Títẹ̀lé Krístì
Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọlẹ́hìn Krístì, ẹ jẹ́ kí a kọ́nì kí a sì jẹri nípa Jésù Krístì, Àwòkọ́ṣe Pípé wa. Nítorínáà ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé E nípa ìjà tó nlọ lọ́wọ́.
Ní ọdún yí àwọn mílíọ́nù ti gba ìmísí nípasẹ̀ ètò àṣàrò ìhìnrere tí a mọ̀ nípasẹ̀ ìfipè Olùgbàlà “Wá, tẹ̀lé mi.” Títẹ̀lé Krístì kìí ṣe asán tàbí ìṣe ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó jẹ́ títẹ̀síwájú ìfọkànsìn kan àti ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ó níláti tọ́ wa sọ́nà ní gbogbo ìgbà àti níbi gbogbo. Àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ àti àpẹrẹ Rẹ̀ fi ipa-ọ̀nà fún gbogbo ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì hàn. Gbogbo ènìyàn ni a sì pè sí ipa-ọ̀nà yí, nítorí Ó npe gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀, “dúdú àti funfun, ìdè àti òmìnira, ọkùnrin àti obìnrin; … gbogbo wọn jẹ́ bákannáà sí Ọlọ́run.”
I.
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ní títẹ̀lé Krístì ni láti gbọ́ran sí ohun tí Òun ti túmọ̀ bí “òfin nlá nínú òfin”:
“Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.
“Èyí ni èkínní àti òfin ńlá.
“Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.
“Nínú àwọn òfin méjèjì yí ni gbogbo òfin àti wòlíì rọ̀ mọ́.”
Àwọn òfin Ọlọ́run pèsè ìtọ̀nisọ́nà àti ipa ìmúdúró nínú ayé wa. Àwọn ìrírí wa nínú ayé-ikú dàbí ọmọdékùnrin kékeré àti baba rẹ̀ tó nfo káìtì ní ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ nfẹ́. Bí káìtì náà ti nga sókè si, afẹ́fẹ́ nmú kí o fàmì sórí okùn ìsopọ̀ ní ọwọ́ ọmọdékùnrin kékeré náà. Ní àìní ìrírí pẹ̀lú ipa afẹ́fẹ́ ayé-ikú, ó ní kí ó gé okùn náà kí káìtì náà lè gòkè ní gíga si. Baba rẹ ọlọgbọ́n dámọ̀ràn pé rárá, ó ṣe àlàyé pé okùn náà ni ohun tí ó di káìtì náà mú ní ipò ní ìlòdì sí afẹ́fẹ́ ayé-ikú. Bí a bá sọ ìdìmú wa nù lórí okùn náà, káìtì náà kò ní gòkè gíga si. A ó gbé e ká nípa afẹ́fẹ́ ayé-ikú àti ìṣubú àìlèyẹ̀ wọ̀nyí sí ilẹ̀ ayé.
Okùn pàtàkì náà nrọ́pò àwọn májẹ̀mú wa tí ó so wá pọ̀ mọ́ Ọlọ́run, Baba wa Ọ̀run, àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Bí a ti nbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú wọnnì nípa pípa àwọn òfin Wọn mọ́ àti títẹ́lé ètò ìràpadà Wọn, Ìlérí ìbùkún wọn mú wa gòkè sí ibi gíga sẹ̀lẹ́stíà.
Ìwé ti Mọ́mọ́nì kéde lemọ́lemọ́ pé Krístì ni “ìmọ́lẹ̀ ayé.” Ní ìgbà ìfarahàn Rẹ̀ sí àwọn ará Néfì, Olúwa olùjínde ṣe àlàyé ìkọ́ni náà nípa wíwí fún wọn pé: “Mo ti fi àpẹrẹ lélẹ̀ fún yín.” “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ èyí tí ẹ ndìmú sókè—èyí tí ẹ ti rí tí mo ṣe.” Òun ni àwòkọ́ṣe wa. A kọ́ ohun tí ó ti sọ tí ó sì ṣe nípa ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ àti títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni ti-wòlíì bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti rọ̀ wá láti ṣe. Nínú ìlànà oúnjẹ Olúwa, a dá májẹ̀mú ní ọjọọjọ́ Ìsinmi pé a ó “rántí rẹ̀ nígbàgbogbo a ó sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.”
ll.
Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Olúwa fún wa ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ nínú ohun tí Ó pè ní “ẹ̀kọ́ Krístì.” Ìwọ̀nyí ni ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, gbígba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, fíforítì dé òpin, àti dídà bí ọmọ kékeré, èyí tí ó túmọ̀ sí láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa àti láti juwọ́lẹ̀ sí gbogbo ohun tí Ó bèèrè lọ́wọ́ wa.
Àwọn òfin Olúwa jẹ́ ẹ̀yà méjì, ó dúró pẹ́ títí, bíiti ẹ̀kọ́ Krístì, àti ránpẹ́. Àwọn òfin ránpẹ́ ni àwọn wọnnì tí ó pọndandan fún ìnílò Ìjọ Olúwa tàbí òtítọ́ nínú àwọn ipò ránpẹ́, ṣùgbọ́n tí a ní láti gbé sẹgbẹ nígbàtí ìnílò bá ti kọjá. Àpẹrẹ kan nípa àwọn àṣẹ ránpẹ́ ni àwọn ìdarí Olúwa sí ipò-olórí ìṣíwájú Ìjọ láti kó àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti New York sí Ohio, sí Missouri, àti sí Illinois àti ní òpin láti darí ìkólọ olùlànà sí Ìlà-oòrùn Intermountain. Bíótilẹ̀ jẹ́ ránpẹ́ nìkan, nígbàtí ó bá ṣì wà ní ipa àwọn àṣẹ wọ̀nyí ni a fúnni láti jẹ́ gbígbọ́ran sí.
Àwọn òfin tó wà pípẹ́-títí ti gba àkokò púpọ̀ láti ṣe àkíyèsí lọ́pọ̀lọpọ̀. Fún àpẹrẹ, ìwàásù olókìkí Ààrẹ Lorenzo Snow lórí òfin idamẹwa tẹnumọ́ òfin kan tí a fúnni ní ìṣíwájú ṣùgbọ́n tí a kò kíyèsí lọ́pọ̀lọpọ̀ síbẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ọmọ Ìjọ. Ó nílò àtún-tẹnumọ́ nínú àwọn ipò nígbànáà ìdojúkọ nípa Ìjọ àti àwọn ọmọ̀-ìjọ rẹ̀. Àwọn àpẹrẹ àìpẹ́ jùlọ àtun-tẹnumọ́ ni a ti nílò nítorí ti àwọn ipò lọ́wọ́lọ́wọ́ tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tàbí Ìjọ dojúkọ. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú ìkéde lórí ọ̀ràn ẹbí tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Ààrẹ Gordon B. Hinckley ní ìran kan sẹ́hìn, àti ìpè àìpẹ́ Ààrẹ Russell M. Nelson fún Ìjọ láti di mímọ̀ nípasẹ̀ ìfihàn orúkọ rẹ̀, Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.
lll.
Àwọn ìkọ́ni míràn nípa Olùgbàlà wa dàbí ó nílò àtún-tẹnumọ́ nínú àwọn ipò ọjọ́ wa.
Èyí ni àkokò ti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ líle àti ìpalára nínú àwọn ìbárasọ̀rọ̀ gbàngba wa àti nígbàmíràn àní nínú àwọn ẹbí wa. Àwọn ìyàtọ̀ mímú lórí àwọn ọ̀ràn ètò gbangba nígbàkugbà nyọrí sí àwọn ìṣe ìgbógun—àní ìkóríra—ní àwọn ìbáṣepọ̀ gbangba àti ti araẹni. Àyíká ti ọ̀tá yí nígbàmíràn àní àwọn okun rírọpá fún ṣíṣe òfin lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì níbití àwọn ọmọ-ìlú púpọ̀ ti nrí ìnílò kíákíá fún àwọn ìṣe kan nínú ìnífẹ́sí gbàngba.
Kíni àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì níláti kọ́ni àti ṣe ní àkokò ti àwọn ìbárasọ̀rọ̀ olóró yí? Kíni àwọn ìkọ́ni àti àpẹrẹ Rẹ̀?
Ó jẹ́ pàtàkì ní àárín àwọn ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ tí Jésù kọ́ni nígbàtí Ó farahàn sí àwọn ará Néfì ni láti yẹra fún ìjà. Nígbàtí Ó kọ́ni ní èrò ti àríyànjiyàn lórí ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn yí, àwọn èrèdí tí Ó fúnni wúlò kedere sí ìbárasọ̀rọ̀ àti ìbáṣepọ̀ nínú òṣèlù, ètò gbangba, àti ìbáṣepọ̀ ẹbí. Jésù kọ́ni:
“Ẹnití ó bá ní ẹ̀mí ìjà kĩ ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ti èṣù nií ṣe, ẹnití íṣe baba asọ̀, òun a sì máa rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè láti bá ara wọn jà pẹ̀lú ìbínú, ní ọ̀kan sí òmíràn.
“Ẹ kíyèsĩ, èyí kĩ íṣe ẹ̀kọ́ mi, láti rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè pẹ̀lú ìbínú, ọ̀kan sí òmíràn; ṣùgbọ́n èyĩ ni ẹ̀kọ́ mi, pé kí a mú irú ohun wọnnì kúrò.”
Nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ tó kù ní àárín àwọn ará Néfì, Jésù kọ́ni ní àwọn òfin míràn tí ó wà ní ìbámu tímọ́tímọ́ sí èèwọ̀ Rẹ̀ nípa ìjà. A mọ̀ látinú Bíbélì pé Òun ti kọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn Ìwàásù Lórí Òkè nlá Rẹ̀ wọ̀nyí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, bí àtẹ̀hìnwá ní déédé sí irú èdè kannáà tí Ó lò pẹ̀lú àwọn ará Néfì. Èmi ó ṣe àyọsọ èdè Bíbélì tí a mọ̀ jù:
“Ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín, ẹ súre fún àwọn ẹnití nfi yín ré, ẹ máa ṣe oore fún àwọn tí ó kórìra yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tí nfi àránkan bá yín lò, tí wọn sì nṣe inúnibíni sí yín.”
Èyí ni ọ̀kan lára àwọn òfin tí Krístì mọ̀ jùlọ—tí ó ní rògbòdìyàn jùlọ àti líle jùlọ láti tẹ̀lé. Síbẹ̀ ó jẹ́ ara ìpìlẹ̀ jùlọ nípa ìfipè Rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti tẹ̀lé E. Bí Ààrẹ David O. McKay ti kọ́ni, “Kò sí ọ̀nà tí ó dárajùlọ láti fi ìfẹ́ fún Ọlọ́run hàn ju láti fi ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan hàn fún ènìyàn ọmọlàkejì.”
Nihin ni ìkọ́ni ìpìlẹ̀ míràn nípa Rẹ̀ ẹnití ó jẹ́ àwòkọ́ṣe wa: “Alábùkún-fún ni fún àwọn onílàjà: nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.”
Àwọn Onílàjà! Bí yíò ti yí àwọn ìbáṣepọ̀ araẹni padà bí àwọn ọmọlẹ́hìn Krístì yíò bá mú àwọn ọ̀rọ̀ líle àti ìpanilára kúrò nínú gbogbo àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ wọn.
Nínú ìpàdé àpapọ̀ ọdún tó kọjá, Ààrẹ Russell M. Nelson fún wa ní àwọn ìpènijà wọ̀nyí:
“Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìrọ̀rùn láti mọ àtẹ̀lé tòótọ́ ti Jésù Krístì ni bí ẹni náà ti nṣe ìṣesí pẹ̀lú àánú sí àwọn ẹ̀nìyàn míràn. …
“… Àwọn ọmọẹ̀hìn tòótọ́ ti Jésù Kristì jẹ́ onílàjà.
“… Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà dídárajùlọ tí a fi lè bu ọlá fún Olùgbàlà ni láti di onílàjà.”
Ní píparí àwọn ìkọ́ni rẹ̀: “Ìjà jẹ́ àṣàyàn kan. Lílàjà jẹ́ yíyàn kan. Ẹ ní agbára òmìnira yín láti yan ìjà tàbí ìlàjà. Mo rọ̀ yín láti yàn láti jẹ́ onílàjà, nísisìyí àti nígbàgbogbo.”
Ìfiyesí dída ọ̀tá níláti bẹ̀rẹ̀ nípa yíyẹ ìbi ìwọpọ̀ wò lórí èyí tí gbogbo wọn ó fohùnṣọ̀kan.
Láti tẹ̀lé Àwòkọ́ṣe Pípé wa àti wòlíì Rẹ̀, a nílò láti ṣe ohun tí a mọ̀ bí Òfin Oníwúra: “Ohun gbogbo tí ẹ bá fẹ́ kí a ṣe fún yín, àní ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́: nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì.” A nílò láti fẹ́ràn àti láti ṣe rere sí gbogbo ènìyàn. A nílò láti yẹra fún ìjà kí a sì jẹ́ onílàjà nínú gbogbo ìbánisọ̀rọ̀ wa. Èyí kò túmọ̀ sí pé kí a tẹ́mbẹ́lú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti ààyò wa ṣùgbọ́n kí a fi títako àwọn ẹlomíràn lílelíle fún tiwọn. Iyẹn ni ohun tí Àwòkọ́ṣe Pípé wa ṣe nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni àpẹrẹ tí Òun ti filélẹ̀ fún wa bí Ó ti pè wá láti tẹ̀lé E.
Nínú ìpàdé àpapọ̀ yí fún ọdún mẹ̀rin sẹ́hìn, Ààrẹ Nelson fún wa ní ìpènijà ti-wòlíì fún ọjọ́ tiwa:
“Njẹ́ ẹ fẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín? Njẹ ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ ipa pàtàkì jùlọ nínú ayé yín? Ṣe ẹ ó fàyè gba àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, òfin Rẹ̀, àti májẹ̀mú Rẹ̀ láti ní ipá lórí ohun tí ẹ ó ṣe lójojúmọ́? Ṣe ẹ ó fàyè gba ohùn Rẹ̀ láti wà ní ipò ìṣíwájú eyikeyi míràn?”
Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọlẹ́hìn Krístì, ẹ jẹ́ kí a kọ́nì kí a sì jẹri nípa Jésù Krístì, Àwòkọ́ṣe Pípé wa. Nítorínáà ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé E nípa fífi ìjà tó nlọ lọ́wọ́ sílẹ̀. Bí a ti nlépa àwọn ètò ààyò wa nínú àwọn ìṣe gbangba, ẹ jẹ́ kí a yege fún àwọn ìbùkún Rẹ̀ nípa lílo èdè àti ọ̀nà àwọn onílàjà. Nínú àwọn ẹbí wa àti àwọn ìbáṣepọ̀ araẹni míràn ẹ jẹ́ kí a yẹra fún ohun tí ó le tí ó sì ní ìkóríra. Ẹ jẹ́ kí a wá láti jẹ́ mimọ́, bíiti Olùgbàlà wa, nípa orúkọ ẹnití mo jẹri tí mò si pe ìbùkún Rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.