Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Wíwá Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Tẹ̀mí
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


Wíwá Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Tẹ̀mí

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, mo jẹ́rìí pé àwọn ìbéèrè ihinrere tọkàntọkàn lè pèsè Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì pẹ̀lú àwọn àǹfààní láti ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà.

Mo mọ̀ pé èyí lè yà ni lẹ́nu, ṣùgbọ́n mo ti dàgbà tó láti rántí nígbàtí wọ́n kọ́ wa ní ilé ẹ̀kọ́ pé àwọn pílánẹ́ẹ̀tì mẹ́sàn ló wà nínú ètò oòrùn wa. Ọ̀kan nínú àwọn pílánẹ́ẹ̀tì wọ̀nnì, Plútò, ni a fún ní orúkọ rẹ̀ nípasẹ̀ ọmọ-ọdún-mọ̀kànlá Venetia Barney ti Oxford, England, lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàwárí i rẹ̀ ní ọdún 1930. Àti pé títí di 1992, Pluto jẹ́ ohun tó jìnnà jùlọ nínú ètò oòrùn wa. Ní àkókò yi, ó wọ́pọ̀ láti rí àwọn àwòṣe pápíer mâché ìgbà ọmọdé ti àwọn agbègbè ayé wa ní àwọn yàrá ìkàwé àti àwọn ìpàtẹ sáyẹ́ǹsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan nṣe àpèjúwe ipò Plútò lórí ààlà mímọ̀ náà. Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbàgbọ́ pé lẹ́yìn etí-ààla náà, ètò oòrùn lóde jẹ́ wìwà ní àlàfo tó ṣófo.

Síbẹ̀síbẹ, ìbéèrè kan wà nínú àwùjọ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ irú eré ìpìlẹ̀ kan pàtó tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà máa ntọpinpin déédéé. Ìbéèrè yi sì wà fún ọ̀pọ̀ dẹ́kéèdì kí a tó ṣàwárí ẹkùn ilẹ̀ mìíràn tó jìnnà gan-an ti ètò oòrùn wa. Pẹ̀lú ìmọ́ tó lópin tí wọ́n ní , àwọn onímọ sáyẹ́nsì lo àwọn dẹ́kéèdì láarin àwọn ọdún láti ṣe àgbéjáde àwọn ìlọsíwájú ìmọ̀ ẹ̀rọ pàtàkì tí ó fi àyè gba ìkẹ̀kọ àti ìwádi síwájú sí i. Âṣeyọrí wọn nígbẹ̀hìn ṣe àtúnto agbègbè ilẹ̀ ayé wa ó sì yọrísí pé Pluto di àtúngbé sí ẹkùn ti àlàfo tuntun yíi àti ètò oòrùn wa tí ó ní àwọn ayé pílánẹ́ẹ̀tì mẹjọ.

Olórí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pílánẹ́ẹ̀tì kan àti olùṣàwárí àgbà fún iṣẹ́ àyànfẹ́ pápá òfuurufú New Horizons tí a yàn láti ṣe àyẹ̀wò Pluto nítòsí ní èyí láti sọ nípa ìrírí yìí pé: “A rò pé a lóye bí ilẹ̀ ayé ṣe rí nínú ètò oòrùn wa. A kò ṣé. A ro pe a loye awọn olugbe ti awọn ayé pílánẹ́ẹ̀tì ninu eto oorun wa. A sì ṣe aṣiṣe.”

Ohun tí ó yà mí lẹ́nu nípa àsìkò ìtàn ìwákiri ààyè yíi jẹ́ àwọn àfiwéra àti àwọn ìyàtọ̀ pàtàkì láarín ìlépa ìṣàpẹẹrẹ ti ìmúgbòòrò já àwọn ààyè ìmọ-jinlẹ̀ àti ìrìn-àjò ti àwa, bí ọmọ Ọlọ́run, nṣe láti wá àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa ti-ẹ̀mí. Ní pàtàkì, bí a ṣe lè dáhùn padà sí ààlà òye wa nípa tẹ̀mí ká sì múra ara wa sílẹ̀ de ìpele ìdàgbàsókè ti araẹni tó kàn—àti ibití a lè yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́.

Ẹsẹ lórí Ẹsẹ

Bibeere awọn ibeere ati wiwa itumọ jẹ àdánidá ati apakan deede ti ìrírí ayé-iku wa. Nígbà míì, àìní ìdáhùn tó pé pérépéré ní àrọ́wọ́tó lè mú wa dé góńgó òye wa, àwọn ààlà wọ̀nnì sì lè nímọ̀lára ìjákulẹ̀ tàbí kí ó le koko. Lọ́nà àgbàyanu, ètò ìdùnnú ti Bàbá Ọ̀run fún gbogbo wa ni a ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú láìka àwọn ààlà wa sí kí á sì ṣe àṣeparí ohun tí a kò lè ṣe fúnra wa, àní láìsí ìmọ̀ pípé nípa ohun gbogbo. Ètò Ọlọ́run jẹ́ aláàánú sí àwọn ààlà ẹ̀dá ènìyàn wa; pese wa pẹlu Olugbala wa, Jésù Krístì, lati jẹ Oluṣọ-agutan Rere wa; ó sì ń fún wa ní ìmísí láti lo agbára òmìnira wa láti yan Òun.

Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti kọ́ni pé “bíbéèrè àwọn ìbéèrè kìí ṣe àmì àìlera,” ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ “ó jẹ́ ìṣàwájú ìdàgbàsókè.” Ni sisọ taara si akitiyan ti ara ẹni bi awa ti nwa otitọ, wolii wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti kọ́ni pé a gbọ́dọ̀ ní “ìfẹ́-inú jíjinlẹ̀” àti “kí a sì bèèrè pẹ̀lú ọkàn òtítọ́ [àti] èrò gidi, pẹ̀lú níní ìgbàgbọ́ nínú [Jésù] Krístì.” Ó ti kọ́ni síwájú síi pé “‘èrò gidi’ túmọ̀ sí pé ẹnì kan ní lọ́kàn láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá tí a fifunni.”

Ìsapá tiwa fúnra wa láti dàgbà nínú ọgbọ́n lè ṣamọ̀nà wa láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè wa, dídíjú tàbí lọ́nà mìíràn, nípasẹ̀ ojú ìwòye ìdí àti àbájáde, ní wíwá àti dídámọ̀ àwọn ìlànà àti lẹ́yìn náà ní dídá àwọn ìtàn sílẹ̀ láti fi ìpìlẹ̀ sí òye wa àti láti kún àwọn àlàfo tí a rí nínú ìmọ̀. Nígbàtí a bá ṣàgbéyẹ̀wò ìlépa ìmọ̀ ti ẹ̀mí, bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìlànà ìrònú wọ̀nyí lè jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nígbà míràn, ṣùgbọ́n ní tiwọn fúnra wọn lè jẹ́ aláìpé bí a ṣe nwo àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ Bàbá Ọ̀run àti Olùgbàlà wa, Jesu Kristi, ihinrere Wọn, Ìjọ Wọn, ati eto won fun gbogbo wa.

Ọ̀nà Ọlọ́run Bàbá àti ti Ọmọ Rẹ̀ láti fi ọgbọ́n wọn fún wafi pípe agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe àkọ́kọ́ láti jẹ́ olùkọ́ ti araẹni wa bí a ṣe fi Jésù Kristi sí ààrin gbúngbùn nínú ìgbésí ayé wa àti nínú fífi òtítọ́ lépa fún àwọn ìdáhùn Wọn àti ìtumọ̀ Wọn. Wọ́n pè wá láti ṣe àwárí òtítọ́ nípasẹ̀ àkókò ìfọkànsìn tí a lò fún ṣíṣe àṣàrò ìwé mímọ́ àti láti wá kiri fún òtítọ́ tí a fihàn ní ọjọ́ ìkẹyìn fún ọjọ́ wa àti àkókò wa, tí àwọn wòlíì àti àpọ́sítélì òde òní kọ́ni. Wọ́n rọ̀ wá pé kí a lo àkókò déédé, ti ìjọ́sìn nínú ilé Olúwa àti láti lọ sí eékún wa nínú àdúrà “láti rí ìwífúnni láti ọ̀run wá.” Ìlérí tí Jésù ṣe fún àwọn tó wà níbẹ̀ láti gbọ́ Ìwàásù Rẹ̀ Lórí Òkè jẹ́ òtítọ́ ní ọjọ́ wa bí ó ṣe rí nígbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé: “Ẹ béèrè, a ó sì fi fún yín; ẹ wákiri, ẹnyin o si ri; ẹ kànkùn, a o si ṣí i silẹ fun nyin.” Olùgbàlà wa mú un dá wa lójú pé “Baba yín tí nbẹ ní ọ̀run nf[i] àwọn ohun rere fún àwọn tí wọ́n bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”

Ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Olúwa ni “ìlà lórí ìlà, ìlànà lé ìlànà.” A le rii pe a le nilo lati “duro de Oluwa” ninu alafo tó wà laarin ìlà òye wa lọwọlọwọ ati atẹle ti a kò tíì fi jiṣẹ. Ààfo mímọ́ yìí lè jẹ́ ibi tí ìmúrasílẹ̀ tẹ̀mí wa títóbi jùlọ ti lè wáyé—ibùdó tí a ti lè “faradà pẹ̀lú sùúrù” ìtara wa ní wíwá àti láti ṣe ìsọdọ̀tun agbára waláti tẹ̀síwájú láti máa pa àwọn ìlérí mímọ́ tí a ti ṣe fún Ọlọ́run nípasẹ̀ májẹ̀mú mọ́.

Ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú wa pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì nṣàpẹẹrẹ jíjẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tí ó gbilẹ̀ nínú ìjọba Ọlọ́run. Bá a sì ṣe ngbé inú rẹ̀ nbéèrè pé ká mú ìgbésí ayé wa bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu ká sì máa sapá láti dàgbà nípa tẹ̀mí.

Ìgbọ́ran

Ìlànà pàtàkì kan tí a kọ́ni jálẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run bá yàn láti fi ìgbọràn hàn tí wọ́n sì pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́, wọ́n ngba ìtọ́sọ́nà àti ìdarí ti ẹ̀mí títí lọ. Olúwa ti sọ fún wa pé nípa ìgbọràn àti ìtara wa a lè jèrè ìmọ̀ àti òye. Awọn ofin ati awọn àṣẹ Ọlọrun ko ṣe apẹrẹ lati jẹ idiwọ ninu igbesi aye wa ṣugbọn ẹnu-ọna ti o lagbara si ifihan ti ara ẹni ati ikẹkọ ti ẹmi. Ààrẹ Nelson ti kọ́ni ní òtítọ́ pàtàkì pé “ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run máa nfi ìgbà gbogbo wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin ayérayé Rẹ̀” àti síwájú síi pé “kìí tako ẹ̀kọ́ Rẹ̀ láéláé.” Ìgbọràn rẹ tinútinú sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn èrèdí Rẹ̀, fi ọ́ sínú ẹgbẹ́ àwọn wòlíì Rẹ̀. Mose karun ko wa nipa ibaraenisepo kan pato laarin Adam ati ti angẹli Oluwa kan.

Lẹ́yìn tí Olúwa ti fún Ádámù àti Éfà ní “àwọn òfin, pé kí wọ́n sin Olúwa Ọlọ́run wọn, kí wọ́n sì fi àkọ́bí agbo ẹran wọn sílẹ̀, fún ìrúbọ sí Olúwa,” àwọn ìwé mímọ́ sọ pé “Ádámù ṣè ìgbọ́ran sí àwọn àṣẹ Olúwa.” A tẹsiwaju lati ka pe “lẹhin ọjọ pupọ angẹli Oluwa farahan sí Adamu, o wipe: Ẽṣe ti iwọ fi nrúbọ si Oluwa? Adamù sì wí fùn un pé: Èmi kò mọ̀, bíkòṣe pé Olúwa pàṣẹ fún mi.

Ìgbọràn Ádámù ṣáájú òye rẹ̀ ó sì múra rẹ̀ sílẹ̀ láti gba ìmọ̀ mímọ́ pé òun nkópa nínú àmì mímọ́ ti Ètùtù Jésù Krístì. Ìgbọràn wa onírẹ̀lẹ̀, bákannáà, yóò ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún òye ti ẹ̀mí nípa àwọn ọ̀nà Ọlọ́run àti èrò àtọ̀runwá Rẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Nínàgà láti gbé ìgbọràn wa ga nmú wa súnmọ́ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì síi, nítorí pé ìgbọràn sí àwọn òfin àti àṣẹ Rẹ̀ nnàgà sí I lọ́nà gbígbéṣẹ́.

Ní àfikún, jíjẹ́ olõtọ́ wa sí ìmọ̀ àti ọgbọ́n tí a ti jogún tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìfaramọ́ olõtọ́ wa sí àwọn ìlànà ìhìnrere àti àwọn májẹ̀mú mímọ́ jẹ́ ìmúrasílẹ̀ pàtàkì fún ṣíṣetán wa láti gba àti láti jẹ́ ìríjú àwọn ìbánisọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

Baba orun ati Jesu Kristi ni orisun gbogbo otito wọ́n si pin ogbon Wọn lofe. Bákannáà, mímọ̀ pé a kò ní ìmọ̀ ti ara ẹni kankan láìdásí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ẹni tó yẹ ká yíjú sí àti ibi tí a lè fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa àkọ́kọ́ sí.

Ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ Jíjinlẹ̀

Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé nípa Náámánì, olórí àwọn ológun tí a wòsàn ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Èlíṣà, jẹ́ àyànfẹ́ tèmi gan-an. Ìtàn náà ṣàpèjuwe bí ìgbàgbọ́ dídúróṣinṣin ti “ọmọbìrin kékeré” ṣe yí ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé ọkùnrin kan padà àti, fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́, ṣe àfihàn àrọ́wọ́tó àánú Ọlọ́run fún àwọn wọ̀nnì tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Òun àti wòlíì Rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní orúkọ, ọ̀dọ́ ọmọbìnrin yìí tún ṣèrànwọ́ láti ti òye wa síwájú. Ìgbàgbọ́ Náámánì lórí ẹ̀rí rẹ̀ mí sí i láti gba ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ìmúláradá sí àṣàyàn ìránṣẹ́ Ọlọ́run náà.

Ìdáhùn Náámánì sí ìtọ́ni wòlíì Èlíṣà láti wẹ̀ nínú odò Jọ́dánì ní àkọ́kọ́ jẹ́ ti àníyàn àti ìbínú. Ṣùgbọ́n ìkésíni kan fún òun láti ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn wòlíì ṣe ọ̀nà fún ìmúláradá àti òye àgbàyanu rẹ̀ pé Ọlọrún jẹ́ òtítọ́.

A lè ríi pé díẹ̀ lára ​​àwọn ẹ̀bẹ̀ wa ti ẹ̀mí ní àwọn ìdáhùn tó bọ́gbọ́n mu tí wọ́n sì lè má fa ìbànújẹ́ nláǹlà fún wa. Tàbí, bí i Lámánì, a le ríi pé àwọn àìní míràn jẹ́ ìpènijà díẹ̀ síi àti pé ó lè ṣẹ̀dá àwọn ìkùnsínú tí ó nira àti tó dijú láarín wa. Tábí, tí ó jọra sí àpèjúwe àwọn ìparí ti àwọn awòràwọ̀ ní kùtùkùtù nípa ètò-ìgbékalẹ̀ oòrun wa, nínú wíwàkiri fún òtítọ́ ti ẹ̀mí, a lè débi àwọn ìtumọ̀ tí kò péye tí a bá gbáralé patapata lórí òye tiwa tí ó ní òpin, àbájáde ìbànújẹ́ àti àìrótẹ́lẹ̀ èyítí ó lè darí wa kúrò ní ọ̀nà májẹ̀mú. Àti pẹ̀lúpẹ̀lù, díẹ̀ nínú àwọn ìbéèrè lè dúró títí Ọlọ́run, ẹnití “ó ní gbogbo agbára” àti “gbogbo ọgbọ́n, àti gbogbo òye,” ẹnití “ó ní òye ohun gbogbo” nínú àánú Rẹ̀, yio pèsè òye nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínu orúkọ Rẹ̀.

Ìkìlọ̀ pàtàkì kan látinú àkọsílẹ̀ Náámánì ni pé kíkọ̀ láti ṣègbọràn sí àwọn òfin àti àṣẹ Ọlọ́run lè mú kí ìdàgbàsókè wa gùn síi tàbí kí ó falẹ̀. A ni ibukun lati ni Jesu Kristi gẹgẹbi Ọ̀gá Oluwosan wa. Ìgbọràn wa sí àwọn àṣẹ àti òfin Ọlọ́run lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Olùgbàlà wa láti pèsè òye àti ìwòsàn tí Ó mọ̀ pé a nílò, ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìtọ́jú Rẹ̀ tí a yàn fún wa.

Alàgbà Richard G. Scott kọ́ni pé “Ìrírí ayé yìí jẹ́ ìrírí nínú ìgbẹ́kẹ̀lé jíjinlẹ̀—ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jésù Kristi, gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ Rẹ̀, gbẹ́kẹ̀ lé agbára wa gẹ́gẹ́bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí rẹ̀ láti ṣègbọràn sí àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nnì fún ìdùnnú nísinsìnyí àti fún èrò kan, ayo tí ó ga jù lọ ti wíwà fún ayeraye. Láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé túmọ̀ sí láti ṣègbọràn tinútinú láìmọ òpin láti ìbẹ̀rẹ̀ (wo Òwe 3:5–7). Láti mú èso jáde, ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Olúwa gbọ́dọ̀ jẹ́ alágbára àti onífaradà ju ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú àwọn ìmọ̀lára àti ìrírí tirẹ̀.”

Alàgbà Scott tẹ̀síwájú: “Láti lo ìgbàgbọ́ jẹ́ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Olúwa mọ ohun tí Òun nṣe pẹ̀lú rẹ àti pé Òun lè ṣe àṣeyọrí fún ire ayérayé rẹ bíótilẹ̀jẹ́pé o kò le lóye bí Òun ṣe lè ṣe é.”

Ìjẹ́risi Ìparí

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, mo jẹ́rìí pé àwọn ìbéèrè ihinrere tọkàntọkàn lè pèsè Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì pẹ̀lú àwọn àǹfààní láti ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà. Ìgbìyànjú ti ara mi láti wá àwọn ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa sí àwọn ìbéèrè ti ẹ̀mí—tó kọjá àti tó nlọ lọ́wọ́lọ́wọ́—ti gbà mí láàyè láti lo ààyè láarín àwọn ìlà ti òye è mi àti ti Ọlọ́run láti ṣe àdáṣe ìgbọràn sí I àti ìdúróṣinṣin sí ìmọ̀ ẹ̀mi tí mo ní lọ́wọ́lọ́wọ́.

Mo jẹ́rìí sí i pé gbígbẹ́kẹ̀lé rẹ sí Bàbá Ọ̀run àti sí àwọn wòlíì Rẹ̀ tí Ó ti rán yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ọ ga nípa tẹ̀mí àti láti tì ọ́ síwájú sí ìhà ìlà-oòrùn Ọlọrun. Ànfàní rẹ yóò yípada nítorí ìwọ yóò yípadà. Ọlọ́run mọ̀ pé bí o bá ṣe ga tó, bẹ́ẹ̀ni o ṣe lè ríran tó. Olùgbàlà wa pè ọ́ láti gun àtẹ̀gùn náà. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.