Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109


Ìpín 109

Àdúrà tí a gbà níbi ìyàsímímọ́ tẹ́mpìlì ní Kirtland, Ohio, 27 Oṣù Kejì 1836. Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí Wòlíì kọ sílẹ̀, a fi àdúrà yìí fún un nípa ìfihàn.

1–5, Tẹ́mpìlì Kirtland ni a kọ́ bí ibi kan fún Ọmọ Ènìyàn láti bẹ̀wò; 6–21, Ó nílati jẹ́ ilé àdúrà, ààwẹ̀ gbígbà, ìgbàgbọ́, ẹ̀kọ́ kíkọ́, ògo, àti ètò, àti ilé Ọlọ́run; 22–33, Kí àwọn aláìronúpìwàdà tí wọ́n lòdì sí àwọn èníyàn Olúwa ó dààmú; 34–42, Kí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ó jade lọ nínú agbára láti kó àwọn olõtọ́ jọ sí Síónì; 43–53, Kí á gba àwọn Ènìyàn Mímọ́ kúrò nínú àwọn ohun ìbẹ̀rù tí yíò jẹ́ títú jáde sí orí àwọn ènìyàn búburú ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn; 54–58, Kí àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ènìyàn àti àwọn ìjọ ó múrasílẹ̀ fún ìhìnrere náà; 59–67, Kí àwọn Júù, àwọn ará Lámánì, àti gbogbo Ísráẹ́lì di ríràpadà; 68–80, Kí a le dé àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní adé pẹ̀lú ògò àti ọlá kí wọn ó sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.

1 Ọpẹ́ ni fún orúkọ rẹ, Áà Olúwa Ọlọ́run Ísráẹ́lì, ẹnití ó npa májẹ̀mú mọ́ àti tí ó nfi àánú hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ó nrìn ní mímọ́ níwájú rẹ, pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn—

2 Ìwọ tí ó ti pàṣẹ fún awọn ìránṣẹ rẹ láti kọ́ ilé kan sí orúkọ rẹ ní ìhín yìí [Kirtland].

3 Àti nísisìyí ìwọ ríi, Olúwa, pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ ti ṣe gẹ́gẹ́bí àṣẹ rẹ.

4 Àti nísisìyí àwa béèrè lọ́wọ́ rẹ, Bàbá Mímọ́, ní orúkọ Jésù Krístì, Ọmọ oókan àyà rẹ, ní orúkọ ẹ̀nikan ṣoṣo náà tí a lè fi ìgbàlà fún àwọn ọmọ ènìyàn, àwa béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa, láti tẹ́wọ́gba ilé yìí, tí í ṣe iṣẹ́ ti ọwọ́ àwa, ìránṣẹ́ rẹ, èyítí ìwọ ti pàṣẹ fún wa láti kọ́.

5 Nítorí ìwọ mọ̀ pé àwa ti ṣe iṣẹ́ yìí nínú ìpọ́njú nlá; àti nínú àìní wa àwà ti fi lára ohun tí a ní sílẹ̀ láti kọ́ ilé kan sí orúkọ rẹ, pé kí Ọmọ Ènìyàn ó lè ní ibi kan láti fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀.

6 Àti pé bí ìwọ ṣe wí nínú ìfihàn kan, tí a fi fún wa, ní pípè wá ní ọ̀rẹ́ rẹ, ní wíwí pé—Ẹ pe ìpéjọpọ̀ ọ̀wọ̀ yín, bí mo ṣe pàṣẹ fún yín;

7 Àti pé bí ẹni gbogbo kò ṣe ní ìgbàgbọ́, ẹ wá kiri pẹ̀lú aápọn kí ẹ sì kọ́ ara yín ní àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n; bẹ́ẹ̀ni, ẹ wákiri nínú àwọn ìwé tí ó dára jùlọ àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ẹ wá ẹ̀kọ́ kíkọ́ káàkiri àní nípa ṣíṣe àṣàrò àti bákannáà nípa ìgbàgbọ́;

8 Ẹ ṣe ètò ara yín; ẹ pèsè gbogbo ohun tí ẹ nílò; kí ẹ sì gbé ilé kan kalẹ̀, àní ilé àdúrà, ilé ààwẹ̀, ilé ìgbàgbọ́, ilé ẹ̀kọ́, ilé ògo, ile ètò, ilé Ọlọ́run;

9 Kí àwọn ìwọléwá yín ó lè jẹ́ ní orúkọ Olúwa, kí àwọn ìjádelọ yín ó lè jẹ́ ní orúkọ Olúwa, kí gbogbo ìkíni yín ó lè jẹ́ ní orúkọ Olúwa, pẹ̀lú ìgbọ́wọ́ sókè sí Ẹni Gíga Jùlọ—

10 Àti nísisìyí, Bàbá Mímọ́, àwa béèrè lọ́wọ́ rẹ láti ràn wá lọ́wọ́, àwa ènìyàn rẹ̀, pẹ̀lú ore ọ̀fẹ́ rẹ, ní pípe ìpéjọpọ̀ ọ̀wọ̀ wa, pé kí á lè ṣe é sí ọlá tìrẹ àti ìtẹ́wọ́gbà rẹ ti ọ̀run;

11 Àti ní ọ̀nà tí a ó lè rí wa ní ìkàyẹ, ní ojú rẹ, láti gba ìmúṣẹ ti àwọn ìlerí èyítí ìwọ ti se fún wa, àwa ènìyàn rẹ, nínú àwọn ìfihàn tí a fi fún wa;

12 Pé kí ògo rẹ ó lè sọ̀kalẹ̀ sí órí àwọn ènìyàn rẹ, àti ní orí ilé rẹ yìí, èyítí àwa yà sọ́tọ̀ sí ọ nísisìyí, kí ó lè jẹ́ yíyà sí mímọ́ àti yíyà sọ́tọ̀ láti jẹ́ mímọ́, àti pé kí ìwàníbìkan mímọ́ rẹ ó lè tẹ̀síwájú láti máa wà nínú ilé yìí;

13 Àti pé kí gbogbo ènìyàn tí yíò wọ orí ìloro ilé Olúwa ó lè ní ìmọlára agbára rẹ, àti kí wọ́n ó ní ìmọ̀lára fífi agbára mú láti jẹ́wọ́ pé ìwọ ti yàá sí mímọ́, àti pé ilé rẹ ni í ṣe, ibi jíjẹ́ mímọ́ rẹ.

14 Kí o sì fi fúnni, Bàbá Mímọ́, pé kí á lè kọ́ gbogbo àwọn tí wọn yíò jọ́sìn nínú ilé yìí ní àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n láti inú àwọn ìwé tí ó dára jùlọ̀, àti pé kí wọ́n ó lè wá ẹ̀kọ́ kiri àní nípa ṣíṣe àṣàrò, àti pẹ̀lú nípa ìgbàgbọ́, bí ìwọ ṣe wí;

15 Àti pé kí wọ́n ó lè dàgbà sókè nínú rẹ, kí wọn ó sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, àti kí á ṣe ètò wọn gẹ́gẹ́bí àwọn òfin tirẹ, kí wọ́n ó sì múra láti gba gbogbo ohun tí wọn nílò;

16 Àti pé kí ilé yìí ó lè jẹ́ ilé kan ti àdúrà, ilé kan ti àwẹ̀, ilé kan ti ìgbàgbọ́, ilé kan ti ògo àti ti Ọlọ́run, àní ilé tìrẹ;

17 Pé kí gbogbo àwọn wíwọléwá ti àwọn ènìyàn rẹ, sí inú ilé yìí, lè jẹ́ ní orúkọ Olúwa;

18 Pé kí gbogbo àwọn ìjádelọ wọn kúrò nínú ilé yìí ó lè jẹ́ ní orúkọ Olúwa;

19 Àti pé kí gbogbo àwọn ìkíni wọn ó lè jẹ́ ní orúkọ Olúwa, pẹ̀lú àwọn ọwọ́ mímọ́, ní gbígbé sókè sí Ẹni Gíga Jùlọ;

20 Àti pé a kí yíò gba ohun àìmọ́ kan láàyè láti wá sí inú ilé rẹ láti sọ ọ́ di àìmọ́;

21 Àti pé nígbàtí àwọn ènìyàn bá rú òfin, èyíkéyìí nínú wọn, wọn ó lè ronúpìwàdà kíákíá wọn ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, kí wọn ó sì rí ojúrere ní ojú rẹ, kí á sì mú wọn padà sípò sí àwọn ìbùkún èyítí ìwọ ti yàn láti tú jade sí orí àwọn tí wọn yíò bọ̀wọ̀ fún ọ nínú ilé rẹ.

22 Àwa sì béèrè lọ́wọ́ rẹ, Bàbá Mímọ́, pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ ó lè jade lọ láti ilé yìí pẹ̀lú ìhámọ́ra agbára rẹ, àti pé kí orúkọ rẹ ó lè wà ní orí wọn, àti ògo rẹ yí wọn kákiri, àti kí àwọn ángẹ́lì rẹ ó máa ṣe ìtọ́jú wọn;

23 Àti láti ìhínyìí kí wọn ó lè sọ àwọn ìhìn títóbi lọ́pọ̀lọpọ̀ ati ológo, ní òtítọ́, títí dé àwọn ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé, kí wọn ó lè mọ̀ pé iṣẹ́ rẹ ni èyí í ṣe, àti pé ìwọ ti na ọwọ́ rẹ jáde, láti ṣe ìmúṣẹ èyítí ìwọ ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì, nípa àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn.

24 Àwa béèrè lọ́wọ́ rẹ, Bàbá Mímọ́, láti fi ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn múlẹ̀ tí wọn yíò jọ́sìn, àti tí wọn yío fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ di orúkọ àti ìdúró kan mú nínú ilé rẹ yìí, dé gbogbo àwọn ìran àti fún ayérayé;

25 Pé kì yíò sí ohun ìjà kan tí a ṣe lòdì sí wọn tí yíò ṣe rere; pé ẹni náà tí ó bá gbẹ kòtò kan fún wọn ní yíò jìn sí inú èyí kan náà fúnra rẹ̀;

26 Pé kì yíò sí àgbájọpọ̀ àwọn ìwà búburú kan tí yíò ní agbára láti dìde sókè kí wọ́n sì borí àwọn ènìyàn rẹ ní orí àwọn ẹnití a ó fi orúkọ rẹ sí nínú ilé yìí;

27 Àti bí èyíkéyìí àwọn ènìyàn bá dìde dojúkọ àwọn ènìyàn wọ̀nyìí, kí ìbínú rẹ ó ru sókè lòdì sí wọn;

28 Bí wọ́n bá sì kọlù àwọn ènìyàn wọ̀nyìí ìwọ yíò kọ lù wọ́n; ìwọ yíò jà fún àwọn ènìyàn rẹ bí ìwọ̀ ti ṣe ní ọjọ́ ogun, kí á lè gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn.

29 Àwa béèrè lọ́wọ́ rẹ, Bàbá Mímọ́, láti dààmú, àti lati yà lẹ́nu, àti láti mú wọn wá sí ìtìjú ati ìdàrúdàpọ̀, gbogbo àwọn wọnnì tí wọn ti tan àwọn ìròhìn irọ́ káàkiri ní òkèrè, jákèjádò agbáyé, ní àtakò sí ìránṣẹ́ tàbí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, bí wọn kò bá ronúpìwàdà, nígbàtí a ó kéde ìhìnrere àìlópìn ní etí wọn;

30 Àti pé kí gbogbo àwọn iṣẹ wọn le jẹ́ sísọ di asán, kí á sì gbá wọn kúrò nípa yìnyín, àti nípa àwọn ìdájọ́ èyítí ìwọ yíò rán sí orí wọn nínú ìbínú rẹ, kí òpin ó lè dé sí àwọn irọ́ pípa àti àwọn ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ lòdì sí àwọn ènìyàn rẹ.

31 Nítorí ìwọ mọ̀, Olúwa, pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀ níwájú rẹ ní jíjẹ́rìí sí orúkọ rẹ, nítorí èyítí wọ́n ti jẹ ìyà àwọn nkan wọ̀nyí.

32 Nítorínáà àwa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ fún ìtúsílẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti pátápátá kúro ní abẹ́ àjàgà yìí;

33 Ké e kúrò, Olúwa; ké e kúrò ní ọrùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, nípa agbára rẹ, kí àwa ó lè dìde sókè láàrin ìran yìí, kí a sì ṣe iṣẹ́ rẹ.

34 Jèhófàh, ṣàánú fún àwọn ènìyàn wọ̀nyìí, àti bí gbogbo ènìyàn ṣe ti ṣẹ̀, dárí àwọn ìrékọjá àwọn ènìyàn rẹ jì wọ́n, sì jẹ́kí á pa wọ́n rẹ́ títí láé.

35 Jẹ́kí àmì òróró ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ó di fífi èdídí dì ní orí wọn pẹ̀lú agbára láti òkè wá.

36 Jẹ́kí ó di mímúṣẹ ní orí wọn, bíi ní orí àwọn wọnnì ní ọjọ́ Pẹ́ntekọstì; jẹ́kí á tú ẹ̀bùn àwọn èdè jade sí orí àwọn ènìyàn rẹ, àní ẹ̀là ahọ́n àwọn èdè bíi ti iná, àti ìtúmọ̀ ti èyí náà.

37 Sì jẹ́kí ilé rẹ kí ó kún, bíi ti ìró ẹ̀fũfù líle, pẹ̀lú ògo rẹ.

38 Fi ẹ̀rí ti májẹ̀mú náà sí orí àwọn ìránṣẹ rẹ, pé nígbàtí wọ́n bá jade lọ tí wọ́n sì kéde ọ̀rọ̀ rẹ wọn ó lè fi èdídí dí òfin náà, sì pèsè ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ sílẹ̀ fún gbogbo àwọn ìdájọ́ wọnnì tí ìwọ ṣetán láti rán, nínú ìbínú rẹ, sí orí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, nítorí àwọn ìrékọjá wọn, kí àwọn ènìyàn rẹ má baà ṣàárẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.

39 Èyíkéyìí ilú nlá tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ bá wọ̀, tí àwọn ènìyàn ibẹ̀ bá sì gba ẹ̀rí wọn, jẹ́ kí àlãfíà rẹ àti ìgbàlà rẹ kí ó wà ní orí ìlú nlá náà; pé kí wọ́n o lè kó àwọn olõtọ́ jọ jáde ní ìlú nlá náà, kí wọ́n ó lè jáde wá sí Síónì, tàbí sí àwọn èèkàn rẹ̀, àwọn ibi yíyàn rẹ, pẹ̀lú àwọn orin ayọ̀ àìlópin;

40 Àti títí tí a ó fi mú èyí ṣẹ, máṣe jẹ́kí àwọn ìdájọ́ rẹ ó ṣubú sí orí ìlú nlá náà.

41 Àti èyíkéyìí ìlú nlá tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ bá wọ̀, tí àwọn ènìyàn ìlú náà kò sì gbà ẹ̀rí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àti tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ kìlọ̀ fún wọn láti gba ara wọn là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí, jẹ́kí ó wà ní orí ìlú nlá náà gẹ́gẹ́bí èyí tí ìwọ ti sọ nípa ẹnu àwọn wòlíì rẹ.

42 Ṣùgbọ́n gbani, ìwọ Jèhófàh, àwa bẹ̀ ọ́, àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò lọ́wọ́ wọn, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ wọn.

43 Olúwa, àwa kò ní inú dídùn nínú ìparun àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa; ọkàn wọn jẹ́ ìyebíye ní iwájú rẹ;

44 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́dọ̀ di mímúṣẹ. Ran àwọn ìránṣẹ rẹ lọ́wọ́ láti sọ pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ore ọ̀fẹ́ rẹ fún wọ́n: Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, Olúwa, kìí ṣe tiwa.

45 Àwa mọ̀ pé ìwọ ti sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ nípa àwọn ohun tí ó ní ẹ̀rù sí àwọn ènìyàn búburú, ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn—pé ìwọ yíò tú àwọn ìdájọ́ rẹ jade, láì ní òṣùnwọ̀n;

46 Nítorínáà, Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ nínú ìyọnu àwọn ènìyàn búburú; jẹ́kí ó ṣeéṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ láti fi èdídí di òfin náà, àti lati di ẹ̀rí náà, kí wọ́n ó lè múrasílẹ̀ de ọjọ́ ti jíjóná.

47 Àwa béèrè lọ́wọ́ rẹ, Bàbá Mímọ́, láti rantí àwọn wọnnì tí a ti lé kúrò nípa ọwọ́ àwọn olùgbé ìjọba ìbílẹ̀ Jackson, ní Missouri, ní orí àwọn ilẹ̀ ogún ìní wọn, sì ké e kúrò, Olúwa, àjàgà ìpọ́njú yìí tí a ti gbé lé orí wọn.

48 Ìwọ ṣã mọ̀, Olúwa, pé a ti ni wọ́n lára àti pọ́n wọn lójú púpọ̀púpọ̀ láti ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú; ọkàn wa sàn jade pẹ̀lú ìrora nítorí àwọn ẹrù ìṣòro wọn.

49 Olúwa, yíò ha ti pẹ́ tó tí ìwọ yíò fi jẹ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyìí fi ara da ìpọ́njú yìí, àti igbe àwọn aláìṣẹ̀ wọn láti gòkè wá sí etí rẹ, àti ẹ̀jẹ̀ wọn wá sókè ní ẹ̀rí níwájú rẹ, àti tí ìwọ kì yíò ṣe àfihàn májẹ̀mú rẹ ní ìtìlẹ́hìn wọn?

50 Ṣe àánú, Olúwa, ní orí àgbáríjọ àwọn ènìyàn búburú, tí wọ́n ti lé àwọn ènìyàn rẹ, kí wọn ó lè dáwọ́dúró láti bàjẹ́, kí wọ́n ó lè ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí a ó bá rí ironúpìwàdà;

51 Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá ní ṣe èyí, fi apá rẹ hàn, Olúwa, kí o sì ra èyíinì padà tí ìwọ ti yàn ní Síónì fún àwọn ènìyàn rẹ.

52 Àti bí kò bá le jẹ́ ìdàkejì, pé kí àfojúsùn àwọn ènìyàn rẹ ó má baà kùnà níwájú rẹ, njẹ́ kí ìbínú rẹ ó lè ru sókè, àti kí ìrunú rẹ ó ṣubú lé wọn ní orí, kí á lè fi wọ́n ṣofò danù, ní àpapọ̀ àti egbò àti ẹ̀ka, kúrò lábẹ́ ọ̀run;

53 Ṣùgbọ́n níwọ̀nbí wọn bá rónúpìwàdà, olóore ọ̀fẹ́ àti aláànú ni ìwọ, ìwọ yío sì yí ìbínú rẹ kúrò nígbàtí ìwọ bá wo ojú Ẹ̀ni àmì oróró rẹ.

54 Ṣe àánú, Olúwa, ní orí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé; ṣe àánú ní orí àwọn alákóso ilẹ̀ wa; njẹ́ kí àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ wọnnì, èyítí a dáàbò bo pẹ̀lú ọlá àti iyì, èyí tí í ṣe, Ìwé Òfin ilẹ̀ wa, láti ọwọ́ àwọn bàbá wa, jẹ́ fífi ẹsẹ̀ múlẹ̀ títí láé.

55 Rántí àwọn ọba, àwọn ọmọ aládè, àwọn ẹni iyì, àti àwọn wọnnì tí wọ́n tóbi ní orí ilẹ̀ ayé, àti gbogbo ènìyàn, àti àwọn ìjọ, gbogbo tálákà, aláìni, àti àwọn tí a npọ́n lójú, ti orí ilẹ̀ ayé;

56 Kí á lè mú ọkàn wọn rọ̀ nígbàtí àwọn ìránṣẹ́ rẹ bá jáde lọ láti ínú ilé rẹ, Jèhófàh, láti jẹ́rìí orúkọ rẹ, kí àwọn èrò búburú wọn ó lè fi ààyè sílẹ̀ níwájú òtítọ́, àti kí àwọn ènìyàn rẹ ó lè gba ojú rere ní ojú gbogbo ènìyàn;

57 Kí gbogbo àwọn òpin ilẹ̀ ayé ó lè mọ̀ pé àwa, ìránṣẹ́ rẹ, ti gbọ́ ohùn rẹ, àti pé ìwọ ni ó rán wa;

58 Pé láti ààrin gbogbo ìwọnyìí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọmọkùnrin Jákọ́bù, lè kó àwọn olõtọ́ jọ jade wá láti kọ́ ìlú nlá mímọ́ kan sí orúkọ mi, bí ìwọ ṣe pàṣẹ fún wọn.

59 Àwa béèrè lọ́wọ́ rẹ láti yan fún Síónì àwọn èèkàn lẹ́hìn èyí tí ìwọ ti yàn yìí, pé kí ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn rẹ ó lè máa yí lọ nínú agbára àti ọlá nlá, pé kí iṣẹ́ rẹ ó lè yá kánkán nínú òdodo.

60 Nísisìyí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí, Olúwa, ni àwa ti sọ níwájú rẹ, nípa ti àwọn ìfihàn àti àwọn àṣẹ èyítí ìwọ ti fi fún àwa, ẹnití a dámọ̀ pẹ̀lú àwọn Kèfèrí.

61 Ṣùgbọ́n ìwọ mọ̀ pé ìwọ ní ìfẹ́ nlá fún àwọn ọmọ Jákọ́bù, àwọn tí a ti fọ́nká ní orí àwọn òkè fún ìgbà pípẹ́, nínú ọjọ́ tí ó ní ìkuukù àti òkùnkùn.

62 Nítorínáà àwa béèrè lọ́wọ́ rẹ láti ṣàánú fún àwọn ọmọ Jákọ́bù, pé kí Jérúsalẹ́mù, láti wákàtí yìí, ó lè bẹ̀rẹ̀sí di ríràpadà;

63 Àti kí àjàgà ẹrú ó bẹ̀rẹ̀sí di jíjá kúrò ní ilé Dáfídì;

64 Àti kí àwọn ọmọ Júdà lè bẹ̀rẹ̀sí padà sí àwọn ilẹ̀ èyítí ìwọ ti fi fún Ábráhámù, bàbá wọn.

65 Àti jẹ́kí àwọn ìyókù ti Jákọ́bù, àwọn tí a ti fi bú tí a sì kọlù nítorí ti ìrékọjá wọn, ó lè jẹ́ yíyí lọ́kàn padà kúrò ní ipò ẹhànnà àti ènìyàn kénìyàn, sí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti ìhìnrere àìlópin;

66 Pé kí wọ́n ó lè kó àwọn ohun ìjà ti ìtàjẹ̀sílẹ̀ wọn sílẹ̀, àti kí wọ́n dáwọ́ ìṣọ̀tẹ̀ wọn dúró.

67 Sì jẹ́kí gbogbo àwọn ìyókù Ísráẹ́lì fífọ́nká, àwọntí a ti lé sí àwọn ìpẹ̀kún ilẹ̀ ayé, lè wá sí ìmọ̀ òtítọ́ náà, kí wọn ó lè gbàgbọ́ nínú Mèssía, àti kí wọn lè jẹ́ rírà padà kúrò nínú ìnilára, kí wọn ó sì yọ̀ níwájú rẹ.

68 Olúwa, rantí ìránṣẹ́ rẹ, Joseph Smith Kékeré, àti gbogbo ìpọ́njú àti ọ̀pọ̀ inúnibíni rẹ̀—bí òun ṣe bá Ọlọ́run Olódùmarè dá májẹ̀mú, àti jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí ọ, Ọlọ́run Alágbára Jákọ́bù—àti àwọn òfin èyítí ìwọ ti fi fún un, àti pé òun ti fi òtítọ́ inú gbìyànjú láti ṣe ìfẹ́ rẹ.

69 Ṣe àánú, Olúwa, ní orí ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀, pé kí wọ́n lè dí ẹni ìgbéga ní iwájú rẹ, kí o sì dá wọn sí nípa ọwọ́ ìtọ́jú rẹ.

70 Ṣe àánú fún gbogbo àwọn ìbátan wọn ní ìfarakọ́ra, pé kí àwọn èrò búburú wọn lè jẹ́ títúká àti gbígbá lọ bíi pẹ̀lú ìkún omi; pé kí á lè yí wọn lọ́kàn padà àti rà wọ́n padà pẹ̀lú Ísráẹ́lì, kí wọn ó lè mọ̀ pé ìwọ ni Ọlọ́run.

71 Rántí, Olúwa, àwọn ààrẹ, àní gbogbo àwọn ààrẹ ti ìjọ rẹ, pé kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ó lè gbé wọn ga, pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹbí wọn, àti àwọn ìbátan wọn tààrà ní ìfarakanra, pé kí àwọn orúkọ wọ̀n ó lè wà pẹ́ títí àti kí ó wà ní ìrántí àìlópin láti ìran dé ìran.

72 Rántí gbogbo ìjọ rẹ, Áà Olúwa, pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹbí wọn, àti gbogbo àwọn ìbátan wọn tààrà ní ìfarakanra, pẹ̀lú gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn olùpọ́njú wọn, pẹ̀lú gbogbo tálákà àti oníwà tutu ti ilẹ̀ ayé; pé kí ìjọba náà, èyítí ìwọ ti gbé kalẹ̀ láì lo ọwọ́, lè di òkè nlá kan kí ó sì kún ilẹ̀ ayé pátápátá;

73 Pé kí ìjọ rẹ ó lè jade wá láti ijù ti òkùnkùn, kí ó sì tàn dáradára bíi òṣùpá, kí ó mọ́lẹ̀ bíi oòrùn, kí ó sì ní ẹ̀rù bíi ẹgbẹ́ ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn àsìá;

74 Kí wọn ó sì jẹ́ ṣíṣe ní ọ̀ṣọ́ bíi ìyàwó fún ọjọ́ náà nígbàtí ìwọ yíò ṣí aṣọ ìkéle àwọn ọ̀run, tí ìwọ ó sì mú kí àwọn òkè kí ó ṣàn wá sílẹ̀ níwájú rẹ, àti tí àwọn àfonífojì yíò jẹ́ gbigbé ga, àwọn ibití ó jẹ́ wíwọ́ ó lè di títẹ́jú; pé kí ògo rẹ ó lè kún ilẹ̀ ayé;

75 Pé nígbàtí ìpè náà yíò bá dún fún àwọn òkú, a ó lè gbà wá sí òkè ní àwọ sánmọ̀ láti pàdé rẹ, kí á lè wà títí láé pẹ̀lú Olúwa;

76 Kí àwọn aṣọ wa lè jẹ́ àìlẽrí, kí á lè fi aṣọ òdodo wọ̀ wá, pẹ̀lú àwọn imọ̀ ọ̀pẹ ní ọwọ́ wa, àti àwọn adé ògo ní orí wa, kí a sì kórè ayọ̀ ayérayé fún gbogbo àwọn ìjìyà wa.

77 Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, gbọ́ tiwa nínú àwọn ẹ̀bẹ̀ wa wọ̀nyìí, kí o sì dá wa lóhùn láti ọ̀run, ibùgbé rẹ mímọ́, níbití ìwọ jókòó ní orí ìtẹ́, pẹ̀lú ògo, ọlá, agbára, ọlánlá, ipá, ìjọba, òtítọ́, àiṣègbè, ìdájọ́, àánú, àti ẹ̀kúrẹ́rẹ́ aláìnípẹ̀kun kan, láti àìlópin dé àìlópin.

78 Gbọ́, gbọ́, gbọ́ tiwa, Olúwa! Kí o sì dáhùn àwọn ẹ̀bẹ̀ wọ̀nyìí, kí o sì tẹ́wọ́ gba ìyàsímímọ́ ilé yìí sí ọ, iṣẹ́ ọwọ́ wa, èyítí àwa ti kọ́ sí orúkọ rẹ;

79 Àti ìjọ yìí bákannáà, láti fi orúkọ rẹ sí orí rẹ̀. Sì ràn wá lọ́wọ́ nípa agbára Ẹ̀mí rẹ, pé kí á lè da àwọn ohùn wa pọ̀ pẹ̀lú ti àwọn dídán nnì, àwọn séráfù tí ntàn yíká ìtẹ́ rẹ, pẹ̀lú àwọn ìhó ìyìn, ní kíkọ orin Hòssánà sí Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́ Àgùtàn náà!

80 Sì jẹ́kí àwọn wọ̀nyí, àwọn ẹni àmi òróró rẹ, jẹ́ wíwọ̀ ní aṣọ pẹ̀lú ìgbàlà, àti kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ó pariwo sókè fún ayọ̀. Àmín, àti Àmín.