Ìpín 121
Àdúrà àti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ láti ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith nínú àkanṣe ìwé kíkọ kan sí Ìjọ nígbàtí òun jẹ́ òndè nínú túbú ní Liberty, Missouri, ní ònkà ọjọ́ 20 Oṣù Kẹ́ta 1839. Wòlíì náà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alábárìn ti wà nínú túbú fún oṣù púpọ̀. Àwọn ẹ̀bẹ̀ wọn àti àwọn ìbéèrè wọn sí àwọn aláṣẹ ìjọba àti àwọn alákoso ètò ìdájọ́ ló ti kùnà láti fún wọn ní ìrànlọ́wọ́.
1–6, Wòlíì náà bẹ Olúwa fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí njìyà; 7–10, Olúwa sọ̀rọ̀ àlãfíà sí i; 11–17 Ìfibú ni gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n kígbé èké ti ìrékọjá sí àwọn ènìyàn Olúwa; 18–25, Wọn kì yíò ní ẹ̀tọ́ sí oyè àlùfáà a ó sì dá wọn lẹ́bi; 26–32, Àwọn ìfihàn ológo ni a ṣè ìlérí fún àwọn tí wọ́n forítì pẹ̀lú ìgboyà; 33–40, Ìdí tí a fi pe ọ̀pọ̀ tí a sì yan díẹ̀; 41–46, Oyè àlùfáà ni a níláti lò nínú ìṣòdodo nìkan.
1 Áà Ọlọ́run, níbo ni ìwọ wà? Níbo sì ni àgọ́ tí ó bo ibi ìpamọ́ rẹ wà?
2 Yíò ti pẹ́ tó tí ìwọ yíò dá ọwọ́ rẹ dúró, àti ojú rẹ, bẹ́ẹ̀ni ojú àìléèrí rẹ, yío kíyèsíi láti àwọn ọ̀run ayérayé, àwọn àìṣedéedé àwọn ènìyàn rẹ àti ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àti tí igbe wọ́n yíò wọ inú etí rẹ?
3 Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa, yíò ti pẹ́ tó tí wọn yíò fi jìyà àwọn àìṣedéédé wọ̀nyí àti àwọn ìnilára tí kò bá òfin mu, kí ọkàn rẹ tó yọ́ sí ọ̀dọ̀ wọn, àti kí inú rẹ tó yí pẹ̀lú ìyọ́nú sí ọ̀dọ̀ wọn?
4 Olúwa Ọlọ́run Alágbára Jùlọ, ẹlẹ́dàá ọ̀run, ilẹ̀ ayé, àti àwọn òkun, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn, àti ẹnití ndarí tí ó sì ní agbára ní orí èṣù, àti ìjọba dúdú ati òkùnkùn ti Ṣéòlì—na ọwọ́ rẹ jade; kí ojú rẹ kí ó wò; kí àgọ́ rẹ kí ó di kíká kúrò; kí ibi ìpamọ́ rẹ máṣe jẹ́ bíbò mọ́; kí etí rẹ kí ó gbọ́; kí ọkàn rẹ kí ó yọ́, àti kí inú rẹ kí o yí pẹ̀lú ìyọ́nú sí ọ̀dọ̀ wa.
5 Kí ìbínú rẹ ó rú sókè sí àwọn ọ̀tá wa; àti, ní ìbínú ọkàn rẹ, pẹ̀lú idà rẹ gbẹ̀san àwọn àìṣedéédé wọn sí wa.
6 Rántí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ tí njìyà, Ọlọ́run wa; àwọn iránṣẹ́ rẹ yíò sì yọ̀ nínú orúkọ rẹ títí láé.
7 Ọmọ mi, àlãfíà ni fún ọkàn rẹ; ìdààmú rẹ àti àwọn ìpọ́njú rẹ yíò wà, ṣùgbọ́n fún igbà díẹ̀;
8 Àti nígbànáà, bí ìwọ bá fi orí tì í dáradára, Ọlọ́run yíò gbé ọ ga lókè; ìwọ yíò ní ìṣẹ́gun ní orí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.
9 Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dúró pẹ̀lú rẹ, wọn yíò sì ṣe àyẹ́sí rẹ lẹ́ẹ̀kansíi pẹ̀lú ìfẹ́ àtọkànwá àti ọwọ́ ìbáṣọ̀rẹ́.
10 Ìwọ kò tĩ dàbíì Jobu síbẹ̀; àwọn ọ̀rẹ́ rẹ kò gbógun tì ọ́, tàbí fi ẹ̀sùn kàn ọ pẹ̀lú ìrékọjá, bí wọ́n ti ṣe sí Jóbu.
11 Àti àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn ọ́ pẹ̀lú ìrékọjá, ni ìrètí wọn yíó di bíbàjẹ́, àti àwọn àfojúsọ́nà wọn yíò yọ́ kúrò bí ìrì dídì ṣe í yọ́ níwájú ìtànsán ìmọ́lẹ̀ àsẹ̀sẹ̀yọ oòrùn;
12 Àti bákannáà pé Ọlọ́run ti fi ọwọ́ síi, ó sì ti fi èdídí dìí láti ṣe àyípadà àwọn àkókò àti àwọn ìgbà, àti láti fọ́ wọn ní ojú ẹ̀mi, pé kí wọ́n ó má lè ní òye àwọn iṣẹ́ yíyanilẹ́nu rẹ̀; kí ó lè dán wọn wò bákannáà àti kí ó mú wọn nínú àrékérekè wọn;
13 Bákannáà, nítorípé ọkàn wọ́n ti díbàjẹ́, àti àwọn ohun èyítí wọ́n fẹ́ láti mú wá sí orí àwọn ẹlòmíràn, tí wọ́n sì ní ìfẹ́ pé kí àwọn ẹlòmíràn jìyà rẹ̀, lè wá sí orí àwọn fúnra wọ̀n ní kíkún jùlọ;
14 Pé kí wọn ó le ní ìjákulẹ̀ bákannáà, àti kí ìrètí wọn ó lè di òfo;
15 Àti ní àwọn ọdún tí kò pọ̀ púpọ̀ sí àkókò yìí, pé a ó gbá àwọn àti irú ọmọ wọn kúrò ní abẹ́ ọ̀run, ni Ọlọ́run wí, pé ẹyọ kan nínú wọn kì yíò ṣẹ́kù lati dúro sí ẹ̀bá ògiri.
16 Ìfibú ni gbogbo àwọn wọnnì tí yíò gbé gìgísẹ̀ wọn sókè tako ẹni àmì òróró mi, ni Olúwa wí, tí wọ́n sì kígbe pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ nígbàtí wọn kò tíì dẹ́ṣẹ̀ níwájú mi, ni Olúwa wí, ṣugbọ́n tí wọ́n ti ṣe èyìínì tí ó tọ́ ní ojú mi, àti èyítí mo pàṣẹ fún wọn.
17 Ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí wọ́n nkígbe ìrékọjá nṣe é nítorípé wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ọmọ àìgbọràn fúnra wọ̀n.
18 Àti àwọn wọnnì tí wọ́n búra èké tako àwọn ìránṣẹ́ mi, kí wọ́n ó lè mú wọn sinú ìdè àti ikú—
19 Ègbé ni fún wọn; nítorípé wọ́n ti ṣẹ àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ mi a ó sì yà wọ́n kúrò lára àwọn ìlànà ilé èmi.
20 Agbọ̀n wọn kì yíò kún, àwọn ilé wọn àti àwọn àká wọn yíò ṣègbé, àti pé àwọn tìkalára wọn ni a ó fi ṣẹ̀sín nípasẹ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ti fi ẹ̀tàn yìn wọ́n.
21 Wọn kì yíò ní ẹ̀tọ́ sí oyè àlùfáà náà, tàbí ìrú ọmọ wọn lẹ́hìn wọn láti ìran dé ìran.
22 Ìbá sàn fún wọn kí á so ọlọ mọ́ ọrùn wọn, kí wọ́n ó sì rì sí inú ibú òkun.
23 Ègbé ni fún gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ni àwọn ènìyàn mi lára, àti tí wọ́n lé, àti tí wọ́n pa, àti tí wọ́n jẹ́rìí takò wọ́n, ni Olúwa àwọn Ọmọ Ogun wí; ìran àwọn ejò olóró kan kì yíò bọ́ lọ́wọ́ ìdálẹ́bi ti ọ̀run àpáàdì.
24 Kíyèsíi, ojú mi rí ó sì mọ gbogbo àwọn iṣẹ́ wọn, èmi sì ní ìdájọ́ kíákíá kan ní ìpamọ́ ní àkókò rẹ̀, fún gbogbo wọn;
25 Nítorí a yan àkókò kan fún olúkúlùkù ènìyàn, gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ yíò ti rí.
26 Ọlọ́run yíò fún yín ní ìmọ̀ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, nípa ẹ̀bún ti Ẹ̀mí Mímọ́ tí ẹnu kò lè sọ, èyítí a kò tĩì fihàn láti ìgbàtí àyé ti wà di ìsisìyí;
27 Èyítí àwọn bàbá nlá wa ti dúró dè pẹ̀lú àníyàn ìfojúsọ́nà láti jẹ́ fífihàn ní àwọn ìgbà tí ó kẹ́hìn, èyítí a tọ́ka ọkàn wọn sí nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì, bí ó ṣe wà ní ìpamọ́ fún ẹ̀kúrẹ́rẹ́ ògo wọn;
28 Ìgbà kan tí ó nbọ̀ nínú èyítí a kì yíò dá ohunkan dúró, bóyá Ọlọ́run kan ni ó wà tàbí ọlọ́run púpọ̀, wọn yíò di mímọ̀.
29 Gbogbo àwọn ìtẹ́ àti àwọn ìjọba, àwọn ilẹ̀ ọba àti àwọn agbára, ni a ó fihàn tí a ó sì fi sí orí gbogbo àwọn tí wọ́n bá forítì pẹ̀lú ìgboyà fún ìhinrere Jésù Krístì.
30 Àti bákannáà, bí àwọn ààlà bá wà tí a gbé kalẹ̀ sí àwọn ọ̀run tàbí sí àwọn òkun, tàbí sí ilẹ̀ gbígbẹ, tàbí sí oòrùn, òṣùpá, tàbí àwọn ìràwọ̀—
31 Gbogbo àkókò àwọn ìyípo wọn, gbogbo àwọn ọjọ́ yíyàn, àwọn oṣù, àti àwọn ọdún, àti gbogbo àwọn ọjọ́ ti àwọn ọjọ́ wọn, àwọn oṣù, àti àwọn ọdún, àti gbogbo àwọn ògo wọn, àwọn òfin, àti àwọn àkókò tí a ti gbé kalẹ̀, ni a ó fi hàn ní àwọn ọjọ́ ìṣẹ́ ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò—
32 Ní ìbámu sí èyíinì tí a yàn láàrin àjọ ìgbìmọ̀ ti Ọlọ́run Ayérayé ti gbogbo àwọn ọlọ́run míràn ṣaájú kí ayé yí tó wà, tí a níláti pamọ́ dé píparí àti òpin rẹ̀, nígbàtí olúkúlùkù ènìyàn yíò wọ inú àìlópin wíwà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti sí inú ìsinmi àìkú rẹ̀.
33 Yíò ti pẹ́ tó tí omi tí ó nṣàn ó wà pẹ̀lú èérí? Kínni agbára tí ó lè dá àwọn ọrun dúró? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ kí ènìyàn lè na apá kékeré aláìlágbára rẹ̀ láti dá odò Missouri dúró ní ọ̀nà rẹ̀ tí a ti pinnu, tàbí láti dá ipa sísàn rẹ̀ padà sí òkè, bí láti ṣe ìdíwọ́ fún Alágbára Jùlọ ní títú ìmọ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run sí órí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.
34 Kíyèsíi, ọ̀pọ̀ ni a pè, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn. Àti kíni ìdí rẹ̀ tí a kò fi yàn wọ́n?
35 Nítorípé wọ́n gbé ọkàn wọn lé àwọn ohun ti ayé yìí púpọ̀, wọ́n sì nlépa àwọn oríyìn ti àwọn ènìyàn, tí wọn kò sì kọ́ ẹ̀kọ́ kan yìí—
36 Pé àwọn ẹ̀tọ́ ti oyè àlùfáà ní àsopọ̀ àìlèpínyà pẹ̀lú àwọn agbára ti ọ̀run, àti pé àwọn agbára ti ọ̀run náà kò ṣe é darí tàbí dìmú bíkòṣe ní orí àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ òdodo.
37 Pé wọ́n lè jẹ́ fífi lé wa lórí, òtítọ́ ni; ṣùgbọ́n nígbàtí a bá dáwọ́lé láti bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀, tàbí láti ṣe ìtẹ́lọ́rùn fún ìgbéraga wa, fún ìlépa asán wa, tabí láti lo agbára ìdarí tàbí ìjọba tàbí ipá ní orí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn, ní èyíkéyìí òdiwọ̀n ti àìṣòdodo, kíyèsíi, àwọn ọ̀run yíò fà ara wọn sẹ́hìn; a mú Ẹ̀mí Olúwa banújẹ́; àti nígbàtí a bá mú un kúrò, Àmín sí oyè àlùfáà tàbí àṣẹ ti ọkùnrin náà.
38 Kíyèsíi, kí ó tó mọ̀, a ti fi í sílẹ̀ sí òun tìkalára rẹ̀, láti tàpá sí ẹ̀gún, láti ṣe ìnúnibíni sí àwọn ènìyàn mímọ́, àti láti jà lòdì sí Ọlọ́run.
39 Àwa ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìrírí tí ó bani nínújẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìwà ẹ̀dá àti ìfẹ́ inú ti gbogbo ènìyàn, ní kété tí wọ́n bá gba àṣẹ kékeré kan, bí wọ́n ṣe rò, wọn yíò bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti lo agbára àìṣòdodo.
40 Nítorínáà ọ̀pọ̀ ni a pè, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.
41 Kò sí agbára tàbí ipá tí a lè, tàbí tí ó yẹ kí á dìmú nípa àsẹ oyè àlùfáà, bíkòṣe nípa ìyínilọ́kàn-padà, nípa ìpamọ́ra, nípa ìrẹ̀lẹ̀ àti ọkàn pẹ̀lẹ́, àti nípa ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn nìkan;
42 Nípasẹ̀ inú-rere, àti ìmọ̀ tí kò ní èérí, èyítí yíò mú kí ọkàn gbòòrò lọ́pọ̀lọpọ̀ láìsí àgàbàgebè, àti láìsí ẹ̀tàn—
43 Bíbáwí ní àkókò pẹ̀lú ìyára, nígbàtí a bá ní ìmísí nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́; àti nígbànáà fífi àlékún ìfẹ́ hàn jade lẹ́hìnwá sí ẹni náà tí ìwọ báwí, bí bẹ́ẹ̀kọ́ òun á kà ọ́ sí ọ̀tá rẹ̀;
44 Kí òun lè mọ̀ pé ìsòtítọ́ tìrẹ ní agbára ju àwọn okùn ikú lọ.
45 Kí inú rẹ pẹ̀lú kún fún ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ sí ìhà ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn, àti sí ará ilé ìgbàgbọ́, kí ìwa ọ̀run ó sì ṣe èrò ọkàn rẹ lọ́ṣọ̀ọ́ láì dáwọ́ dúró; nígbànáà ni ìfi ọkàn tán rẹ yíò ní agbára síi ní ọdọ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀kọ́ ti oyè àlùfáà yíò sàn térétéré sí orí ọkàn rẹ bí àwọn ìrì láti ọ̀run.
46 Ẹ̀mí Mímọ́ yíò jẹ́ alábàárìn rẹ ní gbogbo ìgbà, àti pé ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pa àṣẹ tí kìí yípadà ti ìṣòdodo àti òtítọ́; àti ìjọba rẹ yíò jẹ́ ìjọba àìlópin, àti láìsí ọ̀nà tipátipá yíò sàn sí ọ̀dọ̀ rẹ láé àti títí láéláé.