Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Fífi Ìfẹ́ Wa Sí Ìbámu pẹ̀lú Tirẹ̀
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


15:20

Fífi Ìfẹ́ Wa Sí Ìbámu pẹ̀lú Tirẹ̀

Títẹ̀lé ìfẹ́ Olúwa nínú ayé wa yíò mú wa rí píálì iyebíye jùlọ nínú ayé—ìjọba ọ̀run.

Nínu òwe náà, Olùgbàlà sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin oníṣòwò kan tí ó nṣe ìwákiri fún “àwọn píálì rere.” Ní ìgbà ìwákiri ọkùnrin oníṣòwò náà, ó rí ọ̀kan “lára píálì olówó iyebíye.” Bákannáà, ní èrò láti gba píálì títóbi náà, ọkùnrin yí ní láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, èyí tí ó fi ìṣíléti àti pẹ̀lú ayọ̀ ṣe.

Nípasẹ̀ òwe kúkúrú àti elérò yí, Olùgbàlà kọ́ni dáradára pé ìjọba ọ̀run ni a fi wé píálì àìlóye, nítòótọ́ ìṣura iyebíye jùlọ tí a níláti fẹ́ lórí ohun gbogbo míràn. Òtítọ́ náà pé ọkùnrin oníṣòwò náà ta gbogbo àwọn ohun ìní rẹ̀ láti gba píálì oníyebíye náà fihàn kedere pé a níláti fi ọkàn àti ìfẹ́-inú wa sí ìbàmu pẹ̀lú ìfẹ́ Olúwa kí a si fi ìfẹ́ ṣe ohun gbogbo tí a lè ṣe ní ìgbà ìrìnàjò ayé-ikú wa láti ní àwọn ìbùkún ayérayé ti ìjọba Ọlọ́run.

Láti jẹ́ yíyẹ ti èrè nlá yí, a nílò dájúdájú, ní àárín àwọn ohun míràn, láti fi ìtiraka dídárajùlọ wá funni láti gbé àwọn ìlépa ìmọtara-ẹni-nìkan sẹgbẹ́ kí a sì pa eyikeyi ìdìmọ́ tí yíò dí wá mú kúrò nínú ìfarasìn sí Olúwa tì àti àwọn ọ̀nà gígajù àti mímọ́ Rẹ. Àpóstélì Páùlù tọ́ka sí àwọn ìlépa wọ̀nyí bí “ní[ní] ọkàn Krístì.” Bí a ti ṣe àpẹrẹ nípasẹ̀ Jésù Krístì, èyí túmọ̀sí “[ṣíṣe] àwọn ohun wọnnì tí ó nmú inú [Olúwa dùn]” nínú ayé wa nígbàgbogbo, tàbí bí àwọn ènìyàn kan ṣe nsọ nísisìyí, èyí ni “ṣíṣe ohun tí ó nṣiṣẹ́ fún Olúwa.”

Ní ọgbọ́n ìhìnrere kan, “[ṣíṣe] àwọn ohun wọnnì tí ó nmú inú [Olúwa dùn nígbàgbogbo]” bá fífi ìfẹ́ wa sílẹ̀ sí ìfẹ́ Rẹ̀ mu. Olùgbàlà fi pẹ́lú èrò kọ́ni ní pàtàkì ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ yí nígbàtí ó nkọ́ àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ lẹkọ.

“Nítorí èmi sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ ti ara mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.

“Èyí sì ni ìfẹ́ Baba èyítí ó rán mi, pé nínú gbogbo èyí tí ó ti fún mi èmi kò níláti sọ ohunkankan nù, ṣùgbọ́n láti gbé e sókè lẹ́ẹ̀kansi ní ọjọ́ ìkẹhìn.

“Èyí sì ni ìfẹ́ ẹnití ó rán mi, pé gbogbo ẹni tí ó bá rí Ọmọ, tí ó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, lè ní ìyè ayérayé: Èmi ó sì gbé e sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn.”

Olùgbàlà ṣe àṣeyege ipele ìtẹríba pípé àti àtọ̀runwa sí Baba nípa fífi àyè gba ìfẹ́ Rẹ̀ láti di gbígbé mì nínú ìfẹ́ Baba. Ó wí nígbàkan pé, “Ẹnití ó rán mi wà pẹ̀lú mi: Baba kò tíì fi mí sílẹ̀; nítorí èmi nṣe àwọn ohun wọnnì tí ó dùn mọ ọ nínú nígbàgbogbo.” Nínú ìkọ́ni Wòlíì Joseph Smith nípa àròkan àti ìrora Ètùtù, Olùgbàlà wípé:

“Nítorí kíyèsi, Èmi, Ọlọ́run, ti jìyà àwọn ohun wọ̀nyí fún gbogbo ènìyàn, kí wọ́n mà lè jìyà bí wọ́n bá ronúpìwàdà; …

“Ìjìyà èyí tí ó mú èmi tikara mi, àní Ọlọ́run, tí ó tóbi ju ohun gbogbo lọ, láti gbọn-rìrì nítorí ìrora, àti láti ṣẹ̀jẹ̀ nínú gbogbo ihò ara, àti láti jìyà ní ara àti ẹ̀mí—àti láti fẹ́ pé kí èmi máṣe mu nínú ago kíkorò náà, kí èmi sì fàsẹ́hìn—

“Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ògo ni fún Baba, àti pé èmi kópa mo sì ṣe àṣepari àwọn ìmúrasílẹ̀ mi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”

Ní ìgbà àtìpó wa nínú ayé ikú, à njá-ìjàkadì léraléra pẹ̀lú ohun tí a rò pé a mọ̀, ohun tí a rò pé ó dárajù, àti ohun tí a lérò pé ó nṣiṣẹ́ fún wa, bí ó ti lòdì sí níní òye ohun tí Baba Ọ̀run mọ̀ nítòótọ́, ohun tí ó darajùlọ ní ayérayé, àti ohun tí ó nṣiṣẹ́ pátápátá fún àwọn ọmọ nínú ètò Rẹ̀. Ìjàkadì nlá yí lè di líle gan an, nípàtàkì ní yíyẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ìwé-mímọ́ fún ọjọ́ wa wò : “Mọ èyí bákannáà, pé ní ọjọ́ ìkẹhìn … àwọn ènìyàn yíò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, … olùfẹ́ ìgbádùn ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ.”

Àmì kan tí ó fi ìmúṣẹ ti àsọtẹ́lẹ̀ yí hàn ni ó ngbèrú lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ayé, tí a gbà nípasẹ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, ènìyàn tí wọ́n ndi píparun pẹ̀lú arawọn tí wọ́n sì nkede lemọ́lemọ́, “Bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó gbé ìgbésí ayé òtítọ́ ti ara mi tàbí èmi ó ṣe ohun tí ó nṣiṣẹ́ fún mi.” Bí Àpóstélì Páùlù ti sọ, wọ́n “nwá ti ara wọn, kìí ṣe àwọn ohun èyí tí ó jẹ́ ti Jésù Krístì.” Ọ̀nà ríronú yí ni ó dabí ó yẹ ní jíjẹ́ “ojúlówó” nípa àwọn wọnnì tí wọ́n ngba àwọn ìlépa ìmọtara-ẹni-nìkan mọ́ra, àwọn ààyò araẹni, tàbí nfẹ́ láti yẹ ní irú ìwà kan tí kò bá ètò ìfẹ́ni Ọlọ́run mu àti ìfẹ́ Rẹ fún wọn léraléra. Bí a bá jẹ́ kí ọkàn àti inú wa rọ̀mọ́ ríronú ní ọ̀nà yí, a lè dá àwọn ìdènà pàtàkì sílẹ̀ fún ara wa ní gbígba píálì oníyebíye jùlọ tí Ọlọ́run ti fi pẹ̀lú ìfẹ́ murasílẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀—ìyè ayérayé.

Nígbàtí ó jẹ́ òtítọ́ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa nrin ìrìnàjò bí ẹnìkọ̀ọ̀kan jíjẹ́-ọmọlẹ́hìn ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú, ní títiraka láti pa ọkàn àti inú wa mọ́ ní óókan Jésù Krístì, a nílò láti ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí a sì ṣọ́ra léraléra kí a maṣe wọnú àdánwò láti gba irú ìmọ̀ ọgbọ́n ayé yí sínú ayé wa. Alàgbà Quentin L. Cook wí pé “jíjẹ́ ẹni bíi ti Krístì lódodo ni àní ni àfojúsùn pàtàkì ju jíjẹ́ ojúlówó.”

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, nígbàtí a bá yàn láti jẹ́ kí Ọlọ́run jẹ́ ipa alágbára jùlọ nínú ayé wa lórí àwọn ìlépa sísin-araẹni, a lè ní ìlọsíwájú nínú jíjẹ́-ọmọlẹ́hìn wa kí a sì mú okun wa pọ̀si láti da inú àti ọkàn wa pọ̀ mọ́ Olùgbàlà. Ní ọ̀nà míràn, nígbàtí a kò bá fi àyè gba ọ̀nà Ọlọ́run láti borí nínú ayé wa, a ó fi wa sílẹ̀ sí arawa, àti láìsí ìtọ́nisọ́nà ìmísí Olúwa, a lè fẹ́rẹ̀ yẹ fún ohunkóhun tí a ṣe tàbí máṣe. Bákannáà a lè dá gáfára fún arawa nípa ṣíṣe àwọn ohun ní ọ̀nà arawa, ní sísọ ní ipa pé, “Èmi kàn nṣe àwọn nkan ní ọ̀nà mi.”

Ní ọ̀ràn kan, nígbàtí Olùgbàlà nkede ẹ̀kọ́ Rẹ̀, àwọn ènìyàn kan, nípàtàkì àwọn Farisí olódodo-araẹni, kọ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kéde gbangba pé wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ Ábráhámù, ó túmọ̀sí pé ìran yíò fún wọn ní àwọn ànfàní pàtàkì ní ojú Ọlọ́run. Làákàyè náà darí wọn láti gbáralé òye ti ara wọn àti láti ṣe àìgbàgbọ́ sí ohun tí Olùgbàlà nkọ́ni. Àdẹ̀hìnbọ̀ àwọn Farisí sí Jésù ni ẹ̀rí kedere pé ìwà ìpànìyàn wọn kò fi àyè sílẹ̀ nínú ọkàn wọn fún àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà àti ọ̀nà Ọlọ́run. Ní ìdáhùn, Jésù fi ọgbọ́n àti pẹ̀lú ìgboyà kéde pé bí wọ́n bá jẹ́ àwọn olótítọ́ ọmọ Ábráhámù, wọn yíò ṣe àwọn iṣẹ́ Ábráhámù, ní ṣíṣe àyẹ̀wò nípàtàkì pé Ọlọ́run Ábráhámù ndúró níwájú wọn ó sì nkọ́ wọn ní òtítọ́ ní àkokò náà gan.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí ẹ ti lè ri, ṣíṣe ìṣe lórí làákàyè ti ibi-ìdárayá “ohun to nṣiṣẹ́ fún mi díje ohun tí ó nṣiṣẹ́ fún Olúwa” kìí ṣe ìtẹ́sí tí ó jẹ́ titun àìlékejì kan sí ọjọ́ wa. Ó jẹ́ làákáyè ọjọ́ pípẹ́ tí ó sọdá àwọn sẹ́ntúrì tí ó sì nfọ àwọn ọlọgbọ́n-ní-ojú-arawọn lójú léraléra tí ó sì ndàmú tí ó sì nmú rírẹ̀ bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ọlọ́run. Làákàyè yí, lóòótọ́, ni ìtànjẹ àtijọ́ ọ̀tá; ó jẹ́ ipa-ọ̀nà ẹ̀tàn tí ó nfi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn ọmọ Ọlọ́run kúrò nínú òtítọ́ àti ipa-ọ̀nà májẹ̀mú òdodo. Nígbàtí àwọn ipò araẹni bí irú àwọn ìpèníja jíìnì, ẹ̀kọ́ ilẹ̀-ayé, àti àìlera ara àti ọpọlọ ṣe nní ipa lórí ìrìnàjò wa, nínú àwọn ohun tí ó pọndandan nítòótọ́, àyè inú wà níbití a ti ní òmìnira láti yàn bóyá tàbí a ó pinnu láti tẹ̀lé àwòṣe tí Olúwa ti múrasílẹ̀ fún ìgbésí ayé wa. Nítòótọ́, “ó ti la ipa-ọ̀nà ó sì dari ọ̀nà náà, àti ní gbogbo àmì [ṣàpèjúwe].”

Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọẹ́hìn Krístì, a ní ìfẹ́-inú láti rìn ní ipa-ọ̀nà tí Ó làsílẹ̀ fún wa ní ìgbà iṣẹ̀-irànṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀. A kò ní ìfẹ-inú láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ nìkàn àti gbogbo ohun tí yíò mú inú Rẹ̀ dùn ṣùgbọ́n kí a wá láti bá A dọ́gba. Bí a ti ntiraka láti jẹ́ òtítọ́ sí gbogbo májẹ̀mú tí a ti wọ inú rẹ̀ tí a sì ngbé nípa “gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó njáde láti ẹnu Ọlọ́run,” a ó gba ààbò ní àtakò sí ṣíṣubú ìpalára sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe ti ayé—àwọn àṣìṣe ìmọ̀ ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ tí yíò darí wa kúrò nínú àwọn píálì iyebíye jùlọ wọnnì.

Mo ti ní ìmísí ti araẹni nípa bí irú ìtẹríba ti ẹ̀mí sí Ọlọ́run ṣe ti ní ipá nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọẹ́hìn Krístì bí wọ́n ti yàn láti ṣe àwọn ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún tí ó sì ndùn ní ojú Olúwa. Mo mọ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó ní àìbalẹ̀-ọkàn nípa lílọ sí Míṣọ̀n ní ìmọ̀lára ìmísí láti lọ àti láti sin Olúwa nígbàtí ó fetísílẹ̀ sí olórí àgbà ti Ìjọ ní pínpín ẹ̀rí araẹni tirẹ̀ àti ìrírí mímọ́ ti sísìn bí òjíṣẹ́-ìhìnrere kan.

Nínú àwọn ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin yí, nísisìyí òjíṣẹ́-ìhìnrere tó padàbọ̀, wípé: “Bí mo ṣe fétísílẹ̀ sí ẹ̀rí Àpóstélì Olùgbàlà Jésù Krístì kan, mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run fún mi, mo sì ní ìfẹ́-inú láti pín ìfẹ́ náà pẹ̀lú àwọn míràn. Ní àkokò náà mo mọ̀ pé mo níláti sìn ní míṣọ̀n kan pẹ̀lú àwọn ẹ̀rù, iyèméjì, àti àníyàn mi. Mo ní ìmọ̀lára ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú àwọn ìbùkún àti ìlérí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Ní òní, mo jẹ́ ẹni titun; mo ní ẹ̀rí kan pé ìhìnrere yí jẹ́ òtítọ́ àti pé Ìjọ ti Jésù Krístì ni a ti múpadàbọ̀sípò lórí ilẹ̀-ayé.” Ọ̀dọ́mọkùnrin yí yan ọ̀nà Olúwa ó sì di àpẹrẹ ọmọẹ́hìn òtítọ́ kan ní gbogbo ìṣe.

Ọ̀dọ́mọbìnrin olótítọ́ kan pinnu láti máṣe fi àwọn òṣùwọ̀n rẹ̀ wọ́lẹ̀ nígbàtí a ní kí ó wọṣọ tí kò bójúmu láti wà ní ìbámu nínú ìpín òwò ti ilé-iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́-aṣọ níbití ó ti nṣiṣẹ́. Ní lílóye pé ara rẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run àti ibi tí Ẹ̀mí lè gbé, ó ní ìmọ̀lára láti gbé nípa òṣùwọn gíga ju ti ayé lọ. Òun kò jèrè ìgbẹ́kẹ̀lé nípa àwọn tí ó rí i ní gbígbé nípa òtítọ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ó di iṣẹ́ rẹ̀ mú, èyí tí ó wà nínú ewu ní àkokò kan. Ìfẹ rẹ̀ láti ṣe ohun tí ó ndùnmọ́ Olúwa, sànju ohun tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ayé, fun un ní májẹ̀mú ìgbẹ́kẹ̀lé ní àárín àwọn àṣàyàn líle.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, à nní ìdojúkọ lemọ́lemọ́ nípa irú àwọn ìpinnu kannáà nínú ìrìnàjò ojojúmọ wa. Ó gba ìgboyà àti ìfẹ́ ọkàn láti dádúró àti láti lépa àwòsínú òtítọ́ àti ọ̀kan-tútù láti dá wíwà àìlera ti ẹran-ara mọ̀ nínú ayé wa tí ó lè dínà okun wa láti fi arawa sílẹ̀ sí Ọlọ́run, àti nígbẹ̀hìn láti pinnu láti gba ọ̀nà Rẹ̀ sànju ti ara wa. Ìdánwò ìgbẹ̀hìn ti jíjẹ́-ọmọlẹ́hìn wa ni a rí nínú ìfẹ́ wa láti jùwọ́lẹ̀ kí a sì já ara wa àtijọ́ gbà kí a sì fi ọkàn wa sílẹ̀ àti gbogbo ẹ̀mí wa sí Ọlọ́run kí ìfẹ́ Rẹ̀ ó di tiwa.

Ọ̀kan lára àwọn àkokò ológo jùlọ ti ayé ikú nṣẹlẹ̀ nígbàtí a bá ṣàwárí ayọ̀ tí ó nwá nígbàtí a bá nfi ìgbàgbogbo ṣe àwọn ohun wọnnì tí “ó ṣiṣẹ́ fún Olúwa” àti “ohun tí ó nṣiṣẹ́ fún wa” bá di ọ̀kan àti irúkannáà! Láti fi àìyípadà àti àìjiyàn mú ìfẹ́ Olúwa jẹ́ tiwa bèèrè fún jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn ọlọ́lá àti akọni! Ní àkokò ọlánlá náà, à ndi yíyàsọ́tọ̀ sí Olúwa, a sì nfi ìfẹ́ wa sílẹ̀ sí I. Irú ìtẹríba ti-ẹ̀mí, ní sísọ bẹ́ẹ̀, jẹ́ dídára, alágbára, àti yíyíni-padà.

Mo jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé títẹ̀lé ìfẹ́ Olúwa nínú ayé wa yíò mú wa rí píálì iyebíye jùlọ nínú ayé—ìjọba ọ̀run. Mo gbàdúrà pé ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa, ní ìgbà tìwa àti ìyípo, yíò lè kéde, pẹ̀lú májẹ̀mú ìgbẹ́kẹ̀lé, sí Baba wa Ọ̀run àti Olùgbàlà Jésù Krístì pé “ohun tó nṣiṣẹ́ fún Yín, nṣiṣẹ́ fún mi.” Mo sọ àwọn ohun wọ̀nyí ní orúkọ mímọ́ Olùgbàlà Jésù Krístì, àmín.