Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138


Ìpín 138

Ìran kan tí a fifún Ààrẹ Joseph F. Smith ní Ìlú nlá Salt Lake, Utah, ní 3 Oṣù Kẹwã 1918. Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀ ní ibi Ìpàdé Gbogbogbò ti ìdajì ọdún ẹlẹ́ẹ̀kọkàndínláàdọ́rùn ti Ìjọ, ní 4 Oṣù Kẹwã 1918, Ààrẹ Smith kéde pé òun ti gba onírúurú ìbánisọ̀rọ̀ àtọ̀runwá láàrin àwọn oṣù díẹ̀ sẹ́hìn. Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí, nípa àbẹ̀wò Olùgbàlà sí ẹ̀mí àwọn òkú nígbàtí ara Rẹ̀ wà nínú ibojì, Ààrẹ Smith ti gba á ní ọjọ́ kan sẹ́hìn. A kọ ọ́ lọ́gán tẹ̀lé ìparí ìpadé àpapọ̀ náà. Ní 31 Oṣù Kẹwã 1918, a gbé e kalẹ̀ fún àwọn olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Ìgbìmọ̀ ti àwọn Méjìlá, àti Pátríákì, ní ìfohùnṣọ̀kan ni ó sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí wọn.

1–10, Ààrẹ Joseph F. Smith ṣe àròjinlẹ̀ ní orí àwọn ohun tí Pétérù kọ àti àbẹ̀wò Olúwa wa sí ayé ti àwọn ẹ̀mí; 11–24, Ààrẹ Smith rí òkú àwọn olódodo tí wọ́n péjọpọ̀ ní párádísè àti ìṣẹ́ ìránṣẹ́ Krístì ní ààrin wọn; 25–37, Ó ríi bí a ṣe ṣe ètò wíwàásù ìhìnrere ní ààrin àwọn ẹ̀mí; 38–52, Ó rí Ádámù, Éfà, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì mímọ́ ní ayé àwọn ẹ̀mí tí wọ́n ka ipò tí ẹ̀mí wọn wà sáájú àjínde wọn sí oko-ẹrú; 53–60, Òkú àwọn olódodo ti àkókò yí tẹ̀síwájú nínú lãlã wọn ní ayé àwọn ẹ̀mí.

1 Ní ọjọ́ kẹta Oṣù Kẹwã, nínú ọdún 1918, mo jókòó nínú yàrá mi ní ríronújinlẹ̀ nípa àwọn ìwé mímọ́;

2 Àti ní ríronú nípa ètùtù ẹbọ-ọrẹ nlá tí a ṣe láti ọwọ́ Ọmọ Ọlọ́run, fún ìràpadà aráyé;

3 Àti ìfẹ́ nlá àti tí ó kún fún ìyanu tí Bàbá àti Ọmọ fi hàn nínú wíwá Olùràpadà sínú ayé;

4 Pé nípasẹ̀ ètùtù rẹ̀, àti nípa ìgbọ́ràn sí àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere, aráyé le di gbígbàlà.

5 Nígbàtí mo nṣe èyí lọ́wọ́, ọkàn mi padà sí àwọn ohun tí Pétérù àpóstélì kọ, sí àwọn ẹni mímọ́ ti ìbẹ̀rẹ̀ tí wọ́n ti fọ́nkáàkiri ilẹ̀ òkèrè jákèjádò Pontù, Galátíà, Kappadókíà, àti àwọn apá ibòmíràn ní Asíà, níbití ìhìnrere ti jẹ́ kíkéde lẹ́hìn ìyà kíkàn Olúwa mọ́ àgbélèbú.

6 Mo ṣí Bíbélì mo sì ka orí ìwé ẹ̀kẹta àti ẹ̀kẹrin ti epistélì ìkíní ti Pétérù, bí mo sì ṣe kàá mo ní ìtẹ̀mọ́ra gidigidi, ju bí mo ṣe ti ní tẹ́lẹ̀rí lọ, pẹ̀lú àwọn ìpín kékèké tí ó tẹ̀lée yìí:

7 “Nítorí Krístì pẹ̀lú ti jìyà lẹ́ẹkan nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀, olõtọ́ fún àwọn aláìṣõtọ́, kí ó le mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹ̀nití a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di alààyè nínú Ẹ̀mí;

8 “Nínú èyítí òun lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú;

9 “Àwọn tí wọ́n ṣe aláìgbọràn nígbàkan, nígbàtí ìpamọ́ra Ọlọ́run dúró ní àwọn ọjọ́ Nóà, nígbàtí wọ́n nkan ọkọ̀, nínú èyítí díẹ̀, èyí ni pé, ènìyàn mẹ́jọ di gbígbàlà nípasẹ̀ omi.” (1 Peterù 3:18–20.)

10 “Nítorí fún ìdí èyí ni a ṣe wàásù ìhìnrere sí àwọn òkú pẹ̀lú, kí á lè ṣe ìdájọ́ wọn ní ìbámu sí ènìyàn nínú ara, ṣùgbọ́n tí wọ́n ngbé ní ìbámu sí Ọlọ́run nínú ẹ̀mí.” (1 Peter 4:6.)

11 Bí mo ṣe nronú nípa àwọn ohun wọ̀nyí èyítí a kọ, a ṣí ojú àgbọ́yé mi, Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òkú, àti kékeré àti nlá.

12 Níbẹ̀ ni wọ́n sì péjọpọ̀ sí ní ojú kan, àìníye ọ̀wọ́ àwọn ẹ̀mí ti àwọn olódodo, tí wọ́n ti jẹ́ olõtọ́ nínú ẹ̀rí Jésù nígbàtí wọ́n gbé nínú ara kíkú;

13 Àti tí wọ́n ti rú ẹbọ ní àpẹrẹ ẹbọ́ nlá ti Ọmọ Ọlọ́run, àti tí wọ́n ti jìyà ìpọ́njú ní orúkọ Olùràpadà wọn.

14 Gbogbo àwọn wọ̀nyí ti lọ kúrò nínú ayé ti-ikú, ní dídúróṣinṣin nínú ìrètí àjínde ológo, nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Bàbá àti Ọmọ Bibí rẹ̀ Kanṣoṣo, Jésù Krístì.

15 Mo kíyèsíi pé wọ́n kún fún ayọ̀ àti ìdùnnú, wọ́n sì nyọ̀ lápapọ̀ nítorítí ọjọ́ ìtúsílẹ̀ wọn dé tán.

16 Wọ́n kórajọpọ̀ ní dídúró de bíbọ̀ Ọmọ Ọlọ́run sínú ayé àwọn ẹ̀mí, láti kéde ìràpadà wọn kúrò nínú àwọn ìdè ikú.

17 Erùpẹ́ wọn tí ó nsùn ni yíó jẹ́ mímú padà sí ipò pípé rẹ̀, egungun sí egungun rẹ̀, àti àwọn iṣan àti ẹran ara ní orí wọn, ẹ̀mí àti ara lati jẹ́ dídàpọ̀ tí wọn kì yíò sì pínyà mọ́ láé, kí wọ́n kí ó lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀.

18 Nígbàtí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àìníye yìí dúró tí wọ́n sì bá ara wọn sọ̀rọ̀, ní yíyọ̀ nínú wákàtí ìtúsílẹ̀ wọn kúrò nínú àwọn ẹ̀wọ̀n ikú, Ọmọ Ọlọ́run farahàn, ní kíkéde òmìnira sí àwọn ìgbèkùn tí wọ́n ti jẹ́ olõtọ́;

19 Àti níbẹ̀ ni òun wàásù ìhìnrere àìlópin sí wọn, ẹ̀kọ́ ti àjínde àti ti ìràpadà aráyé kúrò nínú ìṣubú, àti kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikọ̀kan ní orí àwọn àdéhùn ironúpìwàdà.

20 Ṣùgbọ́n sí ọ̀dọ̀ ènìyàn búburú ni òun kò lọ, àti sí àrin àwọn aláìwàbíọlọ́run àti aláìronúpìwàdà ti wọ́n ti sọ ara wọn dí àìmọ́ nigbàtí wọ́n wà nínú ara, ni kò gbé ohùn rẹ̀ sókè;

21 Bẹ́ẹ̀ni àwọn ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n kọ àwọn ẹ̀rí àti àwọn ìkìlọ̀ àwọn wòlíì àtijọ́ sílẹ̀ kì yíó rí ògo ọ̀dọ̀ rẹ̀, tàbí wo ojú rẹ̀.

22 Níbití ìwọ̀nyí wà, òkùnkùn jọba, ṣùgbọ́n ní àrin àwọn olódodo àlãfíà wà;

23 Àwọn ènìyàn mímọ́ sì yọ̀ nínú ìràpadà wọn, wọ́n sì tẹ eékún wọn ba wọ́n sì jẹ́wọ́ Ọmọ Ọlọ́run bí Olùràpadà àti Olùgbàlà wọn kúrò nínú ìkú àti àwọn ẹ̀wọ̀n ọ̀run apãdì.

24 Àwọn ìwò ojú wọn tàn, dídán láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì bà lé wọn, wọ́n sì kọ àwọn orin ìyìn sí orúkọ mímọ́ rẹ̀.

25 Ẹnu yà mí, nítorí ó yé mi pé Olùgbàlà lo nkan bíi ọdún mẹ́ta nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àrin àwọn Júù àti àwọn ti ilé Ìsráẹ́lì, ní gbígbìyànjú láti kọ́ wọn ní ìhìnrere àìlópin àti láti pè wọ́n sí ironúpìwàdà;

26 Àti síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ àwọn iṣẹ́ alágbára rẹ̀, àti àwọn iṣẹ́ ìyanu, àti ìkéde òtítọ́ náà, nínú agbára nlá àti àṣẹ, díẹ̀ ni àwọn tí wọ́n fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ̀, wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì gba ìgbàlà ní ọwọ́ rẹ̀.

27 Ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn wọnnì tí wọ́n ti kú mọ ní àkókò kúkúrú tí ó wà láàrin ìyà ìkànmọ́ àgbélẽbú àti àjínde rẹ̀;

28 Àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù sì yàmílẹ́nu—nínú èyí tí ó sọ pé Ọmọ Ọlọ́run wàásù sí àwọn ẹ̀mí nínú túbú, àwọn tí wọn ti fi ìgbà kan jẹ́ aláìgbọ́ràn, nígbàtí ìpamọ́ra Ọlọ́run dúró nígbàkan ní àwọn ọjọ́ Nóà—àti bí ó ti ṣeéṣe fún un láti wàásù sí àwọn ẹ̀mí wọnnì àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ láàrin wọn nínú àkókò kúkúrú kan bẹ́ẹ̀.

29 Bí ó sì ṣe nyà mí lẹ́nu, ojú mi là, òye mi sì di ààyè, mo sì wòye pé Olúwa kò lọ bí èniyàn sí àrin àwọn ènìyàn búburú àti àwọn aláìgbọ́ràn àwọn tí wọ́n ti kọ òtítọ́, láti kọ́ wọn;

30 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, láti àrin àwọn olódodo, òun ṣètò àwọn ikọ̀ rẹ̀ ó sì yan àwọn ìránṣẹ́, tí ó wọ̀ láṣọ pẹ̀lú agbára àti àṣẹ, ó sì fi àṣẹ fún wọn láti jade lọ àti láti mú ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere náà fún àwọn tí wọ́n wà nínú òkùnkùn, àní sí gbogbo àwọn ẹ̀mí ènìyàn; báyìí sì ni ìhìnrere jẹ́ wíwàásù sí àwọn òkú.

31 Àwọn àṣàyàn ìránṣẹ́ náà sì jade lọ láti kéde ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà Olúwa àti láti kéde òmìnira sí àwọn ìgbèkùn tí wọ́n wà nínú ìdè, àní sí gbogbo ẹnití ó bá ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọn sì gba ìhìnrere náà.

32 Báyìí ni ìhinrere jẹ́ wíwáàsù sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, láì ní ìmọ̀ òtítọ́, tàbí nínú ìwà ìrékọjá, lẹ́hìn tí wọ́n ti kọ àwọn wòlíì sílẹ̀.

33 Àwọn wọ̀nyí ni a kọ́ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ironúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, ṣíṣe ìribọmi ní ipò ẹlòmíràn fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ nípasẹ̀ ìgbọ́wọ́léni,

34 Àti gbogbo àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere míràn tí ó ṣe dandan fún wọn láti mọ̀ kí wọ́n ó lè mú ara wọn kún ojú òṣùnwọ̀n kí á lè ṣe ìdájọ́ wọn ní ìbámu sí àwọn ènìyàn nínú ara, ṣùgbọ́n tí wọ́n ngbé ní ìbámu sí Ọlọ́run nínú ẹ̀mí.

35 Bẹ́ẹ̀ ni a sì sọ ọ́ di mímọ̀ ní àrin àwọn òkú, méjèjì, ní kékeré àti nlá, àwọn aláìṣòdodo àti àwọn olõtọ́ bákannáà, pé ìràpadà ni a ti múwá nípasẹ̀ ẹbọ-ọrẹ Ọmọ Ọlọ́run ní orí àgbélèbú.

36 Báyìí ni a sọ ọ́ di mímọ̀ pé Olùrapadà wa lo àkókò rẹ̀ ní ìgbà àtìpó rẹ̀ ní ayé àwọn ẹ̀mí, ní kíkọ́ni àti mímúra ẹ̀mí àwọn olõtọ́ wòlíì sílẹ̀ àwọn tí wọ́n ti jẹ́rìí rẹ̀ nínú ara;

37 Kí wọ́n ó lè mú ìhìn ìràpadà náà lọ fún gbogbo àwọn òkú, sí àwọn ẹnití òun kò lè lọ tìkárarẹ̀, nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ àti ìrékọjá wọn, kí àwọn nípasẹ̀ iṣẹ́ ìrànṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ó lè gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ bákannáà.

38 Nínú àwọn ẹni nlá ati alágbára tí wọ́n péjọpọ̀ nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìpéjọpọ̀ yìí ti àwọn olõtọ́ ni Bàbá Ádámù, Arúgbó Ọjọ́ náà àti bàbá gbogbo ènìyàn.

39 Àti Ìyá wa ológo Éfà, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olõtọ́ ọ̀mọbìnrin rẹ̀ àwọn tí wọ́n ti gbé ní gbogbo àwọn àkókò tí wọ́n sì jọ́sìn fún Ọlọ́run òtítọ́ àti alàyè.

40 Ábẹ́lì, ajẹ́rìíkú àkọ́kọ́, wà níbẹ̀, àti arákùnrin rẹ̀ Sẹ́tì, ọ̀kan nínú àwọn alágbára nnì, ẹnití ó wà ní àwòrán bàbá rẹ̀ gan an, Ádámù.

41 Nóà, ẹnití ó ṣe ìkìlọ̀ ìkún omi; Ṣémù, àlùfáà gíga nlá; Ábráhámù, bàbá àwọn olõtọ́; Ísákì, Jákọ́bù, àti Mósè, ẹni nlá afúnni-lófin ti Ísráẹ́lì;

42 Àti Isaiah, ẹnití ó kéde nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ pé Olùrapadà náà ni a fi àmì òróró yàn láti ṣe ìwòsàn ọkàn àwọn oníròbìnújẹ́, láti kéde òmìnira fún àwọn ìgbèkùn, àti láti ṣe ìtúsílẹ̀ àwọn túbú fún àwọn òndè, náà wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

43 Pẹ́lú-pẹ̀lù, Èsékíẹ́lì, ẹnití a fi àfonífòjì nlá ti àwọn egungun gbígbẹ hàn nínú ìran, èyítí a ó wọ̀ láṣọ pẹ̀lú ẹran ara, láti jade wá lẹ́ẹ̀kansíi ní àjínde àwọn òkú, bíi àwọn alàyè ọkàn;

44 Dáníẹ́lì, ẹnití ó rí tẹ́lẹ̀ àti tí ó sọtẹ́lẹ̀ nípa ìdásílẹ̀ ìjọba Ọlọ́run ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, tí a kì yíò tún parun mọ́ láé tàbí fi fún àwọn ènìyàn míràn;

45 Élíásì, ẹnití ó wà pẹ̀lú Mósè ní orí Òkè Ìyípadà ní ti ara;

46 Àti Málákì, wòlíì náà tí ó jẹ́rìí bíbọ̀ Èlíjà—ẹnití Mórónì pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún Wòlíì Joseph Smith, ní kíkéde pé òun yíò wá ṣaájú ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ nlá àti tí ó ni ẹ̀rù ti Olúwa—wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

47 Wòlíì Èlíjà náà ní yío gbìn sí ọkàn àwọn ọmọ àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn bàbá wọn;

48 Tẹ́lẹ̀ ṣíwájú iṣẹ́ nlá náà tí a ó ṣe nínú àwọn tẹ́mpìlì Olúwa ní ìgbà ìríjú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò, fún ìràpadà àwọn òkú, àti fífi èdídí di àwọn ọmọ sí àwọn òbí wọn, bíbẹ́ẹ̀kọ́ gbogbo ayé ni a ó kọlù pẹ̀lú ègún yío sì di ìfiṣòfò ní bíbọ̀ rẹ̀.

49 Gbogbo àwọn wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi, àní àwọn wòlíì tí wọ́n gbé ní ààrin àwọn ará Néfì àti tí wọ́n jẹ́rìí bíbọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, darapọ̀ nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpéjọ nlá náà wọ́n sì dúró fún ìtúsílẹ̀ wọn,

50 Nítorí àwọn òkú ti wo bí ó ṣe pẹ́ tó tí ẹ̀mí wọn ti kúrò nínú àgọ́ ara wọn bíi àkókò oko-ẹrú.

51 Àwọn wọ̀nyí ni Olúwa kọ́, tí ó sì fún ní agbára láti jade wá, lẹ́hìn àjínde rẹ̀ kúrò nínú òkú, láti wọ inú ìjọba Bàbá rẹ̀, níbẹ̀ láti dé wọn ní adé àìkú àti ìyè ayerayé,

52 Àti láti tẹ̀síwájú láti ìgbà náà lọ nínú lãlã wọn bí Olúwa ti ṣe ìlérí, àti láti jẹ́ alábãpín gbogbo àwọn ìbùkún èyítí a ti fi pamọ́ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀.

53 Wòlíì Joseph Smith, àti bàbá mi, Hyrum Smith, Brigham Young, John Taylor, Wilford Woodruff, àti àwọn àṣàyàn ẹ̀mí míràn tí a ti fi pamọ́ láti jade wá ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò láti kópa nínú fífí àwọn ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nlá ọjọ́-ìkẹhìn lélẹ̀,

54 Nínú rẹ̀ ni kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì àti ṣíṣe àwọn ìlànà níbẹ̀ fún ìràpadà àwọn òkú, náà wà ní ayé àwọn ẹ̀mí bákannáà,

55 Mo kíyèsíi pé wọn wà láàrin àwọn ọlọ́lá àti àwọn ẹni nlá bákannáà àwọn ẹnití a ti yàn ní ìbẹ̀rẹ̀ láti jẹ́ àwọn alákóso nínú Ìjọ Ọlọ́run.

56 Àní ṣaájú kí á tó bí wọn, àwọn, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn, ti gba àwọn ẹ̀kọ́ wọn àkọ́kọ́ nínú ayé àwọn ẹ̀mí wọ́n sì ti gbáradì láti jade wá ní àkókò tí ó yẹ lójú Olúwa láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà rẹ̀ fún ìgbàlà ọkàn àwọn ènìyàn.

57 Mo kíyèsíi pé àwọn olõtọ́ alàgbà ìjọ ti ìgbà ìríjú yìí, nígbàtí wọ́n bá lọ kúrò ní ayé ti ikú, ntẹ̀síwájú nínú àwọn iṣẹ́ wọn ní wíwàásù ìhìnrere ti ìrònúpìwàdà àti ìràpadà, nípasẹ̀ ìrúbọ ti Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Ọlọ́run, ní àrin àwọn tí wọ́n wà nínú òkùnkùn àti lábẹ́ oko-ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ nínú àyé nlá ti ẹ̀mí àwọn òkú wà.

58 Àwọn òkú tí wọ́n bá ronúpìwàdà ni a ó ràpadà, nípasẹ̀ ìgbọ́ràn sí àwọn ìlànà ti ilé Ọlọ́run,

59 Àti lẹ́hìn tí wọ́n bá ti jìyà fún àwọn ìrékọjá wọn, àti tí a wẹ̀ wọ́n mọ́, wọn yíò gba èrè kan ní ìbámu sí àwọn iṣẹ́ wọn, nítorí wọ́n jẹ́ ajogún ìgbàlà.

60 Báyìí ni ìran náà ti ìràpadà àwọn òkú tí a fi-hàn sí mi, mo sì jẹ́rìí síi, mo sì mọ̀ pé ẹ̀rí yìí jẹ́ òtítọ́, nípasẹ̀ ìbùkún Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ànì bẹ́ẹ̀ni. Àmín.