Gbígbẹ́kẹ̀lé Baba wa
Ọlọ́run gbẹ́kẹ̀lé wa láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ ìpinu pàtàkì àti nínú ohun gbogbo, Ó wí fún wa kí á gbẹ́kẹ̀lé Òun.
Ní Ọjọ́ kinni Oṣù kẹfà, 1843, Addison Pratt kúrò ní Nauvoo, Illinois, láti wàásù ìhìnrere ní Erékùṣù Hawaii, ó sì fi ìyàwó rẹ̀, Louisa Barnes Pratt, sílẹ̀ láti bójú tó ẹbí kékeré wọn.
Bí àwọn inúnibíni ní Nauvoo ṣe npọ̀si, ní fífi ipá mú àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti lọ, àti lẹ́hìnnáà ní Winter Quarters bí wọ́n ṣe múra láti lọ sí àfonífojì Salt Lake, Louisa dojúkọ ìpinnu bóyá láti lọ ìrìn-àjò náà. Ìbá ti rọrùn láti dúró àti láti dúró fún ìpadàbọ̀ Addison ju láti dánìkan rin ìrìnàjò.
Nígbà méjèèjì, ó wá ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ wòlíì Brigham Young, ẹni tó gbà á níyànjú láti lọ. Pẹ̀lú ìṣòro nlá àti ìlọ́ra ti araẹni, ó ṣàṣeyọrí ní rírin ìrìn-àjò náà ní àkokò kọ̀ọ̀kan.
Níbẹ̀rẹ̀, Louisa rí ayọ̀ kékeré nínú ìrìn-ajò. Ṣùgbọ́n, láìpẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í gba koríko tútù, àwọn òdòdó igbó aláwọ̀ mèremère, àti àwọn pápá ilẹ̀ tí ó wà ní etí bèbè odò náà mọ́ra. “Ó ṣe akọsílẹ̀ pé: “Ìbànújẹ́ tó wà lọ́kàn mi parẹ́ kúrò díẹ̀díẹ̀, kò sì sí obìnrin tó láyọ̀ jùlọ nínú gbogbo ẹgbẹ́ náà.”
Ìtàn Louisa ti mísí mi lọ́nà tó jinlẹ̀. Mo gbóríyìn fún ìfẹ́ rẹ̀ láti gbé àwọn ohun tó wù ú sí ẹ̀gbẹ́ kan, agbára rẹ̀ láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti bí lílo ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe ràn án lọ́wọ́ láti rí ipo náà lọ́nà tó yàtọ̀.
Ó ti rán mi létí pé a ní olùfẹ́ni Baba ní Ọ̀run kan, tó nṣe ìtọ́jú fún wa níbikíbi tí a bá wà, àti pé a lè gbẹ́kẹ̀lé E ju ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míràn lọ.
Orísun Òtítọ́ Náà
Ọlọ́run gbẹ́kẹ̀lé wa láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ ìpinu pàtàkì, àti nínú ohun gbogbo Ó wí fún wa kí á gbẹ́kẹ̀lé Òun. Èyí nípàtàkì nira nígbàtí ìdájọ́ wa tàbí èrò-inú gbangba bá yàtọ̀ sí ìfẹ́ Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀.
Àwọn kan dámọ̀ràn pé kí a tún àwọn ìlà tí ó wà láàrin ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fà nítorí wọ́n sọ pé òtítọ́ báramu, òtítọ́ jẹ́ títúmọ̀ ara-ẹni, tàbí Ọlọ́run ní inúrere tóbẹ́ẹ̀ tí kò bìkítà nípa ohun tí a nṣe.
Bí a ṣe nwá láti lóye tí a sì tẹ́wọ́gba ìfẹ́ Ọlọ́run, ó máa nṣèrànwọ́ láti rántí pé ààlà tó wà ní àárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ kìí ṣe fùnwa lati túmọ̀. Ọlọ́run ti gbé àwọn ààlà wọ̀nyí kalẹ̀ Fúnrarẹ̀, tí ó dá lórí àwọn òtítọ́ ayérayé fún ànfààní àti ìbùkún wa.
Ìfẹ́-inú láti yí òtítọ́ ayérayé Ọlọ́run padà ní àkọọ́lẹ̀-ìtàn gígùn. Ó bẹ̀rẹ̀ kí ayé tó bẹ̀rẹ̀, nígbàtí Sátánì ṣọ̀tẹ̀ sí ètò Ọlọ́run, tó nwá pẹ̀lú ìmọtara-ẹni-nìkan láti pa agbára òmìnira ènìyàn run. Ní títẹ̀lé àwòṣe yìí, àwọn ènìyàn bíi Ṣẹ́rẹ́mù, Nehórì, àti Kóríhórì ti jiyàn pé ìgbàgbọ́ jẹ́ òmùgọ̀, ìṣípayá kò ṣe pàtàkì, ohunkóhun tí a bá sì fẹ́ ṣe ló tọ́. Ó bani nínú jẹ́ pé, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn yíyà kúrò nínú òtítọ́ Ọlọ́run wọ̀nyí ti yọrí sí ìbànújẹ́ nlà.
Nígbàtí díẹ̀ nínú àwọn nkan lè dálé orí àgbékalẹ̀-ọ̀rọ̀, kìí ṣe ohun gbogbo ni ó ṣe. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni ní léraléra pé àwọn òtítọ́ tó ngbàlà ti Ọlọ́run jẹ́ pípé, òmìnira, àti títumọ̀ nípasẹ̀ Ọlọ́run Fúnrarẹ̀.
Yíyàn Wa
Ẹnití a yàn láti gbẹ́kẹ̀lé jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìpinnu pàtàkì ti ìgbésí ayé. Ọba Bẹ́njámínì kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, “Ẹ gba Ọlọ́run gbọ́; ẹ gbàgbọ́ pé ó jẹ́ … ; ẹ gbàgbọ́ pé ó ní gbogbo ọgbọ́n … ; ẹ gbàgbọ́ pé ènìyàn kò lóye gbogbo ohun tí Olúwa lè lóye rẹ̀.”
Ní oríire, a ní àwọn ìwé-mímọ́ àti ìtọ́nisọ́nà làti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì alãyè láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa ní òye òtítọ́ Ọlọ́run. Bí ó bá nílò àlàyé tí ó kọjá ohun tí a ní, Ọlọ́run pèsè rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀. Òun yíò sì dáhùn sí àwọn àdúrà àtọkànwá wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ bí a ṣe nwá ọ̀nà láti lóye àwọn òtítọ́ tí a kò tíì mọrírì ní kíkún.
Alàgbà Neil L. Andersen kọ́ni nígbà kan pé kò yẹ kó yà wá lẹ́nu “bí ní àwọn ìgbà míràn àwọn ojú ìwòye [wa] kò bá bá àwọn ìkọ́ni ti wòlíì Olúwa mu. Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn àkokò ikẹẹkọ,” ó wípé, “nípa ìrẹ̀lẹ̀, nígbàtí a bá lọ sórí ẽkún wa nínú àdúrà. A nrìn síwájú nínú ìgbàgbọ́, ní gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, ní mímọ̀ pé bí àkokò bá tó a ó gba ìmọ̀ kedere ti ẹ̀mí síi láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run.”
Nígbogbo ìgbà, ó nrànni-lọ́wọ́ láti rántí ẹ̀kọ́ Álmà pé Ọlọ́run nfúnni ní ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àfiyèsí àti ìsapá tí a bá fi lélẹ̀ sí i. Bí a bá kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó gba púpọ̀ síi, bí a bá kọ ìmọ̀ràn Rẹ̀, a ó máa gba dídínkù àti dídínkù títí a kò fi ní ní ohunkóhun mọ́. Ìpàdánù ìmọ̀ yí kò túmọ̀ sí pé òtítọ́ jẹ́ àṣìṣe; dípò bẹ́ẹ̀, ó fihàn pé a ti pàdánù agbára láti lóye rẹ̀.
Ẹ Máa Wo Olùgbàlà
Ní Kapernaumu, Olùgbàlà kọ́ni nípa ìdánimọ̀ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣòro fún láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀, tí ó darí wọn láti yí ẹ̀hìn wọn padà kí wọ́n sì “má rìn pẹ̀lú rẹ̀ mọ́.”
Kínìdí tí wọ́n fi rìn lọ?
Nítorí wọn kò fẹ́ràn ohun tí Ó sọ. Nítorínáà, ní gbígbẹ́kẹ̀lé ìdájọ́ tiwọn fúnra wọn, wọ́n rìn lọ, wọ́n dun ara wọn ní àwọn ìbùkún tí ìbá dé bí wọ́n bá ti dúró.
Ó rọrùn fún ìgbéraga wa láti wá sí aarin àwa àti òtítọ́ ayéraye. Nígbàtí a kò bá lóye, a lè dánu dúró, jẹ́ kí àwọn ìmọ̀lára wa yanjú, àti lẹ́hìnnáà yàn bí a ṣe lè dáhùn. Ṣùgbọ́n Olùgbàlà rọ́ wa láti “máa wo [Òun] nínú gbogbo èrò; má siyèméjì, má bẹ̀rù.” Nígbàtí a bá dojúkọ Olùgbàlà, ìgbàgbọ́ wa lè bẹ̀rẹ̀ láti bórí àwọn àníyàn wa.
Bí Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti gbàwá níyànjú láti ṣe, “jọ̀wọ́, kọ́kọ́ ṣe iyèméjì awọn iyèméjì rẹ kí o tó ṣe iyèméjì ìgbàgbọ́ rẹ. A kò gbọdọ̀ gba iyèméjì láàyè láti fi wá sí ìhámọ́ àti láti fi wá pamọ́ kúrò ní ìfẹ́ àtọ̀runwá, àláfíà, àti àwọn ẹ̀bùn tí ó nwá nípa ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì.”
Àwọn Ìbùkún Nwá sọ́dọ̀ Àwọn tí wọ́n Dúró
Bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn ṣe nkúrò lọ́dọ̀ Olùgbàlà lọ́jọ́ náà, Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn Méjìlá náà pé, “Ẹ̀yin náà yíò ha lọ bí?”
Pétérù dáhùn:
“Olúwa, sọ̀dọ̀ tani àwa yíò lọ? Ìwọ ní ọ̀rọ̀ ìyè ayérayé.
“A gbàgbọ́ ó sì dáwá lójú pé ìwọ ni Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”
Bayi, àwọn Àpọ́sítélì gbé nínú ayé kannáà, wọ́n sì dojúkọ àwọn títẹ̀mọ́lẹ̀ àwùjọ kannáà bí ti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tí wọ́n rìn lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ní àkokò yí, wọ́n yan ìgbàgbọ́ wọ́n, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, nípa báyí, wọ́n ṣe ìpamọ́ àwọn ìbùkún ti Ọlọ́run fifún àwọn tí wọ́n dúró.
Bóyá ẹ̀yin, bí ti èmi, nígbàkan rí ara yín ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ti ìpinnu yìí. Nígbàtí ó bá ṣòro fún wa láti lóye tàbí gba ìfẹ́ Ọlọ́run mọ́ra, ó jẹ́ ìtùnú láti rántí pé Ó fẹ́ràn wa bí a ti wa, níbikíbi tí a bá wà. Òún sì ní ohun dídárajù fún wa. Bí a ti nnawọ́ sóde sí I, Òun yíò ràn wá lọ́wọ́.
Nígbàtí a bá nínawọ́ jáde sí I lè ṣòro, gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà ti wí fún baba tí ó nwá ìwòsàn fún ọmọ rẹ̀, “Ohun gbogbo di ṣíṣe fún ẹni náà tí ó bá gbàgbọ́.” Ní àwọn àkokò itiraka wa, àwa náà lè kígbe jáde pé, “Ran àìgbàgbọ́ [mi] lọ́wọ́.”
Fífi Ìfẹ́ Wa sílẹ̀ fún Tirẹ̀
Alàgbà Neal A. Maxwell kọ́ni nígbàkanrí pé “fífi ìfẹ́ ti ẹnikàn sílẹ̀ nitòótọ́ jẹ́ ohun àìláfiwé ti araẹni kanṣoṣo tí a níláti fi sí orí pẹpẹ Ọlọ́run.” Abájọ tí Ọba Bẹ́ńjámínì fi ní ìtara tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn rẹ̀ fi dà “gẹ́gẹ́bí ọmọdé, onítẹ̀ríba, ọlọ́kàn tútù, onírẹ̀lẹ̀, onísùúrù, kún fún ìfẹ́, tí ó múra tán láti tẹrí ba fún ohun gbogbo tí Olúwa rí pé ó yẹ láti fi lé e lórí, àní gẹ́gẹ́bí ọmọdé ti ntẹríba fún baba rẹ̀.”
Bíi ti ìgbàgbogbo, Olùgbàlà ṣètò àpẹrẹ pípé fún wa. Pẹ̀lú ọkàn tó wúwo, àti mímọ̀ iṣẹ́ ìrora tí Òun níláti ṣe, Ó fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ìfẹ́ Baba Rẹ̀, ní mímú iṣẹ́-ìránṣẹ́ messia Rẹ̀ ṣẹ Ó sì nṣí ìlérí ti ayérayé fún ẹ̀yin àti èmi.
Yíyàn láti fi ìfẹ́ wa sílẹ̀ fún ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ìṣe ìgbàgbọ́ tí ó wà ní ọkàn ti jíjẹ́ ọmọ lẹ̀hìn wa. Ní ṣíṣe àṣàyàn náà, a ṣe àwárí pé agbára òmìnira wa kò dínkù; dípò bẹ́ẹ̀, a mú un tóbi a sì san èrè rẹ̀ nípa wíwàníbẹ̀ ti Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí ó mú èrò, ayọ̀, àláfíà, àti ìrètí wá tí a kò lè rí ní ibòmíràn.
Ní ọ̀pọ̀ oṣù sẹ́hìn, ààrẹ èèkàn kan àti èmi bẹ arábìnrin kan àti ọmọkùnrin ọ̀dọ̀ àgbà rẹ̀ wò nínú èèkàn rẹ̀. Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kúrò ní Ìjọ, tí ó nrìn kiri ní ọ̀nà tí ó ṣòro àti aláìnífẹ̀ẹ́, ó ti padà. Lákokò àbẹ̀wò wa, a bèèrè ìdí tí ó fi padà.
Ó wípé, “Mo ti fi ìgbésí ayé mi ṣerékéré, mo sì mọ ibi tí mo nílò láti wà.”
Mo wá bi í pé kí ló kọ́ nínú ìrìn àjò rẹ̀.
Pẹ̀lú ìmí-ẹ̀dùn díẹ̀, ó sọ pé òun ti kẹ́kọ̀ọ́ pé òun níláti lọ sí ilé ìjọsìn pẹ́ tó láti jáwọ́ nínú àṣà àìwá àti pé òun nílò láti dúró títí dé ibi tí òun fẹ́ wà. Ìpadàbọ̀ rẹ̀ kò rọrùn, ṣùgbọ́n bí ó ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú ètò Baba, ó nímọ̀lára pé Ẹ̀mí padà.
Ó wá fi kún un pé, “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ fúnra mi pé Ọlọ́run dára àti pé àwọn ọ̀nà Rẹ̀ dáraju tèmi lọ.”
Mo jẹ́ ẹ̀rí Ọlọ́run, Baba wa Ayérayé, tó fẹràn wa; ti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, tí ó gbàwá là. Wọ́n mọ àwọn ìpalára àti àwọn ìpèníjà wa. Wọn kì yíò kọ̀ wá sílẹ̀ àtipé wọ́n mọ̀ ní pípé bí wọ́n ṣe lè tùwá nínú. A lè tújúká bí a ṣe gbẹ́kẹ̀lẹ Wọn jú ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míràn lọ. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.