Ìpín 133
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, 3 Oṣù Kọkànlá 1831. Nínú ọ̀rọ̀ ìsaájú rẹ̀ sí ìfihàn yìí, ìtàn Joseph Smith sọ pé, “Ní àkókò yìí ọ̀pọ̀ ohun ni ó wà tí àwọn Alagbà nfẹ́ láti mọ̀ nípa wíwàásù Ìhìnrere sí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, àti nípa kíkójọpọ̀ náà; àti ní ètò láti rìn nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ òtítọ́, kí a sì jẹ́ kíkọ́ láti òkè wá, ní ọjọ́ kẹta oṣù Kọkànlá, 1831, mo béèrè lọ́wọ́ Olúwa mo sì gba ìfihàn pàtàkì tí ó tẹ̀lé náà.” Ìpín yìí ni a kọ́kọ́ fi kún ìwé Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú bíi àfikún kan àti ní àsẹ̀hìnwá a yan ònkà ìpín kan fún un.
1–6, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni a pàṣẹ fún láti gbáradì fún Bíbọ̀ Èẹ̀kejì; 7–16, Gbogbo ènìyàn ni a pàṣẹ fún láti sá kúrò ní Bábílónì, láti wá sí Síónì, àti láti gbáradì fún ọjọ́ nlá Olúwa; 17–35, Òun yíò dúró ní orí Òkè Síónì, àwọn ìpín orílẹ̀ ayé yíò di ilẹ̀ kan, àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì tí wọ́n ti sọnù yíò sì padà; 36–40, Ìhìnrere ni a múpadàbọ̀ sípò nípasẹ̀ Joseph Smith láti wàásù rẹ̀ ní gbogbo ayé; 41–51, Olúwa yíò sọ̀kalẹ̀ wá ní gbígbẹ̀san ní orí àwọn ènìyàn búburú; 52–56, Yíò jẹ́ ọdún ti àwọn ẹni ìràpadà Rẹ̀; 57–74, Ìhìnrere ni a ó rán jade lọ láti gba àwọn Ènìyàn Mímọ́ là àti fún ìparun àwọn ènìyàn búburú.
1 Ẹ fetísílẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn ìjọ mi, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa nípa yín—
2 Olúwa ẹnití yíò wá lójijì sí inú tẹ́mpìlì rẹ̀; Olúwa ẹnití yíò sọ̀kalẹ̀ wá sí orí ayé pẹ̀lú ègún kan fún ìdájọ́; bẹ́ẹ̀ni, sí orí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, àti sí orí gbogbo aláìwà bí Ọlọ́run ní àrin yín.
3 Nítorí òun yíò fi apá mímọ́ rẹ̀ hàn ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, àti gbogbo àwọn òpin ilẹ̀ ayé yíò rí ìgbàlà Ọlọ́run wọn.
4 Nítorí èyí, ẹ gbáradì, ẹ gbaradì, ẹ̀yin ènìyàn mi; ẹ ya ara yín sí mímọ́; ẹ kó ara yín jọ, ẹ̀yin ènìyàn ìjọ mi, ní orí ilẹ̀ Síónì, gbogbo ẹ̀yin tí a kò tíì pàṣẹ fún láti dúró.
5 Ẹ jade kúrò ní Bábílónì. Ẹ jẹ́ aláìlẽrí ẹ̀yin tí ó ngbé ohun èlò Olúwa.
6 Ẹ pe àpéjọ yín tí ó ní ọ̀wọ̀, kí ẹ sì bá ara yín sọ̀rọ̀ nígbà-kúùgbà. Ẹ sì jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó ké pe orúkọ Olúwa.
7 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́ ni mo wí fún yín lẹ́ẹ̀kansíi, àkókò náà ti dé nígbàtí ohùn Olúwa jẹ́ síi yín: Ẹ jade kúrò ní Bábílónì; ẹ kó ara yín jọ jade kúrò ní àrin àwọn orílẹ̀ ède, láti ibi mẹ́rẹ̀rin afẹ́fẹ́, láti òpin kan ti ọ̀run sí òmíràn.
8 Ẹ rán àwọn alàgbà ìjọ mi jáde sí àwọn orílẹ̀-èdè èyítí ó wà ní ọ̀nà jíjìn; sí àwọn erékùsù òkun; ẹ ránṣẹ́ jade sí àwọn ilẹ̀ òkèrè; ẹ ké pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ní àkọ́kọ́ sí àwọn Kèfèrí, àti nígbànáà sí àwọn Júù.
9 Ẹ sì kíyèsíi, ẹ sì wòó, èyí ni yíò jẹ́ igbe wọn, àti ohùn Olúwa sí gbogbo ènìyàn: Ẹ jade lọ sí ilẹ̀ Síónì, kí àwọn ààlà ti àwọn ènìyàn mi kí ó lè tóbi síi, àti kí a le fún àwọn èèkàn rẹ̀ ní okun, àti kí Síónì ó lè jade lọ sí àwọn agbègbè yíká kiri.
10 Bẹ́ẹ̀ni, jẹ́kí igbe náà kí ó jade lọ láàrin gbogbo ènìyàn: Ẹ jí ẹ sì dìde kí ẹ sì jade lọ láti pàdé Ọkọ ìyàwó; ẹ kíyèsíi ẹ sì wòó, Ọkọ ìyàwó dé tán; ẹ jade sí ìta láti pàdé rẹ̀. Ẹ gbáradì fún ọjọ́ nlá Olúwa.
11 Ẹ máa ṣọ́nà, nítorínáà, nítorí ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.
12 Ẹ jẹ́kí àwọn, nítorínáà, ẹnití ó wà láàrin àwọn Kèfèrí ó sá lọ sí Síónì.
13 Ẹ sì jẹ́kí àwọn ẹnití ó jẹ́ ti Júdah ó sá lọ sí Jérúsálẹ́mù, sí àwọn òkè ti ilé Olúwa.
14 Ẹ jade lọ kúrò ní àrin àwọn orílẹ̀-èdè, àní kúrò ní Bábílónì, kúrò ní àrin ìwà búburú, èyítí í ṣe Bábílónì ti ẹ̀mí.
15 Ṣùgbọ́n lõtọ́, báyìí ní Olúwa wí, máṣe jẹ́ kí sísá kúrò yín kí ó jẹ́ ní ìkánjú, ṣùgbọ́n jẹ́kí ohun gbogbo jẹ́ pípèsè níwájú yín; ẹnití ó bá sì lọ, kí òun kí ó máṣe bojúwẹ̀hìn bíbẹ́ẹ̀kọ́ ìparun òjijì ni yíò wá sí orí rẹ̀.
16 Ẹ fetísílẹ̀ kí ẹ sì gbọ́, ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ ayé. Ẹ tẹ́tísílẹ̀, ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi lápapọ̀, kí ẹ sì gbọ́ ohùn Olúwa; nítorí òun pe gbogbo ènìyàn, òun sì pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà.
17 Nítorí kíyèsíi, Olúwa Ọlọ́run ti rán ángẹ́lì jade tí nkígbe ní àárin agbedeméjì ọ̀run, ní wíwí pé: Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ sì ṣe àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́, nítorí wákàtí bíbọ̀ rẹ̀ súnmọ́—
18 Nígbàtí Ọ̀dọ́-Àgùtàn náà yíò dúró ní orí Òkè Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí wọ́n ní orúkọ Bàbá rẹ̀ ní kíkọ sí iwájú orí wọn.
19 Nítorínáà, ẹ gbáradì fún bíbọ̀ Ọkọ ìyàwó náà; ẹ lọ, ẹ jáde lọ láti pàdé rẹ̀.
20 Nítorí kíyèsíi, òun yíò dúró ní orí òkè Ólífẹ́tì, àti ní orí òkun nlá, àní ibú nlá náà, àti ní orí àwọn erékùsù òkun, àti ní orí ilẹ̀ Síónì.
21 Òun yíò sì fọ ohùn rẹ̀ jade láti Síónì wá, òun yíò sì sọ̀rọ̀ láti Jérúsálẹ́mù, ohùn rẹ̀ ni a ó sì gbọ́ ní àrin gbogbo ènìyàn;
22 Yíò sì jẹ́ ohùn kan bíi ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn omi, àti bíi ohùn ààrá nlá, èyítí yíò wó àwọn òkè lulẹ̀, àwọn àfonífojì ni a kì yíò sì rí mọ́.
23 Òun yíò pàṣẹ fún ibú nlá náà, a ó sì darí rẹ̀ padà sí inú àwọn orílẹ̀-èdè àríwá, àwọn erèkùsù ni wọn yíò sì di ilẹ̀ kan;
24 Àti ilẹ̀ Jérúsálẹ́mù àti ilẹ̀ Síónì ni yíó di yíyípadà sẹ́hìn sí ààyè tiwọn, ilẹ̀ ayé yíò sì rí bí ó ṣe wà ní àwọn ọjọ́ saájú kí ó tó di pípín.
25 Àti Olúwa, àní Olùgbàlà, yíò dúró láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀, yíò sì jọba ní orí gbogbo ẹran ara.
26 Àti àwọn ẹnití wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè àríwá yíò wá ní ìrántí níwájú Olúwa; àwọn wòlíì wọn yíò sì gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn kì yíò dá ara wọn dúró; wọn yíò sì lu àwọn àpáta, omi dídì yíò sì ṣàn wá sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wọn.
27 Òpópó ọ̀nà nlá kan ni yíó sì di kíkọ́ sókè láàrin ibú nlá.
28 Àwọn ọ̀tá wọn yíò sì di ìgbèkún ní abẹ́ agbára wọn,
29 Àti nínú àwọn aṣálẹ̀ aláìléso níbẹ̀ ni àwọn adágún omi alàyè yíò jade wá; àti pé ilẹ̀ gbígbẹ ni kì yíò jẹ́ ilẹ̀ tí ó npòungbẹ mọ́.
30 Wọn yíò sì mú àwọn ohun ìṣúra oníyebíye wọn jade wá fún àwọn ọmọ Éfráímù, àwọn ìránṣẹ́ mi.
31 Àti pé àwọn ààlà ti àwọn okè àìlópin yíò wárìrì níwájú wọn.
32 Níbẹ̀ ni wọn yíò sì ṣubú lulẹ̀ tí a ó sì dé wọn ní ade pẹ̀lú ògo, àní ní Síónì, nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, àní àwọn ọmọ Éfráímù.
33 Wọn yíó sì kún fún àwọn orin ayọ̀ àìlópin.
34 Kíyèsíi, èyí ni ìbùkún ti Ọlọ́run àìlópin ní orí àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì, àti ìbùkún tí ó ṣe iyebíye jù sí orí Éfráímù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.
35 Àti àwọn bákannáà ti ẹ̀yà Júdà, lẹ́hìn ìrora wọn, ni a ó yà sí mímọ́ ní ìwà mímọ́ níwájú Olúwa, láti máa gbé ní iwájú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, láé ati títí láéláé.
36 Àti nísisìyí, lóotọ́ ni Olúwa wí, pé kí àwọn nkan wọ̀nyìí lè di mímọ̀ ní àrin yín, ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ ayé, èmi ti rán ángẹ́lì mi jade tí nfò ní ààrin agbedeméjì ọ̀run, tí ó ní ìhìnrere àìlópin, ẹnití ó ti fi ara hàn sí àwọn kan àti tí ó ti fi í fún ènìyàn, ẹnití yíò fi ara hàn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ó ngbé ní orí ilẹ̀ ayé.
37 Àti ìhìnrere yìí ni a ó wàásù sí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ìbátan, àti èdè, àti ènìyàn.
38 Àti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yíò jade lọ, ní wíwí pẹ̀lú ohùn rara: Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ ti dé;
39 Ẹ sì sìn òun tí ó dá ọ̀run, àti ayé, àti òkun, àti àwọn orisun àwọn omi—
40 Ní pípe orúkọ Olúwa ní ọ̀sán àti ní òru, ní wíwí pé: ìwọ ìbá jẹ́ ṣí àwọn ọ̀run, kí ìwọ sì sọ̀kalẹ̀ wá, kí àwọn òkè nlá kí ó lè ṣàn wá sílẹ̀ níwájú rẹ.
41 A ó sì mú ìdáhùn wá sí orí wọn; nítorí iwájú Olúwa yíò dàbí iná yíyọ́ tí njó, àti bí iná èyítí ó nmú kí omi hó.
42 Olúwa, ìwọ yíò sọ̀kalẹ̀ wá láti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ sí àwọn ọ̀tá rẹ, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yíò sì wárìrì ní iwájú rẹ—
43 Nígbàtí ìwọ bá ṣe ohun wọnnì tí ó lẹ́rù, àwọn ohun tí wọn kò fi ojú sọ́nà fún;
44 Bẹ́ẹ̀ni, nígbàtí ìwọ bá sọ̀kalẹ̀ wá, àti tí àwọn òkè ṣàn wá sílẹ̀ níwájú rẹ, ìwọ̀ yíò pàdé rẹ̀ ẹnití nyọ̀ àti tí ó nṣe iṣẹ́ òdodo, ẹnití ó rántí rẹ ní àwọn ọ̀nà rẹ.
45 Nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé ni àwọn ènìyàn kò ti gbọ́ tàbí wòye nípasẹ̀ etí, bẹ́ẹ̀ni ojú kankan kò tíì rí, Ọlọ́run, bíkòṣe pé ìwọ, bí àwọn ohun náà ti tóbi tó tí ìwọ ti pèsè fún ẹni náà tí ó dúró dè ọ́.
46 A ó sì wí pé: Tani èyí tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀run pẹ̀lú àwọn aṣọ pípa láró; bẹ́ẹ̀ni, láti àwọn agbègbè èyítí a kò mọ̀, tí a wọ̀ láṣọ nínú ẹ̀wù ológo rẹ̀, tí nrin ìrìnrìnàjò nínú títóbi agbára rẹ̀?
47 Òun yíò sì wí pé: Èmi ni ẹnití ó sọ̀rọ̀ nínú òdodo, alágbára láti gbàlà.
48 Olúwa yíò sì wà nínú aṣọ rẹ̀ pupa, àti àwọn ẹ̀wù rẹ̀ bíi ẹni náà tí ó ntẹ̀ ohun èlò ìfúntí wáínì.
49 Ògo ọ̀dọ̀ rẹ̀ yíò sì ti pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí oòrun yíò fi ojú rẹ̀ pamọ́ ní ìtìjú, àti òṣùpá yíò dá ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ dúró, àti àwọn ìràwọ̀ ni a ó fi sọ̀kò láti àwọn ibi ààyè wọn.
50 Ohùn rẹ̀ ni a ó sì gbọ́: Èmi ti nìkan tẹ ohun èlò ìfúntí wáinì, mo sì ti mú ìdájọ́ wá sí orí gbogbo ènìyàn; kò sì sí ẹnikankan pẹ̀lú mi;
51 Èmi si ti tẹ̀ wọ́n nínú ìbínú mi, mo sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ nínú ìrúnú mi, ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi sì ti fọ́n sí ara àwọn aṣọ mi, mo sì ṣe gbogbo aṣọ mi ní àbàwọ́n; nítorí èyí jẹ́ ọjọ́ ẹ̀san èyítí ó wà nínú ọkàn mi.
52 Àti nísisìyí ọdún àwọn ẹni ìrapadà mi ti dé; wọn yíò sì sọ nípa ìfẹ́ inu rere ti Olúwa wọn, àti gbogbo èyí tí òun ti fi bùn wọn gẹ́gẹ́bí oore rẹ̀, àti gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú rere rẹ̀, láé àti títí láéláé.
53 Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn a pọ́n ọn lójú. Ángẹ́lì ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì gbà wọ́n là; àti nínú ìfẹ́ rẹ̀, àti nínú ìkáànú rẹ̀, ó rà wọ́n padà, òun sì mú wọn, ó sì gbé wọ́n ní gbogbo àwọn ọjọ́ wọnnì;
54 Bẹ́ẹ̀ni, àti Enọ́kù pẹ̀lú, àti àwọn ẹnití ó wà pẹ̀lú rẹ̀; àwọn wòlíì tí wọ́n ti wà saájú rẹ̀; àti Nóah pẹ̀lú, àti àwọn tí wọ́n ti wà saájú rẹ̀; àti Mósè pẹ̀lú, àti àwọn tí wọ́n ti wà saájú rẹ̀;
55 Àti láti orí Mósè sí Èlíjàh, àti láti orí Èlíjàh sí Jòhánnù, ẹnití ó wà pẹ̀lú Krístì nínú àjínde rẹ̀, àti àwọn àpóstélì mímọ́, pẹ̀lú Ábráhámù, Ísákì, àti Jákọ́bù, yíò wà ní iwájú Ọ̀dọ́-Àgutàn náà.
56 Àti pé àwọn isà òkú ti àwọn ènìyàn mímọ́ ni a ó ṣí; wọn yíò sì jade wá wọn yío sì dúró ni ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀dọ́-Àgùtàn náà, nígbatí òun yíò dúró ní orí òkè Síónì, àti ní orí ìlú mímọ́ náà, Jérúsálẹ́mù Titun; wọn yíò sì kọ orin ti Ọ̀dọ́-Agùtàn, ní ọ̀sán àti ní òru láé àti títí láéláé.
57 Àti fún ìdí èyí, pé kí a lè mú ènìyàn jẹ́ alábápín àwọn ògo èyítí a ó fi hàn, Olúwa rán ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere rẹ̀ jade wá, májẹ̀mú àìlópin rẹ̀, ní sísọ ìdí ọ̀rọ̀ ní kedere àti pẹ̀lú ìrọ̀rùn—
58 Láti pèsè àwọn aláìlágbára sílẹ̀ fún àwọn ohun wọnnì èyítí ó nbọ̀ wá sí orí ilẹ̀ ayé, àti fún iṣẹ́ tí Olúwa rán ní ọjọ́ náà tí àwọn aláìlágbára yíò dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n, àti àwọn tí ó kéré yíò di orílẹ̀ ède alágbára kan, ẹ̀ni méjì yíò sì lé ẹgbãrún sá.
59 Àti nípasẹ̀ àwọn ohun aláìlágbára ti ilẹ̀ ayé ni Olúwa yíò yọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí rẹ̀.
60 Àti pé fún ìdí èyí ni a ṣe fi àwọn òfin wọ̀nyí fún yín; a pàṣẹ pé wọ́n níláti jẹ́ pípamọ́ kúrò nínú ayé ní ọjọ́ náà tí a fi fún wọn, ṣùgbọ́n nísisìyí wọn yíò jáde lọ sí gbogbo ẹran ara—
61 Àti èyí gẹ́gẹ́bí ọkàn àti ìfẹ́ inú Olúwa, ẹnití ó nṣe àkóso gbogbo ẹran ara.
62 Àti ẹni náà tí ó ronúpìwàdà tí ó sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ níwájú Olúwa ni a ó fún ní ìyè ayérayé.
63 Àti ní orí àwọn wọnnì tí wọn kò fetísílẹ̀ sí ohùn Olúwa ni a ó ṣe ìmúṣẹ èyíinì tí a ti kọ nípasẹ̀ wòlíì Mósè, pé kí wọn ó jẹ́ kíké kúrò láàrin àwọn ènìyàn.
64 Àti bákannáà èyíinì tí a kọ nípasẹ̀ wòlíì Málákì: Nítorí, kíyèsíi, ọjọ́ náà nbọ̀wá tí yíò jóná bí ààrò, àti pé gbogbo àwọn agbéraga, bẹ́ẹ̀ni, àti gbogbo àwọn olùṣebúburú, yíò dàbí àkékù koríko; ọjọ́ náà tí nbọ̀wá yíò sì jó wọn pátápátá, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, tí kì yíò ku gbòngbò tàbí ẹ̀ka sílẹ̀ fún wọn.
65 Nísisìyí, èyí ni yíò jẹ́ ìdáhùn Olúwa sí wọn:
66 Ní ọjọ́ náà nígbàtí èmi wá sí ọ̀dọ̀ àwọn tèmi, kò sí ẹnikan ní àrin yín tí ó gbà mí, a sì lé e yín jade.
67 Nígbàtí èmi tún pè lẹ́ẹ̀kansíi kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín látí dáhùn; síbẹ̀ apá mi kò kúrú rárá tí èmi kì yió le rà padà, tàbí agbára mi láti gbàni.
68 Kíyèsíi, ní ìbáwí mi mo gbẹ òkun. Mo sọ àwọn odò nlá di aginjù; ẹja wọn rùn, wọ́n sì kú nítorítí òùngbẹ.
69 Mo fi dúdú wọ àwọn ọ̀run láṣọ, mo sì fi òkùnkùn ṣe ìbora wọn.
70 Èyí sì ni ẹ̀yin yíò ní láti ọwọ́ mi—ẹ̀yin yíò dùbúlẹ̀ nínú ìrora.
71 Kíyèsíi, sì wòó, kò sí ẹnikẹ́ni láti gbà yín; nítorí ẹ̀yin kò gbọ́ràn sí ohùn mi nígbàtí mo pè yín láti inú awọn ọ̀run; ẹ̀yin kò gba àwọn ìránṣẹ́ mi gbọ́, àti nígbàtí a rán wọn sí yín ẹ̀yin kò gbà wọ́n.
72 Nítorínáà, wọ́n fi èdídí di ẹ̀rí náà wọ́n sì di òfin náà, a sì fi yín lé òkùnkùn lọ́wọ́.
73 Àwọn wọ̀nyí yíò lọ sínú òkùnkùn lode, níbití ẹkún, àti ìpohùnréré ẹkún, àti ìpahínkeke wà.
74 Kíyèsíi Olúwa Ọlọ́run yín ti sọ ọ́. Àmin.