Ìpín 130
Àwọn ohun èlò ìtọ́sọ́nà tí a fifúnni lati ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith ní Ramus, Illinois, 2 Oṣù Kẹrin 1843.
1–3, Bàbá àti Ọmọ lè fi ara hàn sí àwọn ènìyàn fúnra ara wọn; 4–7, Àwọn ángẹ́lì ngbé ní àyíká Sẹ̀lẹ́stíà kan; 8–9, Ilẹ̀ ayé sẹ̀lẹ́stíà yíò jẹ́ Úrímù àti Túmímù nla kan; 10–11, Òkúta funfun kan ni a fún gbogbo àwọn tí wọ́n wọlé sí ayé sẹ̀lẹ́stíà; 12–17, Àkókò ti Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ní a kò fún àwọn wòlíì; 18–19, Ẹ̀mí òye tí a bá jèrè ní ayé yìí ndìde pẹ̀lú wa ní Ajínde; 20–21, Gbogbo àwọn ìbùkún nwá nípasẹ̀ ìgbọ́ràn sí òfin; 22–23, Bàbá àti Ọmọ ní àgọ́ ara ti ẹran àti àwọn egungun.
1 Nígbàtí Olùgbàlà bá fi ara hàn, àwa yíò rí i bí òun ti rí. Àwa yíò ríi pé òun jẹ́ ènìyàn bíi àwa fúnrawa.
2 Àti pé irú ìbáraẹni kẹ́gbẹ́ tí ó wà ní ààrin wà níhĩn yíò wà ní ààrin wà lọ́hũn, kìkì pé yíò ní ìṣopọ̀ pẹ́lú ògo ayérayé, ògo èyítí a kò jẹ̀ ìgbádùn rẹ̀ nísisìyí.
3 Jòhánnù 14:23—Ìfarahàn ti Bàbá àti Ọmọ, nínú ẹsẹ yìí, jẹ́ ìfarahàn ti ara ẹni; àti pé èrò inú pé Bàbá àti Ọmọ ngbé ínú ọkàn ènìyàn jẹ́ ògbólógbòó èrò inú kan ní ààrin àwọn ẹlẹ́sìn kan, kìí sìí ṣe òtítọ́.
4 Ní ìdáhùn sí ìbéèrè pé—Ṣé kìí ṣe ìṣirò ti àkókò Ọlọ́run, àkókò ti ángẹ́lì, àkókò ti wòlíì, àti àkókò ti ènìyàn, ní ìbámu sí ohun tí ó nyípo oòrùn nínú èyítí wọn ngbé?
5 Mo dáhùn, Bẹ́ẹ̀ni. Ṣùgbọ́n kò sí àwọn ángẹ́lì tí ó njíṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ilẹ̀ ayé yìí ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí í ṣe ara rẹ̀ tàbí tí wọ́n ti jẹ́ ara rẹ̀ rí.
6 Àwọn ángẹ́lì kìí gbé ní orí ohun kan tí ó nyípo oòrùn bíi ilẹ̀ ayé yìí;
7 Ṣùgbọ́n wọ́n ngbé ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ní orí ìṣù kan bíi òkun ti dígí àti iná, níbití ohun gbogbo fún ògo wọn ti fi ara hàn, ti ìkọjá, ti ìsisìyí, àti tí ó nbọ̀, wọ́n sì wà títílọ níwájú Olúwa.
8 Ibi náà tí Ọlọ́run ngbé jẹ́ Úrímù àti Túmímù nlá kan.
9 Ilẹ̀ ayé yìí, nínú ipò yíyàsímímọ́ àti àìkú rẹ̀, ni a ó ṣe bíi Krístálì yíò sì jẹ́ Úrímù àti Túmímù kan sí àwọn olùgbé tí wọ́n ngbé níbẹ̀, nínú èyítí gbogbo àwọn ohun tí wọ́n jẹmọ́ ti ìjọba ayédèrú, tàbí gbogbo àwọn ìjọ̀ba tí wọn wà ní ipò kékeré jù, ni a ó fihàn sí àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ̀dó sí orí rẹ̀; ilẹ̀ ayé yìí yíò sì jẹ́ ti Krístì.
10 Nígbànáà ni òkúta funfun náà tí a dárúkọ nínú Ìwé Ìfihàn 2:17, yíò di Úrímù àti Túmímù kan sí olúkúlùkù ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó gba ọ̀kan, nípa èyí tí a ó sọ àwọn ohun tí ó jẹmọ́ ètò gíga ti àwọn ìjọba di mímọ̀;
11 A sì fi òkúta funfun kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan àwọn wọnnì tí wọ́n wá sí inú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, ní orí èyítí a kọ orúkọ titun kan, èyítí ẹnìkan kò mọ̀ bíkòṣe ẹni náà tí ó gbà á. Orúkọ titun náà ni kọ́kọ́rọ́ ọ̀rọ̀.
12 Èmi sọtẹ́lẹ̀, ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run, pé ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ìsòro náà èyítí yíò mú ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀ wá síwájú bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn yíò jẹ́ ní Gúúsù Carolina.
13 Ó lè dìde bọ́yá nípasẹ̀ ìbéèrè sí òwò ẹrú. Èyí ni ohùn kan kéde sí mi, nígbàtí mo ngbàdúrà kíkan-kíkan ní orí àkòrí náà, 25 Oṣù Kejìlá, 1832.
14 Èmi ngbàdúrà kíkan-kíkan nígbàkan láti mọ àkókò ti bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn, nígbàti mo gbọ́ ohùn kan tí ó ṣe àtúnwí ìwọ̀yìí:
15 Joseph, ọmọ mi, bí ìwọ bá sì wà láàyè títí ìwọ̀ fi pé ọdún márùn-dín-laàdọ́rùn, ìwọ yíò rí ìwò ojú Ọmọ Ènìyàn; nítorínáà jẹ́ kí èyí kí ó tó fún ọ, kí o má sì ṣe yọmí lẹ́nu mọ́ ní orí ọ̀rọ̀ yí.
16 A fi mí sílẹ̀ báyìí, láìní agbára láti pinnu bọ́yá bíbọ̀ yìí tọ́ka sí ìbẹ̀rẹ̀ ti ẹgbẹ̀rún ọdún náà tàbí sí àwọn ìfarahàn ti àtẹ̀hìnwá, tàbí bóyá kí èmi ó kú àti nípa bẹ́ẹ̀ kí n rí ìwò ojú rẹ̀.
17 Èmi gbàgbọ́ pé bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn kì yíò jẹ́ sísúnmọ́ rárá ju àkókò náà lọ.
18 Èyíkéyìí ìpele tí a bá jèré ẹ̀mí òye níní dé nínú ayé yìí, yíó dìde pẹ̀lú wa ní àjínde.
19 Bí ẹnìkan bá sì jèrè ìmọ̀ àti ẹ̀mí òye púpọ̀ síi nínú ayé yìí nípasẹ̀ aápọn àti ìgbọràn rẹ̀ ju ẹlòmíràn lọ, òun yíò ní ànfàní púpọ̀ bẹ́ẹ̀ náà ní ayé tí ó nbọ̀.
20 Òfin kan wà, tí a ti pàṣẹ láìlèyípadà ní ọ̀run ṣaájú àwọn ìpìlẹ̀sẹ̀ ayé yìí, ní orí èyítí gbogbo àwọn ìbùkún dá lé—
21 Nígbàtí a bá sì gba èyíkéyìí ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó jẹ́ nípa ìgbọ́ràn sí òfin náà ní orí èyí ti ó dá lé.
22 Bàbá ní àgọ́ ara ti ẹran ara àti àwọn egungun tí ó ṣe é fi ọwọ́ kàn bíi ti ènìyàn; Ọmọ bákannáà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní àgọ́ ara ti ẹran ara àti àwọn egungun, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìrí ènìyàn ti Ẹ̀mí. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ kì yíò lè gbé nínú wa.
23 Ènìyàn lè gba Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì lè sọ̀kalẹ̀ lé e ní orí kí ó má sì dúró pẹ̀lú rẹ̀.