Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Èyí Ni Ìhìnrere Mi”—“Èyí Ni Ìjọ Mi”
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


13:49

“Èyí Ni Ìhìnrere Mi”—“Èyí Ni Ìjọ Mi”

Èyí ni ìhìnrere Olùgbàlà, èyí sì ni Ìjọ Rẹ̀ (wo 3 Nefi 27:21; Mosiah 26:22; 27:13). Àpapọ̀ ti àwọn ẹméjì mú ẹtù alágbára líla òkúta wà ní yíyípadà.

Fún àwọn Sẹ́ntúrì, ẹtù dúdú jẹ́ ohun ìjà alágbára títóbijùlọ tí ó wà. Ó lè ju àwọn bọ́ọ̀lù ìbọn-nlá, ṣùgbọ́n kò múnádóko fún púpọ̀ jùlọ ìwakùsà àti àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé òpópónà. Ó jẹ́ àìlera jù láti fọ́ òkúta yányán.

Ní 1846 oníwòsàn ará Italy kan tí a pè ní Ascanio Sobrero ṣe ẹtù titun kan, ẹtù-elépo tó npani. Elépo ṣíṣàn yí ni ó kéréjù ẹgbẹ̀rún àwọn ìgbà tó lágbára ju páúdà dúdú lọ. Ó lè fọ́ òkútà yányán. Ní àìdára, ẹtù-elépo tó npani kò dúró-déédé. Bí ẹ bá jùú sílẹ̀ láti ibi gíga díẹ̀, yíò ti gbiná sókè. Bí ó bá ti gbóná jù, yíò gbiná sókè. Bí ó bá ti tutù jù, yíò gbiná sókè. Àní kí a gbe sí ibi tútù, yàrá ṣíṣókùnkùn tí a dánìkàn fisílẹ̀, yíò gbiná sókè nígbẹ̀hìn. Àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀jùlọ gbẹ́sẹ̀lé ìkónilọ rẹ̀, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbẹ́sẹ̀lé ṣíṣe lọ́pọ̀ rẹ̀.

Ní 1860 amòye sáyẹ́nsì ará Sweden kan tí a pè ní Alfred Nobel bẹ̀rẹ̀ sí gbìyànjú láti ṣé ìmúdúró ẹtù-elépo tó npani. Lẹ́hìn ọdún méje ti ṣíṣe àyẹ̀wò, ó ṣe àṣeyọrí ibi-afẹ́dé rẹ̀ nípa fífa ẹtù-elépo tó npani sínú ohun-èlò tí ó fẹ́rẹ̀ má níye tí a mọ̀ sí ilẹ́-ayé diatomásíọ́sì tàbí kíẹ́sígọ̀. Kíẹ́sígọ̀ ni òkúta tí ó ní ohun-èlò tí ó lè ṣísílẹ̀ sínú páúdà dídára. Nígbàtí a bá ròó mọ́ ẹtù-elépo tó npani, Kíẹ́sígọ̀ ngba ẹtù-elépo tó npani mọ́ra, àti lílẹ̀ àbájáde tí a lè fi ṣápẹrẹ sínú “àwọn igi.” Nínú fọ́ọ̀mù yí, ẹtù-elépo tó npani ni ó ní ìmúdúró púpọ̀ si. Ó lè di fífi pamọ́, kíkónilọ, àti lílò pẹ̀lú àìdínkù agbára ẹtù láìléwu. Nobel dárúkọ àpapọ̀ ẹtù-elépo tó npani àti kíẹ́sígọ̀ “ẹtù alágbára líla òkúta.”

Ẹtù alágbára líla òkúta nyí ayé padà. Bákannáà ó mú Nobel di ọlọ́rọ̀. Láìsí ìmúdúró, ẹtù-elépo tó npani kàn jẹ́ olóró púpọ̀ láti di oníyelórí lọ́pọ̀lọpọ̀, bí Ascanio Sobrero ti ṣé àwárí. Nípa ararẹ̀, bí mo ti sọ, kíẹ́sígọ̀, jẹ́ oníye kékeré. Ṣùgbọ́n àpapọ̀ ti àwọn ẹ̀yà méjì mú ẹtù alágbára líla òkúta wà ní yíyípadà.

Ní irú ọ̀nà kannáà, àpapọ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì àti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn npèsè àwọn èrè ìyípadà àti alágbára fún wa. Ìhìnrere jẹ́ pípé, ṣùgbọ́n ìjọ àtọ̀runwá tí a yàn ni a nílò láti wàásù rẹ̀, mú wíwà ní mímọ́ rẹ̀ dúró, kí a sì ṣe ìpínfúnni àwọn ìlànà mímọ́ pẹ̀lú àṣẹ Olùgbàlà.

Ẹ yẹ àpapọ̀ ìhìnrere Olùgbàlà wò àti Ìjọ Rẹ̀ bí a ti gbekalẹ̀ nípasẹ̀ wólíì Álmà Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ìjọ náà ni ó dúró fún wíwàásù pé “kò sí ohun kan bíkòṣe ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ lórí Olúwa, ẹnití [yíò ra] àwọn ènìyàn rẹ̀ padà.” Lílo àṣẹ Ọlọ́run, Ìjọ ní ojúṣe fún ìpínfúnni ìlànà ìrìbọmi “ní orúkọ Olúwa, bí ajẹri [ti wíwọ] inú májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ̀ [láti] sìn Ín àti láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.” Àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣe ìrìbọmi gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí ara wọn, darapọ̀ mọ́ Ìjọ Rẹ̀, a sì ṣe ìlérí agbára nlá nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ ti Ẹ̀mí.

Àwọn ènìyàn nrọ́ lọ sí ibi omi Mọ́mọ́nì láti gbọ́ ìwàásù ìhìnrere Álmà. Bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n fi ọ̀wọ́ fún àwọn omi wọnnì àti aginjù tó yí wọn ká, Ìjọ Olúwa kìí ṣe ibi tàbí ilé kan, tàbí bẹ́ẹ̀náà ní òní. Ìjọ kàn jẹ́ àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ, ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, tí a kójọ tí a ṣètò sínú ìlànà yíyàn tọ̀run tí ó nran Olúwa lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyege àwọn èrèdí Rẹ̀. Ìjọ ni ohun èlò nípasẹ̀ èyí tí à nkọ ẹ̀kọ́ àárín-gbùngbun ojúṣe Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ nínú ètò Baba Ọ̀run. Ìjọ fúnni ní ọ̀nà ti-àṣẹ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láti kópa nínú àwọn ìlànà kí wọ́n sì dá àwọn májẹ̀mú pípẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Pípa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́ nfá wá súnmọ́ Ọlọ́run, nfún wa ní àyè sí agbára Rẹ̀, ó sì nyí wa padà sí ẹni tí Ó fẹ́ kí a dà.

Gẹ́gẹ́ bí ẹtù alágbára líla òkúta láìsí ẹtù-elépo tó npani kò ṣe jẹ́ olókìkí, Ìjọ Olùgbàlà jẹ́ ọ̀kanṣoṣo pàtàkì bí a bá kọ lé ìhìnrere Rẹ̀. Láìsí ìhìnrere Olùgbàlà àti àṣẹ láti ṣe ìpínfúnni àwọn ìlànà níbẹ̀, Ìjọ kìí ṣe yíyàtọ̀.

Láìsí ipa ìmúdúró ti kíẹ́sígọ̀, ẹtù-elépo tó npani ní òpin iye bíiti ẹtù kan. Bí ìwé-ìtàn ti fihàn, láìsí Ìjọ Olúwa, lílóye ti ẹ̀dá nípa ìhìnrere Rẹ̀ bákannáà kò lè dúró—ní ìtẹ́sí sí yíyíkúrò ẹ̀kọ́ àti kókó-ọ̀rọ̀ sí ipá àwọn ẹ̀sìn, ọ̀làjú, àti ọgbọ́n-ímọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìdàlù ti àwọn ipá wọnnì ni ó ti farahàn nínú gbogbo àkokò iṣẹ́-ìríjú tí ó ndarí lọ sí èyí tí ó kẹ́hìn. Bíótilẹ̀jẹ́pé ìhìnrere ni a fihàn ṣíwájú nínú ìwà-mímọ́ rẹ̀, ìtumọ̀ àti lílo ìhìnrere náà díẹ̀díẹ̀ gba àwòrán ìwà-bí-ọlọ́run tí ó sọ agbára nù nítorítí kò sí ìlànà tí ó ní àṣẹ àtọ̀runwá.

Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn fi àyè ìlèṣè sí agbára Ọlọ́run nítorí ó jẹ́ àṣẹ nípasẹ̀ Rẹ̀ láti kọ́ ẹ̀kọ́ Krístì àti láti fi ìhìnrere ìgbàlà àti àwọn ìlànà ìgbéga fúnni pẹ̀lú. Olùgbàlà nfi tọkàntọkàn dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jì wa, nrànwálọ́wọ́ láti ní àyè sí agbára Rẹ̀, àti láti yí wa padà. Ó jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ó sì nfẹ́ láti dáríjì wa kúrò nínú ìjìyà tí àwa ìbá tí lẹ́tọ́ sí. Ó nfẹ́ kí a di mímọ́ kí a sì di pípé nínú Rẹ̀.

Jésù Krístì ní agbára láti ṣe èyí. Òun kò kàn bá wa kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn àìpé wa kí ó sì pohùnréré ìdálẹ́bi ayérayé wa nínú àbájáde ẹ̀ṣẹ̀. Rárá, Ó lọ kọjá ìyẹn, ní àìlópin kọjá òyẹn, ó sì mú Ìjọ Rẹ̀ padàsípò láti lè ní àyè sí agbára Rẹ̀.

Kókó ìhìnrere tí Ìjọ nkọni ni pé Jésù Krístì gbé “ìbànújẹ́ wa, ó sì gbé àwọn ìkorò wa.” Òun ni a “gbé ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé lórí.” Ó “farada agbelebu,” ó já “ìdè ikú,” “ó gòkè re ọ̀run, ó sì … joko ní ọwọ́ ọtún Ọlọ́run, láti gba ẹ̀tọ́ àánú rẹ̀ lọ́wọ́ Baba.” Olùgbàlà ṣe gbogbo èyí nítorí Ó fẹ́ràn Baba Rẹ̀ Ó sì fẹ́ràn wa. Ó ti san oye àìlópin kí Òun lè “[gba] gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ [kí ó sì ṣe àgbàwí]” fún wọn—fún wa. Jésù Krístì kò fẹ́ ohunkankan ju fún wa láti ronúpìwàdà kí a sì wá sọ̀dọ̀ Rẹ̀ kí Òun lè dáláre kí Ó sì yá wá sí mímọ́. Nínú ìfẹ́-inú yí, Ó sì jẹ́ àìsimi àti àìmikàn.

Àyè sí agbára ti-májẹ̀mú Ọlọ́run àti ìfẹ́ ti-májẹ̀mú Rẹ̀ wà nípasẹ̀ Ìjọ Rẹ̀. Àpapọ̀ ìhìnrere Olùgbàlà àti Ìjọ Rẹ̀ nyí ìgbésí-ayé wa padà. Ó yí àwọn òbí àgbà tí apá ìyá mi padà. Baba mi àgbà, Oskar Andersson, ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ọkọ̀ ojú-omi lórí Högmarsö, erékùṣù kan ní Stockholm archipelago. Ìyàwó Rẹ̀, Albertina, àti àwọn ọmọ wọn gbé lórí òkè-odò Swedish. Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ní ọ̀sẹ̀ méjì-méjì, ní Sátidé, Oskar yí ọkọ-ojú omi rẹ̀ lọ sílé fún òpin-ọ̀sẹ̀ ṣíwájú pípadà lọ sí Högmarsö ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́-ìsinmi. Níjọ́ kan, nígbàtí ó wà ní Högmarsö, ó gbọ́ tí àwọn òjíṣẹ́-ìhìnrere Amẹ́ríkà méjì nwàásù ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì. Oskar ní ìmọ̀lára pé ohun tí òun gbọ́ ni òtítọ́ kedere, ó sì kún fún ayọ̀ àìlèsọ.

Ní àkokó míràn tí ó padà wálé, Oskar fi inúdídùn wí ohun gbogbo fún Albertina nípa àwọn òjíṣẹ́-ìhìnrere. Ó ṣe àlàyé pé òun gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n kọ́ni. Ó ní kí ó ka àwọn ìwé-pelebe tí àwọn òjíṣẹ́-ìhìnrere ti fi fún òun; ó sì wí fún un pé òun kò rò pé eyikeyi lára ọmọ wọn níjọ́ iwájú níláti ṣe ìrìbọmi bí àwọn ọmọdé. Albertina ní ìrunú ó sì ju àwọn ìwé-pelebe náà sórí ebè ìdọ̀tí. A kò sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ ní àárín wọn ṣíwájú kí Oskar tó padà fún iṣẹ́ ní ìrọ̀lẹ̀ Ọjọ́-ìsìnmi.

Ní àìpẹ́ bí ó ti lọ, Albertina yọ àwọn ìwé-pelebe náà kúrò. Ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣe àfiwé ẹ̀kọ́ wọn pẹ̀lú àwọn ìkọ́ni nínú Bíbélì rẹ̀ tó ti gbó gidi. Ó yàá lẹ́nu láti ní ìmọ̀lára pé ohun tí òun kà jẹ́ òtítọ́. Ní àkokó míràn tí Oskar padà wálé, ó gbá ìkíni-káàbọ̀ ìyárí kan, bí Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti ó mu wá pẹ̀lú rẹ ti ṣe. Albertina fi ìtara kàá, lẹ́ẹ̀kansi ó fi wé ẹ̀kọ́ sí èyí tí ó wà nínú Bíbélì rẹ̀. Bíi ti Oskar, ó da òtítọ́ kedere mọ̀ tí ó sì kún fún àyọ̀ àìlèjúwe.

Oskar, Albertina, àti àwọn ọmọ wọn lọ sí Högmarsö láti súnmọ́ díẹ̀ lára àwọn ọmọ Ìjọ níbẹ̀. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́hìn tí Oskar àti Albertina ṣe ìrìbọmi ní 1916, Oskar ni a pè láti jẹ́ olórí ẹgbẹ fún Högmarsö. Bíi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùyípadà titun, Oskar àti Albertina dojúkọ ọ̀fíntótó nítorí ìgbàgbọ́ titun wọn. Àwọn àgbẹ̀ ìbílẹ̀ kọ̀ láti ta mílíkì fún wọn, nítorínáà Oskar yí lọ sọdá fjord lojojúmọ́ láti ra mílíkì láti ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ tí ó ní àmúmọ́ra jù.

Síbẹ̀ ní àwọn ọdún tó tẹ̀le, oye àwọn ọmọ Ìjọ ní Högmarsö pọ̀si, ní apákan nítorí ti ẹ̀rí alágbára Albertina àti okun gbígbóná ti òjíṣẹ́-ìhìnrere. Nígbàtí ẹgbẹ́ náà di ẹ̀ká kan, Oskar ni a pè bí ààrẹ ẹ̀ka.

Àwọn ọmọ ìjọ ti ẹ̀ká Högmarsö fi ọ̀wọ̀ fún erékùṣù náà. Èyí ni Omi ti Mọ́mọ́nì wọn. Èyí ni ibití wọn wá láti ní ìmọ̀ nípa Olùràpadà wọn.

Ní àwọn ọdún sẹ́hìn, bí wọ́n ṣe npa májẹ̀mú ìrìbọmi mọ́, Oskar àti Albertina ni a yípadà nípasẹ̀ agbára Jésù Krístì. Wọ́n nfẹ́ láti dá àwọn májẹ̀mú si kí wọ́n sì gba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì. Láti gba àwọn ìbùkún wọnnì, wọ́n kólọ̀ pẹ́ títí láti ilé wọn ní Sweden sí Ìlú Salt Lake ní 1949. Oskar ti sìn bí olórí àwọn ọmọ ìjọ ní Högmarsö fún ọdún métàlélọ́gbọ́n.

Àpapọ̀ ti ẹtù-elépo tó npani àti kíẹ́sígọ̀ mú ẹtù alágbára lila òkúta ní iye lórí; àpapọ̀ ìhìnrere Jésù Krístì àti Ìjọ Rẹ̀ ni ó kọjá oye. Oskar àti Albertina gbọ́ nípa ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere nítorí wòlíì Ọlọ́run kan ti pè, yàn, àti àwọn òjíṣẹ́-ìhìnrere tí a rán lọ Sweden. Nípa ìfilọ́lẹ̀ àtọ̀runwá, àwọn òjíṣẹ́-ìhìnrere kọ́ni ní ẹ̀kọ́ Krístì àti nípa àṣẹ oyè-àlùfáà wọ́n ṣe ìrìbọmi Oskar àti Albertina. Bí àwọn ọmọ ìjọ, Oskar àti Albertina ti tẹramọ́ kíkọ́ ẹ̀kọ́, gbígbèrú, àti sísin àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n di Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nítorí wọ́n pa àwọn Májẹ́mú tí wọ́n dá mọ́.

Olùgbàlà tọ́ka sí Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bí “Ìjọ mi” nítorí Ó ti fi lọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá láti ṣe àṣeyege àwọn èrèdí Rẹ̀—ní wíwàásù ìhìnrere Rẹ̀, fífúnni ní àwọn ìlànà àti májẹ̀mú Rẹ̀, àti pé mímu ṣeéṣe fún agbára Rẹ̀ láti dáláre àti láti yà wá sí mímọ́. Láìsí Ìjọ Rẹ̀, kò sí àṣẹ kankan, kò sí ìwàásù àwọn òtítọ́ tí a fihàn ní orúkọ Rẹ̀, kò sí àwọn ìlànà tàbí májẹ̀mú, kò sí ìfihàn agbára ti ìwà-bí-ọlọ́run, kò sí ìyípadà sínú ẹnití Ọlọ́run nfẹ́ kí a dà, àti pé ètò Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀ ni ó di asán. Ìjọ náà ní àkokò iṣẹ́-ìríjú yí jẹ́ ìṣepọ̀ sí ètò Rẹ.

Mo pè yín láti fi ara yín jìn ní kíkún sí Olùgbàlà, ìhìnrere Rẹ̀, àti Ìjọ Rẹ̀. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó ríi pé àpapọ̀ ìhìnrere Olùgbàlà àti Ìjọ Rẹ̀ nmú agbára wá sínú ayé yín. Agbára yí ni ó tobi gan an ju ẹtù alágbára líla òkúta. Yíò fọ́ àwọn òkúta yányán ní ọ̀nà yín, yíò sì yí yín padà sí ajogún nínú ìjọba Ọlọ́run. “Ẹ ó sì kún fún ayọ̀ nnì èyítí ẹnu kò lè sọ àti tí ó kún fún ògo.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Agbára dúdú ni ápòpọ̀ potassium nitrate (saltpeter), sọ́lfọ̀, àti èédú charcoal. A kàá sí bíi ẹtù kékeré tàbí ẹtù èso-kékeré nítorí ti ìwọ̀n ìpínsíwẹ́wẹ́ díẹ̀díẹ̀ rẹ̀, tí ó njóná ní ìyára ìbámu. Àwọn ẹtù gíga tàbí ẹtù èso-gíga ntúká ju jíjóná, ní mímú gbígbọ̀n ìjì gíga.

  2. Ẹ̀tù alágbára líla òkúta ní fífi àyè gba “ìrusókè àìmúra ní ìṣẹ̀dá ọ̀nà àjà-ilẹ̀ ojú-irin, àwọn ètò kòtò ìdọ̀tí, àti alájà-ilẹ̀ yíká ayé—kókó àwọn iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ìbá ti májẹ́ kó ṣeéṣe láti [ṣe àṣeyọrí] láìsí àkóso àwọn ẹtù tí ẹtù alágbára líla òkúta [tí ó fi àyè gbà]. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ààmì iṣẹ́-ẹ̀rọ [ìparí àwọ sẹ́ntúrì 19th àti early 20th]— Abẹ́lẹ̀ Afárá London, ní Brooklyn, the Transcontinental Railroad, [àti] kànàlì Panamal—gbáralé ẹ̀tù pípani titun” (Steven Johnson, The Infernal Machine: A True Story of Dynamite, Terror, and the Rise of the Modern Detective [2024], 24).

  3. Nítorí ẹ̀tù-elépo tó npani fúnrarẹ̀ kì ṣe rírí lọ́pọ̀lọpọ̀, scanio Sobrero kò di ọlọ́rọ̀ nítorí ohun tí ó ṣe. Nígbàtí Alfred Nobel kọ́ ilé-iṣẹ́ ẹtù alágbára líla òkúta ní Avigliana, Italy ní 1873, Sobrero ni a yàn bí olùdámọ̀ràn tí a sanwó dáadáa fún láti ṣe ìdámọ̀ àti ìjẹ́wọ́ rẹ̀ bí olùwádí ti ẹtù-elépo tó npani. Sobrero di iṣẹ́rẹ̀ mú títí di ikú rẹ̀ ní 1888. (Wo G. I. Brown, The Big Bang: A History of Explosives [1998], 106.)

  4. Fún àkọọ́lẹ̀ páúdà dúdú, ẹtù-elépo tó npani, àti ẹtù alágbára tó npani, wo Brown, The Big Bang, 1–121.

  5. Ìhìnrere Jésù Krístì wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Krístì.

  6. Wo Mosiah 18:7, 20; 25:15, 22.

  7. Mòsíàh 18:10.

  8. Wo 2 Néfì 31:13.

  9. Wo Mosiah 18:17; 25:18, 23; Alma 4:4–5; Helaman 3:24–26; 3 Nephi 28:18, 23.

  10. Wo 2 Néfì 31:12-14; Mòsíàh 18:10.

  11. Ìjọ ni kókó sí fífi àwọn májẹ̀mú mímọ́ fún àwọn ọmọ Baba Ọ̀run. Èyí ni ìdí, tí àwọn ọmọ ìjọ fi ndá májẹ̀mú láti pa òfin ìyàsọ́tọ̀ mọ́, ní ìgbà ìfúnni ní ẹ̀bùn tẹ́mpìlì. Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n “fi àkokò, tálẹ́ntì, àti ohungbogbo pẹ̀lú èyí tí Olúwa ti bùkún wọn láti gbé Ìjọ Jésù Krístì ga lórí ilẹ̀ ayé” (Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìng nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 27.2, Ibi-ìkàwé Ìnìnrere).

  12. Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti Ẹ̀mí,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2019, 77.

  13. Wo Mosiah 18:22; Moses 6:68; Atọ́nà sí àwọn Ìwé-mímọ́, “Àwọn Ọmọkùnrin àti Ọmọbìnrin Ọlọ́run,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  14. Wo 3 Néfì 27:13–21.

  15. Wo Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:5.

  16. Wo Russell M. Nelson, “Ẹ Yọ̀ nínú Ẹ̀bùn àwọn Kọ́kọ́rọ́ Oyè-àlùfáà,” Liahona, May 2024, 121; 3 Nefi 27:9–11.

  17. Olùgbàlà “fi àwọn kan fúnní bí, àpóstélì; àti àwọn míràn, bí wòlíì; àti àwọn míràn, bí efángẹlistì; àti àwọn míràn bí, Olùṣọ́-àgùtàn àti olùkọ́ni” kí gbogbo “wa [lè] fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, … kí àwà ó máṣe jẹ́ èwè mọ́, tí a nfi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá sẹ́hìn, tí a sì fi ngbá kiri, nípa ìtànjẹ́ ènìyàn, nípa àrèkérekè fún ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti múni ṣìnà” (Ephesians 4:11–16

  18. Syncretism is the technical term for the amalgamation of different religions, cultures, or schools of thought.

  19. Wo Àkọọ́lẹ̀-ìtàn—Josefu Smith 1:19.

  20. Wo “Ìmúpadàbọ̀sípò Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhinrere Jésù Krísti: Ìkéde Igba Ọdún Kan Sí Àgbáyé,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere. Ìkéde èyí ni a kà láti ọwọ́ Ààrẹ Russell M. Nelson bí ara ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Àádọ́ọ̀wá Ọlọ́dọdún, Ọjọ́ Karun Oṣù Kẹrin, 2020, ní Ìlú-nlá Salt Lake, Utah (wo Russell M. Nelson “Gbọ́ Tirẹ̀,” Làìhónà, May 2020, 91–92).

  21. A lè ní àyè sí agbára Ọlọ́run nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ríronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti pípa àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì nínú àwọn ìlànà bí irú ìrìbọmi, ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, àti oúnjẹ Olúwa mọ́.

  22. Wo Ìtọ́nisọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́, “Dídáláre, Dáláre,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  23. Wo Ìtọ́nisọ́nà sí Àwọn Ìwé Mímọ́, “Ìyàsímímọ́,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  24. Wo Mórónì 10:32–33.

  25. Wo Hebrews 4:15; bákannáà wo àkọsílẹ̀-ìsàlẹ̀ a.

  26. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:15-18.

  27. Wo Isaiah 53:4–12.

  28. Hébérù 12:2.

  29. Mòsíàh 15:23.

  30. Moroni 7:27-28; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 45:3-5.

  31. Wo Mòsíàh 18:30.

  32. Wo Inger Höglund and Caj-Aage Johansson, Steg i Tro: Jesu Kristi Kyrka av Sista Dagars Heliga i Sverige 1850–2000 (2000), 66–67.

  33. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 115:4.

  34. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:19–21.

  35. Bí ẹ bá gba ohun tí Ìjọ Olúwa fúnni, ẹ ó di pípé nínú Krístì ṣíwájú kí Ìjọ Rẹ̀ tó di pípè, tí ó bá rí bẹ́ẹ̀ láé. Ibi-afẹ́dé Rẹ̀ ni láti sọ yí di pípé, kìí ṣe Ìjọ Rẹ̀. Ibi-afẹ́dé Rẹ̀ kìí ṣe kò sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ rí, ní ọ̀rọ̀-àfiwé, láti yí kíẹ́sígọ̀ sínú òkúta oníyebíye jùlọ; ibi-afẹ́dé Rẹ̀ ti jẹ́ láti tún yín ṣe sínú wúrà àìlẹ́gbẹ́, láti gbàlà àti láti gbé wa ga bí ara-ajogún pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ìjọba ti Baba wa Ọ̀run. Ṣùgbọ́n ìnílò náà láti di ibi-afẹ́dé yín, pẹ̀lú. Eyí ni yíyàn yín.

  36. Hẹ́lámánì 5:44.