Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 122


Ìpín 122

Ọ̀rọ̀ Olúwa sí Wòlíì Joseph Smith, nígbàtí ó jẹ́ òndè nínú túbú ní Liberty, Missouri. Ìpín yìí jẹ́ àyọjáde nínú àkànṣe ìwé kíkọ kan sí Ìjọ tí ó ní ònkà ọjọ́ 20 Oṣù Kejì 1839 (wo àkọlé sí ìpín 121).

1–4, Awọn òpin ilẹ̀ ayé yíò béèrè nípa orúkọ Joseph Smith; 5–7, Gbogbo àwọn ewu àti àwọn ìjìyà rẹ̀ yíò fún un ní ìrírí yíó sì jẹ́ fún ire rẹ̀; 8–9, Ọmọ Ènìyàn ti sọ̀kalẹ̀ sí ìsàlẹ̀ wọn gbogbo.

1 Àwọn òpin ilẹ̀ ayé yíò béèrè nípa orúkọ rẹ, àwọn aṣiwèrè yíò sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà, ọ̀run àpáàdì yíò sì bínú takò ọ́;

2 Nígbàtí àwọn ọlọ́kàn mímọ́, àti ọlọ́gbọ́n, àti àwọn ọlọ́lá, àti oníwà rere, yíò wá ìmọ̀ràn, àti àṣẹ, àti àwọn ìbùkún ní gbogbo ìgbà láti abẹ́ ọwọ́ rẹ.

3 Àwọn ènìyàn rẹ kì yíò sì yípadà takò ọ́ nípa ẹ̀rí ti àwọn ọ̀dàlẹ̀.

4 Àti bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipá wọn yíò kó ọ sínú ìyọnu, àti sínú àtìmọ́lé àti àhámọ́, ìwọ yíò jẹ́ bíbu ọlá fún; àti ṣùgbọ́n fún àkókò kékeré kan ohùn rẹ yíò sì ní ẹ̀rù síi láàrin àwọn ọ̀tá rẹ ju ti kìniún búburú, nítorí òdodo rẹ; Ọlọ́run rẹ yíò sì dúró tì ọ́ láé àti títí láéláé.

5 Bí a bá pè ọ́ láti kọjá nínú ìpọ́njú; bí ìwọ bá wà nínú àwọn ewu láàrin àwọn aláìṣòótọ́ arákùrin; bí ìwọ bá wà nínú àwọn ewu láàrin àwọn ọlọ́ṣà; bí ìwọ bá wà nínú àwọn ewu ní orí ilẹ̀ tàbí ní orí òkun;

6 Bí a bá fi ẹ̀sùn kàn ọ́ pẹ̀lú oríṣiríṣi àwọn ẹ̀sùn ti wọn kìí ṣe òtítọ́; bí àwọn ọ̀tá rẹ bá kọlù ọ́; bí wọ́n bá ya ọ́ kúrò nínú ìbákẹ́gbẹ́ ti bàbá àti ìyá àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin rẹ; àti pẹ̀lú fífa idà yọ bí àwọn ọ̀tá rẹ bá fà ọ́ ya kúrò ni oókan àyà ìyàwó rẹ, àti ti àwọn omo bíbí inú rẹ, àti ọmọkùnrin rẹ àgbà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ bíi ẹni ọdún mẹ́fà, bí ó rọ̀ mọ́ aṣọ rẹ, tí ó sì wí pé, Bàbá mi, bàbá mi, kíní ṣe tí ìwọ kò lè dúró tì wá? Bàbá mi, kíni àwọn ènìyàn náà fẹ́ ṣe pẹ̀lú rẹ? àti nígbànáà bí wọn bá tìí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ nípa idà, tí wọ́n sì wọ́ ìwọ sí túbú, àti tí àwọn ọ̀tá rẹ rìn kiri yí ọ ká bí àwọn ìkookò fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùtàn náà;

7 Àti bí wọ́n bá jù ọ́ sínú kòtò náà, tàbí sí ọwọ́ àwọn apànìyàn, àti tí wọ́n ṣe ìdájọ́ ikú fún ọ; bí a bá jù ọ́ sínú ibú; bí ríru omi òkun bá dìtẹ̀ takò ọ́; bí ẹ̀fúùfù líle di ọ̀tá rẹ; bí àwọn ọ̀run bá ṣú dúdú, àti tí gbogbo àwọn ohun ìpilẹ̀sẹ̀ parapọ̀ láti dí ọ̀nà; àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, bí àgbọ̀n ọ̀run àpáàdì tilẹ̀ rọ̀ sílẹ̀ lati la ẹnu rẹ̀ gbòòrò nítorí rẹ, ìwọ mọ̀, ọmọ mi, pé gbogbo àwọn ohun wọ̀nyìí yíò fún ọ ní ìrírí, yíò sì jẹ́ fún ire rẹ.

8 Ọmọ Ènìyàn ti sọ̀kalẹ̀ sí ìsàlẹ̀ wọn gbogbo. Ìwọ ha tóbi ju òun lọ bí?

9 Nítorínáà, dúró ní ojú ọ̀nà rẹ, oyè àlùfáà náà yíò sì wà pẹ̀lú rẹ; nítorí ààlà wọn wà ní lílà sílẹ̀, wọn kì yíò le tayọ rẹ̀. Àwọn ọjọ́ rẹ ni a mọ̀, àti àwọn ọdún rẹ ni a kì yíò kà dínkù; nítorínáà, má bẹ̀rù ohun tí ènìyàn lè ṣe, nítorí Ọlọ́run yíò wà pẹ́lú rẹ láé ati títí láéláé.