Àwọn Ọmọkùnrin àti Ọmọbìnrin Ọlọ́run
A gbàgbọ́ nítòótọ́ pé a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run bí ó ti wà, àti pé nítorí ìyẹn, a ní ìlèṣe láti dàbíi Tirẹ̀.
Lónìí èmi fẹ́ láti sọ̀rọ̀ lórí ọkàn nínú àwọn òtítọ́ ìhìnrere ológo, aláyọ̀, àti alágbára jùlọ tí Ọlọ́run ti fihàn. Lákokò kannáà, ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àfiwé èyí tí a ti nṣàríwísí. Ìrírí kan tí mo ní ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn mú ìmọrírì mi jinlẹ̀ síi fún òtítọ́ ìhìnrere pàtó yìí.
Bíi aṣojú Ìjọ, wọ́n pè mí nígbàkan sí ìpàdé àpapọ̀ ẹ̀sìn kan níbi tí wọ́n ti kéde pé láti àkokò náà lọ wọn yíò dá gbogbo ìrìbọmi mọ̀ bíi ojúlówó tí o bá jẹ́ ṣíṣe nípasẹ̀ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn ìjọ Kristẹni yòókù, níwọ̀n ìgbà tí ìlànà náà bá jẹ́ ṣíṣe pẹ̀lu omi àti ní orúkọ ti Baba ati Ọmo àti Ẹmí Mímọ́. Lẹ́hìnnáà, a ṣàlàyé pé ìlànà yìí kò kan àwọn ìrìbọmi tí Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn nṣe.
Lẹ́hìn ìpàdé náà mo ní ànfààní láti wádìi jinlẹ̀ jinlẹ̀ sínú àwọn èrèdí fún ìyàsọ́tọ̀ náà pẹ̀lú adarí tó wà nídi ṣíṣe àbojútó ìkéde náà. A ní ìbáraẹnìsọ̀rọ̀ yíyanilẹ́nu tí ó si kún fún òye.
Ní kúkúrú, ó ṣàlàyé fún mi pé ìyàtọ̀ náà ní pàtàkì láti ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa pàtó nípa Àjọ Olórí-ọ̀run, èyí tí àwọn ẹ̀sìn Kristẹni míràn sábà máa npè ní Mẹ́talọ́kan. Mo fi ìmọrírì mi hàn fún bó ṣe lo àkokò náà láti ṣàlàyé àwọn ìgbàgbọ́ àti ìlànà ìjọ rẹ̀ fún mi. Ní ìparí ìbáraẹnìsọ̀rọ̀ wa, a gbá ara wa mọ́ra, a sì dágbére fúnra wa.
Bí mo ṣe nronú nípa ìjíròrò wa lẹ́hìnwá, ohun tí olórí yìí sọ nípa àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn ní àìlóye ohun tí ó pè ní “ìjìnlẹ̀ ti Mẹ́talọ́kan” dúró ní ọkàn mi. Kínni ohun tí ó ntọ́ka sí? Ó dára, ó ní í ṣe pẹ̀lú òye wa nípa irú àdánidá tí Ọlọ́run. A gbàgbọ́ pé Ọlọ́run Baba “jẹ́ ènìyàn tí a ti gbéga” pẹ̀lú ìṣelógo “ara ti ẹran àti àwọn egungun tí ó jẹ́ ojúlówó bíi ti ènìyàn; [àti] Ọmọ pẹ̀lú.” Bayi nígbàkugbà tí a bá nsọ̀rọ̀ nípa ìwà-ẹ̀dá ti Ọlọ́run, ní àwọn ọ̀nà kan a nsọ̀rọ̀ nípa ìwà-ẹ̀dá tiwa bákannáà.
Èyí sì jẹ́ òtítọ́ kìí ṣe nítorí pé a dá gbogbo wa “ní àwòrán [Rẹ̀], ní ìrísí [Rẹ̀], nìkan” ṣùgbọ́n bákannáà nítorí pé, bí Onípsálmù ti ṣe àkọsílẹ̀, Ọlọ́run wí pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́run; gbogbo yín sì jẹ́ ọmọ ẹni Gíga-Jùlọ.” Èyí jẹ́ ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye fún wa tí a wárí nísisìnyí pẹ̀lú dídé ti Ìmúpadàbọ̀sípò. Ní àkópọ̀, kìí ṣe ohun kankan tí ó pọ̀ tàbí kéré síi ju ohun tí àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere wa nkọ́ni bí ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́, ìpínrọ̀ àkọ́kọ́, ìlà àkọ́kọ́: “Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, awá sì jẹ́ Ọmọ Rẹ̀.”
Nísisìnyí, ẹ lè wí pé, “Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ pé àwa jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run.” Bẹ́ẹ̀ni, òtítọ́ nìyẹn, ṣùgbọ́n òye wọn lè yàtọ̀ díẹ̀ sí àyọrísí ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ rẹ̀ tí àwa fì ìdí rẹ̀ múlẹ̀. Fún Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn, ìkọ́ni yìí kìí ṣe àfiwé. Dípò bẹ́ẹ̀, a gbàgbọ́ nítòótọ́ pé gbogbo ènìyàn jẹ́ ọmọ Ọlọ́run gangan. Òun ni “Baba àwọn ẹ̀mí [wa],” àti nítorí èyí, a ní agbára-ìleṣe láti dà bìi Rẹ̀, èyí tó dà bí ẹnipé kò lè ṣeé rò sí àwọn kan.
Ó ti lé ní igba ọdún báyìí láti ìgbà tí Ìran Àkọ́kọ́ ti ṣí àwọn ilẹ̀kùn fún Ìmúpadàbọ̀sípò. Ní àkókò náà, ọ̀dọ́mọkùnrin Joseph Smith wá ìtọ́sọ́nà láti ọ̀run láti mọ ìjọ tí yíò dara pọ̀ mọ́. Nípasẹ̀ ìfihàn tó gbà ní ọjọ́ náà, àti nínú àwọn ìfihàn tí a fi fún un lẹ́hìnwá, Wòlíì Joseph gba ìmọ̀ nípa àdánidà ti Ọlọ́run àti ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Rẹ̀ bí àwa ọmọ Rẹ̀.
Nítorí èyí, a kọ́ ẹ̀kọ́ ní kedere síi pé Baba wa Ọ̀run ti kọ́ni ní ẹ̀kọ́ iyebíye yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ gan-an. Ẹ jẹ́kí ntọ́ka sí ó kéré tán àwọn àkọsílẹ̀ méjì láti inú àwọn ìwé-mímọ́ láti ṣàkàwé èyí.
Ẹ lè rántí àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run fún Mósè bí a ṣe kọ ọ́ sínú Píálì Olówo Iyebíye.
A kà pé “Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsíi, èmi ni Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, Àìlópin sì ni orúkọ mi.” Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, Mósè, mo fẹ́ kí o mọ̀ ẹnití èmí jẹ́. Lẹ́hìnnáà Ó fi kún un pé, “Sì wòó, ọmọ mi ni ìwọ íṣe.” Lẹ́hìnwá ó wí pé, “Mo sì ní iṣẹ́ kan fún ọ, Mósè, ọmọ mi; ìwọ sì wà ní àfijọ ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo.” Àti níkẹhìn, Ó parí pẹ̀lú, “Àti nísisìyí, kíyèsíi, ohun kan yìí ni èmi fi hàn sí ọ, Mósè, ọmọ mi.”
Ó dàbí ẹnipé Ọlọ́run ti pinnu láti kọ́ Mósè ó kéré tán òtítọ́ kan yìí pé: “Ìwọ ni ọmọ mi,” èyí tí Ó tún sọ ní ìgbà mẹ́ta ó kéré tán. Àní ò tilẹ̀ lè dárúkọ Mósè láì fi kun kíákíá pé ọmọ Òun níí ṣe.
Bí-ó-tilẹ̀-rí-bẹ́ẹ̀, lẹ́hìn ti a fi Mósè níkan sílẹ̀, ó nímọ̀lára àìlágbára nítorípé kò sí níwájú Ọlọ́run mọ́. Nígbànáà ni Sátánì wá láti dán an wò. Ṣé o lè wo àpẹrẹ kan níbí? Ohun àkọ́kọ́ tí Sátánì sọ fún Mósè ni, “Mósè, ọmọ ènìyàn, fi orí balẹ̀ fún mi.”
Nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ìbéèrè Sátánì láti fi orí balẹ̀ fún fún lè jẹ́ ìyọlẹ̀nu nìkan. Ìdánwò pàtàkì kan fún Mósè nínú àkokò àìlágbára náà ni láti dààmú kí ó sì gbàgbọ́ pé òun jẹ́ “ọmọ ènìyàn,” nìkan dípò ọmọ Ọlọ́run.
“Ó sì ṣe tí Mósè wo Sátánì ó sì wí pé: Tani ìwọ? Nítorí kíyèsi, ọmọ Ọlọ́run ni èmi ìṣe, ní àwòrán ti Ọmọ Bíbí rẹ̀ Kanṣoṣo.” Pẹ̀lú ìdùnmọ́ni, Mósè kò dààmú, òun kò sì fi ààyè gba ara rẹ̀ láti di yíyọlẹ́nu. Ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ẹni tó jẹ́ gan-an.
Àkọsílẹ̀ tí ó tẹ̀le ni a rí nínú Máttéù 4. Àwọn onkàwé ti gba èyí “àwọn àdánwò mẹ́ta ti Jésù,” bí ẹnipé Olúwa ti gbìdánwò ní ìgbà mẹ́ta, èyí tí ó jẹ́ pè kìí ṣe bẹ́ẹ̀.
Àwọn ọgọọ́gọ́ọ̀rún gálọ́nù ínkì ní a ti lò láti ṣe àlàyé ìtumọ̀ àti àkoónú ti àwọn ìdánwò wọ̀nyí. Bí a ti mọ̀, orí-ìwé náà bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àlàyé pé Jésù ti lọ sínú aṣálẹ̀, “àti nígbàtí ó sì ti gbàwẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, lẹ́hìn náà, ebi npa á.”
Ìdánwò àkọ́kọ́ ti Sátánì ní í ṣe pẹ̀lú títẹ́ àwọn àìní Olúwa nípa ti ara lọ́rùn nìkan. “Pàṣẹ pé kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà,” ó pè é níjà.
Ìtànjẹ kejì ní í ṣe pẹ̀lú dídán Ọlọ́run wò: “Bẹ́ sílẹ̀ fúnra rẹ: nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, Yíò pàṣẹ fún àwọn ángẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ.”
Níkẹhìn, ìdánwò Sátánì kẹta tọ́ka sí àwọn ìfojúsùn àti ògo ayé. Lẹ́hìn tí a ti fi “gbogbo ìjọba ayé han Jésù, … [Sátánì] wí fún un pé, Gbogbo nkan wọ̀nyí li èmi ó fi fún ọ, bí ìwọ́ bá wólẹ̀ kí o sì foríbalẹ̀ fún mi.”
Ní òtítọ́, ìdánwò ìgbẹ̀hìn ti Sátánì lè má ní í ṣe tóbẹ́ẹ̀ sí àwọn ìmúnibínú mẹ́ta pàtó wọnnì, ó sì ní i ṣe díẹ̀ síi pẹ̀lú dídán Jésù Krístì wò láti ṣiyèméjì àdánidá àtọ̀runwá Rẹ̀. Ó kéré tán lẹ́ẹ̀mejì, ìdánwò náà jẹ́ ṣíṣaájú pẹ̀lú ẹ̀sùn ìpeniníjà láti ọ̀dọ̀ Sátánì “Bí ìwọ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run”—bí ìwọ bá gbà á gbọ́ lootọ, lẹ́hìnnáà ṣe èyí tàbí ìyẹn.
Ẹ jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ní kété ṣaájú kí Jésù tó lọ sí aginjù láti gbàwẹ̀ àti àdúrà: a rí àkọọ́lẹ̀ ti ìrìbọmi Krístì. Nígbàtí ó sì ti inú omi jáde, ohùn “kan láti ọ̀run wá, wípé, Èyí ní àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹnití inú mì dùn sí gidigidi.”
Njẹ́ a rí àsopọ̀ náà bí? Njẹ́ a lè ṣe ìdámọ̀ àpẹrẹ kan bí?
Kò yani lẹ́nu pé nígbàkúgbà tí a bá nkọ́ wa nípa ìwà-ẹ̀dá àtọ̀runwá àti àyànmọ́-ìpín wa, ọ̀tá ti gbogbo òdodo náà a máa ndán wa wò láti pè wọ́n sínú ìbéèrè.
Àwọn ìpinnu wa yìó ti yàtọ̀ tó bí a bá mọ ẹnití a jẹ́ nítòótọ́.
À ngbé ní ayé ìpèníjà, ayé tí ariwo ti npọ̀ si, níbití àwọn ọlọ́lá ènìyàn ti ntiraka láti tẹnumọ iyì ẹ̀dá-ènìyàn wa, o kéréjù, nígbàtí àwa jẹ́ ti ìjọ tí a sì gba ìhìnrere kan mọ́ra tó gbé ìran-ojú wa sókè tí ó sì pè wá sínú ti ọ̀run.
Òfin Jésù pé kí a jẹ́ “pípé àní bí Baba [wa] tí nbẹ ní ọ̀run ti pé” jẹ́ àwòrán kedere ti àwọn ìfojúsọ́nà gíga Rẹ̀ àti àwọn ànfààní ayérayé wa. Nísisìyí, kò sí nínú èyí tí yíò ṣẹlẹ̀ mọ́júmọ́. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Jeffrey R. Holland, yìó ṣẹlẹ̀ “nígbẹ̀hìn.” Ṣùgbọ́n ìlérí náà ni pé bí a bá “wá sọ́dọ̀ Krístì,” a ó di ”pípé nínú rẹ̀.” Ìyẹn nbéèrè fún iṣẹ́ púpọ̀—kì í ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ti ọ̀run. Iṣẹ́ Rẹ̀!
Nísisìyí, ìròhìn ayọ̀ náà ni pé Baba wa ní Ọ̀run gan-an ni ẹni tó kéde pé, “Nítorí kíyèsĩ, èyí ni iṣẹ́ mi àti ògo mi—láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn ṣẹ.”
Ìpè Ààrẹ Nelson láti “ronú sẹ̀lẹ́stíà” túmọ̀ sí ìránnilétí ìyanu kan ti ìwà-ẹ̀dá àtọ̀runwá, ìpilẹ̀ṣẹ̀, àti ibi agbára ìleṣe wa ti a fẹ́ dé. A lè gba sẹ̀lẹ́stíà náà nípasẹ̀ ẹbọ ètùtù Jésù Krístì nìkan.
Bóyá ìdí nìyẹn tí Sátánì fi dán Jésù wò pẹ̀lú ìdánwò kannáà láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Máttéù ṣe àkọsílẹ̀ pé nígbàtí a so Jésù kọ́ lóri agbelebu, àwọn “tó nkọjá lọ gàn án, … wọ́n wípé, … Bí ìwọ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu.” Ògo ní fún Ọlọ́run pé kò fetísílẹ̀ ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ Ó pèsè ọ̀nà náà fún wa láti gba gbogbo àwọn ìbùkún sẹ̀lẹ́stíà.
Ẹ jẹ́kí a rántí nígbàgbogbo pé iye owó nlá kan wà tí a san fún ìdùnnú wa.
Mo jẹ́ ẹ̀rí bíi pẹ̀lú Páùlù Àpọ́sítélì pé “Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ njẹ́ ẹ̀rí pẹ̀lú ẹ̀mí wa, pé ọmọ Ọlọ́run ni àwa: bí a bá sì jẹ́ ọmọ, nígbànáà ajogún; ajogún ti Ọlọ́run, àti àjùmọ̀-jogún pẹ̀lú Krístì; bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ pé kí a jìyà pẹ̀lú rẹ̀, pé kí àwa bákannáà lè jẹ́ ṣíṣe lógo papọ̀.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.