Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 13


Ìpín 13

Àyọkúrò láti inú ìwé ìtàn ti Joseph Smith tí ó ṣe àpéjúwe ìlànà ìfinijoyè ti Wòlíì náà àti Oliver Cowdery sí oyè àlufáà ti Aarónì ní itòsí Harmony, Pennsylvania, ọjọ́ kẹ̃dógún Oṣù karũn 1829. Ìfinijoyè náà ni a ṣe lati ọwọ́ angẹ́lì kan tí ó kéde ara rẹ̀ bíi Jòhánnù, ẹ̀ni kannáà tí a pè ní Jòhánnù Onítẹ̀bọmi nínú Májẹ̀mu Titun. Angẹ́lì náà ṣe àlàyé pé òun nṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Péterù, Jákọ́bù, àti Johannù, àwọn Àpostélì ìgbàanì, tí wọ́n ní àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà gíga, èyítí a pè ní Òyè àlùfáà ti Melkizedekì. Ìlérì náà ni a fi fún Joseph àti Oliver pé nígbàtí àkókò bá tó òyè àlufáà gíga yìí yíó di fífi lé wọn ní orí. (Wo ìpín 27:7–8, 12.)

Àwọn kọ́kọ́rọ́ àti agbára oyè àlùfáà ti Aarónì ni a fi lélẹ̀.

1 Ní orí yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi, ní orúkọ Mèssíà mo fi oyè àlùfáà ti Aarónì fũn yín, èyí tí ó ní kọ́kọ́rọ́ ti ìṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì, àti ti ìhìnrere ironúpìwàdà, àti ti ìrìbọmi nípa rírì bọmi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀; àti pé a kì yíò mú èyí kúrò ní ilé ayé mọ́ láé, títí tí àwọn ọmọ Léfì yíò fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan síi ẹbọ-ọrẹ kan sí Olúwa nínú òdodo.