Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Ẹ̀yin Ni Ọ̀rẹ́ Mi”
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


10:48

“Ẹ̀yin Ni Ọ̀rẹ́ Mi”

Ìkéde ti Olùgbàlà pé “ẹ̀yin ni ọ̀rẹ́ mi” jẹ́ fèrè ìpè kan láti ṣe ìgbéga àwọn ìbáṣepọ̀ gígajù àti mímọ́jù láàrin gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Nínú ayé tó kún pẹ̀lú ìjà àti ìyapa, nibití àsọyé ìmọyì ti jẹ́ rírọ́pò pẹ̀lú ìdájọ́ àti ẹ̀gàn, àti tí ìbáṣepọ̀ ti njẹ́ títúmọ̀ nípa -ará ibí àti -ará ọ̀hún, mo ti wá mọ̀ pé àpẹrẹ kedere, rírọrùn, àti ti ọ̀run kan wà tí a lè wò fún ìrẹ́pọ̀, ìfẹ́, àti jíjẹ́ ti ara kan. Àpẹrẹ náà ni Jésù Krístì. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Òun ni olùrẹ́pọ̀ nlá náà.

Àwa Ni Ọ̀rẹ́ Rẹ̀.

Ní Oṣù Kejìlá ti 1832, bí “àwọn ìfarahàn ìdààmú láàrin àwọn orílẹ̀-èdè” ti ndi “híhàn síi” ju èyíkéyí àkokò láti ìgbà ìgbékalẹ̀ Ìjọ, àwọn olórí Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní Kirtland, Ohio, péjọ fún ìpàdé àpapọ̀ kan. Wọ́n gbàdúrà “lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ àti ní ohùn òkè sí Olúwa láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí [wọn].” Ní ìtẹ́wọ́gbà àdúrà àwọn onígbàgbọ́ ọmọ-ìjọ wọ̀nyí ní àkókò ìdààmú líle, Olúwa tù wọ́n nínú, ní bíbá Àwọn Ènìyàn Mímọ́ náà sọ̀rọ̀ ní ìgbà mẹ́ta pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ méjì tó lágbára: ”ẹ̀yin ọ̀rẹ́mi.”

Ó ti pẹ́ tí Jésù Krístì ti pe áwọn olõtọ́ àtẹ̀lé Rẹ̀ ní àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀. Ìgbà mẹ́rìnlá ninu Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú, Olùgbàlà lo ọ̀rọ̀ nàà friend làti túmọ̀ ìbáṣepọ̀ mímọ́ àti tí a mọyì. Èmi kò sọ nípa ọ̀rọ̀ náà ọ̀rẹ́ bí aráyé ti túmọ̀ rẹ—tó níi ṣe sí àwọn atẹ̀lé ìròhìn ibákẹ́gbẹ́ tàbí “àwọn ìfẹ́ràn.” A kò lè ká a mọ́ nínù áṣìtáàgì ìdámọ̀ tàbí nọ́mbà kan lórí ínsítágiráàmù tàbí X.

Ní tòótọ́, bíi ọ̀dọ́ kan, mo rántí àwọn ìbáraẹni sọ̀rọ̀ tí mo bẹ̀rù nígbàtí mo bá gbọ àwọn ọ̀rọ̀ ìrora wọnnì “Éè ṣé a kàn lè jẹ́ ọ̀rẹ́?” tàbí “Jẹ́kí a kan dúró nínú agbo-ọ̀rẹ́.” Kò sí ibikíbi ninu ìwé àṣẹ mímọ́ tí a ti gbọ́ Òun tó wí pé, “Ẹ̀yin kàn jẹ́ ọ̀rẹ́ mi.” Dípò bẹ́ẹ̀, Ó kọ́ni pé “kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tobi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mi rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Àti pé “ẹ̀yin ni àwọn tí Baba mi ti fi fún mi; ẹ̀yin ni ọ̀rẹ́ mi.”

Ìrò náà ṣe kedere—Olùgbàlà ka ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ó sì nṣe ìṣọ́ lórí wa. Ìtojú ìṣọ́ yí kìí ṣe kékeré tàbí àìṣepàtàkì. Dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ gbígbéniga, tí ó ngbéni sókè, àti ti ayérayé. Mo rí ìkéde ti Olùgbàlà “ẹ̀yin ni ọ̀rẹ́ mi” bí fèrè ìpè kan láti ṣe gbígbéga àwọn ìbáṣepọ̀ gígajù àti mímọ́jù láàrin gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run “pé kí a lè jẹ́ ọ̀kan.” A nṣe èyí bí a ti nwá papọ̀ ní lílepa àwọn ànfààní méjéèjì láti rẹ́pọ̀ àti ọgbọ́n jíjẹ́ ti ara kan fún ẹni gbogbo.

Àwa Jẹ́ Ọ̀kan ninu Rẹ̀

Olùgbàlà fi pẹ̀lú ẹwà ṣe àfihàn èyí ninu ìpè Rẹ̀ láti “wá, tẹ̀lé mi.” Ó fà sórí àwọn ẹ̀bùn àti ìwà olúkúlùkù ti oriṣiriṣi ẹgbẹ́ àwọn atẹ̀lé láti pe àwọn Àpóstélì Rẹ̀. Ó pe àwọn apẹja, àwọn onítara, àwọn arákùnrin tí a mọ̀ fún irú ẹni bí ààrá ti wọ́n jẹ́, àti agbowo-òde pàápàá. Ìgbàgbọ́ wọn ninu Olùgbàlà àti ìfẹ́-inú láti sún mọ́ Ọ ni ó mú wọn rẹ́pọ̀. Wọ́n nwò Ó, wọ́n rí Ọlọ́run nípasẹ̀ Rẹ̀, àti “lójúkannáà wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀lé E.”

Èmi náà ti ríi bí ṣíṣe ìgbéga àwọn ìbáṣepọ̀ gígajù àti mímọ́jù ti nmú wa wá papọ̀ bí ọ̀kan. Ìyàwó mi, Jennifer, àti èmi ni a bùkún làti tọ́ àwọn ọmọ wa màrun ni New York City. Níbẹ̀ ní agbègbè tó díwọ́ náà, a ṣe áwọn ìbáṣepọ̀ iyebíye àti mímọ́ pẹ̀lú àwọn aládugbò, àwọn ọ̀rẹ́ ilé ìwé, àwọn alábáṣiṣẹ́pọ̀, awọn olórí ìgbàgbọ́, àti àwọn Ènìyàn mímọ́ ara wa.

Ninu Oṣù Karun 2020, àní bí aráyé ti njìjàkadì pẹ̀lú títànkiri àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé kan, àwọn ọmọ Àjọ Àwọn Olórí Ẹ̀sìn ní New York City pàdé lórí afẹ́fẹ́ ninu ìpàdé pàjáwìrì kan. Kò sí ètò-ìlànà. Kò sí àwọn àlejò pàtàkì. Ó kàn jẹ́ ìbéèrè kan láti wá papọ̀ kí a sì sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìpèníjà tí a nkojú bí olùdarí ẹ̀sìn. Ẹ̀ka fún Ṣíṣe Àkóso Àwọn Àrùn ti ṣẹ̀ṣẹ̀ ròhìn pé ìlú wa jẹ́ ẹpisẹ́ntà ti àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní Amẹ́ríkà. Èyí túmọ̀ sí pé kò sí ìpéjọpọ̀ mọ́. Kò sí wíwá papọ̀ mọ́.

Fún àwọn olórí ẹ̀sìn wọ̀nyí, yíyọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ara-ẹni kúrò, ìpéjọpọ̀ ti àwọn ọmọ-ìjọ, àti ìjọ́sìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́ fífẹ́ ìpanirun. Ẹgbẹ́ kékeré wa—ninu èyítí kádínà kan wà, awọn ẹni-ọ̀wọ̀, awọn rábì, awọn ìmáàmù, awọn olùṣọ́-àgùtàn, awọn oníṣẹ́-ìránṣẹ́, ati alàgbà kan—fetísílẹ sí, tùni-nínú, àti títi arawa lẹ́hìn. Dípò fífi ojú sùn sí orí àwọn ìyàtọ wa, a rí àwọn ohun tí ó wọ́pọ̀ síwa. A sọ̀rọ̀ nípa awọn ohun tó ṣeéṣe ati awọn ohun tí kò dájú láti ṣeéṣe. A fìmọ̀ ṣọ̀kan a sì dáhùn sí àwọn ìbéèré nípa ìgbàgbọ́ ati ọjọ́ iwájú. Àti nígbànáà a gbàdúrà. Áà, a ti gbàdúrà tó.

Nínu ìlú ànító oríṣiríṣi nkan tó kún pẹ̀lú ìṣòro àti àkọlù-kọgbà àwọn àṣà, a rí bí awọn ìyàtọ̀ wa ti nparẹ́ bí a ti wá papọ̀ bí ọ̀rẹ́ pẹ̀lú ohùn kan, èrò kan, àti àdúrà kan.

A kò wo ara wa mọ́ ni òdìkejì tábìlì ṣùgbọ́n sí ìhà ọ̀run pẹ̀lú ara wa. A kúrò ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpàdé ẹ̀hìnwá ní ìrẹ́pọ̀ síi àti ní síṣetán láti mú “àwọn ṣọ́bìrì” wa kí a sì lọ ṣiṣẹ́. Àjọṣepọ̀ tí ó yọrísí àti iṣẹ́-ìsìn tí ó jẹ́ ṣíṣe sí ẹgbẹgbẹ̀rùn àwọn ará New York kọ́mi pé ninu ayé tó npè fún ìyapa, jíjìnnà sí, àti àìbáraẹniṣe, ohun púpọ̀ ló wà nígbà-gbogbo tí ó sowápọ̀ ju tí ó yàwá lọ. Olùgbàlà bẹ̀bẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ ọ̀kan; bí ẹ̀yin kò bá sì jẹ́ ọ̀kan ẹ̀yin kìí ṣe tèmi.”

Ẹ̀yin arákùnrin ati arábìnrin, a gbọ́dọ̀ dáwọ́dúró ní wíwá àwọn ìdí láti pínyà kí a sì wá àwọn ànfààní láti “jẹ́ ọ̀kan.” Ó ti bùkún wa pẹ̀lu àwọn ẹ̀bùn àmúyẹ àrà ọ̀tọ̀ tó npe ẹ̀kọ́ kíkọ́ láti ọ̀dọ̀ ara wa àti ìdàgbàsókè ti ara-ẹni. Mo máa nfi ìgbà púpọ̀ sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ unifásítì mi pé bí mo bá nṣe ohun ti ìwọ nṣe àti tí ìwọ nṣe ohun ti èmi nṣe, a kò nílò ara wa. Ṣùgbọ́n nítorípé ìwọ kò ṣe ohun tí èmi nṣe tí èmi ko sì ṣe ohun tí ìwọ nṣe, a nílò ara wa. Àti pé ìnílò náà nmú wa papọ̀. Láti pín kí a sì ṣẹ́gun jẹ́ ètò ọ̀tá láti ba àwọn ìbáṣepọ̀, àwọn ẹbí, àti ìgbàgbọ́ jẹ́. Olùgbàlà ni ó nṣe ìrẹ́pọ̀.

Àwa Jẹ́ ti Òun

Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tí a ṣe ìlérí ti “dídi ọ̀kan” ni èrò orí kan tó lágbára ti jíjẹ́ ti ara kan. Alàgbà Quentin L. Cook kọ́ni pé “àkójá ti jíjẹ́ ti ara kan lódodo ni láti jẹ́ ọ̀kàn pẹ̀lú Krístì.”

Nínú àbẹ̀wò mi pẹ̀lú ẹbí mi láìpẹ́ yí sí orílẹ̀-èdè Ghana ni Ìwọ̀ Oòrùn Áfríkà, a gbé ohun kan wọ̀mi pẹ̀lú àṣà ìbílẹ̀ Bí a bá ti dé ilé ìjọsìn tàbí ibùgbé kan, wọ́n nkí wa pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ “ẹ kú àbọ̀.” Nigbàtí wọ́n bá gbé oúnjẹ kalẹ̀, onílé wa yío sọ pe, “Ẹ wá jẹun.” Àwọn ìkíni ìrọ̀rùn wọ̀nyí njẹ́ fífúni pẹ̀lú èrèdí àti jíjẹ́ àtinúwá. Ẹ kú àbọ̀. Ẹ wá jẹun.

A nfi àwọn ìkéde mímọ́ irúkannáà sí ara àwọn ìlẹ̀kùn ilé ìjọsìn wa. Ṣùgbọ́n àmì A Kí Ẹ̀yin Àlejò Káàbọ̀bọ̀ kò tó. Njẹ́ a nfi pẹ̀lú ọ̀yàyà kí gbogbo ẹnití o wá nípasẹ̀ àwọn ìlẹ̀kùn náà bi? Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, kò tó láti kàn jóko sínú àwọn ijoko. A gbọ́dọ̀ fetísí ìpè Olùgbàlà láti gbé àwọn ìbáṣepọ̀ gígajù àti mímọ́jù ga pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ wa! Baba mi máa nrán mi létí nígbà gbogbo pé jíjókòó lásán ninu ijoko ní Ọjọ́ Ìsinmi kò sọni di Krístíánì rere jù bí sísùn ninu gáréèjì kò ṣe lè sọni di káà kan.

A gbọ́dọ̀ gbé ìgbé ayé wa tóbẹ́ẹ̀ tí aráyé kò ní rí wa ṣùgbọ́n kí wọn rí Òun nipasẹ̀ wa. Èyí kìí wáyé ní àwọn Ọjọ́ Ìsinmi nìkan. Ó nwáyé ní ilé ìtajà, ni ibi epo ọkọ̀, ní ìpàdé ilé iwé, ní àpéjọ àdúgbò, ní gbogbo ibi tí àwọn ọmọlẹ́bí wa tí a ti rìbọmi àti tí a kò tíì rìbọmi ti nṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ngbé.

Mo njọsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi bíi ìránnilétí pé a nílò ara wa àti lápapọ̀ àwa nílò Rẹ̀. Àwọn àrà ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn ati tálẹ́ntì wa tó múwa yàtọ̀ ní ti ayé ṣe wá lọ́kan ni ibi àlàfo mímọ́ kan. Olùgbàlà ti ké si wa láti ran ara wa lọ́wọ́, gbé ara wa sókè, kí a sì mú ara wa dàgbàsókè. Èyí ni ohun tí Ó ṣe nígbàtí ó wo obìnrin onísun-ẹ̀jẹ̀ sàn, wẹ adẹ́tẹ̀ tó bẹ̀bẹ̀ fún àánú Rẹ̀ mọ́, gba ọ̀dọ́ ọmọ-ọba nímọ̀ràn ẹnití ó bèèrè ohun tí òun tún lè ṣe síi, fẹ́ràn Nikodémù ẹnití ó mọ̀ ṣùgbọ́n tí ó kọsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀, àti nígbàtí ó jókòó pẹ̀lú obìnrin náà ni ibi kànga ẹnití kò bá àṣà ìgbà náà mu ṣùgbọ́n ẹni tí Ó sọ fún nípa iṣẹ́ ti-mèssáyà Rẹ̀. Sí mi èyí ni ìjọ—ibi ìpéjọpọ̀ áti ìgbà-padà, àtúnṣe áti ìtẹ̀síwájú. Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni: Àwọ̀n ìhìnrere ni àwọ̀n títóbi jùlọ ní ayé. Ọlọ́run ti pe gbogbo ènìyàn láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. … Àyè wà fún gbogbo ènìyàn.”

Àwọn kan le ti ní àwọn írírí tí ó mú yín ní ìmọ̀lára pé ẹ kìí ṣe ara kan. Ọ̀rọ̀ Olùgbàlà sí ẹ̀yin àti èmí jẹ́ ìkannáà: “Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó ńṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.” Ìhìnrere Jésù Krístì ni ibi pípé fún wa. Wíwá sí ilé ìjọsìn nfúnni ní ìrètí àwọn ọjọ́ dídárajù, ìlérí pé ìwọ kò dá nìkan wà, àti ẹbí kan tí ó nílò wa púpọ̀ tó bí àwa náà ṣe nílò wọn. Alàgbà D. Todd Christofferson fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé “jíjẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́, láìsí iyèméjì ìgbẹ̀hìn ti jíjẹ́ ti ara kan.” Sí ẹnikẹ́ni tó ti gbésẹ̀ kúrò tí ó sì nlépa àyè láti padà, mo fúnni ní òtítọ́ ati ìpè ayérayé kan: Ẹ Wàpapọ̀. Ẹ padà wá. Àkokò ti tó.

Nínú ayé kìkì ìjà àti yíyapa kan, mo jẹ́ ẹ̀ri pé Olùgbàlà Jésù Krístì ni Olùrẹ́pọ̀ nlá náà. Njẹ́ kí npe ọ̀kọ̀ọ̀kan wa láti yẹ fún ìpè Olùgbàlà láti “jẹ́ ọ̀kan” àti láti sọ pẹ̀lú ìgboyà bí Òun ti ṣe pé, “Ẹ̀yin ni ọ̀rẹ́ mi.” Ní orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.