Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Afẹ́fẹ́ Kìí Dáwọ́dúró Ní Fífẹ́ Láéláé
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


Afẹ́fẹ́ Kìí Dáwọ́dúró Ní Fífẹ́ Láéláé

A lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti nílọsíwájú nínú ìrìnàjò wọn láti gba àwọn ìbùkún Ọlọ́run.

Ní 2015, ní ìpínlẹ̀ ti Permambuco, Brazil, Méjìlelọgọta àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ ti Àwùjọ Amòfin J. Reuben Clark ní àjùmọ̀ṣe pẹ̀lú Ilé-iṣẹ́ ìpínlẹ̀ Abánirojọ́ ní ṣíṣe iwadi àwọn ìpènijà òfin ti olùgbé àwọn ilé nọ́ọ̀sì mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Fún wákàtí marun ní ọjọ́ Sátidé kan, àwọn agbẹjọ́rò wọ̀nyí ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí àwọn olùgbé igba ọ̀kan sí ọ̀kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan ti èyí tí ó ti jẹ́ ìṣe ìgbàgbé nípàsẹ̀ àwùjọ.

Nínú ìfọ̀rọ̀wànilẹ̀nuwò wọn, wọ́n rí onírurú ìwàkiwa tí wọ́n ti ṣe sí àwọn àgbàlagbà olùgbé bí irú ìpatì, ìlòkulò, àti lílo owó ní àìtọ́. Kókó òpó ti òfin àwùjọ yí ni láti ṣètọ́jú fún àwọn òtòṣì àti àwọn nínú àìní. Oṣù méjì péré lẹ́hìnnáà, abanirojọ́ náà fi yíyege gbé ìpèjọ́ kalẹ̀ lórí àwọn ẹgbẹ́ tó kàn.

Ìrànlọ́wọ́ wọn jẹ́ àpẹrẹ pípé kan nípa ìkọ́ni Ọba Benjamin “wípé bí ẹ̀yin bá wà nínú iṣẹ́-ìsìn arákùnrin yín inú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run nyín ni ẹ̀yin ṣã wà.”

Olùgbé kan tí mo fọ̀rọ̀wálẹ́nuwò fúnrami ní ìgbà iṣẹ́ pro bono náà jẹ́ onínúrere obìnrin ọjọ́ orí ọdún mẹ́tà-lé-ní-àádọ́wá ti a pè ní Lúcia. Ní ìmoore fún iṣẹ́-ìsìn wa, ó fi tẹ̀fẹ̀tẹ̀fẹ̀ kígbe pé, “Fẹ́ mi!”

Ní ìyàlẹ́nu, mo fèsì pé: “Wo ọ̀dọ́mọ̀bìrin rírẹwà náà ní ibẹ̀ yẹn! Òun ni ìyàwó mi òun sì ni abánirojọ́ ìpínlẹ̀.”

Ó dáhùn padà kíákíá pé: “Nítorínáà nkọ́? Ó jẹ́ ọ̀dọ́, ó lẹ́wà, ó sì tún lè ṣe ìgbeyàwó ní ìrọ̀rùn. Ìwọ ni gbogbo ohun tí mo ní!”

Àwọn oníyanu olùgbé náà kò ní ìyanjú sí gbogbo wàhálà wọn ní ọjọ́ náà. Láìṣiyèméjì wọ́n tẹ̀síwájú láti ní ìrírí lílé láti ìgbà sí ìgbà bíiti àwọn ará Járẹ́dì nínú ọkọ̀-ojú omi wọn lórí ìrìnàjò pípeni-níjà sí ilẹ̀ ìlérí, “òkun bò wọ́n mọ́lẹ̀ nínú jíjìn rẹ̀, nítorí àwọn ìbìlù-omi gíga tí ó nbì jáde lórí wọn.”

Ṣùgbọ́n ní Sátidé náà, àwọn olùgbé ilé nọ́ọ̀sì mọ̀ pé láìka àìdánimọ̀ ti ayé wọn sí, a dá wọn mọ̀ níti-araẹni nípasẹ̀ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run, àní Ẹni tí ó nfèsì sí àwọn àdúrà tó rọrùnjùlọ̀.

Olùkọ́ni ti àwọn olùkọ́ni mú kí “afẹ́fẹ́ tó lágbára” fẹ́ lu àwọn ara Járẹ́dì síwájú ìlérí àwọn ìbùkún. Bákannáà, a lè pinnu láti sìn bí afẹ́fẹ́ òjijì ti ìrẹ̀lẹ̀ ní ọwọ́ Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí “afẹ́fẹ́ kò ṣe dáwọ́dúró ní fífẹ́” àwọn ará Járẹ́dì síwájú ilẹ̀ ìlérí láéláé, a lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìlọsíwájú nínú ìrìnàjò wọn láti gba àwọn ìbùkún Ọlọ́run.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, nígbàtí Chris, ìyàwó mi ọ̀wọ́n, àti èmi gba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún ìpè mi bíi bíṣọ́ọ̀pù, ààrẹ èèkàn wa ni kí nfi pẹ̀lú àdúrà ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ láti kàyẹ bí àwọn olùdámọ̀ràn. Lẹ́hìn gbígbọ́ àwọn orúkọ tí mo kàyẹ, ó wípé èmi níláti mọ àwọn ohun díẹ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà.

Àkọ́kọ́, arákùnrin yí kò lè kàwé. Ìkeji, kò ní ọkọ̀ tí ó lè fi bẹ àwọn ọmọ-ìjọ wo. Ìkẹ́ta, nígbàgbogbo, nígbàgbogbo ni ó—máa—nlo jígí òòrùn ní ìjọ. Pẹ̀lú àwọn àníyàn òtítọ́ ti ààrẹ̀, mo ní ìmọ̀lára alágbára pé mo ṣì lè kà á yẹ bí olùdámọ̀ràn mi, àti pé ààrẹ èèkàn ṣe àtìlẹhìn.

Ọjọ́-ìsinmi tí a ṣe ìmúdúró èmi àti olùdámọ̀ràn mi ní ìpàdé oúnjẹ́ Olúwa, ìyanu ojú àwọn ọmọ-íjọ hàn kedere. Arákùnrin ọ̀wọ́n yí mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n díẹ̀díẹ̀ lọ síbi pẹpẹ, níbití àwọn iná ti hàn dídán ní ìsọdá jígí-òòrùn rẹ̀.

Bí ó ti joko ní ẹgbẹ́ mi ó ní, “Arákùnrin, ṣe ó ní wàhálà pẹ̀lú ojú rẹ̀ ni?”

“Rárá,” ni ó wí.

“Nígbànáà kinìdí tí ó fi nlo jígí-òòrùn ní ìjọ?” Mo bèèrè. “Ọ̀rẹ́ mi, àwọn ọmọ-ìjọ nílò làti rí ojú rẹ, o sì gbọ́dọ̀ lè rí wọn dáradára bákannáà.”

Ní àkokò náà, ó mú jígí-òòrùn rẹ̀ kúrò kò sì lò wọ́n ní ìjọ mọ́.

Àyànfẹ́ arákùnrin yí sìn ní ẹ̀gbẹ́ mi títí a fi dá mi sílẹ̀ bí bíṣọ́ọ̀pù. Ní òní, ó tẹ̀síwájú láti sìn lódodo nínú Ìjọ àti pé ó jẹ́ àpẹrẹ ìfọkànsìn àti ìfarajìn sí Olúwa Jésù Krístì. Àti pé síbẹ̀, ní àwọn ọdún sẹ́hìn, ó jẹ́ aláìmọ̀ olùwọ̀-jígí òòrùn tí ó joko nípàtàkì ní ìgbàgbé nínú ijoko ilé-ìjọsìn. Ó máa nyàmílẹ́nu nígbàkugbà, “Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìrin olótítọ́ fi njoko ìgbàgbé ní àárín wa ní òní?”

Bóyá a jẹ́ mímọ̀-dáadáa tàbí ìgbàgbé, ó jẹ́ ìṣeéṣe pé àwọn àdánwò yíò wá sọ́dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wa. Bí a ti nyípadà sí Olùgbàlà, Òun lè “ya ípọ́njú [wa] sọ́tọ̀ fún èrè [wa]” yíò sì ràn wá lọ́wọ́ láti fèsì sí àwọn àdánwò wa ní ọ̀nà kan tí ó nmú ìlọsíwájú ti ẹ̀mí wa wá. Bóyá fún àwọn olùgbé ilé nọ́ọ̀sì, ọmọ Ìjọ tí a dálẹ́jọ́ àìtọ́, tàbí ẹnikẹ́ni míràn, a lè jẹ́ “afẹ́fẹ́ [náà] tí kò dáwọ́dúró ní fífẹ́ láéláé,” tí ó nmú ìrètí àti ìtọ̀nisọ́nà àwọn míràn wá sí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú.

Àyànfẹ́ wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, ṣe ìfipè alárinrin onímísí fún àwọn ọ̀dọ́: “Mo ṣe àtúnsọ alágbára pé Olúwa ti ní kí gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yíyẹ, ó múrasílẹ̀ fún àti sísin míṣọ̀n. Fún ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere jẹ́ ojúṣe òyè àlùfáà. … Fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ àti àwọn arábìnrin tí ó ní okun, iṣẹ́ ìránṣẹ́ bákannáà jẹ́ alágbára kan, ṣùgbọ́n ànfàní bí ó bá, wuni.”

Ní ojojúmọ́, ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti obìnrin ndáhùn ìpè wòlíì Olúwa nípa sísìn bí òjíṣẹ́ ìhìnrere. Ẹ jáfáfá, àti bí Ààrẹ Nelson ti sọ ẹ lè “ní ipa lórí ayé ju ìràn àtẹ̀hìnwá!” Bẹ́ẹ̀ni, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ẹ jẹ́ ẹ̀yà dídárajùlọ ti arayín ní àkokò tí ẹ bá tẹ ẹsẹ̀ bọ inú gbàgede idanilẹkọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere.

Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ lè ní ìmọ̀lára bíiti Néfì, “ẹ̀mi sì n tọ́ mi, n kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ àwọn ohun èyí tí èmi ìbá ṣe. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ [ẹ̀] nlọ síwájú.”

Bóyá ẹ ní ìmọ̀lára àìní-ààbò bí Jeremiah ti ṣe mo sì fẹ́ láti sọ pé, “Èmi kò lè sọ̀rọ̀: nítorí mo jẹ́ ọmọdé.”

Àní ẹ lè rí àlébù araẹni yín kí ẹ sì fẹ́ láti kígbe jáde bí Mósè ti ṣe: “Ah Olúwa mi, Èmi kìí ṣe ẹni ọ̀rọ̀-sísọ … : ṣùgbọ́n olóhùn wúwo ni èmi, àti aláhọ́n wúwo.”

Bí ẹnikẹ́ni lára ẹ̀yin àyànfẹ́ àti alágbára ọ̀dọ́mọkùnrin àti obìnrin bá ní èrò bíiti èyí nísisìyí, ẹ rántí pé Olúwa ti dáhùn pé, “Ma wípé, ọmọdé ni èmi: ṣùgbọ́n ìwọ ó lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi ó rán ọ” Ó sì ṣe ìlérí, “Lọ nísisìyí, èmi ó sì pẹ̀lú ẹnu rẹ, èmi ó sì kọ́ ọ ní èyí tí ìwọ ó wí.”

Ìyípòpadà yín látinú àbínibí yín sí ti-ẹ̀mí araẹni yíò ṣẹlẹ̀ “ìlà lórí ìlà, ìlànà lórí ìlànà” bí ẹ ti nfi ìtara tiraka láti sin Jésù Krístì ní pápá iṣẹ́ ìránṣẹ́ nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà ojojúmọ́, ìgbàgbọ́, ìgbọ́ran déédé, àti iṣẹ́ àṣekára láti “rí léraléra, kọ́ ìgbọràn, àti láti ṣe ìrìbọmi àwọn olùyípadà.”

Bíótilẹ̀jẹ́pé ẹ̀ nwọ táàgì orúkọ, nígbàmíràn ẹ lè ní ìmọ̀lára àìdámọ̀ tàbí ìgbàgbé. Bákannáà, ẹ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ẹ ní Baba Ọ̀run pípé, ẹni tí ó mọ̀ yín níti-araẹni, àti pé Olùgbàlà kan, tí ó fẹ́ràn yín. Ẹ ó ní àwọn olórí míṣọ̀n ẹnití, pẹ̀lú àwọn àìpé wọn, yíò sìn yín bí “afẹ́fẹ́ [tí] kò dáwọ́dúró ní fífẹ́ láéláé” ní títọ́ yín sọ́nà lẹgbẹ́ ìrìnàjò yín ti ìyípadà araẹni.

Nínú “ilẹ̀ náà tí ó nṣàn fún oyin àti ọ̀rá” ẹ ó sìn ní míṣọ̀n yín, ẹ ó jẹ́ àtúnbí níti-ẹ̀mí ẹ ó sì di ọmọẹ̀hìn pípẹ́ nípa Jésù Krístì bí ẹ ti nfà súnmọ́ Ọ. Ẹ lè wá láti mọ̀ pé a kò gbàgbé yín láéláé.

Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn kan lè dúró fún “ìgbà pípẹ́” fún ìrànlọ́wọ́, nítorí wọn “kò ní ọkùnrin kankan” ìyẹn lè ṣèránwọ́ síbẹ̀, Olúwa Jésù Krístì ti kọ́ wa pé kò sí ẹnìkankan tí a gbàgbé láé nípasẹ̀ Rẹ̀. Ní ìlòdì sí, Òun jẹ́ àpẹrẹ pípé ti wíwá ẹnìkan jáde ní gbogbo àkokò ti iṣẹ́-ìránṣẹ́ ayé-ikú Rẹ̀.

Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa—àti àwọn wọnnì ní àyíká wa—nkojú àwọn ìjì ti àti ìgbì-omi àwọn àdánwò ti ó nrì wá mọ́lẹ̀ lójojúmọ́. Ṣùgbọ́n “afẹ́fẹ́ [náà kò ní] dáwọ́dúró ní fífẹ́ lọ síwájú ilẹ̀ ìlérí … ; àti pé bayi [a ó] di gbígbé lọ níwájú afẹ́fẹ́.”

Ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wa lè jẹ́ ara àfẹ́fẹ́ yí—afẹ́fẹ́ kannáà tí ó bùkún àwọn ará járẹ́dì nínú ìrìnàjò wọn àti afẹ́fẹ́ kannáà tí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ wa, yíò bùkún àwọn aláìmọ̀ àti ìgbàgbé láti dé ilẹ̀ ìlérí ti ara wọn.

Mo jẹri pé Jésù Krístì ni alágbàwí wa pẹ̀lú Baba. Òun ni Ọlọ́run alààyè àti pé ó nṣe ìṣe bí afẹ́fẹ́ alágbára tí yíò tọ́ wa sọ́nà nígbàgbogbo lẹgbẹ ipa-ọ̀nà májẹ̀mú. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. J. Reuben Clark Òfin Àwùjọ ni ẹgbẹ́ tí kìí powó tí a dásílẹ̀ nípasẹ̀ àwọn amòfin àti akẹkọ òfin tí a sì ṣètò sínú ó pọ̀ ju orí ọgọrun nínú ayé. A sọ ní orúkọ ní bibọ́lá fún Joshua Reuben Clark Jr., ẹnití ó sìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún bí olùdámọ̀ran nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

  2. Mòsíàh 2:17.

  3. Pro bono ni irú ìdínkù ti gbólóhùn ní Latin pro bono publico, tí ó túmọ̀ sí “fún rere gbogbo ènìyàn” tàbí “fún èrè gbogbo ènìyàn.” Èyí jẹ́ irú iṣẹ́ ìyọ̀ọ̀da ti, kìí ṣe bíiti yíyọ̀ọ̀da àṣà, tí ó bèèrè fún ìyege ìgboyè, bíótilẹ̀jẹ́pé kò ní owó sísan.

  4. Étérì 6:6.

  5. Étérì 6:5.

  6. Wo 2 Nefi 2:14,16.

  7. Étérì 6:8.

  8. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:106.

  9. Wo Abrahamu 3:25.

  10. 2 Néfì 2:2; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 122:7.

  11. Russell M. Nelson, “Wíwàásù Ìhìnrere Àlàáfíà,” Làìhónà, Oṣù Karun 2022, 6.

  12. Russell M. Nelson, “Ìrètí ti Ísráẹ́lì,” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  13. 1 Néfì 4:6-7.

  14. Jeremíàh 1:6.

  15. Exodus 4:10.

  16. Jeremíàh 1:7.

  17. Exodus 4:12.

  18. Wo Mòsíàh 3:19.

  19. 2 Néfì 28:30.

  20. Wo Álmà 26:22.

  21. Neil L. Andersen, “Ìgbàgbọ́ láti Rí àti láti Ṣe Ìrìbọmi àwọn Olùyípadà” (ọ̀rọ̀ tí a fúnni níbi idanilẹkọ fún àwọn ààrẹ míṣọ̀n titun, June 25, 2016), 6.

  22. Wo Deuterónómì 28:1–9.

  23. Wo “Dída àwọn Ọmọẹ̀hìn Pípẹ́ ti Jésù Krístì,” Wàásù Ìhìnrere Mi: Ìtọ́nisọ́nà Kan láti Pín Ìhìnrere ti Jésù Krístì (2023), 76–100.

  24. Jòhánù 5:6–7.

  25. Wo Lúkù 10:29.

  26. Étérì 6:8.

  27. Àarẹ Dallin H. Oaks sọ̀rọ̀ nípa kíkún kan láti ọwọ́ Maynard Dixon tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Ọkùnrin Ìgbàgbé, tí a fi kọ́ sí ibi-iṣẹ́ rẹ̀ nínú Ilé Ìṣàkóso Ìjọ Ìlú Salt Lake: “Ẹ rí òòrùn tí ó ntàn sí orí rẹ̀. Baba Rẹ̀ Ọ̀run mọ̀ pé ó wà níbẹ̀. Ó di ìgbàgbé nípa àwọn èrò kíkọjá, ṣùgbọ́n nínú ìlàkàkà rẹ̀, Baba rẹ̀ Ọ̀run mọ̀ pé ó wà níbẹ̀. …. Mo ti wà pẹ̀lú kíkùn náà fún ó tó ogójì ọdún, ó sì nsọ̀rọ̀ sí mi ó sì nrán mi léti àwọn ohun tí mo nílò láti rántí” (nínú Sarah Jane Weaver, “Mo kẹkọ láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Oaks nípa ‘Ọkùnrin Ìgbàgbé náà,’” Àwọn Ìròhìn Ìjọ, Sept. 18, 2022, thechurchnews.com).