Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1


Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú náà

Ìpín 1

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith ní 1 Oṣù Kọkànlá 1831, ní àkókò àkànṣe ìpàdé kan tí àwọn alàgbà ìjọ ṣe ní Hiram, Ohio. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihan ni a ti rígba láti ọwọ́ Olúwa sáájú àkókò yìí, àti pé àkójọpọ̀ ti àwọn wọ̀nyi fún títẹ̀ jade ní ẹ̀dà ìwé jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí a gbà wọlé ní ìpàdé àpapọ̀ náà. Ìpín yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ ìsaájú ìwé Olúwa sí àwọn ẹ̀kọ́, àwọn májẹ̀mú, àti àwọn òfin tí a fi fúnni ní ìgbà ìríjú yí.

1–7, Ohùn ìkìlọ̀ yíó wà fún gbogbo ènìyàn; 8–16, Ìṣubú kúrò nínú òtítọ́ àti ìwà búburú síwájú Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì; 17–23, Joseph Smith ni a pè lati mú òtítọ́ àti agbára Olúwa padàbọ̀ sípò ní orí ilẹ̀ ayé; 24–33, Ìwé Ti Mọ́mọ́nì ni a mú jade tí a sì fi ìjọ òtítọ́ kalẹ̀; 34–36, A o mú àlãfíà kúrò ní orí ilẹ̀ ayé; 37–39, Wádìí àwọn òfin wọ̀nyi.

1 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin ènìyàn ìjọ mi, ni ohùn ẹnití ngbé ní ibi gíga, àti ẹnití ojú rẹ̀ wà lára gbogbo ènìyàn nwí; bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́ ni mo wí: Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn lati ọ̀nà jíjìn; àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní orí àwọn erékùsù òkun, ẹ jùmọ̀ tẹ́tísílẹ̀.

2 Nítorí lõtọ́ ni ohùn Olúwa nkọ sí gbogbo ènìyàn, kò sì sí ẹnikan tí yíò yọ; àti pé kì yíò sí ojú tí kì yíò rí, tàbí etí tí kì yíò gbọ́ tàbí ọkàn tí kì yíò wọnú rẹ̀.

3 Àti pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ yíò gbọgbẹ́ ìbànújẹ́ púpọ̀, nítorí àwọn àìṣedéédé wọn yíó di sísọ ní àwọn orí-ilé, àti àwọn ìṣe ìkọ̀kọ̀ wọn ni yíò di fífihàn.

4 Àti pé ohùn ìkìlọ̀ yíò wá fún gbogbo ènìyàn lati ẹnu àwọn ọmọ-ẹhìn mi, àwọn tí mo ti yàn ní awọn ọjọ́ ìkẹ́hìn yìí.

5 Àti pé wọn yíò jade lọ, ẹnikẹ́ni kì yíò sì dá wọn dúró, nítorí èmi Olúwa ti pàṣẹ fún wọn.

6 Kíyèsíi, èyí jẹ́ àṣẹ mi, àti àṣẹ ti àwọn ìránṣẹ mi, àti ọ̀rọ̀ ìṣaájú mi sí ìwé àwọn òfin mi, èyí tí mo fi fún wọn lati tẹ̀ fún yin, Áà ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ ayé.

7 Nítorínáà, ẹ bẹ̀rù kí ẹ sì wárìrì, Áà ẹ̀yin ènìyàn, nítorí ohun tí èmi Olúwa ti pàṣẹ nínú wọn yíò wá sí ìmúṣẹ.

8 Àti pé lõtọ́ ni mo wí fún yin, pé àwọn tí wọ́n jade lọ, ní jíjẹ́ àwọn ìhìn wọ̀nyí fún àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, àwọn ni a fi agbára fún lati fi èdídí dì ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run, awọn aláìgbàgbọ́ àti awọn ọlọ̀tẹ̀;

9 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́, lati fi èdídí dì wọn títí di ọjọ́ náà nígbàtí ìbínú Ọlọ́run yíò di títú jade sí orí àwọn ènìyàn búburú láì ní òṣùnwọ̀n—

10 Títí di ọjọ́ tí Olúwa yíò dé lati san fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ rẹ̀, àti lati wọ̀n fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí òsùnwọ̀n tí òun ti fi wọ̀n fún arákùnrin rẹ̀.

11 Nítorínáà ohùn Olúwa nkọ sí awọn ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé, pé kí gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ gbọ́ lè gbọ́:

12 Ẹ múra, ẹ múra nítorí èyí tí ó mbọ̀, nítorí Olúwa súnmọ́ itosí;

13 Àti pé ìbínú Olúwa ti ru sókè, àti idà rẹ̀ ti di wíwẹ̀ ní ọ̀run, àti pé yíò ṣubú ní orí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.

14 Àti pé apá Olúwa yíò di fífihàn, ọjọ́ náà sì dé tán tí àwọn ẹnití kì yíò gbọ́ ohùn Olúwa, bẹ́ẹ̀ni ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni ní ṣíṣe àkíyèsí sí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì àti àwọn àpóstélì, yíò di kíké kúrò láàrin àwọn ènìyàn;

15 Nítorí wọ́n ti yapa kúrò ní àwọn ìlànà mi, wọn sì ti sẹ́ májẹ̀mú ayérayé mi;

16 Wọn kò wá Olúwa láti fi ẹsẹ̀ òdodo rẹ̀ múlẹ̀, ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn nrìn ní ọ̀nà tirẹ̀, àti ní títẹ̀lé àwòrán ọlọ́run tirẹ̀, èyí tí àwòrán rẹ̀ wà ní ìrí ti ayé, àti èyí tí ohun ìní inú rẹ̀ jẹ́ ti òrìṣà kan, èyítí ó di ogbó tí yíò sì ṣègbé nínú Bábilónì, àní Babiloni nlá, èyítí yíò ṣubú.

17 Nítorínáà, èmi Olúwa, ní mímọ àwọn ewu tí yíò wá sí orí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, ké pe ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, mo sì sọ̀rọ̀ sí i lati ọ̀run, mo sì fún un ní àwọn òfin;

18 Àti pé bákannáà mo fi àwọn òfin fún àwọn míràn, pé wọn nílati kéde àwọn nkan wọ̀nyi sí ayé; àti gbogbo eléyi kí ó lè wá sí ìmúṣẹ, èyítí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wolíì—

19 Àwọn ohun aláìlágbára ti ayé yíò jade wá, wọn yíó sì wó àwọn alágbára àti àwọn tí wọn ní ipá lulẹ̀, pé kí ènìyàn máṣe gba ọmọnìkejì rẹ̀ ní ìmọ̀ràn, bẹ́ẹ̀ni kí ó má gbẹ́kẹ̀lé apá ẹran ara—

20 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù ènìyàn lè sọ̀rọ̀ ní orúkọ Ọlọ́run, tí í ṣe Olúwa, àní Olùgbàlà aráyé;

21 Kí ìgbàgbọ́ pẹ̀lú lè gbilẹ̀ nínú ilẹ̀ ayé.

22 Kí májẹ̀mú mi ti ayérayé lè fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.

23 Kí á lè kéde ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi láti ẹnu aláìlagbára àti òpè sí àwọn òpin ayé, àti níwájú àwọn ọba àti àwọn alakoso.

24 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run, mo sì ti sọ ọ́; àwọn òfin wọ̀nyi jẹ́ tèmi, a sì fi wọn fún àwọn ìránṣẹ́ mi nínú àìní agbára wọn, ní irú èdè wọn, kí wọn ó lè ní òye.

25 Àti pé níwọnbí wọn bá ṣe àṣìṣe kí á lè sọọ́ di mímọ̀;

26 Àti pé níwọnbí wọn bá nwá ọgbọ́n kí á lè fún wọn ní ẹ̀kọ́;

27 Àti pé níwọ̀nbí wọn bá dẹ́ṣẹ̀ kí á lè bá wọn wí, kí wọn lè ronúpìwàdà.

28 Àti pe níwọnbí wọn bá ní ìrẹ̀lẹ̀ kí á lè sọ wọn di alágbára, àti kí a bùkún wọn láti òkè wá, kí wọn sì rí ìmọ̀ gbà láti àkókò dé àkókò.

29 Àti lẹ́hìn rírí àkọsílẹ̀ ti àwọn ará Néfì gbà, bẹ́ẹ̀ni, àní ìránṣẹ mi Joseph Smith Kékeré, lè ní agbára láti túmọ̀ Iwé ti Mọ́mọ́nì, nípa àánú Ọlọ́run, pẹ̀lú agbára Ọlọ́run.

30 Àti bákannáà àwọn ẹnití a fún ní àwọn òfin wọnyìí, lè ní agbára láti fi ìpìlẹ̀ ìjọ mi yìí lélẹ̀, àti láti mú-un jade kúrò nínú ìfarasin àti jáde kúrò nínú òkùnkùn, ìjọ kan ṣoṣo tí ó jẹ́ òtítọ́ àti alààyè ní orí gbogbo ilẹ̀ ayé, èyí tí Emi, Olúwa ní inú dídùn sí, ní sísọ̀rọ̀ sí ìjọ ní àpapọ̀ ati kìí ṣe ẹni kọ̀ọ̀kan—

31 Nítorí èmi Olúwa kò lè bojúwo ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n ìyọ́nú tí ó kéré jùlọ;

32 Bí ó tilẹ̀ ríbẹ́ẹ̀, ẹnití ó bá ronúpìwàdà tí ó sì nṣe àwọn òfin Olúwa yíò rí ìdáríjì.

33 Àti ẹnití kò bá ronúpìwàdà, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó ti gba àní ìmọ́lẹ̀ tí ó ti ní; nítorí Ẹmí mi kì yíò fi ìgbà gbogbo wà pẹ̀lú ènìyàn, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

34 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yin, Áà ẹ̀yin olùgbé orí ilẹ̀ ayé: èmi Olúwa ní ìfẹ́ láti sọ gbogbo nkan wọ̀nyi di mímọ̀ sí gbogbo ẹlẹ́ran ara;

35 Nítorí èmi kìí ṣe ojúṣaájú ẹnikẹ́ni, àti kí gbogbo ènìyàn lè mọ̀ pé ọjọ́ náà dé kánkán; wákàtí náà kò tíì dé, ṣugbọ́n ó súnmọ́, nígbàtí a ó mú àlãfíà kúrò ní orí ilẹ̀ ayé, àti tí eṣù yíò ní agbára ní orí ìjọba tirẹ̀.

36 Àti pé bákannáà, Olúwa yíò ní agbára ní orí àwọn èniyàn mímọ́ rẹ̀, yíò sì jọba láàrin wọn, yíò sì sọ̀kalẹ̀ wá pẹ̀lú ìdajọ́ sí orí Idumea, tàbi ayé.

37 Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn òfin wọnyí, nítorí wọn jẹ́ òtítọ̀ àti òdodo, àti pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti àwọn ìlérí tí ó wà nínú wọn gbogbo ni yíò wá sí ìmúṣẹ.

38 Ohun tí èmi Olúwa ti sọ, mo ti sọ, èmi kò sì ṣe àwáwí fún ara mi, ati pé bí àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé bá tilẹ̀ kọjá lọ, ọ̀rọ̀ mi kì yíò kọjá lọ, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ yíò wá sí ìmúṣẹ, bóyá nípa ohùn tèmi tàbí ohùn àwọn ìránṣẹ mi, ọ̀kan náà ni.

39 Nítorí kíyèsíi, sì wòó, Olúwa ni Ọlọ́run, Ẹ̀mí sì jẹ́ri àkọsílẹ̀, àkọsílẹ̀ náà sì jẹ́ òtítọ́, àti pé òtítọ́ náà dúró láé ati títí láéláé. Amin.