Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọwọ́ Rẹ̀ Ṣetán Láti Rànwá Lọ́wọ́
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


10:13

Ọwọ́ Rẹ̀ Ṣetán Láti Rànwá Lọ́wọ́

Bí a ṣe nnawọ́ jáde sí Jésù Krístì nínú ìgbàgbọ́, Òun yíò wà níbẹ̀ nígbàgbogbo.

Nígbàtí mo ṣì wà lọ́mọdé, gẹ́gẹ́bí ẹbí a lọ fún ìsinmi sí etí òkun kan ní bèbè okun ti orílẹ̀-èdè ìbílẹ̀ mi, Chile. Inú mi dùn láti lo àwọn ọjọ́ díẹ̀ ní gbígbádùn ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn náà pẹ̀lú ẹbí mi. Inú mi dùn gan-an torí pé mo rò pé mo lè darapọ̀ láti ṣe ohun tí àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjèèjì sábà máa nṣe fún ìgbádùn lórí omi.

Lọ́jọ́ kan, àwọn ẹ̀gbọ́n mi lọ ṣeré níbití ìgbì omi ti nrú, mo sì ní ìmọ́lára títobi àti dídàgbà tó láti tẹ̀lé wọn. Bí mo ṣe nlọ sí agbègbè náà, mo ríi pé àwọn ìgbì omi náà tóbi jù bí wọ́n ti farahàn láti bebe òkun. Lójijì, ìgbì kan yára súnmọ mi, ó bá mi ní ìyàlẹ́nu. Mo nímọ̀lára bí ẹnipé agbára àdánidá ti gbémi wọ̀, àtipé a fà mí sínú ibú okun. Èmi kò lè rí tàbí nímọ̀lára àyè ìtọ́kasí èyíkèyí bí a ti nsọ mi káàkiri. Gẹ́gẹ́bí mo ṣe rò pé ìrìn àjò mi lórí ilẹ̀ ayé lè wá sí òpin, mo nímọ̀lára pé ọwọ́ kan nfà mí lọ sí orí ilẹ̀. Níkẹhìn, mo lè rí oòrùn tí mo sì gba èémí mi.

Ẹ̀gbọ́n mi Claudio ti rí ìgbìyànjú mi láti ṣe gẹ́gẹ́bí àgbàlagbà ó sì wá fún ìgbàsílẹ̀ mi. Èmi kò jìnnà sí bèbè-òkun. Bíótilẹ̀jẹ́pé omi náà kò jìn, mo dààmú nkò sì mọ̀ pé mo lè ran ara mi lọ́wọ́. Claudio wí fún mi pé mo ní láti ṣọ́ra àti pé, tí mo bá fẹ́, òun lè kọ́ mi. Láìka àwọn gálọ́ọ̀nù omi tí mo gbé mì sí, ìgbéraga àti ìfẹ́ ọkàn mi láti jẹ́ ọmọdékùnrin nlá túbọ̀ lágbára sí i, mo sì wí pé, “Dájúdájú.”

Claudio wí fún mi pé mo nílò láti tako àwọn ìgbì náà. Mo wí fún ara mi pé èmi yíò pàdánù ìjàkadì náà ní ìlòdì sí ohun tí ó dàbí odi omi nlà kan.

Bí ìgbì nlá titun ṣe nsún mọ́, Claudio yára wí pé, “Wò mí; bí o ó ṣe ṣe é nìyí.” Claudio sáré lọ síhà ìgbì tí nbọ̀, ó sì rì sínú rẹ̀ kí ó tó fọ́. Bíbẹ́ rẹ̀ wú mi lórí tí mo fi pàdánù wíwo ìgbì tó nbọ̀. Nítorínáà lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tì mi lọ sí ìsàlẹ̀ òkun mo sì di yíyílọ nípasẹ̀ àwọn ipa àdánidá sì nsọ mi káàkiri. Ní ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan lẹ́hìnwá, ọwọ́ kan dì mí mú, wọ́n sì tún fà mí sí orí ilẹ̀ àti atẹ́gùn. Iná ìgbéraga mi ndipíparun.

Lọ́tẹ̀ yìí ẹ̀gbọ́n mi ní kí nbẹ́ sínú omi pẹ̀lú òun. Gẹ́gẹ́bí ipè rẹ̀, mo tẹ̀ lé e, a sì rì sínú omi papọ̀. Mo nímọ̀lára bí ẹni pé mo nṣẹ́gun ìpèníjà dídíjú jùlọ. Dájúdájú, kò rọrùn púpọ̀, ṣùgbọ́n mo ṣe é, ọpẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ àti àpẹrẹ tí ẹ̀gbọ́n mi fihàn. Ọwọ́ rẹ̀ gbàmí lẹ́ẹ̀mejì; àpẹrẹ rẹ̀ fihàn mí bí mo ṣe lè kojú ìpèníjà mi kí nsì ṣẹ́gun lọ́jọ́ náà

Ààrẹ Russell M. Nelson ti pè wá láti ronú sẹ̀lẹ́stíà, àti pé mo fẹ́ tẹ̀lé ìmọ̀ràn rẹ̀ kí nsì lò ó sí ìtàn ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn mi.

Agbára Olùgbàlà Lórí Ọ̀tá

Bí a bá ronú sẹ̀lẹ́stíà, a ó lóye pé ìgbésí ayé wa yíò kojú àwọn ìpèníjà tí ó dàbí pé ó tóbi ju agbára wa lọ láti borí wọn. Ní àkokò ìgbésí ayé ikú wa, a wà lábẹ́ àwọn ìkọlù ọ̀tá. Bíi àwọn ìgbì tí ó lágbára lórí mi ní ọjọ́ ẹ̀ẹ̀rùn náà, a lè nímọ̀lára àìlágbára àti láti fẹ́ jọ̀wọ́ ara sí àyànmọ́ tí ó lágbárajú. Àwọn “ìgbì ònrorò” wọ̀nnì lè gbá wa kiri láti ẹ̀gbẹ́ kan dé ẹ̀gbẹ́ míràn. Ṣùgbọ́n ẹ má gbàgbé ẹnití ó lágbára lórí àwon ìgbì àti, ní òtítọ́, lórí ohun gbogbo. Olùgbàlà wa, Jésù Krístì nìyẹn. Ó ní agbára láti ràn wá lọ́wọ́ kúrò nínú gbogbo ipò òṣì tàbí ipò búburú. Láìbìkítà bóyá a nímọ̀lára sísúnmọ́ Ọ, Ó tún lè dé ọ̀dọ̀ wa níbití a wà bí a ti wà.

Bí a ti nna ọwọ́ jáde sí I nínú ìgbàgbọ́, Òun yíò máa wà níbẹ̀ nígbàgbogbo, àti ní àkokò Rẹ̀, Òun ó múra àti ṣetán láti di ọwọ́ wa mú, kí ó sì fà wá sókè sí ibi ààbò.

Olùgbàlà àti Àpẹrẹ Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Rẹ̀.

Bí a bá ronú sẹ̀lẹ́stíà, a ó mọ̀ Jésù Krístì bí àpẹrẹ iṣẹ́-ìránṣẹ́ tí kò ní àbàwọ́n. Àpẹrẹ kan wà fún wa nínú àwọn ìwé-mímọ́ nígbàtí Òun tàbí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ nawọ́ jáde sí ẹnìkan nínú ìnílò ìrànlọ́wọ́, ìgbàlà, tàbí ìbùkún bí wọ́n ṣe nawọ́ wọn jáde. Bí ó ti wà nínú ìtàn mi, mọ mọ̀ pé ẹ̀gbọ́n mi wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n wíwà níbẹ̀ fún mi kò tó. Claudio mọ̀ pé mò wà nínú ìdàmú, ó sì lọ láti ṣèrànwọ́ gbé mi kúrò nínú omi.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a nrò pé a nílò láti kàn wà níbẹ̀ fún ẹnìkan tí ó nílò ìrànlọ́wọ́, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ohun púpọ̀ díẹ̀ ṣì wà tí a lè ṣe. Níní ojú ìwòye ti ayérayé lè ràn wá lọ́wọ́ láti gba ìfihàn láti pèsè ìrànwọ́ tó bọ́ sí àkokò fún àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n wà nínú àìní. A lè gbẹ́kẹ̀lé ìtọ́sọ́nà àti ìmísí ti Ẹ̀mí Mímọ́ láti ní òye ìrànlọ́wọ́ tí a nílò, bóyá ó jẹ́ àtìlẹ́hìn ti ara bíi ìtùnú ẹ̀dùn ọkàn, oúnjẹ, tàbí ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́-ṣíṣe ojoójúmọ́, tàbí ìtọ́sọ́nà ti ẹ̀mí láti ṣèrànwọ́ fún àwọn míràn nínú ìrìn-àjò wọn láti múrasílẹ̀, dá, àti láti bu ọlá fún awọn májèmú mímọ́.

Olùgbàlà Ṣetán Láti Gbà Wá

Nígbàtí Pétérù, Àpóstélì àgbà, “rìn lórí omi, láti lọ bá Jésù … ẹ̀rù bá á; ó sì bẹ̀rẹ̀sí rì”; nígbànáà “ó kígbe, wípé, Olúwa, gbà mi.” Jésù mọ ìgbàgbọ́ tí Pétérù ti lò láti wá sọ́dọ́ Rẹ̀ lórí omi. Ó tún mọ ìbẹ̀rù Pétérù. Gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ náà, Jésù “lójúkanáà … na ọwọ́ rẹ, ó si dìí mú,” ní sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ìwọ onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì?” Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í ṣe láti bá Pétérù wí, ṣùgbọ́n láti rán an létí pé Òun, Messia náà, wà pẹ̀lú rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn.

Bí a bá ronú sẹ̀lẹ́stíà, a ó gbà ìdánilójú nínú ọkàn wa pé Jésù Krístì ni Olùdándè wa nítõtọ́, Alágbàwí wa pẹ̀lú Baba, àti Olùràpadà wa. Bí a ṣe nlo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, Òun yíò gbà wá là kúrò lọ́wọ́ ipò ìṣubú wa, tayọ àwọn ìpèníjà, àìlera, àti àwọn àìní wa nínú ìgbésí ayé ti ìgbà díẹ̀ yí, yíò sì fún wa ní èyí tí ó tóbi jùlọ nínú gbogbo ẹ̀bùn, èyí tí í ṣe ìyè ayérayé.

Olùgbàlà Kò Juwọ́ Sílẹ̀ Lórí Wa

Ẹ̀gbọ́n mi ò jọ̀wọ́ sílẹ̀ lórí mi lọ́jọ́ náà, ṣùgbọ́n ó tẹra mọ́ kí èmi ó lè kọ́ bí mo ṣe lè ṣe é fún ara mi. Ó tẹramọ́ ọn, àní bí èyí tilẹ̀ béèrè gbígbà mí sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì. Ó tẹramọ, àní bí èmi kò tilẹ̀ lè mọ̀ ọ́ ní àkọ́kọ́. Ó tẹramọ́ kí èmi ó lè borí ìpèníjà náà kí nsì ṣàṣeyọrí. Bí a bá ronú sẹ̀lẹ́stíà, a ó mọ̀ pé Olùgbàlà wa yíò wà níbẹ̀ ní iye ìgbà tí ó bá ṣe dandan láti pèsè ìrànlọ́wọ́ bí a bá fẹ́ kọ́ ẹ̀kọ́, yí padà, borí, farada, tàbí ṣe àṣeyọrí nínú ohunkóhun tí yíò mú òtítọ́ àti ayọ̀ àìnípẹ̀kun wá sínú ayé wa.

Ọwọ́ Olùgbàlà Náà.

Àwọn ìwé-mímọ́ ṣe àmì àti pàtàkì àwọn ọwọ́ Olùgbàlà ní wíwà títíláè. Nínú ẹbọ ètùtù Rẹ̀, ọwọ́ Rẹ̀ ni a fi ìṣó gún láti kàn Án mọ́ àgbélèbú. Lẹ́hìn àjíǹde Rẹ̀, Ó farahàn àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ nínú ara pípé, ṣùgbọ́n àwọn àpá ní ọwọ́ Rẹ̀ dúró bí ìrántí ẹbọ àìlópin Rẹ̀. Ọwọ́ Rẹ̀ yíò wà níbẹ̀ nígbàgbogbo fún wa, àní bí a kò tilẹ̀ lè ríi tàbí nímọ̀lára rẹ̀ ní àkọ́kọ́, nítorípé Baba wa Ọ̀run yàn Án láti jẹ́ Olùgbàlà wa, Olùràpadà gbogbo ẹ̀dá ènìyàn.

Olùgbàlà Na Ọwọ́ Jáde

NínúỌwọ́ Wa, nípasẹ̀ Jay Bryant Ward

Ọwọ́ Ìgbàlà Olùgbàlà

Ọwọ́ Ọlọ́run, nípasẹ̀ Yongsung Kim

Bí mo bá ronú sẹ̀lẹ́stíà, mo mọ̀ pé a kò fi wá sílẹ̀ nìkan ní ayé yí. Nígbàtí a gbọ́dọ̀ kojú àwọn ìpèníjà àti àwọn àdánwò, Baba wa Ọrun mọ̀ àwọn agbára wa ó sì mọ̀ pé a lè farada tàbí borí àwọn ìṣòro wa. A gbọ́dọ̀ ṣe apákan tiwa kí a sì yípadà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínu ìgbàgbọ́. Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ni Olùdandè wa yìó sì máa wà níbẹ̀ nígbàgbogbo. Ní orúkọ Rẹ̀, orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Ronú Sẹ̀lẹ́stíà!,” Liahona, Nov. 2023, 118.

    “Nígbàtí ẹ bá nṣe àwọn àṣàyàn, mo pè yín láti mú ìwòye pípẹ́—ìwòye ti ayérayé kan. Ẹ fi Jésù Krístì ṣe àkọ́kọ́ nítorípé ìyè ayérayé yín gbáralé ìgbàgbọ́ yín nínú Rẹ̀ àti nínú Ètùtù Rẹ̀. …

    “Nigbàtí ẹ bá ní ìdojúkọ pẹ̀lú wàhálà, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Nígbàtí a bá dán yín wò nípasẹ̀ ìdánwò, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Nígbàtí ayé tàbí olùfẹ́ kan bá já yín kulẹ̀, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Nígbàtí ẹnìkan bá kú láìpé ọjọ́, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà. Nígbàtí ẹnìkan bá dúró pẹ́ pẹ̀lú àìsàn ayọnilẹ́nu, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà. Nígbàtí àwọn ẹrù ayé bá kórajọ lé yín lórí, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Bí ẹ ti nbọ̀sípò láti inú ìjàmbá tàbí ìfarapa kan, bí èmi ti nṣe nísisìyí, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà!”

  2. Wo Markù 4:35–41.

  3. Lakoko tí a gbàgbọ́ pé Baba wa Ọ̀run àti Jésù Krístì ní agbára láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa nígbàkugbà tí a nílò rẹ̀, ìrànlọ́wọ́ wọn lè má wa nígbàgbogbo ní ọ̀nà tí a nírètí. Ó ṣe pàtàkì láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Wọ́n mọ̀ wá ju bí a ti mọ̀ra wa lọ, tí wọn yíò sì pèsè ìtìlẹ́yìn àti ìrànlọ́wọ́ tí ó dára jùlọ fún wa ní àkokò tí ó tọ́: “Mọ, ọmọ mi, pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni yíò fún ọ ní ìrírí, yíò sì jẹ́ rere fún ọ” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 122:7).

    Àwọn àdánwò àti ìpèníjà tí a ń dojú kọ ràn wá lọ́wọ́ láti ní agbára àti ìwà láti kọjú ìjà sí ìdẹwò àti láti borí ènìyàn àdánidá.

  4. Wo Márkù 1:31; Márkù 5:41; Márkù 9:27; Máttéù 14:31; Ìṣe Àwọn Àpóstélì 3:7; 3 Néfì 18:36.

  5. Nígbàtí Ààrẹ Russel M. Nelson pè wá láti ṣe iṣẹ́-ìrànṣẹ́ ní ọ̀nà titun àti mímọ́ síi (wo “Ṣíṣe Iṣẹ́-ìránṣẹ́,” Làìhónà, Oṣù karun 2018, 100), ó tún bèèrè pé kí á ní òye pé ọ̀nà ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ titun yìí kìíṣe nípa ti èmi àti ohun tí mo fẹ́ láti pèsè ṣùgbọ́n ohun tí àwọn míràn nílò. Jésù Krístì nfún wa ní ààyè láti nifẹ ọmọlàkejì wa (wo Lúkù 10:27) ní ọ̀nà gíga àti mímọ́ si.

  6. Máttéù 14:29–30.

  7. Máttéù 14:31.

  8. Láti lóye ìdùnnú tòótọ́, a nílò láti lóye ipa ti àwọn ìbùkún nínú ìgbésí ayé wa. Ìtumọ̀ blessings ṣèrànwọ́ láti mú ọ̀rọ̀ yìí yéni pé: ìbùkún “ni láti fi ojú rere Ọlọ́run lé ẹnì kan lọ́wọ́. Ohunkóhun tí ó ṣe ìdásíràn sí ayọ̀ tòótọ́, níní-àláfíà, tàbí aísìkí jẹ́ ìbùkún” ( Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé-Mímọ́, “Bùkún, Alábùkún, Bíbùkún,”Ibi-ikàwé Ìhìnrere). Ayé sábà máa nda ayọ̀ tòótọ́ rú pẹ̀lú ìgbádùn fún ìgbà díẹ̀, èyí tí ó nfara wé “ayọ̀” tí kò tọ́jọ́.

  9. Wo Isáíàh 49:16.