Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 10


Ìpín 10

Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith, ní Harmony, Pennsylvania, tí ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ àyíká Oṣù Kẹrin 1829, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn abala kan le ti jẹ́ gbígbà láti ìbẹ̀rẹ̀ bíi ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1828. Nínú èyí Olúwa sọ fún Joseph nípa àwọn àtúnṣe tí àwọn ènìyàn búburú ṣe nínú àwọn ojú ewé ìwé àfọwọ́kọ mẹ́rìndínlọ́gọ́fà lati ínú ìtumọ̀ ìwé ti Léhì, nínú Ìwé Ti Mọ́mọ́nì. Àwọn ojú ewé ìwé àfọwọ́kọ wọ̀nyí ti sọnù ní ìpamọ́ Martin Harris, ẹnití a fa àwọn ewé ìwé náà lé lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀. (Wo àkọlé sí ìpín kẹta.) Ète búburú náà ni láti dúró de àtúnṣe tí wọ́n retí sí ìtúmọ̀ àwọn ohun tí ó wà nínú àwọn ojú ewé ìwé tí wọ́n jí gbé lọ, àti lẹ́hìnnáà kí wọn ó le sọ olùtúmọ̀ di aláìmọ̀kan nípa fífi àwọn àìṣedéédé hàn tí àwọn àtúnṣe náà ti múwá. Pé ète búburú yìí ti di rírò sínú fún ènìyàn ibi náà ti ó sì jẹ́ mímọ̀ sí Olúwa àní nígbàtí Mọ́mọ́nì, ará Néfì olùpìtàn ìgbàanì, nṣe àkekúrú àwọn àwo tí a ti kójọ sílẹ̀, ni ó fara hàn nínú Ìwé Ti Mọ́mọ́nì (wo Àwọn Ọ̀rọ̀ ti Mọ́mọ́nì 1:3–7).

1–26, Sátánì rú àwọn ènìyàn búburú sókè láti ṣe àtakò iṣẹ́ Olúwa; 27–33, Òun nwá láti pa ọkàn àwọn ènìyàn run; 34–52, Ìhìnrere yíò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì àti sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nípa Ìwé Ti Mọ́mọ́nì; 53–63, Olúwa yíò gbé Ìjọ Rẹ̀ àti ìhìnrere Rẹ̀ kalẹ̀ ní ààrin àwọn ènìyàn; 64–70, Òun yíò kó gbogbo àwọn ẹni ironúpìwàdà jọ sí inú Ìjọ Rẹ̀ yíò sì gba àwọn olùgbọ́ràn là.

1 Nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé nítorí tí o gbé àwọn ohun kíkọ wọnnì tí a ti fi agbára fún ọ láti túmọ̀ nípasẹ̀ Urímù àti Túmmímù, sílẹ̀ sí ọwọ́ ènìyàn búburú, ìwọ ti sọ wọ́n nù.

2 Àti pé ìwọ ti sọ ẹ̀bùn rẹ nù ní ìgbà kannáà, iyè rẹ sì ti ṣókùnkùn.

3 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nísisìyí a ti mú un padà sípò fún ọ lẹ́ẹ̀kansíi; nítorínáà ríi pé o jẹ́ olótĩtọ́ kí o sì tẹ̀síwájú sí píparí ìyókù iṣẹ́ ìtumọ̀ náà gẹ́gẹ́bí o ṣe bẹ̀rẹ̀.

4 Má ṣe sáré púpọ̀ jù tàbí kí o ṣe iṣẹ́ ju bí o ti ní okun lọ àti àwọn ohun èlò tí a pèsè fún ọ láti ṣe ìtúmọ̀; ṣugbọ́n jẹ́ aláìṣemẹ́lẹ́ títí dé òpin.

5 Máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ìwọ lè di aṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ni, kí ìwọ o lè ṣẹ́gun Sátánì, àti pé kí ìwọ lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Sátánì tí wọ́n di iṣẹ́ rẹ̀ mú.

6 Kíyèsíi, wọn ti wá ọ̀nà láti pa ọ́ run; bẹ́ẹ̀ni, àní ẹni náà nínú ẹni tí ìwọ ní ìgbẹkẹ̀lé, ti wá ọ̀nà láti pa ọ́ run.

7 Àti pé fún ìdí èyí mo sọ pé ó jẹ́ ènìyàn búburú, nítorí òun ti wá ọ̀nà láti kó àwọn ohun tí a fi sí ìpamọ́ rẹ lọ; àti bákannáà òun ti lépa láti pa ẹ̀bùn rẹ run.

8 Àti pé nítorí tí ìwọ ti gbé àwọn ìwé náà lé e lọ́wọ́, kíyèsíi, àwọn ènìyàn búburú ti gbà wọ́n lọ́wọ́ rẹ.

9 Nítorínáà, ìwọ ti gbé àwọn nkan wọ̀nyí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, èyíinì tí ó jẹ́ mímọ́, sí inũ búburú.

10 Àti pé, kíyèsíi, Sátánì ti fi sí ọkàn wọn láti pààrọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí ìwọ ti mú kí a kọ, tàbí tí ìwọ ti túmọ̀, àwọn èyí tí wọn ti lọ kúrò ní ọwọ́ rẹ.

11 Àti kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé nítorí tí wọn ti pààrọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọn kà ní ìlòdì sí ohun tí ìwọ túmọ̀ àti tí o mú kí a kọ;

12 Àti, ní ọ̀nà yìí, Sátánì ti lépa lati gbé ète àrékérekè kan kalẹ̀, kí òun lè pa iṣẹ́ yìí run.

13 Nítorí ó ti fi sí ọkàn wọn láti ṣe èyí, pé nípa irọ́ pípa wọn yíò lè sọ pé àwọn ti mú ọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ìwọ ṣe bí ẹni pé o túmọ̀.

14 Lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé èmi kì yíò fi ààyè gbà pé kí Sátánì ṣe àṣeyọrí ète ibi rẹ̀ nínú ohun yìí.

15 Nítorí kíyèsíi, òun ti fi sí ọkàn wọn láti mú kí ìwọ ó dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò, nípa bíbéèrè lati tún ìtúmọ̀ rẹ̀ ṣe lẹ́ẹ̀kan síi.

16 Àti nígbànáà, kíyèsíi, wọ́n sọ, wọ́n sì rò nínú ọkàn wọn—Àwa yíò wòó bóyá Ọlọ́run ti fún un ní agbára láti túmọ̀, bí ó bá sì rí bẹ́ẹ̀, yíò tún fún un ní agbára bákanáà lẹ́ẹ̀kan síi.

17 Àti pé bí Ọlọ́run bá fún un ní agbára lẹ́ẹ̀kan síi, tàbí bí òun bá ṣe ìtúmọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi, tàbí, ní ọnà míràn, bí òun bá lè mú awọn ọ̀rọ̀ kannáà jáde wá, kíyèsíi, a ti ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọwọ́ wa, àwa sì ti pààrọ̀ wọn;

18 Nítorínáà wọn kò lè bá ara mu, àwa yíò sì sọ pé òun ti pa irọ́ nínú awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti pè òun kò ní ẹ̀bùn, òun kò sì ní agbára.

19 Nítorínáà a ó paárun, àti iṣẹ́ náà bákannáà; àti pé a ó ṣe èyí kí ojú má baà tì wá ní ìkẹhìn, àti kí á ba lè gba ògo ti ayé.

20 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé Sátánì ti gba ọkàn wọn; ó rú ọkàn wọn sókè sí àìṣedéédé ní ìlòdì sí ohun èyítí ó dára;

21 Àti pé ọkàn wọn ti bàjẹ́, ó sì kún fún búburú àti àwọn ohun ìríra; àti pé wọn fẹ́ràn òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, nítorí awọn iṣẹ́ wọn jẹ́ ibi; nítorínáà wọn kì yíò béèrè mi.

22 Sátánì rú wọn sókè, kí ó lè sin ọkàn wọn lọ sí ìparun.

23 Àti báyìí ni òun ti gbé ète àrékérekè kan kalẹ̀, ní ríro láti pa iṣẹ́ Ọlọ́run run; ṣugbọ́n èmi yíò beerè èyí ní ọwọ́ wọn, yíò sì padà di ìtìjú àti ìdálẹ́bi fún wọn ní ọjọ́ ìdájọ́.

24 Bẹ́ẹ̀ni, òun ti rú ọ̀kàn wọ́n sókè láti bínú tako iṣẹ́ yìí.

25 Bẹ́ẹ̀ni, òun ti sọ fún wọn: Ẹ tàn jẹ kí ẹ sì dúró ní ìkọ̀kọ̀ láti mú, kí ẹ lè pa run; kíyèsíi; èyí kìí ṣe ìbàjẹ́. Àti báyìí ni òun pọ́n wọn, ó sì wí fún wọn pé kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ lati pa irọ́ kí wọ́n lè mú ènìyàn nínú irọ́, kí wọ́n lè pa á run.

26 Àti báyìí ni ó pọ́n wọn lé, ó sì sìn wọn títí ó fi wọ́ ọkàn wọn lọ sí ọ̀run àpáàdì; àti báyìí ni ó jẹ́ kí wọn ó mú ara wọn bọ́ sínú ìkẹ́kùn tí àwọn tìkara wọn dẹ.

27 Àti báyìí ni òun nlọ sí òkè àti sí ilẹ̀, síwá àti sẹ́hìn nínú ilé ayé, ní wíwá lati pa ọkàn àwọn ènìyàn run.

28 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, ègbé ni fún ẹnití ó parọ́ láti tan ni jẹ nítorí òun rò pé ẹlòmíràn ti parọ́ láti tan ni jẹ, nítorí a kì yíò dá irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí nínú ìdájọ́ Ọlọ́run.

29 Nísisìyí, kíyèsíi, wọ́n ti pààrọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorípé Sátánì wí fún wọn: Òun ti tàn ọ́ jẹ—àti pé báyìí ni ó pọ́n wọn sí ìṣìnà lati ṣe àìṣedéédé, láti jẹ́ kí ìwọ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.

30 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé ìwọ kì yíò tún túmọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì tí o ti jáde lọ kúrò ní ọwọ́ rẹ.

31 Nitori, kíyèsíi, wọn kì yíò ṣe àṣeyọrí awọn ète ibi wọn ní pípa irọ́ lòdì sí àwọn ọ̀rọ wọnnì. Nítorí, kíyèsíi, bí ìwọ bá le mú àwọn ọ̀rọ̀ kannáà jade, wọ́n yíò sọ pé ìwọ ti pa irọ́, àti pé ìwọ ti ṣe bíi ẹnipé o túmọ̀, ṣùgbọ́n pé o ti tako ara rẹ.

32 Àti, kíyèsíi, wọn yíò tẹ èyí jade, àti pé Sátánì yíò sé ọkàn àwọn ènìyàn le láti rú wọ́n sókè lati bínú lòdì sí ọ, kí wọn má baà gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́.

33 Báyìí ni Sátánì ronú láti fi agbára tẹ ẹ̀rí rẹ mọ́lẹ̀ ní ìran yìí, pé kí iṣẹ́ náà má baà lè jade wá ní ìran yìí.

34 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, ọgbọ́n nìyí, àti nítorí tí mo fi ọgbọ́n hàn ọ́, tí mo sì fún ọ ní àwọn òfin nípa àwọn nkan wọ̀nyí, ohun tí ìwọ yíò ṣe, má ṣe fi hàn sí ayé títí tí ìwọ yíò fi ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ ìtumọ̀ náà.

35 Kí ó má yà ọ lẹ́nu pé mo wí fún ọ: Ọgbọ́n nìyí, má ṣe fi hàn sí ayé—nítorí mo wí, má ṣe fi hàn sí ayé, kí á lè pa ọ́ mọ́.

36 Kíyèsíi, èmi kò sọ pé ìwọ kò ní fi hàn àwọn olódodo.

37 Ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbàtí ìwọ kò lè fi ìgbà gbogbo ṣe ìdájọ́ olódodo, tàbí níwọ̀n ìgbàtí ìwọ kò lè fi ìgbà gbogbo mọ ẹni búburú yàtọ̀ sí olódodo, nítorínáà mo wí fún ọ, pa ẹnu rẹ mọ́ títí tí èmi yíò fi ríi pé ó tọ́ láti sọ ohun gbogbo di mímọ̀ sí ayé nípa ohun náà.

38 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, pé àkọsílẹ̀ àwọn ohun wọnnì tí ìwọ ti kọ, èyítí o ti lọ kúrò ní ọwọ́ rẹ, wà ní fífín sí orí àwọn àwo ti Néfì;

39 Bẹ́ẹ̀ni, kí o sì rantí pé a ti sọ nínú àwọn ìwé kíkọ pé àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì kan ni a ti fi fúnni nípa àwọn ohun wọ̀nyí ní orí àwọn àwo Néfì.

40 Àti nísisìyí, nítori àkọsílẹ̀ èyí tí a fín sí orí àwọn àwo ti Néfì ṣe pàtàkì jùlọ nípa àwọn ohun tí, nínú ọgbọ́n mi, èmi yíó mú wá sí ìmọ̀ àwọn ènìyàn nínú àkọsílẹ̀ yìí—

41 Nítorínáà, ìwọ yíò tumọ̀ àwọn ìfín tí wọn wà ní orí àwọn àwo ti Néfì, sí ìsàlẹ̀ àní títí tí ìwọ yíò fi dé àkókò ìjọba ọba Bẹ́njámẹ́nì, tàbí títí ìwọ yíò fi dé ibi tí ìwọ túmọ̀ dé, àwọn èyí tí ìwọ ti dá dúró sí ọwọ́;

42 Àti kíyèsíi, ìwọ yíò tẹ̀ẹ́ jade gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti Néfì; àti báyìí èmi yíò dà àwọn wọnnì láàmú tí wọn yí àwọn ọ̀rọ̀ mi padà.

43 Èmi kì yíò fi ààyè sílẹ̀ pé kí wọn ba iṣẹ́ mi jẹ́; bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò fi hàn sí wọn pé ọgbọ́n ti èmi ga ju àrékérekè ti èṣù lọ.

44 Kíyèsíi, abala kan péré ni wọ́n ti gbà, tàbí akékúrú ti àkọsílẹ̀ ti Néfì.

45 Kíyèsíi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ni a fín sí orí àwọn àwo ti Néfì èyí tí ó fúnni ní òye títóbi jù ní orí ìhìnrere mi; nítorínáà, èyí jẹ́ ọgbọ́n nínú mi pé kí ìwọ ó túmọ̀ abala kìnní ti àwọn ìfín ti Néfì yìí, kí o sì rán jáde nínú iṣẹ́ yìí.

46 Àti, kíyèsíi, gbogbo ìyókù iṣẹ́ yìí ní gbogbo àwọn abala ìhìnrere mi nínú, èyí tí àwọn wòlíì mímọ́ mi; bẹ́ẹ̀ni, ati bákannáà àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, ti fẹ́ nínú àdúrà wọn pé kí wọ́n lè jáde wá sí àwọn ènìyàn wọ̀nyìí.

47 Àti pé mo wí fún wọn, pé a ó fi fún wọn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn àdúrà wọn;

48 Bẹ́ẹ̀ni, èyí sì ni ìgbàgbọ́ wọn—pé ìhìnrere mi, èyí tí mo fi fún wọn pé kí wọn lè máa wàásù rẹ̀ ní ọjọ́ ayé wọn, lè wá sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn àwọn ará Lámánì, àti bákannáà gbogbo àwọn tí wọn ti di ara Lámánì nípa ìyapa wọn.

49 Nísisìyí, èyí nìkan kọ́—ìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn àdúrà wọn ni pé kí ìhìnrere yìí lè di mímọ̀ bákannáà, bí ó bá jẹ́ pé ó ṣeéṣe pé kí àwọn orílẹ̀-èdè míràn ó ní ilẹ̀ yìí ní ìní;

50 Àti báyìí ni, wọ́n fi ìbùkún sílẹ̀ sí orí ilẹ̀ yìí nínú àwọn àdúrà wọn, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ìhìnrere yìí gbọ́ ní ilẹ̀ yìí lè ní ìyè ayérayé;

51 Bẹ́ẹ̀ni, pé kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́ sí gbogbo èyíkéyìí orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, tàbí ènìyàn tí wọ́n lè jẹ́.

52 Àti nísisìyí, kíyèsíi, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn nínú àdúrà wọn ni èmi yíò mú abala yìí ti ìhìnrere mi wá sí ìmọ̀ àwọn ènìyàn mi. Kíyèsíi, èmi kò mú un wá láti pa èyíinì run tí wọ́n ti gbà, ṣùgbọ́n láti gbé e ró.

53 Àti nítorí èyí ni èmi ti wí pé: Bí ìran yìí kò bá sé ọkàn wọn le, èmi yíò gbé ìjọ mi kalẹ̀ ní ààrin wọn.

54 Nísisìyí, èmi kò sọ èyí láti pa ìjọ mi run, ṣùgbọ́n mo sọ èyí láti gbé ìjọ mi ró;

55 Nítorínáà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ti ìjọ mi kí ó máṣe bẹ̀rù, nítorí irú wọn yíò jogún ìjọba ọ̀run.

56 Ṣùgbọ́n àwọn ẹnití kò bẹ̀rù mi, tàbí pa àwọn òfin mi mọ́ ṣùgbọ́n tí wọn kọ́ àwọn ìjọ fún ara wọn fún èrè jíjẹ, bẹ́ẹ̀ni, àti gbogbo àwọn wọnnì tí wọn nṣe búburú tí wọn ngbé ìjọba èṣù ró—bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé àwọn ni èmi yíò dí lọ́wọ́, èmi yíó mú kí wọn ó wárìrì àti pé wọn yíò sì gbọ̀n dé ààrin gbùngbùn.

57 Kíyèsíi, èmi ni Jésu Krísti ọmọ Ọlọ́run. Mo wá sí ọ̀dọ̀ àwọn tèmi, àwọn tèmi kò sì gbà mí.

58 Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó ntàn nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì mọ̀ ọ́.

59 Èmi ni ẹni náà tí ó sọ—Àwọn àgùntàn míràn ni emi ní tí wọn kìi ṣe ti agbo yìí—fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n wà tí ọ̀rọ̀ mi kò yé.

60 Àti pé èmi yíò fi hàn àwọn ènìyàn yìí pé mo ní àwọn àgùntàn míràn, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀ka ti ilé Jakọbù;

61 Àti pé èmi yíò mú un wá sí ìmọ́lẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu wọn, tí wọn ṣe ní orúkọ mi.

62 Bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò sì mú ìhìnrere mi wá sí ìmọ́lẹ̀ bákannáà, èyí tí a ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ fún wọn, àti, kíyèsíi, wọn kí yíò sẹ́ àwọn ohun náà èyítí o ti gbà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbé e ró, wọn yíò sì mú un wá sí ìmọ́lẹ̀ àwọn kókó òtítọ́ ẹ̀kọ́ mi, bẹ́ẹ̀ni, àti ẹ̀kọ́ kansoso tí ó wà nínú mi.

63 Àti pé èyí ni mo ṣe kí èmi ó lè gbé ìhìnrere mi kalẹ̀, kí á má baà rí ìjà púpọ̀, bẹ́ẹ̀ni, Sátánì máa nru ọkàn àwọn ènìyàn sókè sí ìjà nípa àwọn kókó ẹ̀kọ́ mi, àti nínú àwọn nkan wọ̀nyí wọn nṣe àṣìṣse, nítorí wọn nyí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run po, òye rẹ̀ kò sì yé wọn.

64 Nítorínáà, èmi yíò sọ ohun ìjìnlẹ̀ nlá yìí di mímọ̀ fún wọn.

65 Nítorí, kíyèsíi, èmi yíò kó wọn jọ bí àgbébọ̀ ti í ràdọ̀ bò àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, bí wọn kò bá sé ọkàn wọn le.

66 Bẹ́ẹ̀ni, bí wọn yíò bá wá, wọ́n lè wá, kí wọn o sì ṣe àbápín nínú omi ìyè ayérayé lọ́fẹ.

67 Kíyèsíi, èyí ni ẹ̀kọ́ mi—ẹnikẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà tí ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun kannáà ni ìjọ mi.

68 Ẹnikẹ́ni tí ó bá kéde púpọ̀ tàbí kéré jù èyí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kìí ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ alátakò sí mi, nítorínáà kìí ṣe ti ìjọ mi.

69 Àti Nísisìyí, kíyèsíi, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ti ìjọ mi, ati tí ó fi ara da ìjọ mi títí dé òpin, òun ni èmi yíò gbé kalẹ̀ ní orí àpáta mi, ọ̀run àpádì kì yíò sì lè dáa dúró.

70 Àti nísisìyí, rantí àwọn ọ̀rọ̀ ẹni náà tí íṣe ìyè àti ìmọ́lẹ̀ ayé, Olùràpadà rẹ, Olúwa rẹ àti Ọlọ́run rẹ. Amin.