránwa létí pé, “nígbàkugbà ti [a bá ronúpìwàdà] ti a sì [wá] ìdáríjì, pẹ̀lú èrò inú tó tọ́, [a ó jẹ́] dídáríjì.”

Ọ̀kan ninu àwọn ète ti ọ̀tá lóni ni lati mú wa ronú kí a sì gbàgbọ́ pé kò sí ọ̀nà fún wa láti yípadà tàbí pé a kò ní ìrètí mọ́. Ìrònú apanirun yí nmú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa dáwọ́dúró láti máa gbìyànjú. Ó sì jẹ́ pé àkókò yí ni ìgbà tí ìfẹ́ wa, àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú áti àtilẹ́hìn wa, àkókò wa, àti ìrànlọ́wọ́ wa le fún ẹnìkan ní ìrètí tí ó tó láti gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansíi.

Bóyá ẹ nronú pé, “Ó DÁRA, ṣùgbọ́n tani ó nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí èmi?” Nípa lílọ àti bíbùkún ìgbésí ayé àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa, a ó gba àwọn ẹ̀rí tí yío kún ayé wa fún ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì. Àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí yío sọ wá dọ̀tun láti gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansíi fúnra wa. Ẹ̀mí Mímọ́ yío sọ wá jí yío sì rànwá lọ́wọ́ pẹ̀lu àwọn ẹ̀rí titun láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn ìṣoro àti àwọn àdánwò ara ẹni tiwa. Nígbàkugbà tí a bá nwá láti bùkún ayé àwọn ẹlòmíràn, Olúwa nmú àánú wá sórí wa àní ní ọ̀pọ̀ síi; Ó nfún wa lókùn ó sì nranwálọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé wa.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí pé Oluwa Jésù Krístì ni Olùgbàlà yín Ó sì ní òye yín fúnra Rẹ̀. Ó mọ ohun ti ó jẹ́ láti mú ìpè kan ṣẹ àti láti fi àwọn nkan sílẹ̀ láti ran àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ́wọ́. Ó ní agbára láti bùkún yín nínú ohun gbogbo, bi ẹ bá gbàgbọ́ ninu rẹ̀ ti ẹ kò sì ṣiyèméjì.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ní ọjọ́ náà nígbàtí olórí oyè-àlùfáà kan ní ìmọ̀lára ìmísí fúnwa láti ṣe àbẹ̀wò sí ìyá àti ọmọkùnrin tí a kò ní ninu ètò wa, mo kéde pe Ọlọ́run mọ̀ pé wọ́n nílò wa. Àti pé ní ìparí, èmi ni ẹni náà ti a ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí. Ní ọjọ́ náà, mo gba ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ títóbi jùlọ nípa ìfẹ́ Olùgbàlà fún wa.

Mo jẹ́ri pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà aráyé, pe Ó wà láàyè, pé Ó wà láàyè Ó sì kú fún ẹ̀yin àti èmi, àti pé a jí I dìde fún ẹ̀yin àti èmi kí a le fojúsọ́nà sí àwọn ìdàpọ̀ ti sẹ̀lẹ́stíà tí ó kún fún ayọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kejì ìkelè. Mo mọ̀ pé Ó ní òye ẹ̀yin àti èmi ní pípé. Ó ni òye ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àkókò ìṣòro wa, Ó sì ní agbára láti rànwá lọ́wọ́ ní àwọn àkókò náà níbití a ti ní ìmọ̀lára àìlágbára jùlọ. Mo mọ̀ pé Olúwa Jésù Krístì àti Baba wa Ọ̀run fi ara hàn sí Joseph Smith lati mú ìhìnrere padàbọ̀sípò ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí. Mo mọ pé wòlíì wa olùfẹ́, Russell M. Nelson, jẹ́ wòlíì Olúwa, mo sì jẹri nípa èyí ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Ìrètí ti Ísráẹ́lì” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), Gospel Library.

  2. Wo Jòhánnù 10:2–4.

  3. “Ẹ yẹra fún fífí arayín wé àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere míràn àti ní wíwọn àwọn àbájáde òde sí ìlàkàkà yín pẹ̀lú wọn” (Wàásù Ìhìnrere Mi: Ìtọ́nisọ́nà Kan Sí Pípín Ìhìnrere Jésù Krístì [2023], 13).

  4. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Rí Ìsinmi,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2022, 95.

  5. Mórónì 6:8.

  6. Wo Alma 56:47; 57:26.