Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Nínú Àlàfo tí Kìí Ṣe Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọdún
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


Nínú Àlàfo tí Kìí Ṣe Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọdún

Bí àwa kò bá jẹ́ olõtọ́ àti olùgbọràn, a lè yí ìbùkún ìṣerere tí Ọlọ́run-fúnni sí ègún agbéraga èyítí ó le mú wa yà kí ó sì dààmú wa.

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin, jíjókó lórí pẹpẹ ní òní, mo ti wò ó tí Gbàgede Ìpàdé àpapọ̀ kún dé ìlọ́po mẹ́ta, fún ìgbà àkọ́kọ́ látigbà Àjàkálẹ̀ Àrùn. Ẹ jẹ́ olùfọkànsìn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì tí wọ́n ní ìyọ́nú láti kẹkọ. Mo gbóríyìn fún òtítọ́ yín. Àti pé mo nífẹ́ yín.

Ezra Taft Benson sìn bí Ààrẹ̀ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti Oṣù Kọkànlá 1985 títí di Oṣù Karun 1994. Mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nígbàtí Ààrẹ Benson di Ààrẹ Ìjọ ati méjìlélógójì nígbàtí ó kọjá lọ. Àwọn ìkọ́ni àti àwọn ẹ̀rí rẹ̀ sì ni ipa lórí mi ní àwọn ọ̀nà tó jinlẹ̀ tó sì lágbára.

Ọ́kan nínú awọn èdídí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Ààrẹ Benson ni ìfojúsùn rẹ̀ lórí èrèdí ati jíjẹ́ pàtàkì Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó tẹnumọ ní àsọtúnsọ pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì “jẹ́ òkúta ìpìlẹ̀ ti ẹ̀sìn wa—òkúta ìpìlẹ̀ ti ẹ̀rí wa, òkúta ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ wa, àti òkúta ìpìlẹ̀ nínu ijẹri Olúwa àti Olùgbàlà wa.” Bákannáà ó fi ìgbà gbogbo tẹnumọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ati àwọn ìkìlọ nípa ẹ̀ṣẹ̀̀ ìgbéraga tí a rí nínú ẹ̀ri ọjọ́-ìkẹhìn ti Jésù Krístì yí.

Ìkọ́ni kan nípàtó láti ọwọ́ Ààrẹ Benson ní ìtẹ̀mọ́ra sí mi lọ́pọ̀lọpọ̀ ó sì ntẹ̀síwájú láti ní ipa lórí bí mo ti nṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó wí pé:

“Ìwé ti Mọ́mọ́nì … jẹ́ kíkọ fún ọjọ́ wa. Àwọn ara Néfì kò ní ìwé náà rí; bẹ́ẹ̀ni àwọn ará Lámánì ti àwọn ìgbàanì. Ó jẹ́ ṣíṣe fún wa. Mọ́mọ́nì kọ̀wé ní ẹ̀bá òpin ọ̀làjú ti àwọn ará Néfì. Ní abẹ́ ìmísí Ọlọ́run, ẹnití ó rí ohun gbogbo lati ìbẹ̀rẹ̀, [Mọ́mọ́nì] ṣe ìkékúrú àwọn àkọsílẹ̀ ti àwọn sẹ̀ntíúrì, ní yíyàn àwọn ìtàn, àwọn ọ̀rọ̀ sísọ, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti yío ṣe ìrànlọ́wọ́ jùlọ fún wa.”

Ààrẹ Benson: “Ìkọ̀ọ̀kan àwọn ònkọ̀wé pàtàkì Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ri pé òun kọ fún àwọn ìran ọjọ́ iwájú. … Bí wọ́n bá rí ọjọ́ wa tí wọ́n sì yan àwọn ohun wọnnì tí yío jẹ́ oníye lórí jùlọ fún wa, njẹ́ kìí ṣe bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí a ṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì bi? A niláti bi ara wa léèrè léraléra pé, ‘Kini ìdí tí Olúwa fi mísí Mọ́mọ́nì láti fi [ìtàn yí] sínú àkọsílẹ̀ rẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo ni mo le kọ́ làti inú [ìkìlọ yí] láti ràn mí lọ́wọ́ gbé ìgbé ayé ninu ọjọ́ ati ọjọ́ orí yí?’”

Àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Benson ràn wá lọ́wọ́ làti ní òye pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì kìí ṣe àkọsílẹ̀ itàn kan nípàtàkì tí ó nwò ohun tó ti kọjá. Dípò bẹ́ẹ̀, ìwé mímọ́ púpọ̀ yí nwò ọjọ́ iwájú ó sì ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì, àwọn ìbáwí, àti àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó wà fún àwọn ipò àti àwọn ìpèníjà ti ọjọ́ wa. Nítorínáà, Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ìwé nípa ọjọ́ iwájú wa àti àwọn àkókò nínú èyí tí a ngbé nísisìyí tí a sì ṣì máa gbé.

Mo gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ ti Ẹmí Mímọ́ bí a ti nṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì fún wa nisisìyí ní òní láti inú ìwé Hẹ́lámánì nínú ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Àwọn ará Néfì àti Àwọn ara Lámánì

Àkọsílẹ̀ Hẹ́lámánì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe àpéjúwe àwọn ènìyàn kan tí wọ́n nfojúsọ́nà fún ìbí Jésù Krístì. Ìlàjì sẹ́ntíúrì tí wọ́n sọ nínú àkọsílẹ̀ ìwé mímọ́ ṣe àlàyé ìyípadà àti òdodo ti àwọn ara Lámánì àti ìwà búburú, ìyapa-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́, àti àwọn ìríra ti àwọn ara Néfì.

Oríṣiríṣi àwọn àfiwé àti àwọn ìyàtọ̀ láàrin àwọn ara Néfì àti àwọn ara Lámánì láti inú àkọsílẹ̀ àtijọ́ yí jẹ́ èyítí ó kọ́ni jùlọ fún wa ní òni.

“Àwọn ara Lámánì, èyítí ó pọ̀ jù nínú wọn, ti di olódodo ènìyàn, tóbẹ̃ tí ìwà ododo wọn tayọ ti àwọn ará Néfì, nítorí ìwà ìtẹramọ́ wọn àti àìyísẹ̀padà wọn kúrò nínú ìgbàgbọ́ náà.

“[Ati pé] ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Néfì ni ó wà tí wọ́n ti di líle àti àìronúpìwàdà àti oníwà búburú púpọ̀, tóbẹ̃ tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti gbogbo ìwàásù àti sisọtẹ́lẹ̀ èyítí ó wá sí ààrin wọn.”

“Àti báyĩ àwa ríi pé àwọn ará Nífáì bẹ̀rẹ̀sí rẹ̀hìn nínú àìgbàgbọ́, wọ́n sì dàgbà nínú ìwà búburú àti àwọn ìwà ìríra, nígbà tí àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà gidigidi nínú ìmọ̀ Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ni, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí pa àwọn ìlànà àti àwọn òfin rẹ̀ mọ́, àti láti máa rìn nínú òtítọ́ àti ìdúróṣinṣin níwájú rẹ̀.

“Báyĩ ni a sì ríi tí Ẹ̀mí Olúwa bẹ̀rẹ̀sí fà sẹ́hìn ní ọ̀dọ̀ àwọn ará Néfì, nítorí ìwà búburú àti líle ọkàn wọn.

“Báyĩ ni a sì ríi tí Olúwa bẹ̀rẹ̀sí da Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lé orí àwọn ará Lámánì, nítorí ìrọ̀rùn àti ìfẹ́-inú wọn làti gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ rẹ̀.”

Bóyá abala tí ó jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ àti yíyanilẹ́nu jùlọ nínú rírẹ̀hìn sínú ìyapa-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́ yí nípasẹ̀ àwọn ará Néfì ni pé “gbogbo àwọn àìṣedẽdé wọ̀nyí wá sí ọ̀dọ̀ wọn ní àlàfo tí kìí ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.”

Àwọn ará Néfì Yí Kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Báwo ni àwọn olódodo ènìyàn nígbàkan rí ṣe le di líle àti búburú láàrin àkókò kúkúrú bẹ́ẹ̀? Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe le gbàgbé Ọlọ́run kíákíá bẹ́ẹ̀ ẹnití ó ti bùkún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀ tó bẹ́ẹ̀?

Ní ọ̀nà tó lágbára tó sì jinlẹ̀, àpẹrẹ àìtọ́ àwọn ará Néfì jẹ́ ẹ̀kọ́ fúnwa lóni.

“Ìgbéraga … bẹ̀rẹ̀sí wọlé … sínú ọkàn àwọn ènìyàn náà tí wọ́n ti jẹ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ ti ìjọ Ọlọ́run … nítorí àwọn ọrọ̀ wọn tí ó pọ̀ gidigidi àti ìṣe-rere wọn nínú ilẹ̀ náà.”

“[Wọ́n] gbé ọkàn [wọn] lé orí ọrọ̀ àti awọn ohun asán ayé yí” “nítorí ìgbéraga náà èyítí [wọ́n] … ti gbà lãyè láti wọlé [sínú] ọkàn wọn, èyítí … ó ru [wọ́n] sókè kọjá èyítí ó dára nítorí ọrọ̀ [wọn] tí ó pọ̀ gidigidi!”

Àwọn ohùn ìgbàanì láti inu eruku nbẹ̀ wá lóni láti kọ́ ẹ̀kọ́ àìlópin yí pé: ìṣerere, àwọn ohun ìní, àti ìrọ̀rùn máa ndi àdàlù tó lágbára kan tí ó le darí olódodo pàapàá láti mu májèlé ti-ẹ̀mí ìgbéraga.

Fífi àyè gba ìgbéraga lati wọ inú ọkàn wa le mú kí a fi ohun èyítí ó jẹ́ mímọ́ ṣe ẹlẹ́yà, ṣe àìgbàgbọ́ nínú ẹ̀mi ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn; tẹ àwọn òfin Ọlọ́run mọ́lẹ̀ ní abẹ́ ẹsẹ̀ wa; sẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; lé jáde, ṣe ẹlẹ́yà, kí a sì pẹ̀gàn àwọn wòlíì; àti kí a gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wa àti “kí a máṣe fẹ́ kí Olúwa Ọlọ́run [wa], ẹnití ó dá [wa], kí ó ṣe àkóso kí ó sì jọba lóri [wa].”

Nítorínáà, bí a kò bá jẹ́ olõtọ́ kí a sì nígbọràn, a lè yí ìbùkún ìṣerere tí Ọlọ́run-fúnni sí ègún agbéraga èyítí ó le mú wa yà kí ó sì dààmú wa kúrò nínù àwọn òtítọ́ ayérayé àti àwọn ìṣíwájú-ipò pàtàkì ti ẹ̀mí. A gbọ́dọ̀ fi ìgbà-gbogbo wà ní ìṣọ́ra tako èrò orí kíka araẹni sí pàtàki láti inu ìgberaga àti mímú-tóbi, àṣìṣe wíwọ̀nwò ànitó-araẹni ti ara wa, àti lílepa ti araẹni dipò sísin àwọn ẹlòmíràn.

Bí a ti nfi pẹ̀lú ìgbéraga fojúsùn sí ara wa, a njẹ́ pípọ́nlójú bákannáà pẹ̀lú ìfọ́jú ti ẹ̀mí a sì npàdánù púpọ̀, púpọ̀ jùlọ, tàbí bóyá gbogbo ohun tó nṣẹlẹ̀ láàrin àti ní ayíka wa. A kò le wò tàbi fojú sùn sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì bíi “àmì” náà bi a bá nrí ara wa nìkan.

Irú ìfọ́jú ti ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ bákannáà le mu kí a yà jáde ninu ọ̀nà òdodo, ṣubú kúrò sínú àwọn ipa ọ̀nà tí a kà léèwọ̀, ki a sì di sísọnù. Bí a ti nfi pẹ̀lú ìfọ́jú “yà sínú àwọn ọ̀nà ti[wa]” ti a si ntẹ̀lé àwọn àbùjá apanirun, a ntẹ̀ sí gbígbáralé òye ti ara wa, yíyangàn nínú okun ti ara wa, a sì ngbẹ́kẹ̀lé ọgbọ́n ti ara wa.

Sámúẹ́lì ara Lámánì ṣe àkópọ̀ yíyí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa àwọn ará Néfì ní ṣókí: “Ẹ̀yin ti lépa ní gbogbo ọjọ́ ayé yín fún èyítí ẹ̀yin kò le gbà; ẹ̀yin sì ti lépa fún inú dídùn nínú ṣíṣe àìṣedẽdé, ohun èyítí ó tako ìwà àdánidá ti òdodo náà èyítí ó wà nínú Ọba wa nlá àti Ayérayé.”

Mọ́mọ́nì ṣàkíyèsí pé, “Àwọn púpọ̀jù lára àwọn ènìyàn nã [dúró] nínú ìgbéraga àti ìwà búburú wọn, àwọn díẹ̀ sì [rìn] pẹ̀lú ìkíyèsára síi níwájú Ọlọ́run.”

Àwọn ará Lámánì Yípadà sí Ọlọ́run

Nínú Ìwé Hẹ́lámánì, òdodo púpọ̀síi ti àwọn ará Lámánì pèsè ìyàtọ̀ kedere sí yíyára àjórẹ̀hìn ti ẹ̀mí ti àwọn ará Néfì.

Àwọn ará Lámánì yípadà sí Ọlọ́run a sì mú wọn wá sí ìmọ̀ òtítọ́ nípa gbígbà àwọn ìkọ́ni inú àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn wòlíì gbọ́, lílo ìgbàgbọ́ ninu Olúwa Jésù Krístì, ríronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti níní ìrírí ìyípadà nlá ti ọkàn.

“Nítorínã, iye àwọn tí wọ́n ti wá sí èyí, ẹ̀yin mọ̀ fún ara yín pé ẹ wà ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti ìdúróṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ nã, àti nínú ohun nã nípasẹ̀ èyítí a ti sọ nwọ́n di òmìnira.”

“Ẹ níláti ríi pé apákan púpọ̀ nínú [àwọn ará Lámánì] wà ní ipa ọ̀nà ojúṣe wọn, wọ́n sì nrìn pẹ̀lú ìkíyèsára níwájú Ọlọ́run, wọ́n sì fiyèsí láti pa àwọn òfin rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ mọ́ . …

“… Wọ́n ntiraka pẹ̀lú aápọn láìkáarẹ̀ pé kí wọn ó le mú ìyókù àwọn arákùnrin wọn wá sínú ìmọ̀ òtítọ́ náà.”

Bíi àyọrísí, “òdodo [ti àwọn ará Lámánì] tayọ ti àwọn ará Néfì, nítorí ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti ìdúróṣinṣin wọn ninu ìgbàgbọ́ náà.”

Ìkìlọ̀ àti Ìlérí Kan

Mórónì sọ pe: “Ẹ kíyèsĩ, Olúwa ti fi àwọn ohun nla àti yíyanilẹ́nu hàn sí mi nípa eyĩnì tí ó gbọ́dọ̀ wá ní àìpẹ́, ní ọjọ nã nígbàtí àwọn ohun wọnyĩ yíò jáde wa ní ãrín yín.

“Ẹ kíyèsĩ, èmi nbá yín sọ̀rọ̀ bí ẹnipé ẹ̀yin wà níhìn yĩ, síbẹ̀ ẹ̀yin kò sì níhìn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, Jésù Krístì ti fi yín hàn sí mi, èmi sì mọ àwọn ìṣe yín.”

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì nwò sí ọjọ́ iwájú ó sì ní àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́, àwọn ìbáwí, àti àwọn ẹ̀kọ́ tí a gbèrò fún èmi àti ẹ̀yin nínú àwọn ipò àti àwọn ìpèníjà ti ọjọ́ wa.

Ìyapa-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́ le wáyé ní àwọn ìpele méjì pàtàkì—agbo agbékalẹ̀ àti ẹnìkọọkan. Ní ìpele ti agbo agbékalẹ̀, Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kì yío jẹ́ sísọnù nípasẹ̀ ìyapa-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́ tàbí kí a mú un kúrò ní ilẹ̀ ayé.

Wòlíì Joseph Smith kéde: “Òṣùwọ̀n Òtítọ́ ni a ti gbé kalẹ̀; kò sí ọwọ́ àìmọ́ tí ó lè dá iṣẹ́ náà dúró ní lilọsíwájú … ; òtítọ́ Ọlọ́run yíò lọ síwájú pẹ̀lú ìgboyà, tọlátọlá, àti ní òmìnira, títí tí yío fi wọnú gbogbo ìpín ilẹ̀-ayé, bẹ gbogbo ibi gíga wò, gbá gbogbo orílẹ̀-èdè, àti láti dún ní gbogbo ètí, títí tí gbogbo èrò Ọlọ́run a fi di ṣíṣe parí àti tí Jèhófàh nlá yíò wípé iṣẹ́ náà ti ṣetán.”

Ní ìpele ti ẹnìkọ̀ọ̀kan, olukúlùkù wa gbọdọ̀ “kíyèsára fún ìgbéraga, bi bẹ́ẹ̀kọ́ [a] ó dàbí àwọn ará Néfì ìgbà àtijọ́.”

Njẹ́ kí èmi dábàá pé bí ẹ̀yin tàbí èmi bá gbàgbọ́ pé a ní ànító agbára áti ìpinnu láti yẹra fún ìbàjẹ́ ìgbéraga, nígbànáà bóyá a ti njìyà láti ọwọ́ àrùn aṣekúpani ti ẹ̀mi yi. Ní kúkúrú, bí ẹ̀yin tàbí èmi kò bá gbàgbọ́ pé a le jẹ́ pípọ́nlójú pẹ̀lú àti nípasẹ̀ ìgbéraga, nígbànáà a jẹ́ aláìlágbára a sì wa nínú ewu ti ẹ̀mí. Ní àlàfo ti kìí ṣe àwọn ọjọ́, ọ̀sẹ̀, oṣù, tàbí ọdún púpọ̀, a lè pàdánù ẹ̀tọ́-ìbí wa ti ẹ̀mí fún ohun tó kéré ju àbàṣà àṣáró kan lọ.

Ṣùgbọ́n, bí ẹ̀yin tàbí èmi ba gbàgbọ́ pé a le jẹ́ pípọ́nlójú pẹ̀lú àti nípasẹ̀ ìgbéraga, nígbànáà a ó máa fi léraléra ṣe àwọn ohun kékèké àti rírọrùn tí yío dáàbò bò wá tí yío sì rànwá lọ́wọ́ lati dà “bí ọmọdé, olùgbọ́ràn, oníwàtútù, onírẹ̀lẹ̀, onísùúrù, kíkún fún ìfẹ́, tó ṣetán láti jọ̀wọ́ sí ohun gbogbo tí Olúwa rí pé ó tọ́ láti mú bá [wa].” “Ìbùkún ni fún àwọn tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀ láì fi ipá mú láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.”

Bi a ti ntẹ̀lé ìmọ̀ràn Ààrẹ Benson tí a sì nbi ara wa léèrè ìdí tí Olúwa fi mí sí Mọ́mọ́nì láti fi àwọn àkọsílẹ̀, ìkìlọ̀, àti àwọn ìbáwí tí o ṣe sí inú ìkékúrú rẹ̀ ti ìwé Hẹ́lámánì, mo ṣe ìlérí pé a ó ní òye ìwúlò àwọn ìkọ́ni wọ̀nyí sí àwọn ipò kan ti ìgbé ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí wa lóni. Bí a ti nṣe àṣàrò àti àròjinlẹ̀ àkọsílẹ̀ onímísí yí, a ó di alábùkún-fún pẹ̀lú àwọn ojú láti rí, etí láti gbọ́, inú láti mọ̀, àti ọkàn láti ní òye àwọn ẹ̀kọ́ tí a níláti kọ́ láti “kíyèsára fún ìgbéraga, bi bẹ́ẹ̀kọ́ [a ó] wọ inú ìdẹwò.”

Mo fi tayọ̀tayọ̀ jẹri pé Ọlọ́run Baba Ayérayé ni Baba wa. Jésù Krístì ni Àyànfẹ́ Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Nìkanṣoṣo . Òun ni Olùgbàlà wa. Mo si jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ti nrìn nínú ìwà-tútù ti ẹ̀mí Olúwa, a ó yẹra a ó sì borí ìgbéraga a ó sì ní àláfíà ninu Rẹ̀. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín.