Ẹ Tọ́jú Àwọn Gbòngbò, Àwọn Ẹ̀ka Yío sì Dàgbà
Àwọn ẹ̀ka ẹ̀rí yín yío fa agbára láti inú ìgbàgbọ́ yín tó jinlẹ̀ nínu Baba Ọ̀run àti Àyànfẹ̀ Ọmọ Rẹ̀.
Ilé Ìjọsìn Àtijọ́ kan ni Zwickau
Ọdún 2024 jẹ́ ohun kan bíi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì fún mi. Ó ṣe àmì ọdún 75 láti ìgbà ti a rì mí bọmi tí a sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ bíi ọmọ-ìjọ ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní Zwickau, Germany.
Jíjẹ́ ọmọ-ìjọ mi nínú Ìjọ Jésù Krístì jẹ́ iyebíye sími. Láti jẹ́ kíkà mọ́ ààrin awọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run, pẹ̀lú ẹ̀yin, arákùnrin ati arábìnrin mi, jẹ́ ọ̀kan lára awọn ọlá títóbijùlọ ti ayé mi.
Nígbàtí mo bá ronú nípa ìrìnàjò ara-ẹni mi nípa jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn, iyè mi máa nfigbà gbogbo lọ padà sí ilé atijọ́ kan ní Zwickau, níbití mo ti ní àwọn ìrántí aládùn ti wíwà ní àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa ti Ìjọ Jésù Krístì bi ọmọdé. Ibẹ̀ ni ibití irúgbìn ẹ̀rí mi ti gba ìtọ́jú àkọ́kọ́ jùlọ rẹ̀.
Ilé-ìjọsìn yí ní dùrù àtijọ́ kan tí nbá afẹ́fẹ́-ṣiṣẹ́. Ní olukúlùkù Ọjọ́ Ìsinmi ọ̀dọ́mọkùnrin kan njẹ́ yíyàn láti ti lẹ́fà tó lágbára kan to nfa àwọn ẹwìrì sókè ati sísàlẹ̀ láti mú dùrù náà ṣiṣẹ́. Mo ní ànfààní nígbàmíràn ní ṣíṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ pàtàkì yí.
Nígbàtí àwọn ìjọ bá nkọ àwọn àyànfẹ́ orin ísìn wa, èmi a máa fín pẹ̀lú gbogbo agbára mi kí afẹ́fẹ́ má baà tán nínú dùrù náà. Láti ibi ijoko olùfẹ́-afẹ́fẹ́, mo ní ìwòye nlá ti awọn fèrèsé kan onígíláàsì-kíkùn tó yanilẹ́nu, ọ̀kan nṣe àfijọ Olùgbàlà Jésù Krístì àti òmíràn nṣe àpèjúwe Joseph Smith ninu Igbó Ṣúúrú Mímọ́.
Mo ṣì le rántí àwọn ìmọ̀lára mímọ́ ti mo ní bí mo ti nwo àwọn fèrèsé tí ìtànsán-orùn ti ó ntàn nígbàtí mò nfetísílẹ̀ sí ẹ̀rí àwọn ènìyàn mímọ́ ati ní kíkọ àwọn orin ti Síónì.
Ní ibi mímọ́ náà, Ẹ̀mí Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀rí sí inú áti ọkàn mi pé ó jẹ́ òtítọ́: Jésù Krístì ni Olùgbàlà aráyé. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀. Wòlíì Joseph Smith rí Ọlọ́run Bàbá àti Jésù Krístì ó sì gbọ́ ohùn Wọn.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yí, nígbàti mo wà lẹ́nu iṣẹ́ rírán ní Europe, mo ní ànfàní láti padà sí Zwickau. Pẹ̀lu ẹ̀dùn, àyànfẹ́ ilé ìjọsìn àtijọ́ náà kò sí níbẹ̀ mọ́. Ó ti di wíwó lulẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn láti fi ààyè sílẹ̀ fún ilé gbígbé nlá kan.
Kínni Ó Jẹ́ Ti Ayérayé, atì Kínni Kò Jẹ́ Bẹ́ẹ̀?
Mo gbà pé ó jẹ́ ẹ̀dùn láti mọ̀ pé àyànfẹ́ ilé yí láti ìgbà èwe mi jẹ́ ìrántí lásán nísisìyí. Ó jẹ́ ilé mímọ́ sími. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ilé lásán.
Bíi àfijọ, ẹ̀rí ti ẹ̀mí tí mo jèrè láti ọ̀dọ̀ Ẹmí Mímọ́ ni àwọn ọdún púpọ̀ sẹ́hìn náà kò tíì kọjá lọ. Ní tòótọ́, ó ti di alágbára síi. Àwọn ohun tí mo kọ́ ní ìgbà ọ̀dọ́ mi nípa pàtàkì àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì ti jẹ́ ìpìlẹ̀ dídúróṣinṣin ní gbogbo ọjọ́ ayé mi. Àsopọ̀ májẹ̀mú ti mo gbéró pẹ̀lú Baba mi Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ ti dúró pẹ̀lú mi—fún ìgbà pípẹ́ lẹ́hìn tí ilé ìjọsìn Zwickau ti di wíwópalẹ̀ ti àwọn fèrèsé onígíláàsì-kíkùn sì ti sọnù.
“Ọ̀run àti ayé yío kọjá lọ,” ni Jésù wí, “ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yío kọjá lọ.”
“Àwọn òkè-gíga yíò ṣí kúrò, a ó sì ṣí àwọn òkè kékèké ní ìdí, ṣùgbọ́n inú rere mi kì yíò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ̃ni èmi kì yíò ṣí májẹ̀mú àlãfíà mi ní ipò, ni Olúwa wí.”
Ọ̀kan ninu àwọn ohun pàtàkì jùlọ tí a lè kọ́ nínú ayé yí ni ìyàtọ̀ láàrin ohun tí ó jẹ́ ti ayérayé ati ohun tí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bí a bá ti ní òye èyí, ohun gbogbo yío yípadà—àwọn ìbáṣepọ̀ wa, àwọn àṣàyàn tí a nṣe, bí a ti nṣe sí àwọn ènìyàn.
Mímọ ohun ti ó jẹ̀ ti ayérayé ati ohun tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ pàtàkì sí mímú ẹ̀rí nípa Jésù Krístì àti Ìjọ Rẹ̀ dàgbà.
Ẹ Má Ṣe Àṣìṣe Àwọn Ẹ̀ka fún Àwọn Gbòngbò
Ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò, bí Wòlíì Joseph Smith ṣe kọ́ni, “gba ẹni gbogbo, àti olukúlùkù ohun tíi ṣe òtítọ́ mọ́ra.” Ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo òtítọ́ ló níye lórí bákannáà. Àwọn òtítọ́ kan jẹ́ pàtàkì, kókó, ní ibi gbòngbò ìgbàgbọ́ wa. Àwọn míràn jẹ́ àfikún tàbí ẹ̀ka—wọ́n níyelórí, ṣùgbọ́n nígbàtí wọ́n bá jẹ́ sísopọ̀ mọ́ àwọn pàtàkì nìkan.
Wòlíì Jósẹ́fù sọ bákannáà pé, “Àwọn ìpìlẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì ti ẹ̀sìn wa ni ẹ̀rí àwọn Àpóstélì àti àwọn Wòlíì, nípa Jésù Krístì, pé Ó kú, a sín I, Ó sì tún jí ní ọjọ́ kẹ́ta, … ó sì gòkè re ọ̀run; àti pé gbogbo àwọn nkan míràn tí ó jẹmọ́ ẹ̀sìn wa jẹ́ àwọn àfikún nìkan sí i.”
Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, Jésù Krísti àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ ni gbòngbò ẹ̀rí wa. Gbogbo àwọn nkan míràn jẹ́ àwọn ẹ̀ka.
Èyí kìí ṣe láti sọ pé àwọn ẹ̀ka náà kò ṣe pàtàkì. Igi kan nílò àwọn ẹ̀ka. Ṣùgbọ́n bí Olùgbàlà ti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, “Ẹ̀ka kò le mú èso wá fúnra rẹ̀, bíkòṣepé òun gbé nínú àjàrà.” Láìsí àsopọ̀ kan sí Olùgbàlà, sí ìtọ́jú tí a nrí ninu àwọn gbòngbò, ẹ̀ka a máa gbẹ á sì kú.
Nígbàtí ó bá kan títọ́jú àwọn ẹ̀rí wa nípa Jésù Krístì, ó nyàmílẹ́nu bí àwa bá nfi ìgbà míràn ṣe àṣìṣe àwọn ẹ̀ka fún àwọn gbòngbò. Èyí ni àṣìṣe tí Jésù fura sí nínú àwọn Farisí ti àwọn ọjọ́ Rẹ̀. Wọ́n fi iyè púpọ̀ sí àwọn àsọyé tí a le pè ní kèkeré ní ti òfin tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n parí sí pé wọ́n pa ohun tí Olùgbàlà pè ni “àwọn ọ̀ràn tó wúwojù” tì—àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì bíi òdodo ati àánú ati ìgbàgbọ́.”
Bí ẹ bá fẹ́ tọ́jú igi kan, ẹ kò ní da omi sí ara àwọn ẹ̀ka. Ẹ ó fi omi sí àwọn gbòngbò. Ní àfijọ, bí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ẹ̀ka ti ẹ̀rí yín ó dàgbà kí wọ́n ó sì mú èso wá, ẹ tọ́jú àwọn gbòngbò. Bí ohun kan kò bá dá yín lójú nípa ẹ̀kọ́ kan pàtó tàbí ìṣe tàbi abala ìtàn Ìjọ, ẹ mú ìgbàgbọ́ yín hàn kedere ninu Jésù Krístì. Ẹ lépa láti ní òye ìrúbọ Rẹ̀ fún yín, ìfẹ́ Rẹ̀ fún yín, ìfẹ́-inú Rẹ̀ fún yín. Ẹ tẹ̀lé E ní ìrẹ̀lẹ̀ Àwọn ẹ̀ka ẹ̀rí yín yío fa agbára láti inú ìgbàgbọ́ yín tó njinlẹ̀ nínu Baba Ọ̀run àti Àyànfẹ̀ Ọmọ Rẹ̀.
Fún àpẹrẹ, bí ẹ bá fẹ́ ẹ̀rí tó lágbára sìi nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ẹ fi ojú sùn sí ẹ̀rí rẹ̀ nípa Jésù Krístì. Ẹ kíyèsí bí Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti jẹ́rí nípa Rẹ̀, ohun tí ó kọ́ni nípa Rẹ̀, àti bí ó ti pè tí ó sì mísí yín láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Bí ẹ bá nwá ìrírí tó nítumọ̀ síi nínú àwọn ìpàdé Ìjọ tàbí nínú tẹ́mpìlì, ẹ gbìyànjú wíwò fún Olùgbàlà nínú àwọn ìlànà mímọ́ tí a ngbà níbẹ̀. Ẹ Wá Olúwa nínú ilé mímọ́ Rẹ̀
Bí o bá ní ìmọ̀lára àárẹ̀ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì nípasẹ̀ ìpè rẹ ninu Ìjọ, gbìyànjú àtúnṣe fífi ojú iṣẹ́-ìsìn rẹ sùn lé orí Jésù Krístì. Ẹ mú kí ó jẹ́ àfihàn ti ìfẹ́ yín fún Un.
Ẹ tọ́jú àwọn gbòngbò, àwọn ẹ̀ka yío sì dàgbà. Àti ní àkókò, wọn yío so èso.
“Fífìdimúlẹ̀ àti Gbígbé Sókè nínú Rẹ̀
Ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jésù Krístì kìí dédé ṣẹlẹ̀. Rárá, nínú ayé ti-ikú yí, àwọn ẹ̀gun àti òṣùṣu ti iyèméjì ni wọ́n máa ndàgbà pọ̀ lẹ́ẹ̀kannáà. Igi ìgbàgbọ́ tó péye, tó nmú èso wa nílò aápọn àtinúwá. Àti pé apákan pàtàkì ti aápọn náà ni ríríi dájú pé a fìdímúlẹ̀ ṣinṣin nínú Krístì.
Fún àpẹrẹ: Ní àkọ́kọ́, a lè jẹ́ fífà sí ìhìnrere àti Ìjọ Olùgbàlà nítorípé a ní ìwúrí nípa àwọn ọmọ-ìjọ tí wọ́n ṣe bí ọ̀rẹ́ tàbí nípa bíṣọ́pù tó ní inú rere tàbí mímọ́ tónítóní ti ilé ìjọsìn. Àwọn ipò wọ̀nyí ṣe pàtàkì nítòótọ́ láti mú Ìjọ dàgbà.
Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, bí àwọn gbòngbò ẹ̀rí wa kò bá dàgbà jinlẹ̀ ju báyi lọ, kínni yío ṣẹlẹ̀ nígbàtí a bá kó lọ sí wọ́ọ̀dù tí wọ́n npàdé nínù ilé tí kò wúnilórí tó bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọmọ-ijọ tí wọn kò ṣe bí ọ̀rẹ́ tó, àti tí bíṣọ́pù náà sọ ohun kan tí ó bí wa nínú?
Àpẹrẹ míràn: njẹ́ ó dàbí ẹnipé ó mọ́gbọ́n wá láti retí pé bì a bá pa àwọn òfin mọ́ tí a sì jẹ́ fífi èdìdi dì ní tẹ́mpìlì, a ó di alábùkún fún pẹ̀lu ẹbí títóbi àti aláyọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ tó jáfáfá, gbígbọ́ran, tí gbogbo wọn á dúró déédé nínú Ìjọ, sìn ní àwọn míṣọ̀n, kọrin ninu ẹgbẹ́ akọrin wọ́ọ̀dù, àti yíyọ̀ọ̀da ara wọn láti ṣèrànwọ́ tún ilé ìjọsìn ṣe ni gbogbo àárọ̀ ọjọ́ Sátidé?
Mo ní ìrètí dájúdájú pé gbogbo wa yíò rí èyí nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nkọ́? Njẹ́ a ó dúró ní sísopọ̀ sí Olùgbàlà láìka àwọn ipò sí—ní gbígbẹ́kẹ̀lé Òun ati àkókò Rẹ̀?
A gbọ́dọ̀ bi ara wa léèrè pé: Njẹ́ ẹ̀rí mi dá lórí on ti mo nírètí pé yío ṣẹlẹ̀ nínú ayé mi? Njẹ́ ó wà ní àìgbáralé àwọn ìṣe tàbí ìwà àwọn ẹlòmíràn? Tàbí njẹ́ a gbé e kalẹ̀ ṣinṣin lórí Jésù Krístì, “ní fífìdímúlẹ̀ àti kíkọ́ sókè nínú rẹ̀,” láìka àwọn ipò tó nyípadà nínú ayé sí?
Àwọn Àṣà, Àwọn Ìwà Bárakú, àti Ìgbàgbọ́
Ìwé ti Mọ́mọ́nì sọ nipa áwọn ènìyàn kan tí “wọ́n le ní fífiyèsí àwọn ìlànà Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n nígbànáà oníyèméjì kan wá tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Kòrìhórì, tó nfi ìhìnrere Olùgbàlà ṣe ẹlẹ́yà, tó npè é ní àṣà awọn baba wọn to jẹ “ti aṣiwèrè” àti “ti òmùgọ̀.” Kòrìhórì darí “ọkàn àwọn púpọ̀ lọ kúrò, ní mímú wọn gbé orí wọn sókè nínú ìwà búburú wọn.” Ṣùgbọ́n àwọn míràn ni òun kò le tàn jẹ, nitorí sí àwọn, ìhìnrere Jésù Krístì pọ̀ púpọ̀ ju àṣà kan lọ.
Ìgbàgbọ́ nlágbára nígbàtí ó bá ní gbòngbò jíjinlẹ̀ nínú ìrírí ti ara-ẹni, ìfọkànsìn ti ara-ẹni sí Jésù Krístì, ní òmìnira sí ohun tí àwọn àṣà wa jẹ́ tàbí ohun tí àwọn ẹlòmíràn lè máa sọ tàbí ṣe.
Ẹ̀rí wa yio jẹ́ dídánwò àti yíyẹ̀wò. Ìgbàgbọ́ kìí ṣe ìgbàgbọ́ bí a kò bá tíi danwò rí. Ìgbàgbọ́ kò lágbára bí a kò bá tíi takò ó rí. Nítorínáà ẹ má sọ̀rètínù bí ẹ bá ní àwọn àdánwò ìgbàgbọ́ tàbí àwọn ìbéèrè tí kò tíì jẹ́ dídáhùn.
A kò gbọdọ̀ retí láti ní òye ohun gbogbo kí a tó gbé ìgbésẹ̀. Èyíini kkìí ṣe ìgbàgbọ́. Bí Álmà ti kọ́ni, “Ìgbàgbọ́ kĩ ṣe láti ní ìmọ̀ pípé nípa àwọn nkan.” Bí a bá dúró láti gbé ìgbésẹ̀ títí tí gbogbo awọn ìbéèrè wa yio fi jẹ́ dídáhùn, a ṣe àdínkù rere tí a lè ṣe yọrí, a sì ṣe àdíkù agbára ìgbàgbọ́ wa.
Ìgbàgbọ́ rẹwà nítorípé ó tẹ̀síwájú àní nígbàtí àwọn ìbùkún kò wá bí a ti retí. A kò le rí ọjọ́ iwájú, a kò mọ gbogbo ìdáhùn, ṣùgbọ́n a lè gbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì bì a ti ntẹ̀síwájú tí a sì nlọ sókè nítorípé Òun ni Olùgbàlà ati Olùràpadà wa.
Ìgbàgbọ́ nfarada áwọn àdánwò àti àwọn àìdánilójú ilé ayé nítorípé ó fìdímúlẹ̀ ṣinṣin ninu Krístì àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Jésù Krístì, àti Baba wa Ọ̀run tí ó ran Án wá, ní àpapọ̀ àìyẹ̀ kan nínú, ohun pípé gbígbẹ́kẹ̀lé ti ìgbẹ́kẹ̀lé wa.
Ẹ̀rí kìí ṣe ohunkan tí ẹ lè mú dàgbà lẹ́ẹ̀kan ó sì dúró títí láé. Ó dàbí igi kan tí ẹ ntọ́jú lemọ́lemọ́. Gbígbin ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí inú ọkàn yín jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nìkan. Lẹ́ẹ̀kannáà tí ẹ̀rí yín bá bẹ̀rẹ̀sí dàgbà, nígbànáà ni iṣẹ́ gidi bẹ̀rẹ̀! Nígbànáà ni ẹ̀yin yíò “tọ́jú rẹ̀ pẹ̀lú ìtọ́jú nlá, kí ó lè ta gbòngbò, kí ó lè dàgbà, kí ó sì mú èso wá.” Ó gba “aápọn nlá” ati “sũrù pẹ̀lu ọ̀rọ̀ náà.” Ṣùgbọ́n awọn ìlérí Olúwa dájú pé: “Ẹ̀yin yíò kórè èrè ìgbàgbọ́ yín, àti ìpamọ́ra yín, àti sũrù, àti ìfaradà, ní dídúró fún igi nã láti mú èso jáde wá fún yín.”
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, apákan mi wà tí ó nsàárò ilé ìjọsìn àtijọ́ ni Zwickau àti àwọn fèrèsé onígíláàsì-alábàwọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n láàrin ọdún 75 to ti kọjá, Jésù Krístì ti darí mi ní ìrìnàjò kan nínú ayé tí ó dùnmọ́ni ju bí mo ti le léro lọ láe. Ó ti tùmí nínú láàrin àwọn ìpọ́nju mi, rànmí lọ́wọ́ láti mọ àwọn àìlera mi, wo àwọn ọgbẹ́ ti ẹ̀mí mi sàn, Ó sì tọ́jú mi nínú ìgbàgbọ́ mi tó ndàgbà.
Ó jẹ́ àdúrà tóótọ́ àti ìbùkún mi pé a ó máa fi igbà gbogbo tọ́jú àwọn gbòngbò ìgbàgbọ́ wa ninu Olùgbàlà, ninu ẹ̀kọ́ Rẹ̀, àti ninu Ìjọ Rẹ̀. Nípa Èyí ni mo jẹrí ni orúkọ mímọ́ ti Olùgbàlà, Olùràpàdà wa, Olùkọ́ni wa—ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.