Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ríri àwọn Ohun Ìjà-ogun ti Ọ̀tẹ̀ Wa Mọ́lẹ̀
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


13:11

Ríri àwọn Ohun Ìjà-ogun ti Ọ̀tẹ̀ Wa Mọ́lẹ̀

Njẹ́ kí a rì ohun-èlò ọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Ọlọ́run nínú ayé wa mọ́lẹ̀—gidi, gidi jinlẹ̀—kí a sì rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́ àti iyè-inú ìfẹ́.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe àwọn àkọsílẹ̀ pé bíi ọdún àádọ́run ṣíwájú ìbí Krístì, àwọn ọmọ Ọba Mòsíàh bẹ̀rẹ̀ ohun tí yíò jẹ́ iṣẹ́-ìránṣẹ́ ọdún mẹ́rìnlá kan lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì. Àwọn ìtiraka àìyege ni wọ́n ti ṣe lórí àwọn ìran púpọ̀ láti mú àwọn ènìyàn Lámánì wá sí ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ Krístì. Ní àkokò yí, bákannáà, nípasẹ̀ ìlàjà oníyanu ti Ẹ̀mí Mímọ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Lámánì ni a yípada tí wọ́n sì di ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.

A kà pé, “Bí Olúwa sì ti wà lãyè, bẹ̃ni ó sì dájú, tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, tàbí tí gbogbo àwọn tí a mú wá sí ìmọ̀ òdodo nípa ìwãsù Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, nípasẹ̀ ẹ̀mí ìfihàn àti ti ìsọtẹ́lẹ̀, àti agbára Ọlọ́run tí ó nṣe iṣẹ́ ìyanu nínú nwọn—bẹ̃ni, mo wí fún nyin, bí Olúwa ti wà lãyè, gbogbo àwọn ará Lámánì tí nwọ́n gbàgbọ́ nínú ìwãsù nwọn, tí nwọ́n sì yípadà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, kò ṣubú kúrò lọ́nà nã mọ́.”

Kókó sí ìforítì ìyípadà àwọn ènìyàn yí ni a kọ sílẹ̀ ní ẹsẹ tó tẹ̀le: “Nítorítí wọ́n di ènìyàn olódodo; wọ́n sì kó ohun ìjà ọ̀tẹ̀ wọn lélẹ̀, tí wọn kò bá Ọlọ́run jà mọ́, tàbí ẹnikẹ́ni nínú arákùnrin wọn.”

Ìtọ́ka yí sí “àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀” jẹ́ méjèèjì ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ gangan àti àpẹrẹ. Ó túmọ̀ sí àwọn idà àti ohun ìjà ogun wọn míràn ṣùgbọ́n bákannáà àìgbọ́ran wọn sí Ọlọ́run àti àwọn òfin Rẹ̀.

Ọba àwọn olùyípada ara Lámánì sọ ọ́ ní ọ̀nà yí: “Àti nísisìyí kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, … ó ti jẹ́ ohun tí ó yẹ kí àwa ó ṣe … láti ronúpìwàdà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa àti gbogbo ìpànìyàn tí àwa ti ṣe, kí àwa kí ó sì jẹ́ kí Ọlọ́run yọ eleyĩ kúrò lọ́kàn wa, nítorípé èyí ni ohun tí ó tọ́ fún wa láti ṣe pé kí àwa kí ó ronúpìwàdà pátápátá níwájú Ọlọ́run kí ó lè mú àbàwọ́n wa kúrò.”

Kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ ọba—kìí ṣe pé ìrònúpìwàdà òdodo wọn ti darí sí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nìkan, ṣùgbọ́n Ọlọ́run mú àbàwọn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọnnì àní àti ìfẹ́-inú láti ṣẹ̀ kúrò ní ọkàn wọn. Bí ẹ ti mọ̀, sànju fífi ewu eyikeyi ìṣeéṣe láti padà sí ipò ìṣíwájú ọ̀tẹ̀ ṣe ní ìlòdì sí Ọlọ́run wọn, wọ́n ri àwọn idà wọn mọ́lẹ̀. Bí wọ́n sì ti ri àwọn ohun ìjà àfojúrí wọn mọ́lẹ̀, pẹ̀lú ìyípadà ọkàn, bákannáà wọ́n ri ìdarísí wọn sí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

A lè bi ara wa léèrè ohun tí a lè ṣe láti tẹ̀lé àwòṣe yí, láti “gbé àwọn ohun ìjà ti ọ̀tẹ̀ [wa] sílẹ̀” ohunkóhun tí ó lè jẹ́, àti láti dà “olùyípadà [sí] Olúwa” kí a lè mú àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ àti ìfẹ́-inú fún ẹ̀ṣẹ̀ kúrò ní ọkàn wa kí a má sì ṣe ṣubu kúrò láéláé.

Ọ̀tẹ̀ lè jẹ́ ti aápọn tàbí ti sùúrù. Àpẹrẹ ayébáyé ti ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ ni Lúsíférì, ẹnití, nínú ayé ìṣíwájú, tako ètò ìràpadà ti Baba tí a sì yí àwọn ẹlòmíràn ká láti takò ó bákannáà, “àti pé, ní ọjọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ tẹ̀lé e.” Kò le láti ní ìwòye ipa ti ọ̀tẹ̀ tí ó ntẹ̀síwájú ní akokò tiwa.

Àwọn aláìmọ́ aṣòdìsí-Krístì mẹ́ta Ìwé ti Mọ́mọ́nì—Sherem, Nehor, àti Korihor—pèsè àṣàrò ayébáyé ti aápọn ọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Ọlọ́run. Dídarí ìwé-ìwáàdí ti Nehor àti Kòríhọ̀ ni pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀, nítorínáà, kò sí ìnílò fún ìrònúpìwàdà, kò sì sí Olùgbàlà. “Gbogbo ènìyàn nṣe [rere] gẹ́gẹ́bí ìmòye rẹ̀, àti … gbogbo ènìyàn nṣe [rere] gẹ́gẹ́bí okun rẹ̀; àti pé ohunkóhun tí ènìyàn [bá ṣe] kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀.” Àwọn aṣòdìsí-Krístì kọ àṣẹ ẹ̀sìn, wọ́n fi orúkọ fún àwọn ìlànà àti májẹ̀mú bí àwọn ìṣe “tí a gbékalẹ̀ nípasẹ̀ àwọn àlùfáà àtijọ́, láti dojú agbára àti àṣẹ bolẹ̀.”

William W. Phelps

Àpẹrẹ ọjọ́-ìkẹhìn kan nípa ọ̀tẹ̀ aápọn pẹ̀lú òpin ìdùnnú ni ìtàn ti William W. Phelps. Phelps darapọ̀ mọ́ Ìjọ ní 1831 a sì yàn án bí atẹ̀wé Ìjọ. Ó tún onírurú àwọn àtẹ̀jáde ìṣíwájú Ìjọ ṣe, ó kọ oríṣiríṣi àwọn orin, ó sì sìn bí akọ̀wé sí Joseph Smith. Ní àìdára, ó yípadà ní ìlòdì sí Ìjọ àti Wòlíì, àní dé àmì ti fífúnni ní ẹ̀rí èké ní ìlòdì sí Jeoseph Smith ní kóòtù Míssouri, èyí tí ó jásí lílọ sí ẹ̀wọ̀n Wòlíì níbẹ̀.

Lẹ́hìnnáà, Phelps kọ̀wé sí Joseph ní bíbèèrè fún ìdáríjì. “Mo mọ ipò mi, o mọ̀ ọ́, Ọlọ́run sì mọ̀ ọ́, … mo sì fẹ́ láti ní ìgbàlà tí àwọn ọ̀rẹ́ mi yíò bá rànmílọ́wọ́.“

Nínú ìdáhùn rẹ̀ Wòlíì wípé: “Ó jẹ́ òtítọ́ pé a ti jìyà púpọ̀ ní ayọrísí ìwà rẹ. … Ṣùgbọ́n, a ti mu ago náà, a ti ṣe ìfẹ́ Baba Ọ̀run, a sì wà láàyè síbẹ̀. … Máa bọ̀, arákùnrin ọ̀wọ́n, nígbàtí ogun ti kọjá, nítorí ọ̀rẹ́ ní àkọ́kọ́ ti jẹ́ ọ̀rẹ́ lẹ́ẹ̀kansi níkẹhìn.”

Pẹ̀lú ìrònúpìwàdà òdodo, William Phelps ri “àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀,” a sì gbà á lẹ́ẹ̀kansi sínú ìjọsìn kíkún, kò sì ṣubú kúrò títíláé.

Bóyá irú ìṣọ̀tẹ̀ ọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Ọlọ́run, bákannáà, ni ẹ̀yà àìmọ̀—ní pípa ìfẹ́ Rẹ̀ tì nínú ayé wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni tí kò ní ka aápọn ọ̀tẹ̀ sí ṣì lè tako ìfẹ́ àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa lílépa ipa-ọ̀nà tiwọn láìsí ìkàsí sí ìdarí tọ̀run. A rán mi létí nípa orin tí a mú lókìkì ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn nípasẹ̀ akọrin Frank Sinatra pẹ̀lú ìlà ti àkoko, “Mo ṣe ní ọ̀nà tèmi.” Dájúdájú nínú ayé àyè púpọ̀ wà fún ààyò araẹni àti àṣàyàn olúkúlùkù, ṣùgbọ́n nígbàtí ó bá kan ọ̀ràn ìgbàlà àti ìyè ayérayé, àkórí orin wa níláti jẹ́, “Mo ṣe é ní ọ̀nà Ọlọ́run,” nítorí nítòótọ́ kò sí ọ̀nà míràn.

Fún àpẹrẹ, àpẹrẹ Olùgbàlà ní ìkàsí sí ìrìbọmi. Ó gbà láti ṣe ìrìbọmi bí ìjúwe òtítọ́ sí Baba àti bí àpẹrẹ kan sí wa:

“Ó fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn pé, nípa ti ara òun rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Baba, ó sì jẹ́rĩ sí Baba pé òun yíò ní ígbọ́ran sí i ní pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. …

“Ó sì wí fún àwọn ọmọ ènìyàn: Ẹ̀yin ẹ máa tọ̀ mí lẹ́hìn. Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, àwa ha lè tọ Jésù lẹ́hìn bíkòṣe pe àwa yíò ní ìfẹ́ láti pa àwọn òfin Baba mọ́?”

Kò sí “ọ̀nà mi” bí a bá níláti tẹ̀lé àpẹrẹ Krístì. Gbígbìyànjú láti rí ọ̀nà tó yàtọ̀ sí ọ̀run dà bíi àsán ṣíṣe iṣẹ́ lórí ilé-ìṣúra ti Bábélì sànju wíwo Krístì àti ìgbàlà Rẹ̀.

Àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn ohun ìjà tí àwọn olùyípadà ará Lámánì ri àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀ wọn mọ́lẹ̀ nítorí bí wọ́n ti ṣe lò wọ́n tẹ́lẹ̀. Irú àwọn ohun ìjà kannáà nínú ọwọ́ àwọn ọmọ wọn, ní lílò fún ààbò ẹbí àti òmìnira, kìí ṣe àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Ọlọ́run rárá. Ọ̀kannáà jẹ́ òtítọ́ nípa irú àwọn ohun ìjà bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ àwọn ará Néfì: “Wọn kò jà fún ìjọba tàbí àṣẹ, ṣùgbọ́n nwọn njà fún ilẹ̀ àti òmìnira nwọn, àwọn aya nwọn àti àwọn ọmọ nwọn, àti ohun gbogbo tí nwọ́n ní, bẹ̃ni, fún ìlànà ẹ̀sìn àti ìjọ wọn.”

Ní ọ̀nà yí kannáà, àwọn ohun kan wà nínú ayé wa tí ó lè wà ní àárín àní tàbí àmútọ̀runwá rere ṣùgbọ́n tí a lò ní ọ̀nà tí kò tọ́ tí ó di “àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀.” Ọ̀rọ̀ wa, fún àpẹrẹ, lè gbéniga tàbí rẹnisílẹ̀. Bí Jákọ́bù ti wí:

“Ṣùgbọ́n ahọ́n ni [ó dàbí] ẹnìkẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ran ni, ó kún fún oró ikú ti ìpani.

“Òhun ni àwa fi nyin Ọlọ́run, àní Baba; òhun ni a sì fi nbú ènìyàn, tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run.

“Láti ẹnu kannáà ni ìyìn àti èébú ti njáde. Ẹ̀yin ará mi, nkan wọ̀nyí kò yẹ kó ó rí bẹ́ẹ̀.”

Ọ̀pọ̀ ni ó wà nínú ìbánisọ̀rọ̀ gbangba àti araẹni ní òní tí ó ní ìríra àti ti ẹ̀mí-búburú. Ìbárasọ̀rọ̀ púpọ̀ wà tí ó jẹ́ asán àti ìbàjẹ́, àní ní àárín àwọn ọ̀dọ́. Irú ọ̀rọ̀ yí, ni “àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀” ní ìlòdì sí Ọlọ́run, “tí ó kún fún oró ìpani.”

Yẹ àpẹrẹ míràn wò nípa ohunkan rere tí ó ṣe pàtàkì ṣùgbọ́n tí ó lè yípadà sí ọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí àwọn ìdarí àtọ̀runwá—iṣẹ́ ti ẹnìkan. Ẹnìkan lè rí ìtẹ́lọ́rùn òdodo nínú iṣẹ̀-àmọ̀dájú, iṣẹ́-ṣíṣe, tàbí iṣẹ́-ìsìn, àti pé gbogbo wa jẹ́ olùjèrè nípa ohun tí àwọn ènìyàn olùfọkànsìn àti ẹlẹ́bùn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibi iṣẹ́ ti ṣe àṣeyọrí tí a sì ti dásílẹ̀.

Síbẹ̀, ó ṣeéṣe pé ìfọkànsìn sí iṣẹ́ lè di àfojúsùn pàtàkì nípa ayé ẹnìkan. Lẹ́hìnnáà gbogbo ohun míràn ó dì àtẹ̀lé, pẹ̀lú gbígbà eyikeyi tí Olùgbàlà lè ṣe lórí àkokò ẹnìkan àti ẹ̀bùn. Fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ànfàní òtítọ́ tí ó nlọ lọ́wọ́ fún ìgbeyàwó, kíkùnà láti rọ̀mọ́ àti láti gbé lọ́kọ-láyà ẹni ga, kíkùnà láti ṣìkẹ́ àwọn ọmọ ẹni, tàbí àní ìmọ̀ọ́mọ̀ yẹra fún ìbùkún àti ojúṣe ti ọmọ-bíbí nìkàn fún ìdí ìlọsíwájú iṣẹ́ lè yí àṣeyege ìyẹ́sí padà sí irú ọ̀tẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Àpẹrẹ míràn níí ṣe pẹ̀lú wíwà ti ara wa. Páùlù rán wa létí pé a níláti fún Ọlọ́run lógo ní ara àti ẹ̀mí àti pé ara yí ni tẹ́mpìlì Ẹ̀mí Mímọ́, “tí ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹ̀yin kìí sì ṣe ti ara yín.” Bayi, a ní ojúlówó ìnífẹ́sí ní lílo àkokò láti tọ́jú ara wa bíi dídárajùlọ tí a lè ṣe. Díẹ̀ lára wa yíò dé ténté-òkè ìmúṣe tí a ti rí láìpẹ́ nínú àwọn àṣeyọrí ti eré Òlímpíkì àti Paralímpíkì, àti pé àwọn kan lára wa nní ìrírí àbájáde ọjọ́ orí, tàbí ohun tí Ààrẹ M. Russell Ballard pè ní “àwọn èèkan irin tó yọ kúrò.”

Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, mo gbàgbọ́ pé ó dùnmọ́ Aṣẹ̀dá wa nígbàtí a bá ṣe dídárajùlọ wa láti tọ́jú ẹ̀bùn ìyanu Rẹ̀ ti ara àfojúrí. Yíò jẹ́ àmìn ọ̀tẹ̀ láti ba ara ẹni jẹ́ tàbi tàbùkù rẹ̀, tàbí lo nílòkulò, tàbí kùnà láti ṣe ohun tí ẹnikàn lè ṣe láti lépa ìgbé-ayé ìlera. Ní àkokò kannáà, asán àti dída jíjẹrun pẹ̀lú ìrísí, ìwò, tàbí ìwọṣọ ẹnìkan lè jẹ́ irú ìṣọ̀tẹ̀ kan dé òpin òmíràn, tí ó ndarí ẹnìkan láti jọ́sìn ẹ̀bùn Ọlọ́run dípò Ọlọ́run.

Ní ìparí, ríri àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní ìlòdi sí Ọlọ́run kàn túmọ̀ sí fífi arasílẹ̀ sí ìwuni ti Ẹ̀mí Mímọ́, mímú ènìyàn ẹlẹ́ran ara kúrò àti dídi “ènìyàn mímọ́ nípasẹ̀ ètùtù Krístì Olúwa.” Ó túmọ̀ sí fifi òfin àkọ́kọ́ ṣaájú nínú ayé wa. Ó túmọ̀ sí jíjẹ́ kí Ọlọ́run borí. Bí ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti ìpinnu wa láti sìn Ín pẹ̀lú gbogbo agbára, inú, àti okun wa bá di ìtumọ̀ oníwúrà nípa èyí tí à ndájọ́ ohun gbogbo tí a sì nṣe àwọn ìpinnu wa, a ó níláti ri àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀ wa mọ́lẹ̀. Nípa oore-ọ̀fẹ́ Krístì, Ọlọ́run yíò darí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀tẹ̀ wa àtẹ̀hìnwá jì yíò sì mú àbàwọ́n àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀tẹ̀ wọnnì kúrò nínú ọkàn wa. Ní àkokò, àní Òun yíò mú ìfẹ́-inú eyikeyi fún ibi kúrò, bí Ó ti ṣe sí àwọn olùyípadà ará Lámánì ti ìgbẹ̀hìn. Lẹ́hìnnáà, àwa pẹ̀lú “kì [yíò] ṣubú kúrò láéláé.”

Ríri àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀ wa mọ́lẹ̀ ndarí sí ayọ̀ àìláfiwé. Pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n ti di olùyípadà sí Olúwa, a “mú wa wá láti [kọrin ti] ìràpadà ìfẹ́.” Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Olùràpadà wa, ti fi ẹ̀sẹ̀ ìfarajìn àìlèyípadà wọn múlẹ̀ sí ìdùnnú ìgbẹ̀hìn wa nípa ìfẹ́ àti ìrúbọ jíjìnlẹ̀ jùlọ. A nní ìrírí ìfẹ́ wọn lójojúmọ́. Dájúdájú a lè ṣe pàṣípàrọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ ti ara wa àti òdodo. Njẹ́ kí a rì ohun-èlò ọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Ọlọ́run nínú ayé wa mọ́lẹ̀—gidi, gidi jinlẹ̀—kí a sì rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́ àti iyè-inú ìfẹ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.