Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 123


Ìpín 123

Ojúṣe àwọn Ènìyàn Mímọ́ nípa ti àwọn onínúnibíni wọn, bí a ṣe kọọ́ láti ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith nígbàtí òun jẹ́ òndè nínú túbú ní Liberty, Missouri. Ìpín yìí jẹ́ àyọjáde nínú àkànṣe ìwé kíkọ kan sí Ìjọ tí ó ní ònkà ọjọ́ 20 Oṣù Kejì 1839 (wo àkọlé sí ìpín 121).

1–6, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ nílati ṣe àkójọ àti àtẹ̀jáde àwọn ìjìyà àti àwọn inúnibíni wọn; 7–10, Ẹ̀mí kan náà tí ó ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ èké náà ni ó darí sí ṣíṣe inúnibíni ti àwọn Ènìyàn Mímọ́; 11–17, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ láàrin gbogbo àwọn ẹ̀yà ni wọn yíò sì gba òtítọ́ náà síbẹ̀.

1 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, àwa dáa lábàá fún àgbéyẹ̀wò yín bí ó ti ṣe déédé sí kí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ ó kó ìmọ̀ jọ nípa gbogbo àwọn ohun tí ó jẹ́ òtítọ́, àti àwọn ìjìyà àti àwọn ìpalára tí a gbé lé wọn ní orí lati ọwọ́ àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ yìí;

2 Àti bákannáà ti gbogbo ohun ìní àti iye àwọn ìbàjẹ́ èyítí wọ́n ti là kọjá, ní ti ìwà àti ní ti ìfarapa ti ẹnìkọ̀ọ̀kan, àti pẹ̀lú ti ohun ìní gidi;

3 Àti bákannáà àwọn orúkọ ti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n ti lọ́wọ́ nínú àwọn ìjìyà wọn, bí ó ti ṣeéṣe tó láti mú wọn àti láti wá wọn jade.

4 Àti bóyá ìgbìmọ̀ kan le jẹ́ yíyàn láti wá àwọn ohun wọ̀nyìí jade, àti láti gbà ọ̀rọ̀ ẹnu àti àwọn ìbúra; àti bákannáà láti ṣe àkójọ àwọn àtẹ̀jáde ìbanilórúkọjẹ́ tí wọn wà káàkiri òde;

5 Àti gbogbo èyí tí ó wà nínú àwọn ìwé ìròhìn náà, àti nínú àwọn ìwé ti gbogbo ìmọ̀, àti gbogbo àwọn ìtàn ìbanilórúkọjẹ́ tí wọ́n ti jẹ́ títẹ̀ jade, àti tí a ti kọ, àti lati ọwọ́ ẹnití ó kọ ọ́, àti kí á sì ṣe àgbékalẹ̀ gbogbo oríṣiríṣi ibi àti òṣónú àti ìwà ìpànìyàn èyítí wọ́n ti fi ipá ṣe ní orí àwọn ènìyàn yìí—

6 Kí àwa ó má lè tẹ̀ ẹ́ jade nìkan sí gbogbo ayé, ṣùgbọ́n gbé wọn kalẹ̀ sí àwọn olórí ìjọba ní gbogbo ìbi okùnkùn ati onírũrú ìwà búburú wọn, bí ìyànjú tí ó gbẹ̀hìn èyítí Bàbá wa Ọ̀run kìlọ̀ rẹ̀ fún wa, ṣaájú kí á tó lè béèrè ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àti ní pátápátá ìlérí náà èyítí yìò pe òun jade láti ibi ìsápamọ́ sí rẹ̀; àti pẹ̀lú pé kí odidi orílẹ̀-èdè le wà láìsí àwáwí síwájú kí òun tó lè rán agbára ti ọwọ́ alágbára rẹ̀ jade.

7 Ó jẹ́ ojúṣe pàtàkì kan tí a jẹ gbèsè rẹ̀ sí Ọlọ́run, sí àwọn ángẹ́lì, pẹ̀lú ẹnití a ó múwa wá sí ìdúró, àti bákannáà sí àwa tìkarawa, sí àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ wa, ẹnití a ti mú kí wọ́n tẹ orí wọn ba pẹ̀lú ìbànújẹ́, ìrora ọkàn, àti ìtọ́jú, lábẹ́ ọwọ́ ìdánilẹ́bi ti ìpànìyàn, ìwà ipá, àti ìninilára, pẹ̀lú àtìlẹhìn àti ìgbàníyànjú láti tẹ̀síwájú àti gbígbésókè nípa agbára ẹ̀mí èyíinì tí ó ti wọ inú awọn ìjẹ́wọ́ ti àwọn bàbá pẹ̀lú ipá líle tó bẹ́ẹ̀, ẹnití ó ti jogún àwọn èké, ní orí ọkàn ti àwọn ọmọ, tí ó sì kún inú ayé pẹ̀lú ìdàrúdàpọ̀, àti tí ó ti ndàgbà ní agbára àti ní agbára síi, àti nísisìyí ó jẹ́ orísun gãn ti agbára gbogbo ìwà búburú, gbogbo ayé sì nkérora lábẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àìṣedéédé rẹ̀.

8 Àjàgà onírin ni í ṣe, ìdè tí ó ní agbára ni; wọ́n jẹ́ panpẹ́ náà gan an, àti àwọn ẹ̀wọ̀n, àti àwọn ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀, àti àwọn ẹ̀wọ̀n ti ọ̀run àpáàdì.

9 Nítorínáà ó jẹ́ ojúṣe tí ó ṣe pàtàkì tí a jẹ gbèsè rẹ̀, kìí ṣe sí àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa nìkan, ṣùgbọ́n sí àwọn opó àti aláìníbaba, ẹnití awọn ọkọ ati bàbá wọn ti jẹ́ pípa lábẹ́ ọwọ́ irin rẹ̀;

10 Àwọn iwà búburú àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ èyítí ó tó fún ọ̀run àpãdì fúnrarẹ̀ láti wárìrì, àti láti dúró pẹ̀lú ìpayà àti àìlókun, àti kí ọwọ́ ti èṣù gan an kí ó gbọ̀n kí ó sì wà láìlèdúró.

11 Àti pẹ̀lú pé ó jẹ́ ojúṣe tí ó ṣe pàtàkì tí a jẹ gbèsè rẹ̀ sí gbogbo ìran tí ndìde, àti sí gbogbo àwọn ọlọ́kàn mímọ́—

12 Nítorí àwọn púpọ̀ ni ó wà síbẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé láàrin gbogbo àwọn ìyapa ẹ̀sìn, àwọn ẹgbẹ́, àti àwọn ìjọ, tí a ti fọ́ ojú wọn nípa ewu àrékérekè àwọn ènìyàn, nípa èyítí wọ́n lúgọ láti tanni jẹ, àti àwọn ẹnití ó pamọ́ kúrò nínú òtítọ́ nítorípé wọn kò mọ ibití wọn yíò ti rí i—

13 Nítorínáà, pé a níláti fi ayé wa ṣòfò kí á sì lò ó gbó ní mímú gbogbo àwọn ohun ti òkùnkùn tí ó farasin wá sí ìmọ́lẹ̀, bí a tí mọ̀ wọ́n tó; àti bí a ti sọ wọ́n di mímọ̀ lõtọ́ láti ọ̀run—

14 Ìwọ̀nyìí ni a níláti fiyèsí pẹ̀lú ìtara nlá nígbànáà.

15 Kí ẹnikẹ́ni máṣe kà wọ́n sí àwọn ohun kékeré; nítorí ohun púpọ̀ ni ó wà ní ọjọ́ iwájú, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, èyítí ó gbáralé àwọn nkan wọ̀nyìí.

16 Ẹ̀yin mọ̀, ẹ̀yin arákùnrin, pé ọkọ̀ ojú omi nla nrí ànfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ ìtọ́kọ̀ kékeré kan ní àkókò ìjì líle, nípa mímú u dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú afẹ́fẹ́ àti àwọn ìgbì omi.

17 Nítorínáà, ẹ̀yin arákùnrin wa ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí á ṣe ohun gbogbo tí ó wà ní agbára wa pẹ̀lú ọ̀yàyà; àti nígbànáà ni a ó lè dúró jẹ́ẹ́, pẹ̀lú ìdánilójú tí ó ga jùlọ, láti rí ìgbàlà Ọlọ́run, àti fún ọwọ́ agbára rẹ̀ lati di fífi hàn.