Ìwàmímọ́ sí Olúwa nínú Ìgbésí-ayé Ojojúmọ́
Ìwà-mímọ́ sí Olúwa nmú gbígbé lojojúmọ́ jẹ́ mímọ́. Ó nfà wá súnmọ́ ó sì nmú inúdídùn sí Olúwa àti ara wa wá.
Àtún-dàpọ̀ ẹbí Gong làìpẹ́ wà pẹ̀lú ìgbádùn eré tálẹ́ntì kan, pípé pẹ̀lú ìdíje àwọn ẹ̀fẹ̀ baba.
Ṣùgbọ́n ìdíje yí jẹ́ àìwọ́pọ̀. Lórí ẹgbẹ́ kan ni babaàgbà (èmi) àti méjì lára àwọn ọmọ-ọmọ, ọjọ́ orí méjìlá àti mọ́kànlá. Lórí ẹgbẹ́ míràn ni òye àtọwọ́dá kan (OA) ètò ìṣílétí tí ó jẹ́ kí Cousin kan sọ àwọn ẹ̀fẹ̀ baba ní àrà ti Gerrit W. Gong. Baba-àgbà Gerrit Gong figagbága pẹ̀lú (OA) Gerrit W. Gong.
Àwọn ọmọ-ọmọ àti èmi lọ ṣíwájú.
Kíni ẹ npè ní dínósọ̀ kan tí ó ba ọkọ̀ rẹ̀ jẹ́? Ìbàjẹ́ Tíránósọ́sì
OA Gerrit Gong ni a kọ́ lẹkọ—láti ronú bíi ti Gerrit W. Gong. Sọ̀rọ̀ bíi ti rẹ̀.
AI Gerrit Gong: “Nihin ni ẹ̀fẹ̀ baba kan bíí pé a sọ́ nípasẹ̀ Gerrit W. Gong, gbígba mọ́ra ìyárí, elérò, àti ẹ̀yà ìgbéniga rẹ̀ mọ́ra: Kíni ìdí tí igi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe nmú àwọn ènìyàn rẹrin? Nítorí ó ní gbòngbò nínú ìfẹ́ ó sì nà jáde pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka ìwàrere. Bíiti igi náà, àwà bákannáà lè rí okun nínú àwọn gbòngbò wa àti ayọ̀ ní nínawọ́ ìwàrere sí àwọn ẹlòmíràn.”
Ó dara, kíni èrò yín? Ìyẹn ni ìdí tí a fi npèé ní àwọn ẹ̀fẹ̀ baba.
Gbogbo rẹ ní àyíká wa jẹ́ ànfàní láti rẹrin, dunnú, wòó pẹ̀lú ojú ìmoore. Tiwa ni ìhìnrere ayọ̀ àti ìwàmímọ́ ní ìgbésí-ayé ojojúmọ́. Ìwà-mímọ́ ngbé àwọn ohun kalẹ̀ yàtọ̀ fún èrò mímọ́. Ṣùgbọ́n ìwà-mímọ́ bákannáà npè wá láti dàsínú gbígbé ojojúmọ́ pẹ̀lú mímọ́—láti yayọ̀ nínú búrẹ́dì ojojúmọ́, mánnà bí ó ti wa ní àárín ẹ̀gún àti òṣùṣú ayé yí. Láti rìn pẹ̀lú Olúwa, a gbọ́dọ̀ di mímọ́, nítorí mímọ́ ni Òun, àti pé láti ràn wá lọ́wọ́ láti di mímọ́, Olúwa npè wá láti rìn pẹ̀lú Rẹ̀.
Ẹnìkọ̀ọ̀kan Wa Ní Ìtàn kan. Bí arábìnrin Gong àti èmi ti pàdé yín—àwọn ọmọ Ìjọ àti àwọn ọ̀rẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibi àti ipò—àwọn ìtàn yín nípa ìwàmímọ́ sí Olúwa ní ìgbésí-ayé ojojúmọ́ nmí sími. Ẹ ó gbé ìgbésí-ayé àwọn ohun méje: ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ìletò àti àánú pẹ̀lú ara wa, ìfarasìn àti májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹbí, àti àwọn ọ̀rẹ́—dálé oókan Jésù Krístì.
Ẹ̀rí dídàgbà nfi òtítọ́ yíyanilẹ́nu yí hàn: àwọn onígbàgbọ́ ẹ̀sìn wà ní agbede dídunnú si, ní ìlera si, àti mímúṣẹ si ju àwọn wọnnì láìsí ìfarasìn tàbí ìsopọ̀ ti-ẹ̀mi. Ìdùnnú àti ìgbésí-ayé ìrọ̀rùn, ìlera ti ọpọlọ àti ti-ara, ìtumọ̀ àti èrò, ìwà àti inú rere, ìsúnmọ́ àwọn ìbáṣepọ̀ àwùjọ, ìdúró níná-owó àti ohun-èlò—ní ìwọ̀n kọ̀ọ̀kan, òṣìṣẹ́ ẹ̀sìn ngbilẹ̀.
Wọ́n ngbádùn ìlera ọpọlọ àti ti-ara dáadáa àti ìgbésí-ayé títóbi si ìtẹ́lọ́rùn káàkiri gbogbo ọjọ́ orí àti àwọn ẹgbẹ́ iye-ènìyàn.
Ohun tí àwọn olùwádí npè ní “ìgbékalẹ̀ ìdúró ẹ̀sìn” nfúnni ní ìmọ́gaara, èrò, àti ìmísí ní àárín àwọn ìyípo àti àyídà ìgbésí-ayé. Ìdílé ìgbàgbọ́ àti ìletò ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ ja-ìjàkadì ìpatì àti àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àdánìkanwà. Ìwà-mímọ́ sí Olúwa wípé rárá sí ohun àìmọ́, rárá sí ìjáfáfá oníwà-ìbàjẹ́ ní àìbìkítà sí àwọn ẹlòmíràn, rárá sí alugórídímù towó tí ó mú ìrunú àti tọ̀tún tòsì wá. Ìwà-mímọ́ sí Olúwa wípé bẹ́ẹ̀ni sí ti mímọ́ àti ọ̀wọ̀, bẹ́ẹ̀ni sí dídi òmìnira ara wa jùlọ, onínú-dídùn jùlọ, àti olótítọ́ jùlọ, ara wa dídárajùlọ bí a ti ntẹ̀lé E nínú ìgbàgbọ́.
Kíni ìwàmímọ́ sí Olúwa ní ìgbé-ayé ojojúmọ́ ti dàbí?
Ìwàmímọ́ sí Olúwa nínú ìgbésí-ayé ojojúmọ́ dàbí ọ̀dọ́ àgbà méjì, tí wọ́n ṣe ìgbeyàwó fún ọdún kan, ní pípín pẹ̀lú òtítọ́ àti olùpalára àwọn májẹ̀mú ìhìnrere, ìrúbọ, àti iṣẹ́ ìsìn nínú ìṣípayá ìgbé-ayé.
Ó bẹ̀rẹ̀, “Ní ilé-ìwé gíga, mo wà ní ibi òkùnkùn. Mo ní ìmọ̀lára bíi pé Ọlọ́run kò sí níbẹ̀ fún mi. Ní òru kan, àtẹ̀jíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ kan wípé, ‘Héè ṣe ìwọ ti ka Álmà 36 rí?’
“Bí mo ti bẹ̀rẹ̀sí nkàwé,” ó borí, “mo borí pẹ̀lú àláfíà àti ìfẹ́. Mo ní ìmọ̀lára ìfúnni ní ìgbàmọ́ra nlá yí. Nígbàtí mò nka Álmà 36:12, Mo mọ̀ pé Baba Ọ̀run rí mi ó sì mọ déédé bí mo ṣe nmọ̀lára.”
Ó tẹ̀síwájú, “Ṣíwájú kí a tó ṣe ìgbeyàwó, mo jẹ́ olootọ pẹ̀lú ìṣúná-owó mi tí èmi kò fi ní ẹ̀rí nlá ti idamẹwa. Kíni ìdí tí Ọlọ́run fi nílò wa láti fúnni ní owó nígbàtí àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀pọ̀ láti fúnni? Afẹ́sọ́nà mi ṣèrànwọ́ láti ṣàlàyé pé kìí ṣe nípa owó ṣùgbọ́n títẹ̀lé òfin kan tí a bèèrè lọ́wọ́ wa. Ó pè mi níjà láti bẹ̀rẹ̀ si san idamẹwa.
“Mo ri tí ẹ̀rí mi gbèrú lódodo,” ó wípé. “Nígbàmíràn owó ndínkù, ṣùgbọ́n a ri ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún gan, àti pé bákannáà àwọn ìwé-ìsanwó tótó.”
Bákannáà, “nínú kílásì nọ́ọ̀sì mi,”ó wípé,”èmì nìkan ni ọmọ-ìjọ ti Ìjọ àti ẹnìkanṣoṣo tí ó ṣe ìgbeyàwó. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbà ni mo ti fi kílásì sílẹ̀ nínú ìjákulẹ̀ tàbí omijé nítorí mo ní ìmọ̀lára ìpatí àwọn ẹlẹgbẹ́-kílásì mi tí wọ́n sì ṣe àwọn ìdásí nípa ìgbàgbọ́ mi, ti wíwọ àwọn gámẹ́ntì mi, tàbí ti jíjẹ́ ẹnití ó ṣe ìgbeyàwó ní ọ̀dọ́ gan.”
Síbẹ̀ ó tẹ̀síwájú, “Ní ìgbà-ìkàwé tó kọjá mo kọ́ bí n ó ti gbóhùn ìgbàgbọ́ mi sókè àti láti jẹ́ àpẹrẹ rere ìhìnrere. Ìmọ̀ mi àti ẹ̀rí mi dàgbà nítorí mo ní ìdánwò nínú okun mi láti dá dúró àti láti ní agbára nínú ohun tí mo gbàgbọ́.”
Ọkọ ọ̀dọ́ náà fikun pé, “Ṣíwájú míṣọ̀n mi mo ti gbà láti gbá bọ́ọ̀lù-báàtì kọ́lẹ́jì. Ṣíṣe ìpinnu líle, mo fi àwọn ìfúnni náà sẹgbẹ mo sì lọ láti sin Olúwa. Èmi kò fi ọdún méjì yí dúnádúrà fún ohunkankan.
“Pípadàsílé,” ó wípé, “mo retí ìyípòpadà líle kan ṣùgbọ́n mo rí ara mi ní níní agbára si, yíyára si, àti níní ìlera si. Èmi ntiraka púpọ si ju ìgbàtí mo kúrò. Mo ní ìfúnni si láti gbá bọ́ọ̀lù ju ìgbàtí mo kúrò, pẹ̀lú ilé-ìwé àlá mi. Àti, ní pàtàkì jùlọ,” ó wípé, “mo gbáralé Olúwa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”
Ó parí pé, “Bí òjíṣẹ́ ìhìnrere mo kọ́ pé Baba Ọ̀run nṣe ìlérí agbára fún wa nínú àwọn àdúrà wa, ṣùgbọ́n nígbàmíràn mo ngbàgbé ìyẹn fún arami.”
Ìbùkún ìṣúra wa nípa òjíṣẹ́-ìhìnrere ìwà-mímọ́-sí-Olúwa ni ọrọ̀ àti àníkún. Àwọn ìṣúná-owó, àkokò, àti àwọn ipò míràn kìí rọrùn nígbàkugbà. Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ti ìgbàgbogbo àti tí àtilẹ̀ba bá ya ìwa-mímọ́ sọ́tọ̀ sí Olúwa, àwọn nkan lè ṣiṣẹ́ ní àkokò àti ọ̀nà Olúwa.
Nísisìyí pẹ̀lú ìgbìrò ọdún méjìdínlaadọta kan, òjíṣẹ́-ìhìnrere àgbà kan ṣe àbápín pé “Baba mi nfẹ́ kí èmi gba ẹ̀kọ́ kọ́lẹ́jì, kìí ṣe kí nlọ sí míṣọ̀n. Láìpẹ́ lẹ́hìnnáà, ó ní àtakò ọkàn ó sì kú ní ọjọ́ orí mẹ́tàdín-ní-àádọ́ta. Mo ní ìmọ̀lára ẹ̀bi. Báwo ni èmi ó fi lè mú àwọn nkan yẹ pẹ̀lú baba mi?
“Lẹ́hìnnáà,” ó tẹ̀síwájú, “ lẹ́hìnwa mo pinnu láti sin ní míṣọ̀n kan, mo ri baba mi nínú àlá kan. Nínú àláfíà àti ìtẹ́lọ́rùn, inú rẹ̀ dùn pé èmi yíò sìn.”
Òjíṣẹ́-ìhìnrere àgbà yí tẹ̀síwájú, “Bí Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138 ti kọ́ni, mo gbàgbọ́ pé baba mi lè sin bí òjíṣẹ́ ìhìnrere kan nínú ayé ẹ̀mí. Mo gbàgbọ́ pé baba mi ran baba-baba àgbà wa lọ́wọ́, ẹnití ó kúrò ní Germany ní ọjọ́ orí mẹ́tàdínlógún tí ó sì sọnù sí ẹbí, ni a rí lẹ́ẹ̀kansi.”
Ìyàwó rẹ̀ fikun pé, “Ní àárín àwọn arákùnrin marun nínú ẹbí ọkọ mi, mẹ́rin tí wọ́n sin míṣọ̀n ni àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú oyè gíga kọ́lẹ́jì.”
Ìwàmímọ́ sí Olúwa nínú ìgbésí-ayé ojojúmọ́ dàbí ọ̀dọ́ tí ó padàbọ̀ láti ibi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere tí ó kọ́ láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé rẹ̀. Ṣíwájú, nígbàtí a ní kí ó bùkún ẹnìkan tí ó ṣàárẹ̀ gidi, òjíṣẹ́-ìhìnrere yí wípé, “Mo ní ìgbàgbọ́; èmi ó bùkún un láti bọ́sípò. Síbẹ̀,” òjíṣẹ́-ìhìnrere tó padàbọ̀ wípé, “Mo kẹkọ ní àkokò náà láti gbàdúrà kìí ṣe fún ohun tí mo fẹ́, ṣùgbọ́n fún ohun tí Olúwa mọ̀ pé ẹni náà nílò. Mo bùkún arákùnrin náà pẹ̀lú àláfíà àti ìtùnú. Lẹ́hìnnáà ó kọjá lọ lalafia.”
Ìwàmímọ́ sí Olúwa nínú ìgbésí-ayé ojojúmọ́ dàbí ṣíṣáná ọ̀nà kọjá ìkelè láti sopọ̀, tùnínú, fúnlókun. Olùṣàkóso kan ní unifásítì kan wípé òun ní ìmọ̀lára pé olúkúlùkù àwọn ẹnì-kọ̀ọ̀kan tí òun ti mọ̀ nìkan nípa orúkọ rere ni wọ́n ngbàdúrà fún un. Àwọn olúkúlùkù wọnnì tí wọ́n nfi ìgbésí-ayé wọn fọkànsìn sí unifásítì tí wọ́n sì ntẹ̀síwájú láti ṣètọ́jú nípa iṣẹ́-ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn akẹkọ.
Arábìnrin kan nṣe dídárajùlọ rẹ̀ ní ojojúmọ́, lẹ́hìn tí ọkọ rẹ̀ aláìṣòdodo fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀. Mo nífẹ́sí i pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ àti àwọn ẹlòmíràn bíi tirẹ̀. Ọjọ́ kan nígbàtí ó nká àwọn aṣọ fífọ̀, ọwọ́ rẹ̀ lórí àkójọ àwọn ẹ̀wù, ó míkanlẹ̀ sí ara rẹ̀, “Kíni àmì náà?” Ó ní ìmọ̀lára ohùn ìrọ́nú tí ó mu dá a lójú pé, “Áwọn májẹ̀mú rẹ wà pẹ̀lú mi.”
Fún àádọ́ta ọdún, arábìnrin míràn nní ìyọ́nú fún ìbáṣepọ̀ kàn pẹ̀lú baba rẹ̀. “Ní gbígbèrú sókè,” ó wípé, “àwọn arákùnrin mi àti baba mi wà, àti pé nígbànáà ẹ̀mi náà wà—ọmọbìnrin kanṣoṣo. Gbogbo ohun tí mò nfẹ́ láé ni láti jẹ́ ‘rere tó’ fún baba mi.
“Lẹ́hìnnáà ìyá mi kọjá lọ! Òun nìkan ni agbódegbà mi ní àárín baba mi àti èmi.
“Ní ọjọ́ kan,” arábìnrin náà wípé, “mo gbọ́ ohùn kan tí ó wípé, ‘Pe baba rẹ kí ó sì mu lọ sí tẹ́mpìlì pẹ̀lú rẹ.’ Ìyẹn ni ìbẹ̀rẹ̀ ti ẹ̀ẹ̀méjì-ní-oṣù kan pẹ̀lú baba mi sí ilé Olúwa. Mo wí fún baba mi pé mo ní ìfẹ́ rẹ̀. Ó wí fún mi pé òun nifẹ mi pẹ̀lú.
“Lílo àkokò nínú ilé Olúwa ti wò wá sàn. Ìyá mi kò lè ràn wá lọ́wọ́ ní ilẹ̀-ayé. Ó gbà á ní wíwà ní ẹ̀gbẹ́ míràn ti ìkelè láti ṣèrànwọ́ láti tún ohun tí ó já ṣe. Tẹ́mpìlì parí ìrìnàjò wa lọ sí ìwòsàn bí ẹbí ayérayé kan.”
Baba náà wípé, “Ìyàsímímọ́ tẹ́mpìlì náà ni ìrírí nlá ti-ẹ̀mí fún mi àti ọmọbìnrin mi kanṣoṣo. Nísisìyí à nlọ papọ̀ a sì nní ìmọ̀lára ìmúlókun ìfẹ́ wa.”
Ìwàmímọ́ sí Olúwa nínú ìgbésí-ayé ojojúmọ́ wà pẹ̀lú àwọn àkokò ìrọ́nú nígbàtí àwọn olùfẹ́ni kan bá kú. Ṣaájú ní ọdún yí, ìyá mi ọ̀wọ́n, Jean Gong, yọ́ lọ sínú àwọn ọjọ́ àìkú ṣíwájú ọjọ́-ìbí ọdún méjìdínlọgọrun rẹ̀.
Bí ẹ bá bi ìyá mi léèrè, “Njẹ́ ìwọ yíò fẹ́ràn òpópónà olókúta, ṣokolétì jínjà funfun, tàbí yìyín kírímù sírọbẹrì?” Ìyá yíò wípé, “Bẹ́ẹ̀ni, jọ̀wọ́, ṣé èmi lè tọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wò?” Tani ó lè wípé rárá sí ìyá rẹ, nípàtàkì nígbàtí ó bá nifẹ gbogbo àwọn èròjà ìgbésí-ayé?
Nígbàkan mo bèèrè lọ́wọ́ ìyá àwọn ìpinnu èyí tí ó ti tún ayé rẹ̀ ṣe.
Ó wípé, “Ṣíṣe ìrìbọmi bí ọmọ-ìjọ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àti lílọ láti Hawaii sí òkè-odò, níbití mo ti pàdé baba rẹ̀.”
Ṣe ìrìbọmi bí ọmọ ọjọ́ orí marundinlogun, ọmọ-ìjọ kanṣoṣo ti ẹbí títóbi rẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ Ìjọ, ìyá mi ní májẹ̀mú ìgbàgbọ́ ó sì ní gbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa tí ó nbùkún ayé rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìràn ẹbí wa. Mo ṣàfẹ́rí ìyá mi, bí ẹ bá ṣàfẹ́rí ọmọ-ẹgbẹ́ nínú ẹbí yín. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé ìyá mi kò tíì lọ. Kò kàn sí i nihin nísisìyí ni. Mo bu-ọlá fún un àti gbogbo ẹnití ó ti kọjá bí àwọn àpẹrẹ akọni ojojúmọ́ ìwà-mímọ́ sí Olúwa.
Bẹ́ẹ̀ni, ìwàmímọ́ sí Olúwa nínú ìgbésí-ayé ojojúmọ́ wà pẹ̀lú wíwá léraléra si Olúwa ní ilé mímọ́ Rẹ̀. Èyí jẹ́ òtítọ́ bóyá a jẹ́ ọmọ Ìjọ tàbí àwọn ọ̀rẹ́.
Àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́ta wá sí ilé-ṣíṣí Tẹ́mpìlì Bangkok Thailand.
“Èyí jẹ́ ibi ìwòsàn alágbára kan,” ni ọ̀kan wí.
Nínú ibi ìrìbọmi, òmíràn wípé, “Nígbàtí mo bá wà nihin, mo fẹ́ láti di wíwẹ̀mọ́ kí nmá sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”
Ìkẹ́ta wípé, “Ṣe ẹ lè ní ìmọ̀lára agbára ti-ẹ̀mí?”
Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ mẹsan, àwọn tẹ́mpìlì wa npè wọ́n sì nkéde:
“Ìwà-mímọ́ sí Olúwa.
Ìwà-mímọ́ sí Olúwa nmú gbígbé ojojúmọ́ jẹ́ mímọ́. Ó nfà wá súnmọ́ ó sì nmú inúdídùn sí Olúwa àti ara wa wá ó sì nmúra wa sílẹ̀ láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run Baba, Jésù Krístì, àti àwọn olólùfẹ́ wa.
Bí ọ̀rẹ́ mi ti ṣe, ẹ lè ní ìyàlẹ́nu bí Baba yín Ọ̀run bá nifẹ yín. Ìdáhùn náà ni àtúnsọ, bẹ́ẹ̀ni pátápátá! A lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀ bi a ti nmú ìwà-mímọ́ sí Olúwa jẹ́ tiwa lojojúmọ́, nínú ìdùnnú àti títíláé. Njẹ́ kí a ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni mo gbàdúrà ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.