Olúwa Jésù Krístì Yíò Wá Lẹ́ẹ̀kansi
Ìsisìyí ni àkokò náà fún ẹ̀yin àti fún èmi láti múrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo dúpẹ́ pé Olúwa ti bùkún mi láti bá yín sọ̀rọ̀.
Nínú ìpàdé àpapọ̀ yí, Olúwa ti sọ̀rọ̀ sí wá nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀. Mo rọ̀ yín láti ṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ lò wọ́n bí ìdánwò lítímọ́sì ti ohun tó jẹ́ òtítọ́ àti ohun tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀ nínú oṣù mẹ́fà tó nbọ̀.
Ìpamọ́ àti àtúnṣe ti Tẹ́mpìlì Salt Lake àti àwọn agbègbè míràn lórí Igun-mẹ́rin Tẹ́mpìlì ti wà lábẹ́ lílọ-lọ́wọ́ fún bíi ọdún marun. Àwọn ìgbìrò lọ́wọ́lọ́wọ́ fihàn pé iṣẹ́ yí yíò parí ní òpin 2026. A dúpẹ́ fún gbogbo àwọn ẹnití wọ́n nṣiṣẹ́ lórí iṣẹ́ títóbi yí.
Ní oṣù mẹ́fà tó kọjá, a ti ṣe ìyàsímímọ́ tàbí títún-yàsímímọ́ àwọn tẹ́mpìlì mẹsan ní àwọn orílẹ̀-èdè marun. Ní àárín ìsisìyí àti òpin ọdún, a ó ya márun símímọ́ síi.
Ní òní inú wa dùn láti kéde àwọn ètò láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì mẹ́tàdínlógún síi. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi etísílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ bí mo ti nkéde àwọn ibi náà.
-
Juchitán de Zaragoza, Mexico
-
Santa Ana, El Salvador
-
Medellín, Colombia
-
Santiago, Dominican Republic
-
Puerto Montt, Chile
-
Dublin, Ireland
-
Milan, Italy
-
Abuja, Nigeria
-
Kampala, Uganda
-
Maputo, Mozambique
-
Coeur d’Alene, Idaho
-
Queen Creek, Arizona
-
El Paso, Texas
-
Huntsville, Alabama
-
Milwaukee, Wisconsin
-
Summit, New Jersey
-
Price, Utah
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ṣe ẹ rí ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní iwájú wa? Mo gbàdúrà pé a kò ní sọ ọlánlá àkokò yí nù! Olúwa nyára síṣẹ́ Rẹ̀ nítòótọ́.
Kínìdí tí a fi nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì ní irú ìyára àìlèrò bẹ́ẹ̀? Kínìdí? Nítorí Olúwa ti pá láṣẹ fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì nṣèrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèjì ìkelè. Àwọn ìbùkún wọ̀nyí bákannáà nṣèrànwọ́ láti múra àwọn ènìyàn tí yíò múra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ́ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa!
Bí wòlíì Ìsàíàh ti sọtẹ́lẹ̀, àti bíti rírántí ti Handel Messiah, nígbàtí Jésù Krístì bá padàwá, “a ó fi ògo Olúwa hàn, gbogbo ẹran ara yíò sì rí i papọ̀.”
Ní ọjọ́ náà, “ìjọba yíò wa ní èjìká rẹ̀: a ó sì máa pè orúkọ rẹ̀ ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Baba Ayérayé, Aládé Àláfíà.”
Jésù Krístì yíò ṣe àkóso láti Jérúsálẹ́mù àtijọ́ àti Jésúsálẹ́mù titun “tí a kọ́ sórí ilẹ̀ Amẹ́ríkà.” Látinú àwọn gbàgede méjèjì wọ̀nyí, Òun yíò darí àlámọrí Ìjọ Rẹ̀.
Ní ọjọ́ náà Olúwa ni a ó mọ̀ sí “Ọba àwọn Ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa.” Àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú Rẹ̀ ni a ó “pè, tí a ó yàn, tí wọn ó sì jẹ́ olotitọ.”
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìsisìyí ni àkokò náà fún yín àti fún èmi láti múrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Ìsisìyí ni àkokò náà fún wa láti mú jíjẹ́-ọmọlẹ́hìn wa jẹ́ ààyò gígajùlọ wa. Nínú ayé tí ó kún fún àwọn ìyọnu yíyíjú, báwo ni a ṣe lè ṣe èyí?
Ìjọ́sìn déédé nínú tẹ́mpìlì yíò ràn wá lọ́wọ́. Nínú ilé Olúwa, a nfojúsùn Jésù Krístì. À nkọ́ nípa Rẹ̀. À ndá àwọn májẹ̀mú láti tẹ̀lé E. A nwá láti mọ̀ Ọ́. Bí a ti npa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wa mọ́, à njèrè àyè títóbijù sí agbára ìfúnnilókun ti Olúwa. Nínú Tẹ́mpìlì, a ngba ààbò látinú àwọn ìjìyà ti ayé. À nní ìrírí ìfẹ́ àìléèrí ti Jésù Krístì àti Baba wa Ọ̀run ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nlá! À nní ìmọ̀lára àláfíà àti ìtún-dánilójú ti-ẹ̀mí, ní ìlòdì sí àjálù ayé.
Nihin ni ìlérí mi sí yín: Gbogbo olùwádi àtọkànwá ti Jésù Krístì yíò rí I nínú tẹ́mpìlì. Ẹ ó ní ìmọ̀lára àánú Rẹ̀. Ẹ ó rí àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè ríruni-nínú jùlọ yín. Ẹ ó ní òye dáradára ti ayọ̀ ìhìnrere Rẹ̀.
Èmi ti kọ́ pé ìbèèrè líle jùlọ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ dáhùn ni èyí: Sí tani tàbí sí ohun wo ni èmi ó fi ayé mi fún?
Ìpinnu mi láti tẹ̀lé Jésù Krístì ni ìpinnu pàtàkì jùlọ tí mo ti ṣe rí. Ní ìgbà ilé-ìwé oníṣègùn, mo jèrè ẹ̀rí kan nípa àtọ̀runwá Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Láti ìgbà náà Olùgbàlà wa ti jẹ́ àpáta lórí èyí tí mo gbé ayé mi lé. Àṣàyàn náà ti mú gbogbo ohun yàtọ̀! Ìpinnu náà ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpinnu míràn bẹ́ẹ̀ rọ̀rùn. Ìpinnu náà ti fún mi ní èrèdí àti ìdarí. Bákannáà ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn ìjì ayé. Ẹ jẹ́ ki nṣe àbápín àwọn àpẹrẹ méjì.
Àkọ́kọ́, nígbàtí ìyàwó mi Dantzel kọjá lọ láìròtẹ́lẹ̀, èmi kò lè kàn sí eyikeyi àwọn ọmọ wa. Níbẹ̀, ni mo dá wà, nínú ọ̀fọ̀, tí mo sì nké fún ìrànlọ́wọ́. Pẹ̀lú ìmoore, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀, Olúwa kọ́ mi ní ìdí tí a fi mú Dantzel mi ọ̀wọ́n lọ sílé. Pẹ̀lú òye ìyẹn, mo ní ìtùnú. Ní ìgba díẹ̀, mo lè ní ìfaramọ́ pẹ̀lú ọ̀fọ̀ mi dáradára. Lẹ́hìnnáà, mo gbeyàwó olólùfẹ́ ìyàwó mi Wendy. Òun jẹ́ gbùngbun ara àpẹrẹ mi kejì.
Nígbàtí Wendy àti èmi wà níbi ìyànsíṣẹ́ ní ilẹ̀ òkèèrè, àwọn adigun jalè fi ibọ̀n sí orí mi wọ́n sì yín ín. Ṣùgbọ́n ìbọ̀n náà kò dún. Nínú gbogbo ìrírí náà, ayé àwa méjèjì wà nínú ìdẹ́rùbà. Síbẹ̀ Wendy àti èmi ní ìmọ̀lára àláfíà àìlèsẹ́. Àláfíà náà ni “èyítí ó kọjá gbogbo òye.”
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, Olúwa yíò tù yín nínú pẹ̀lú! Òun yíò fún yín lókun. Òun yíò bùkún yín pẹ̀lú àláfíà, àní ní àárín rògbòdìyàn.
Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi ètísílẹ̀ sí ìlérí ti Jésù Krístì yí: “Èmi yíó wà ní ọwọ́ ọ̀tún yín àti ní ọwọ́ òsì, Ẹ̀mí mi yíó sì wà nínú ọkàn yín, àwọn ángẹ́lì mi yío rọ̀gbà yíi yín ká, láti gbée yín sókè.”
Kò sí òpin sí okun Olùgbàlà láti ràn yín lọ́wọ́. Ìjìyà àìláfiwé Rẹ̀ ní Gẹ́tsémánè àti ní Kalfárì wà fún yín! Ètùtù àìlópin Rẹ̀ wà fún yín!
Mo rọ̀ yín láti yan àkokò ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀—fún ìyókù ayé yín—láti mú òye yín pọ̀ si nípa Ètùtù Jésù Krístì. Mo ní ìrora ọkàn fún àwọn ẹnití a dìmú sínú ẹ̀ṣẹ̀ tí wọn kò sì mọ àti jáde. Mo sọkún fún àwọn wọnnì tí wọ́n nlàkàkà níti-ẹ̀mí tàbí tí wọ́n ndá gbé ẹrù wúwo nítorí wọn kò ní òye ohun tí Jésù Krístì ṣe fún wọn.
Jésù Krístì gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìrora yín, ìrora ọkàn yín, àti àwọn àìlera yín lé orí Ararẹ̀. Ẹ kò níláti dá gbé wọn! Òun yíò dáríjì yín bí ẹ ti nronúpìwàdà. Òun ó bùkún yín pẹ̀lú ohun tí ẹ nílò. Òun yíò wo ẹ̀mì ìpalára yín sàn. Bí ẹ ti ngbé arayín lé E, ẹrù yín yíò fúyẹ́. Bí ẹ ti ndá tí ẹ sì npa àwọn májẹ̀mú mọ́ láti tẹ̀lé Jésù Krístì, ẹ ó ri pé ìrora àwọn àkokò ìgbé ayé jẹ́ ránpẹ́. Àwọn ìpọ́njú yín yíò di “gbígbémì nínú ayọ̀ Krístì.”
Kò ní ṣíwájú jù tàbí kó pẹ́ jù fún yín láti di olùfọkànsìn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì. Nígbànáà ẹ ó ní ìrírí kíkún àwọn ìbùkún Ètùtù Rẹ̀. Bákannáà ẹ ó di aláápọn si ní ṣíṣe ìrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ní ọjọ́ kan tó nbọ̀, Jésù Krístì yíò padàwá sí ilẹ̀-ayé bí Mèsíàh mìllẹ́níọ́mù. Nítorínáà ní òní mo pè yín láti tún ìgbésí ayé yín yà sọ́tọ̀ sí Jésù Krístì. Mo ké pè yín láti ṣèrànwọ́ láti kó àwọn olùfọ́nká Ísráẹ́lì jọ àti láti múra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa. Mo pè yín láti bá Krístì sọ̀rọ̀, ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, kí ẹ sì yọ̀ nínú Krístì!
Ẹ wá sọ́dọ̀ Krístì kí ẹ sì “fi gbogbo [ọkàn]” yín fún Un. Èyí ni ìpamọ́ sí ìgbésí-ayé ti ayọ̀!
Dídárajùlọ ṣì nbọ̀ síbẹ̀, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, nítorí Olùgbàlà nbọ̀ wá lẹ́ẹ̀kansi! Dídárajùlọ ṣì nbọ̀ síbẹ̀ nítorí Olúwa nyára sí iṣẹ́ Rẹ̀. Dídárajùlọ ṣì nbọ̀ síbẹ̀ bí a ti nyí ọkàn wa padà àti ìgbésí-ayé wa ní kíkún sí Jésù Krístì.
Mo fì ìrẹ̀lẹ̀ jẹri pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run. Èmi ni ọmọẹ̀hìn Rẹ. Mo ní ọlá láti jẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀. Ní Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀, “a ó fi ògo Olúwa hàn, gbogbo ènìyàn yíò sì rí i papọ̀.” Ọjọ́ náà yíò kún fún ayọ̀ fún olódodo!
Nípasẹ̀ agbára àwọn kọ́kọ́rọ́ mímọ́ oyè-àlùfáà tí mo dìmú, mo kéde òtítọ́ yí sí i yín àti sí gbogbo ayé! Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.