Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Ẹ Kíyèsi Èmi Ni Ìmọ́lẹ̀ Èyí Tí Ẹ̀yin Ó Máa Gbé Sókè”
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


“Ẹ Kíyèsi Èmi Ni Ìmọ́lẹ̀ Èyí Tí Ẹ̀yin Ó Máa Gbé Sókè”

A ngbé ìmọ́lẹ̀ Olúwa sókè nígbàtí a bá di àwọn májẹ̀mú wa mú daindain tí a sì nti wòlíì alààyè wa lẹ́hìn.

Sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀rí ní ìpàdé àpapọ̀, mo fi ẹ̀rí ti-àpóstélì mi kun pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run, Olúwa àti Olùgbàlà wa, Olùràpadà gbogbo àwọn ọmọ Baba wa. Nípa Ètùtù Rẹ̀, Jésù Krístì mu ṣeéṣe fún wa, bí a bá yẹ, láti padà sí ọ̀dọ̀ Baba wa ní Ọ̀run kí a sì wà pẹ̀lú àwọn ẹbí wa fún ayé àìlópin.

Olùgbàlà kò ṣe aláìsí nínú àwọn ìrìnàjò ayé-ikú wa. Fún ọjọ́ méjì tó kọjá a ti gbọ́ Ọ tí ó nsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn olórí Rẹ tí a yàn kí a lè fà súnmọ́ Ọ. Ní àkokò àti lẹ́ẹ̀kansi, pẹ̀lú ìfẹ́ àti àánú mímọ́ Rẹ̀, Ó ṣe ìmúdúró wa bí a ti ndojúkọ eré ìgbésí-ayé. Néfì ṣe àpèjúwe, “Ọlọ́run mi ti jẹ́ alátìlẹhìn mi, ó ti dárí mi nínú àwọn ìpọ́njú mi. … Ó ti kún inú mi pẹ̀lú ìfẹ́ .”

Ìfẹ́ náà hàn nígbàtí a bá ṣe ìmúdúró ara wa nínú iṣẹ́ Rẹ̀.

A nṣe ìmúdúró wòlíì alààyè wa ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, àti Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àti àwọn olóyè Ìjọ. Láti ṣe ìmúdúró túmọ̀ sí láti gbé ẹni míràn sókè, láti fún wọn ní àkíyèsí wa, láti jẹ́ olotitọ sí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn, láti ṣe ìṣe lórí àwọn ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n nsọ̀rọ̀ nípa ìmísí Olúwa; wọ́n ní ìmọ̀ àwọn ọ̀ràn lọ́wọ́lọ́wọ́, rírẹ̀hìn ìwà ti àwùjọ, àti ìtiraka ọ̀tá púpọ̀si láti tú ètò Baba ká. Ní gbígbé ọwọ́ wa sókè, à nfarajìn fún àtìlẹhìn wa, kìí ṣe fún àkokò náà lásán ṣùgbọ́n nínú ìgbésí ayé wa ojojúmọ́.

Ṣíṣe ìmúdúró pẹ̀lú gbígbé àwọn ààrẹ èèkan àti bíṣọ́ọ̀pù, àwọn olórí iyejú àti ìṣètò, àwọn olùkọ́ni, àní àti olùdarí ìpàgọ́ nínú àwọn wọ́ọ̀dù àti èèkan wa sókè. Ní sísúnmọ́ ju sí ilé, à ngbé àwọn ìyàwó àti ọkọ, ọmọ, òbí, ẹbí jíjìn, àti aladugbo wa sókè. Nígbàtí a bá gbé ara wa sókè ní wíwípé, “Èmi wà nihin fún yín, kìí ṣe láti gbé apá àti ọwọ́ sókè nìkàn nígbàtí wọ́n bá ní ‘ìdoríkodò’ ṣùgbọ́n láti jẹ́ olùtùnú àti alágbára kan ní ẹ̀gbẹ́ yín.”

Èrò láti gbé sókè ni ó ní gbòngbò nínú ìwé mímọ́. Ní ibi Omi ti Mọ́mọ́nì, àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìribọmi farajìn “láti gbé àjàgà ara wọn, kí wọ́n lè fúyẹ́; … [láti] tu àwọn tó nílò ìtùnú nínú, àti láti dúró bí àwọn ẹlẹri Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo, àti ní ibi gbogbo.”

Sí àwọn ará Néfì Jésù wípé: “Ẹ gbé ìmọ́lẹ̀ yín sókè kí ó lè tàn sí aráyé. Kíyèsi èmi ni ìmọ́lẹ̀ èyí tí ẹ̀yin ó máa gbé sókè.” A ngbé ìmọ́lẹ̀ Olúwa sókè nígbàtí a bá di àwọn májẹ̀mú wa mú daindain tí a sì nti wòlíì alààyè wa lẹ́hìn bí ó ti nsọ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Ààrẹ Russell M. Nelson, nígbàtí ó nsìn nínú iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá wípé, “Ṣíṣe ìmúdúró ti àwọn wòlíì jẹ́ ìfarajìn araẹni pé a ó ṣe dídára wa jùlọ láti gbé àwọn ààyò ti-wòlíì sókè.”

Láti gbé wòlíì sókè jẹ́ iṣẹ́ mímọ́. Àwà kò kàn joko jẹ́jẹ́ ṣùgbọ́n nínú aápọn láti dá ààbò bò ó, tẹ̀lé àmọ̀ràn rẹ̀, kọ́ni ní àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí a sì gbàdúrà fún un.

Ọba Benjamin, nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, wí fún àwọn ènìyàn náà, “Èmi dàbí yín, ẹnití ó ní onírurú àìlera nínú ara àti ẹ̀mí; síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn yí ti yàn mí … a sì gbà fun un nípa ọwọ́ Olúwa … a sì ti fi mí sí ìtọ́jú àti ìpamọ́ nípa agbára àìlẹ̀gbẹ́ rẹ̀, láti sìn pẹ̀lú gbogbo agbára, ìyè àti ipá tí Olúwa ti fún mi.”

Gbígbé ọwọ́ Mósè sókè.

Bákannáà, ní ọjọ́ orí ọgọrun, Ààrẹ Nelson ni a ti pamọ́ tí ó sì ti wà ní ààbò nípasẹ̀ Olúwa. Ààrẹ Harold B. Lee, ní àkokò tí ó jẹ́ ọmọ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, kọ àpẹrẹ Mósè tí ó dúró ní orí òkè ní Rephidim. “Ọwọ́ [Ààrẹ Ìjọ] lè di rírẹ̀,” ni ó wí. “Wọ́n lè fẹ́ wálẹ̀ nígbàmíràn nítorí ti àwọn ojúṣe rẹ̀ wíwúwo; ṣùgbọ́n bí a ti ngbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, àti bí a ti ndarí lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀, ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ilẹ̀kún ọ̀run-àpáàdì kò ní borí yín àti orí Ísráẹ́lì. Ààbò yín àti tiwa dálé orí bóyá tàbí a kò ní tẹ̀lé àwọn wọnnì tí Olúwa ti fi síbẹ̀ láti ṣe àkóso lórí Ìjọ Rẹ̀. Ó mọ ẹnití Ó nfẹ́ kí ó ṣe àkóso lórí Ìjọ yí, Òun kò sí ní ṣe àṣìṣe rárá.”

Ààrẹ Nelson nmú láti inú àwọn ọdún ti sísin Olúwa. Dídàgbà rẹ̀, oríṣiríṣí ìrírí jákèjádò, ọgbọ́n, àti gbígba ìfihàn lemọ́lemọ́ ni ó dára nípàtàkì fún ọjọ́ wa. Ó ti wípé: “Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nmúra ayé sílẹ̀ fún ọjọ́ náà nígbàtí ‘ayé yíò kún fún ìmọ̀ Olúwa’ (Isaiah 11:9). … Iṣẹ́ yí ni a fún lágbára nípa ìkéde tọ̀run tí a ṣe ní igba ọdún sẹ́hìn. Ó ní àwọn ọ̀rọ̀ méje péré nínú: ‘Èyí Ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!’ (wo Ìwé-ìtàn—Joseph Smith 1:17).”

Ààrẹ Nelson bákannáà wípé: “Kò tíì sí àkókò kan láé nínú ìtàn àgbáyé nígbàtí ìmọ̀ Olùgbàlà wa jẹ́ kókó àti wíwúlò ti ara-ẹni sí gbogbo ọkàn ènìyàn. Ẹ fi ojú inú wòó kíákíá bí àwọn ìjà bíbanilẹ́rù káàkiri àgbáyé—àti àwọn wọnnì nínú ìgbé ayé olukúlùkù wa—yío ti jẹ́ yíyanjú bí ẹni gbogbo bá yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì tí wọ́n sì gbọ́ràn sí àwọn ìkọ́ni Rẹ̀.”

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, a nílò láti ṣe gbígbéga púpọ̀ sí kí a sì dín kíkùnsínu kù, gbígbé ọ̀rọ̀ Olúwa sókè síi, àwọn ọ̀nà Rẹ̀, àti wòlíì Rẹ̀, ẹnití ó ti wípé: “Ọ̀kan lára àwọn ìpènijà títóbijùlọ ní òní ni ìyàtọ̀ ní àárín òtítọ́ Ọlọ́run àti ayédèrú Sátánì. Ìyẹn ni ìdí tí Olúwa fi kìlọ̀ fún wa láti ‘gbàdúrà nígbàgbogbo, … ki [a] lè borí Sátánì, àti … kí a bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Sátánì tí ó ndi iṣẹ́ [ọ̀tá] mú’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 10:5; àfikún àtẹnumọ́].”

Títún Tẹ́mpìlì Manti Utah Yàsímímọ́.

Ní Oṣù Kẹ́rin tó kọjá, Arábìnrin Rasband àti èmi ní ìbu-ọlá-fún ti dídarapọ̀mọ́ àyànfẹ́ wòlíì wa àti Arábìnrin Nelson fún àtún-yàsímímọ́ ti Tẹ́mpìlì Manti Utah.

Ààrẹ Nelson ya gbogbo àwọn tí wọ́n wọnú yàrá náà lẹ́nu. Ìba díẹ̀ lára wa gan ni ó mọ̀ pé ó nbọ̀. Ní iwájú rẹ̀, mo ní ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ àti agbára ti-wòlíì tí ó ní lọ́gán. Ìwò ayọ̀ ní ojú àwọn ènìyàn ní rírí wòlíì yíò wà pẹ̀lú mi títíláé.

Nínú àdúra àtún-yàsímímọ́ náà, Ààrẹ Nelson bẹ Olúwa pé ilé mímọ́ Rẹ̀ yíò gbé gbogbo ẹni tí ó bá wọnú tẹ́mpìlì náà sókè “kí wọ́n lè gba àwọn ìbùkún mímọ́ kí wọ́n sì dúró ní yíyẹ àti olotitọ sí àwọn májẹ̀mú wọn … kí èyí lè jẹ́ ilé àláfíà, ilé ìtùnú, àti ilé ìfihàn araẹni fún gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá wọ inú ìlẹ̀kùn wọ̀nyí ní yíyẹ.”

Gbogbo wa ni a nílò láti di gbígbé ga nípasẹ̀ Olúwa pẹ̀lú àláfíà, ìtùnú, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ pẹ̀lú ìfihàn araẹni láti dojúkọ ẹ̀rù, òkùnkùn, àti ìjà tí ó nyí ayé ká.

Ṣíwájú ìsìn náà, a dúró níta nínú òòrùn pẹ̀lú Ààrẹ àti Arábìnrin Nelson láti wo ìgbékalẹ̀ rírẹwà náà. Àwọn babanlá Ààrẹ Nelson ní ìrọ́mọ́ sí agbègbè náà tí ó lọ jìnlẹ̀jinlẹ̀. Ìyá-ìyá àwọn òbí rẹ̀ kẹ́jọ tẹ̀dó sí àwọn àfonífojì ti ó yí tẹ́mpìlì náà ká, bíi ti àwọn kan ti tèmi. Baba-baba mi Andrew Anderson sìn nínú ìkọ̀ akọ́lé ti àwọn olùlànà ìṣíwájú tí wọ́n ṣiṣẹ́ fún ọdún mọ́kànlá láti parí tẹ́mpìlì Manti, ìkẹ́ta ní àwọn Òkè Àpáta.

Bí a ti dúró pẹ̀lú Ààrẹ Nelson, a ní ànfàní láti gbésókè kí a sì ti wòlíì Ọlọ́run lẹ́hìn ní ṣíṣe ayẹyẹ àtún-yàsímímọ́ ti ilé mímọ́ Olúwa náà. Ó jẹ́ ọjọ́ tí èmi kò lè gbàgbé láéláé.

“A nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì láti bu-ọlá fún Olúwa,” ni Ààrẹ Nelson wí ní ọjọ́ mímọ́ náà. “À nkọ́ wọn fún ìjọsìn àti pé kìí ṣe fún fífihàn. A ndá àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí pàtàkì rẹ̀ jẹ́ ti ayérayé nínú àwọn ògiri mímọ́ wọ̀nyí.” À nkó Ísráẹ́lì jọ.

Ààrẹ Nelson àti àwọn wòlíì ṣíwájú rẹ̀ ti gbé-ìtẹ́ àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ sí ọwọ́ wọn. Ní òní, ní àyíká ayé, a ní àwọn ilé mímọ́ Olúwa àádọ́ta-dín-ní-irínwó tí ó nṣiṣẹ́, tí a kéde, tàbí tí ó wà lábẹ́ kíkọ́. Bíi wòlíì, láti 2018, Ààrẹ Nelson ti kéde àwọn tẹ́mpìlì ọgọ́run kan ati méjìdínláádọ́rin.

“Ní àkokò wa,” ó ti wípé, “ìdàpọ̀ odidi, àṣepé, àti pípé ti gbogbo iṣẹ́ ìríjú, àwọn kọ́kọ́rọ́, àti agbára ni a ó wé papọ̀(wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 128:18). Fún àwọn èrò mímọ́ wọ̀nyí, àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ nkáàkiri ilẹ̀ ayé nísisìyí. Mo tẹnumọ pé kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì wọ̀nyí lè má yí ayé yín padà, ṣùgbọ́n iṣẹ́-ìsìn yín nínú tẹ́mpìlì yíò ṣeé dájúdájú.”

“Olùgbàlà àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀ ni ọkàn tẹ́mpìlì gangan,” ni Ààrẹ wí. “Ohun gbogbo tí a nkọ́ni ní tẹ́mpìlì, nípasẹ̀ ìkọ́ni àti nípasẹ̀ Ẹmí, nmú òye wa nípa Jésù Krístì pọ̀ síi. Àwọn ìlànà pàtàkì Rẹ̀ nso wá mọ́ Ọ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́ oye-àlùfáà. Nígbànáà, bí a ti npa májẹ̀mú wa mọ́, Ó nfún wa ní ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára wíwòsàn, ìfunnilókun Rẹ̀.”

“Gbogbo àwọn ẹnití wọ́n bá njọ́sìn nínú tẹ́mpìlì,” Ààrẹ Nelson wípé, “wọn yíò ní agbára Ọlọ́run àti àwọn ángẹ́lì tí wọ́n nní ‘àṣẹ lórí wọn’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109:22]. Báwo ni ó ṣe nmú ìgbẹ́kẹ̀lé yín pọ̀si sí láti mọ̀ pé, bí obìnrin tàbí ọkùnrin tó ní ẹ̀bùn tẹ́mpìlì tí a dìhámọ́ra fún pẹ̀lú agbára Ọlọ́run, ẹ kò ní láti dá nìkan kojú ìgbésí ayé? Kíni ìgboyà tí ó nfún yín láti mọ̀ pé àwọn ángẹ́lì yíò ràn yín lọ́wọ́ lódodo?”

Àwọn ángẹ́lì tí wọ́n nnawọ́ jáde láti gbé sókè ni a júwe nínú àwọn ìwé mímọ́ nígbàtí Jésù Krístì kúnlẹ̀ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ nínú Ọgbà Gẹ́thsémánè. Nípa ìjìyà Rẹ̀ Ó pèsè Ètùtù àìlópin kan. “Níbẹ̀,” Ààrẹ Nelson wípé, “ìṣe ìfẹ́ kanṣoṣo títóbijùlọ nínú gbogbo àkọọ́lẹ-ìtàn èyí tí a ṣe àkọsílẹ̀ pé ó ṣẹlẹ̀. … Níbẹ̀ ní Gẹ́thsémánè, Olúwa ‘jìyà ìrora gbogbo ènìyàn, kí gbogbo ènìyàn … le ronúpìwàdà kí wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 18:11].”

“Mú ago yí kúro lọ́dọ̀ mi,” Jésù Krístì bèèrè, “bíótilẹ̀rí bẹ́ẹ̀ kìí ṣe ìfẹ́ mi, ṣugbọ́n tìrẹ ni ká ṣe.

“Ángẹ́lì kan si yọ sí i láti ọ̀run wá, ó nfún un lókun.”

A ní àwọn ángẹ́lì ní àyíká wa ní òní. Ààrẹ Nelson ti wípé, “[Nínú tẹ́mpìlì,] ẹ ó kọ́ bí ẹ ó ti pín ìkelè níyà ní àárín ọ̀run àti ayé, bí ẹ ó ti bèèrè fún àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run láti bojú tó yín.”

Àwọn ángẹ́lì nmú ìmọ́lẹ̀ wá. Ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run. Sí àwọn Àpóstélì Rẹ̀ ará Néfì, Jésù Wípé, “Ẹ kíyèsi èmi ni ìmọ́lẹ̀ èyí tí fyin ó máa gbé sókè.” Bí a ti nṣe ìmúdúró wòlíì wa, a jẹri pé a pèé nípasẹ̀ Olùgbàlà wa, ẹnití ó “jẹ́ ìmọ́lẹ̀ … ti ayé.”

Ààrẹ Nelson, ní ìtìlẹhìn àwọn ọmọ-ìjọ àti ọ̀rẹ́ Ìjọ, a di alábùkún-fún láti gbé àwọn ìkọ́ni rẹ sókè, láti gbé àpẹrẹ rẹ ti gbígbé bíi ti Krístì, àti láti gbé ẹ̀rí onítara rẹ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa, Olùràpàdà gbogbo wa sókè.

Mo jẹ́ ẹ̀ri ti-àpóstélì mi pé Jésù Krístì ni “ìmọ́lẹ̀ … ti ayé.” Njẹ́ kí gbogbo wa, bí ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, “gbé ìmọ́lẹ̀” Rẹ̀ sókè. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.