Ayọ̀ Ìràpadà Wa.
Ìfẹ́ àti agbára Jésù Krístì lè gba olúkúlùkù wa là kúrò nínú àwọn àṣìṣe, àìlágbára, àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti di nkan díẹ̀ síi.
Ní nkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́hìn, mo ní ìtẹ̀mọ́ra láti ya àwòrán Olùgbàlà kan. Bíótilẹ̀jẹ́pe mo jẹ́ ọ̀ṣèré kan, o kan lágbára díẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ya àwòrán Jésù Krístì kan tó gbé Ẹ̀mí Rẹ̀ yọ? Níbo lóyẹ kí nti bẹ̀rẹ̀? Àti níbo ni mo ti lè rí àkokò náà?
Àní pẹ̀lú àwọn ìbéèrè mi, mo pinnu láti tẹ̀síwájú mo sì ní ìgbẹkẹ̀lé pé Olúwa yíò ràn mí lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n mo ní láti máa sún ki nsì fi àwọn ṣíṣeéṣe sílẹ̀ fún Un. Mo gbàdúrà, ronú, ṣewadii, mo sì fi ọwọ́ yà, àti pé a bùkúnmi láti rí àwọn orísun àti ìrànlọ́wọ́. Àti pé kíniṣe tí kanfasi funfun kan bẹ̀rẹ̀ sí di nkankan díẹ̀ síi.
Ọ̀nà náà kò rọrùn. Nígbà míràn kìí rí bí mo ti nírètí. Nígbà míràn àwọn àkókò àwọn ohun yíyà àti èrò orí onímísí máa nwà. Àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, mo kàn nílàti gbìyànjú lẹẹ̀kansi àti lẹẹ́kansi àti lẹẹ́kansi.
Nígbàtí mo bá rò pé àwòrán elépo náà ti parí ó sì ti gbẹ, mo máa bẹ̀rẹ̀ síí fi fánííṣì tó hàn kedere lée lórí òkè láti dáàbòbò ó kúrò lọ́wọ́ ìdọ̀tí àti eruku. Bí mo ṣe ṣeé, mo ṣàkíyèsí pé irun tó wà nínú àwòrán náà bẹ̀rẹ̀ síí yípadà, ó ntànká, ó sì nparẹ́. Mo yára mọ̀ pé mo ti tètè lo fánííṣì náà jù, apákan àwòrán náà ṣì tutù!
Ká ṣá sọ pé mo ti nu apákan àwòrán mi kúrò pẹ̀lú fánííṣì náà. Áà, ọkàn mí ti rẹ̀wẹ̀sì tó. Mo nímọ̀lára bíi pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ pa ohun tí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe run. Mo sunkún mo sì ṣàìsàn nínú. Nínú àìnírètí, mo ṣe déédé ohun ti ẹnikẹ́ni yíò ṣe ní irú ipò bí èyí: Mo pe ìyá mi. Ó fi ọgbọ́n àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wípé, “Ìwọ kì yíò ní irú ohun tí o ní tẹ́lẹ̀ padà, ṣùgbọ́n ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe pẹ̀lú ohun tí o ní.”
Nítorínáà mo gbàdúrà mo sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, mo sì yàwòrán ní gbogbo òru láti tún àwọn nkan ṣe. Àtipé mo rántí wíwo àwòrán ní òwúrọ̀—ó dára ní wíwò ju bí ó ti rí ní ìṣáájú. Báwo nìyẹn ṣe ṣeéṣe? Ohun tí mo rò pé ó jẹ́ àṣìṣe láìsí àtúnṣe jẹ́ àyè fún ọwọ́ àánú Rẹ̀ láti farahàn. Òun kò tíì ṣe tán pẹ̀lú àwòrán náà, Kò sì tíì ṣe tán pẹ̀lú èmi. Irú ayọ̀ àti ìtura tó kún ọkàn mi. Mo yin Olúwa fún àánú Rẹ̀, fún iṣẹ́́ ìyanu yí tí kò gba àwòràn náà là nìkan ṣùgbọ́n tó kọ́mi díẹ̀ síi nípa ìfẹ́ àti agbára Rẹ̀ láti gba olúkúlùkù wa là kúrò nínú àwọn àṣìṣe, àìlágbára, àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti di nkan díẹ̀ síi.
Gẹ́gẹ́bí jíjìnlẹ̀ ìmoore mi fún Olùgbàlà ṣe ndàgbà bí Ó ti fi àánú ràn mí lọ́wọ́ láti tún àwòrán “àìlètúnṣe” náà ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ àti ìmoore ti ara mi fún Olùgbàlà mi ti pọ̀ sí i bí mo ti wá láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Rẹ̀ lórí àwọn àìlágbára mi àti láti gba ìdáríjì àwọn àṣìṣe mi. Èmí yíò máa dúpẹ́ fún Olùgbàlà mi títíláé pé mo lè yípadà ki nsì di wíwẹ̀mọ́. Ó ní ọkàn mi, àtipé mo nírètí láti ṣe ohunkóhun tí Òun yíò fẹ́ kí nṣe àti kí ndà.
Ríronúpìwàdà gbà wá láàyè láti nímọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run àti láti mọ̀ àti nifẹ Rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà tí a kò bá má mọ̀ bíbẹ́ẹ̀kọ. Ní ti obìnrin tí ó fi òróró kun ẹsẹ̀ Olùgbàlà, Ó wípé, “Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ púpọ̀, ni a dáríjì; nítorítí ó fẹ́ràn púpọ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bá dáríjì díẹ̀, òun ni ó fẹ́ràn díẹ̀.” Ó fẹ́ràn Jésù púpọ̀, nítorí Ó ti dárìjì í lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
Irú ìdẹrùn àti ìrètí bẹ́ẹ̀ nbẹ nínú mímọ̀ pé a lè tún gbìyánjú lẹ́ẹ̀kansíi—pé, bí Alàgbà Bednar ti kọni, a lè gba ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tó nlọ lọ́wọ́ nípasẹ̀ agbára ìsọdimímọ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ bí a ti nronúpíwàdà nítòótọ́ àti lódodo.
Agbára ìràpadà ti Jésù Krístì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìbùkún nlá ti àwọn májẹ̀mú wa. Ronú nípa èyí bí o ti nṣe àbápín nínú àwọn ìlànà mímọ́. Láìsí i rẹ̀, a kò lè padà sí ilé níwájú Baba wa ní Ọ̀run àti àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn.
Mo mọ̀ pé Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, lágbára láti gbani là. Gẹ́gẹ́bí Ọmọ Ọlọ́run, tí ó ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ayé tí ó sì fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ tí ó sì tún gbé e sókè lẹ́ẹ̀kansíi, Ó di agbára ìràpadà àti ajinde mú. Ó ti mú kí àìlèkú ṣeéṣe fún gbogbo ènìyàn àti ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tí wọ́n yàn Án. Mo mọ̀ pé nípa ẹbọ ètùtù Rẹ̀, a lè ronúpíwàdà kí a sì di mímọ́ nítòótọ́ kí a sì di ríràpadà. Ìyanu ni pé Ó fẹ́ ẹ̀yin àti èmi lọ́nà yi.
Ó ti wípé, “Ẹ̀yin kì yíò ha padàsọ́dọ̀ mi nísisiyìí, kí ẹ sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì yípadà, kí èmi lè mú yín láradá?” Ó lè wòsàn “ibi ahoro” ọkàn rẹ sàn—àwọn ibi tí ó mú gbẹ, tí ó le, tí ó sì di ahoro nípa ẹ̀ṣẹ̀, àti ìbànújẹ́—kí ó sì “sọ aginjù [rẹ] dà bí Édẹ́nì.”
Gẹ́gẹ́bí a kò ti lè lóye ìrora àti jíjìnlẹ̀ ìjìyà Krístì ní Gẹtisémánì àti lórí àgbélébùú, bẹ́ẹ̀ náà ni a kò lè “diwọ̀n àwọn ààlà tàbí mọ̀ ìjìnlẹ̀ ìdáríjì,” àánú, àti ìfẹ́ [Rẹ̀].
Ẹ lè nímọ̀lára nígbà míràn pé kò ṣeéṣe láti jẹ́ ríràpadà, pé bóyá ẹ jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti agbára ètùtù Olùgbàlà nítorí ohun tí ẹ ntiraka pẹ̀lú tàbí nítorí ohun tí ẹ ti ṣe. Ṣùgbọ́n mo jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀yin kò wà ní abẹ́ àrọwọ́tó Ọ̀ga náà. Olùgbàlà “sọ̀kalẹ̀ sísàlẹ̀ ohun gbogbo” Ó sì wà ní ipò àtọ̀runwá láti gbé ọ sókè àti láti gbà ọ́ kúrò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ tí ó ṣókùnkùn jùlọ kí o sì mú ọ wá sínú “ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀.” Nípasẹ̀ àwọn ìjìyà Rẹ̀, Ó ti ṣe ọ̀nà kan fún ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan wa láti bórí àwọn àìlágbára ara ẹni, àwọn ẹ̀ṣẹ̀. “Ó ní gbogbo agbára láti gba olúkúlùkù ènìyàn tí ó bá gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ tí ó sì nso èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.”
Gẹ́gẹ́bí ó ṣe béèrè iṣẹ́ àti bíbẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ ọ̀run láti tún àwòrán náà ṣe, ó gba iṣẹ́, òtítọ́ ọkàn, àti ìrẹ̀lẹ̀ láti mú “èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà jáde wá”. Àwọn èso wọ̀nyí pẹ̀lú lílo ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jésù Krístì àti ẹbọ ètùtù Rẹ̀, fífún Ọlọ́run ní ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, jíjẹ́wọ́ àti fífi ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, mímú ohun tí ó ti bàjẹ́ padàbọ̀sípò nípa gbogbo agbára wa, tí a sì ngbìyànjú làti gbé ìgbé òdodo.
Láti ronúpìwàdà nítòótọ́ kí a sì yípadà, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ “da àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lójú.” Ẹnìkan kìí ríi pé ó nílò láti lo oògùn àyàfi tí wọ́n bá lóye pé wọ́n nṣàìsàn. Àwọn àkokò lè wà tí a lè má fẹ́ láti wo inú arawa kí á sì rí èyítí ó nílò ìwòsàn àti àtúnṣe gan an.
Nínú àwọn ìkọ̀wé C. S. Lewis, Aslan gbé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sókè sí ọkùnrin kan tí ó ti di ara rẹ̀ mọ́ ète inú tirẹ̀: “Áà, [ẹ̀dá-ènìyàn], bí ẹ ṣe nfi ọgbọ́n dáàbò bo ara yín tó [lọ́wọ́] gbogbo ohun tí ó lè ṣe yín rere!”
Níbo ni ẹ̀yin àti èmi ti lè máa ṣe ààbò fún arawa kúrò nínú àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe wá ní ànfàní?
Ẹ máṣe jẹ́kí a dábòbò arawa kúrò lọ́wọ́ rere ti Ọlọ́run fẹ́ láti bùkún wa pẹ̀lú. Kúrò nínú ìfẹ́ àti àánú tí Ó ní ìfẹ́-inú fún wa láti nímọ̀lára rẹ̀. Kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ tí Ó ní ìfẹ́-inú láti fi fún wa. Látinú ìwòsàn náà Ó mọ̀ pé à nílò gidi. Kúrò níbi ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú tó jinlẹ̀jù tí Ó nílọ́kàn fún gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìrin Rẹ̀.
Mo gbàdúrà pé kí a lè fi eyikeyi “àwọn ohun ìjà ogun” sílẹ̀ tí a ti mọ̀ọ́mọ̀ tàbí àni fi àìmọ̀ọ́mọ̀ gbé làti dáàbòbo arawa kúrò lọ́wọ́ àwọn ìbùkún ti ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ohun ìjà ti ìgbéraga, ìmọtara-ẹni-nìkan, ìbẹ̀rù, ìkóríra, ìbínú, àìnítẹ́lọ́rùn, ìdájọ́ àìṣòdodo, owú—ohunkóhun tí yíò pa wá mọ́ kúrò ní fífẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti pípa gbogbo májẹ̀mú wa pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́.
Bí a ṣe npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, Olúwa lè fún wa ní ìrànlọ́wọ́ àti agbára tí a nílò láti dá méjèèjì mọ̀ kí a sì borí àwọn àìlágbára wa, pẹ̀lú àfòmọ́ ẹ̀mí ti ìgbéraga. Ààrẹ Nelson ti wípé:
“Ìronúpìwàdà jẹ́ ipá ọ̀nà sí ìwẹ̀mọ́, àti pé ìwẹ̀mọ́ nmú agbára wá.”
“Àti pé áà, a ó ti nílò agbára Rẹ̀ tó ní àwọn ọjọ́ iwájú.”
Bíi ti àwòrán mi, Olúwa kò tíì ṣe tán pẹ̀lú wa nígbàtí a bá ṣe àṣìṣe, bẹ́ẹ̀ni kò sá nígbàtí a bá kọsẹ̀. Ìnílò wa fún ìwòsàn àti ìrànlọ́wọ́ kìí ṣe ẹrù fún Un, ṣùgbọ́n ìdí gan-an tí Ó fi wá. Olùgbàlà Funrarẹ̀ wípé:
“Ẹ kíyèsĩ, èmi wá sínú ayé láti mú ìràpadà wá fún aráyé, láti gba aráyé là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.”
“Apá ãnú mi nã síi yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun ni èmi yíò gbà; alábùkún-fún sì ni àwọn tí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.”
Nítorínáà ẹ wá—ẹ wá ẹ̀yin tí ẹ rẹ̀wẹ̀sì, tí ó rẹ̀, tí ó sì banújẹ́; ẹ wá fi iṣẹ́ yín sílẹ̀, kí ẹ sì rí ìsinmi lọ́dọ̀ Rẹ̀ ẹni tí ó fẹ́ràn yín jùlọ. Ẹ gba àjàgà Rẹ̀ si ọ̀rùn nyin, nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ní I ṣe.
Baba wa Ọ̀run àti Olùgbàlà ríi yín. Wọ́n mọ ọkàn yín. Wọ́n bìkítà nípa ohun tí ẹ bìkítà nípa, pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn.
Olùgbàlà lè ra ohun tí ó sọnù padà, pẹ̀lú àwọn ìbáṣepọ̀ tí ó ti bàjẹ́ àti tí ó fọ́. Ó ṣe ọ̀nà kan fún gbogbo àwọn tí wọ́n ṣubú láti jẹ́ ríràpadà—láti mí ìyè sínú èyí tí ó nímọ̀lára pé ó jẹ́ ikú àti àìnírètí.
Bí ẹ bá ntiraka pẹ̀lú ipò kan tí ẹ rò pé ó yẹ kí ẹ ti borí báyìí, ẹ máṣe dẹ̀hìn. Ẹ ṣe sùúrù pẹ̀lú ara yín, ẹ pa àwọn májẹ̀mú mọ́, ẹ ronúpìwàdà nígbàkugbà, ẹ wá ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí yín tí ẹ bá nílò, kí ẹ sì lọ sílé Olúwa deede bí ẹ ṣe lè ṣe tó. Ẹ fetísílẹ̀ sí kí ẹ sì ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn ìṣílétí tí Ó fi ránṣẹ́ síi yín. Òun kì yíò pa ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú Rẹ̀ pẹ̀lú yín tì.
Àwọn ìbáṣepọ̀ tó nira tó sì díjú ti wà nínú ìgbési ayé mi tí mo ti tiraka pẹ̀lú àti mo sì lépa nítòótọ́ láti nílọsíwájú. Nígbà míràn mo nímọ̀lára bí ẹnipé mo máa nkùnà lọ́pọ̀ ìgbà ju bóti yẹ lọ. Mo nní ìyàlẹ́nu, “Njẹ́ èmi kò ṣàtúnṣe àwọn nkan ní àkokò tí ó kọjá ni? Njẹ́ mi ò borí àwọn àìlágbára mi nítòótọ́ bí? Mo ti kẹkọ léraléra lákokò pé èmi kò fi bẹ́ẹ̀ ní àlébù; dípò bẹ́ẹ̀, púpọ̀ wà láti ṣiṣẹ́ lè lórí àti ìwòsàn púpọ̀ síi tí a nílò.
Alàgbà D. Todd Christofferson kọ́ni pé: “Dájúdájú Olúwa máa nrẹ́rìn-ín sí ẹni tí ó bá fẹ́ wá sí ìdájọ́ lọ́nà yíyẹ, ẹni tí ó nfi ìpinnu ṣe làálàá lójoojúmọ́ láti fi agbára rọ́pò àìlágbára. Ìrònúpìwàdà tòótọ́, ìyípadà tòótọ́ lè béèrè fún ìgbìyànjú léraléra, ṣùgbọ́n ohun kan wà tó nsọdọ̀tun àti mímọ́ nínú irú ìsapá bẹ́ẹ̀. Ìdáríjì àtọ̀runwá àti ìwòsàn máa nṣàn ní àdánidá sí irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀.”
Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọjọ́ títun tó kún fún ìrètí àti àwọn ìleṣe nítorí Jésù Krístì. Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni èmi àti ẹ̀yin lè mọ̀, bí Màmá Éfà ṣe kéde, “ayọ̀ ìràpadà wa,” ayọ̀ tí ó nsọ wá di odidi, ayọ̀ níní ìmọ̀lára ìfẹ́ àìkùnà ti Ọlọ́run fún yín.
Mo mọ̀ pé Baba wa ní Ọ̀run àti Olùgbàlà nifẹẹ yín. Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà gbogbo ẹ̀dá-ènìyàn. Ó wà láàyè. Nípasẹ̀ ètùtù ẹbọ Rẹ̀, Nípasẹ̀ ẹbọ ètùtù Rẹ̀, àwọn ìdè ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni a já e títí láé kí a lè ní òmìnira láti yan ìwòsàn, ìràpadà, àti ìyè ayérayé pẹ̀lú àwọn tí a fẹ́ràn. Mo sì jẹ́ ẹ̀rí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.