Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20


Ìpín 20

Ìfihàn lóri àkójọ àti àkóso ìjọ, tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní tàbí nítòsí Fayette, New York. Àwọn abala ìfihàn yìí kan le ti jẹ́ fífúnni láti ìbẹ̀rẹ̀ bíi ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1829. Ìfihàn náà ní pípé, tí a mọ̀ ní àkókò náà bíi Àwọn Nkan ati Àwọn Májẹ̀mú, ni ó ṣeéṣe kí a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní kété lẹ́hìn ọjọ́ kẹfà Oṣù Kẹrin 1830 (ọjọ tí a ṣe ìgbékalẹ̀ Ìjọ). Wòlíì kọ pé, “A gbà lati ọ̀dọ̀ Rẹ̀ [Jésu Krístì] àwọn àtẹ̀lé wọ̀nyí, nípa ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn; èyí tí kò fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ nìkan, ṣugbọ́n bákannáà ó tọ́kasí ọjọ́ náà gan an fún wa nígbàtí, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ àti òfin Rẹ̀, a nílati tẹ̀síwájú lati ṣe àkójọ Ìjọ Rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi níhĩn ní orí ilẹ̀ ayé.”

1–16 Ìwé ti Mọ́mọ́nì fi ìdí jíjẹ́ ti ọ̀run iṣẹ́ ọjọ́-ìkẹhìn múlẹ̀; 17–28 Àwọn ẹ̀kọ́ nípa ìṣẹ̀dá, ìṣubú, ètùtù, àti ìrìbọmi ni a fi ìdí wọn múlẹ̀; 29–37, Àwọn òfin tí wọn nṣe àkóso ironúpìwàdà, ìdáláre, ìyàsímímọ́, àti ìrìbọmi ni a fi kalẹ̀; 38–67, Ojúṣe àwọn alàgbà, àlùfáà, olùkọ́, àti àwọn díakonì ni a ṣàlàyé ni ìkékúrú; 68–74, Ojúṣe àwọn omo ìjọ, bíbùkún fún àwọn ọmọdé, àti ọ̀nà ṣíṣe ìrìbọmi ni a fihàn; 75–84, Àwọn àdúrà oúnjẹ alẹ́ Olúwa àti àwọn ìlànà síṣe àkóso jíjẹ́ ọmọ ìjọ ni a fi fúnni.

1 Ìdìde ti Ìjọ Krístì ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rũn mẹ́jọ ati ọgbọ̀n ọdún lati ìgbà wíwá Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì nínú ẹran ara, òun náà ti a ṣe àkójọ rẹ̀ dáradára àti tí a gbé e kalẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin orílẹ̀-èdè wa, nípa ìfẹ́ inú àti àwọn àṣẹ Ọlọ́run, ní oṣù ìkẹrin, àti ní ọjọ́ ìkẹfà ti oṣù náà èyí tí a npè ní Oṣù Kẹrin—

2 Àwọn òfin èyítí a fi fún Joseph Smith Kékeré, ẹnití a pè láti ọwọ́ Ọlọ́run, àti tí a yàn gẹ́gẹ́bí àpóstélì ti Jésù Krístì, láti jẹ́ alàgbà àkọ́kọ́ ti ìjọ yìí;

3 Àti sí Oliver Cowdery, ẹnití Ọlọ́run pè bákannáà, àpóstélì kan ti Jésù Krístì, láti jẹ́ alàgbà ìkejì ti ìjọ yìí, tí a sì yàn ní abẹ́ ọwọ́ rẹ̀;

4 Àti èyí gẹ́gẹ́bí oore ọ̀fẹ́ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì, ẹnití gbogbo ògo jẹ́ tirẹ̀, nísisìyí àti títí lái. Amin.

5 Lẹ́hìn tí a ti fi hàn fún alàgbà àkọ́kọ́ yìí lõtọ́ pe òun ti gba ìmúkúrò àwọn ẹṣẹ̀ rẹ̀, a tún gbé òun dè nínú àwọn ohun asán ayé.

6 Ṣùgbọ́n lẹ́hìn ríronúpìwàdà, àti rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ sí i láti ọwọ́ ángẹ́lì mímọ́ kan, ẹnití ìwò ojú rẹ̀ dàbíi mọ̀nàmọ́ná, àti ẹnití àwọn aṣọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́ àti funfun ju gbogbo fífunfun míràn lọ;

7 Ó sì fún un ní àwọn òfin èyítí ó mísí i;

8 Àti pé Ó fún un ní agbára láti òkè wá, nípa ọ̀nà èyítí a ti pèsè saájú, láti ṣe ìtumọ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì.

9 Èyí tí ó ní àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣubú nínú, àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì sí àwọn Kèfèrí àti sí àwọn Júù bákannáà.

10 Èyítí a fún ni nípa ìmísí, àti tí a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ sí àwọn míràn nípa ìṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àwọn ángẹ́lì, tí a sì kéde rẹ̀ sí ayé nípa wọn—

11 Ní fífihàn sí ayé pé àwọn ìwé mímọ́ jẹ́ òtítọ́, àti pé Ọlọ́run sì nmísí àwọn ènìyàn Ó sì npè wọ́n sí iṣẹ́ mímọ́ rẹ̀ ní àkókò yìí àti ní ìran yìí, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ní àwọn ìran tí ìgbàanì;

12 Nípa bẹ́ẹ̀ Ó nfi hàn pé Òun kannáà ni Ọlọ́run ní àná, ní òní, àti títí láé. Amin.

13 Nítorínáà, níní àwọn ẹlérìí púpọ̀, nípa wọn ni a ó ṣe ìdájọ́ ayé, àní bí wọn ṣe lè jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ tó lẹ́hìnwá tí wọ́n yíò ní ìmọ̀ nípa iṣẹ́ yìí.

14 Àti pé àwọn wọnnì tí wọ́n gbàá nínú ìgbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ òdodo, yíò gba adè kan ti ìyè ayérayé;

15 Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n bá sé ọkàn wọn le nínú àìgbàgbọ́, tí wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yíò yípadà sí ìdálẹbi tiwọn—

16 Nítorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ ọ́; àti pé àwa, tí a jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, ti gbọ́ a sì ti jẹ́rìí sí àwọn ọ̀rọ̀ ti Ọlọ́lá nlá ológo níbi gíga, sí ẹnití a fi ògo fún láé ati títí láeláe. Amin.

17 Nípa awọn ohun wọ̀nyí ni àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run, ẹnití ó jẹ́ àìlópin àti ayérayé, láti àìlópin dé àìlópin Ọlọ́run kan náà tí kò lè yípadà, ẹnití ó ṣe ẹ̀dá ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo èyí tí ó wà nínú wọn;

18 Àti pé ò dá ènìyàn, ọ́kùnrin àti óbìnrin, ní àwòrán ara rẹ̀ àti gẹ́gẹ́bíi ìrí ara rẹ̀, ní ó dá wọn;

19 Àti pé Ó fún wọn ní àwọn òfin pé kí wọ́n ó ní ìfẹ́ kí wọ́n ó sì sìn òun, Ọlọ́run kan ṣoṣo tí ó wà láàyè tí ó sì jẹ́ òtítọ́, àti pé òun nìkan ni ó níláti jẹ́ ẹnití wọ́n ó máa foríbalẹ̀ fún.

20 Ṣùgbọ́n nípa ìwà ìrékọjá sí àwọn òfin mímọ́ wọ̀nyí ènìyàn di ti ara àti ti èṣù, àti pé òun sì di ẹni ìṣubú.

21 Nítorí èyí, Ọlọ́run Alágbára Jùlọ fi Ọmọ Bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, gẹ́gẹ́bí a ṣe kọ́ọ nínú àwọn ìwé mímọ́ wọnnì èyítí a ti fúnni lati ọ̀dọ̀ rẹ̀.

22 Òun sì jìyà àwọn ìdánwò ṣùgbọ́n òun kò fi àkíyèsí rẹ̀ sí wọn.

23 A kàn an mọ́ àgbélèbú, Ó kú, Ó sì tún jínde ní ọjọ́ kẹta;

24 Àti pé Ó gòkè re ọ̀run, láti jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ti Bàbá, láti jọba pẹ̀lú agbára títóbi-jùlọ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú Bàbá;

25 Kí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mímọ́ rẹ̀, àti pé tí wọ́n fi orí tìí nínú ìgbàgbọ́ títí dé òpin, nílati di ẹni ìgbàlà—

26 Kìí ṣe àwọn nìkan tí wọ́n gbàgbọ́ lẹ́hìn tí ó wá ní ààrin gbùngbùn àkókò, nínú ẹran ara, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n gbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, àní gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n wà kí òun tó wá, tí wọ́n gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì mímọ́, tí wọ́n sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ní ìmísí nípasẹ̀ ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnití ó jẹ́rìí tòótọ́ nípa rẹ̀ nínú ohun gbogbo, nilati ní ìyè ayérayé,

27 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni fún àwọn wọnnì tí wọn yío wá lẹ́hìnáà, tí àwon náà yíò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀bùn àti àwọn ìpè ti Ọlọ́run láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó nṣe ìjẹ́rìí nípa Bàbá àti Ọmọ.

28 Tí Bàbá, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ Ọlọ́run kan, àìlópin àti ayérayé, ti kò ní ìpẹ̀kun. Amin.

29 Àti pé àwa mọ̀ pé gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kí wọ́n ó sì gbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù Krístì, àti kí wọ́n ó bu ọlá fún Bàbá ní orúkọ rẹ̀, àti kí wọn ó fi orí tìí nínú ìgbàgbọ́ ní orúkọ rẹ̀ títí dé òpin, bíbẹ́ẹ̀kọ́ wọn kò ní di ẹni ìgbàlà ní ìjọba Ọlọ́run.

30 Àti pé àwa mọ̀ pé ìdáláre nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì jẹ́ títọ́ àti òtítọ́;

31 Àti pé àwa mọ̀ bákannáà, pé ìyàsímímọ́ nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì jẹ́ títọ́ àti òtitọ́, sí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ràn tí wọ́n sì nsìn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo agbára, iyè àti okun wọn.

32 Ṣùgbọ́n ó lè ṣeéṣe kí ènìyàn ṣubú kúrò nínú ore ọ̀fẹ́ kí òun sì yapa kúro lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè;

33 Nítorínáà ẹ jẹ́ kí ìjọ kíyèsára kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí wọ́n má baà bọ́ sínú ìdánwò;

34 Bẹ́ẹ̀ni, àní ẹ sì jẹ́ kí àwọn tí a yà sí mímọ́ náà ó kíyèsára bakannáà.

35 Àti pé àwa mọ̀ pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́ àti gẹ́gẹ́bí àwọn ìfihàn Johannù, láì ní àfikún, tàbí àyọkúrò nínú àsọ̀tẹ́lẹ̀ inú ìwé rẹ̀, àwọn ìwé mímọ́, tabí àwọn ìfihàn ti Ọlọ́run tí wọn yíò wá lẹ́hìnnáà nípa ẹ̀bùn àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́, ohùn Ọlọ́run, tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn angẹ́lì.

36 Àti pé Olúwa Ọlọ́run ti sọ ọ́; àti ọlá, agbára àti ògo ni ó yẹ orúkọ mímọ́ rẹ̀, nísisìyí àti títí láe. Amin.

37 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, gẹ́gẹ́bí ọ̀nà àwọn òfin sí ìjọ nípa ìlàna ìrìbọmi—Gbogbo àwọn tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, tí wọn sì níi lọ́kàn láti ṣe ìrìbọmi, tí wọ́n sì jade wá pẹ̀lú írobìnújẹ́ àti ìròra ọkàn, àti tí wọ́n jẹ́rìí níwájú ìjọ pé àwọn ti ronúpìwàdà lõtọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti tí wọ́n ní ìfẹ́ láti gba orúkọ Jésù Krístì sí orí wọn, pẹ̀lú ìpinnu láti sìn ín títí dé òpin, àti tí wọ́n ti fi hàn lõtọ́ nípa iṣẹ́ wọn pé àwọn ti gbà lára Ẹ̀mí ti Krístì sí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ni a ó gbà nípa ìrìbọmi sí inú ìjọ rẹ̀.

38 Ojúṣe àwọn alàgbà, àwọn àlùfáà, àwọn olùkọ́, àwọn diakoni, àti àwọn ọmọ ìjọ ti Krístì—àpóstélì jẹ́ alàgbà, àti pé ó jẹ́ ìpè rẹ̀ lati ṣe ìrìbọmi;

39 Àti láti yan àwọn alàgbà míràn, àwọn àlùfáà, àwọn olùkọ́, àti àwọn díákónì.

40 Àti láti ṣe àkóso àkàrà àti wáìnì—àwọn àpẹrẹ ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ ti Krístì—

41 Àti láti fì ẹsẹ̀ àwọn wọnnì múlẹ̀ tí a rìbọmi sínú ìjọ, nípa gbígbé ọwọ́ lé wọn ní orí fún ìrìbọmi ti iná àti ti Ẹ̀mí Mímọ́, ní ìbámu sí àwọn ìwé mímọ́;

42 Àti láti kọ́ni, sọ àsọyé, gbàni nímọ̀ràn, rìbọmi, ati dáàbò bo ìjọ;

43 Àti láti fi ìdí ìjọ múlẹ̀ nípa gbígbé ọwọ́ léni ní orí, àti fífúnni ní Ẹ̀mí Mímọ́;

44 Àti láti darí gbogbo àwọn ìpàdé.

45 Àwọn alàgbà ni wọ́n nílati darí àwọn ìpàdé bí Ẹ̀mí Mímọ́ bá ṣe darí wọn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti àwọn ìfihàn ti Ọlọ́run.

46 Ojúṣe àlùfáà ni láti wàásù, kọ́ni, sọ àsọyé, gbani níyànjú, àti ṣe ìrìbọmi, àti ṣe àkóso oúnjẹ àlẹ́ Olúwa,

47 Àti láti ṣe àbẹ̀wò sí ilé ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ ìjọ, kí ó sì gbà wọ́n níyànjú láti máa gbàdúrà ní ohùn òkè àti ní ìkọ̀kọ̀, àti láti máa ṣe gbogbo àwọn ojúṣe ẹbí.

48 Àti pé bákannáà òun lè yan àwọn àlùfáà míràn, àwọn olùkọ́ni, àti àwọn díákónì.

49 Àti pé òun ni yíò darí àwọn ìpàdé nígbàtí alàgbà kankan kò bá sí níbẹ̀.

50 Ṣùgbọ́n nígbàtí alàgbà kan bá wá níbẹ̀, òun ó kàn wàásù, kọ́ni, sọ àsọyé, gbani níyànjú, àti ṣe ìrìbọmi.

51 Àti láti ṣe àbẹ̀wò sí ilé ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ ìjọ, ní gbígbà wọ́n níyànjú láti máa gbàdúrà ní ohùn òkè àti ní ìkọ̀kọ̀, àti láti ṣe gbogbo àwọn ojúṣe ẹbí.

52 Nínú gbogbo ojúṣe wọ̀nyí, àlùfáà níláti ṣe àtìlẹ́hín fún alàgbà bí ó bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

53 Ojúṣe olùkọ́ni ni láti ṣe àmójútó ìjọ nígbà gbogbo, láti wà pẹ̀lú wọn àti láti máa mú wọn lọ́kàn le;

54 Àti lati ríi pé kò sí àìṣedéédé nínú ìjọ, tàbí ìṣòro pẹ̀lú ẹnìkan sí ẹlòmíràn, tàbí irọ́ pípá, tàbí sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀ni lẹ́hìn, tàbí sísọ̀rọ̀ búburú;

55 Ati lati ríi pé ìjọ nní ìpàde papọ̀ nígbàkúùgbà, àti bákannáà lati ríi pé gbogbo ọmọ ìjọ nṣe ojúṣe wọn.

56 Àti pé òun ni yíò darí àwọn ìpàdé bí alàgbà tàbí àlùfáà kankan kò bá sí níbẹ̀—

57 Ati pé àwọn diakónì yíò máa ràn án lọ́wọ́ nígbà gbogbo, nínú gbogbo iṣẹ rẹ̀ nínú ìjọ bí ó bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

58 Ṣùgbọ́n kò sí olùkọ́ni tàbí diakonì tí ó ní àṣẹ láti ṣe ìrìbọmi, ṣe àkóso oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbí gbé ọwọ́ lé ni ní orí;

59 Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn wà, lati ṣe ìkìlọ̀, sọ àsọyé, gbani níyànjú, àti kọ́ni, àti lati pè gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ Krístì.

60 Olukúlùkù alàgbà, àlùfáà, olùkọ́ni, tàbí díakonì ni a ó yàn ní ìbámu pẹ̀lú awọn ẹ̀bùn àti awọn ìpè Ọlọ́run sí i; àti pé a ó yàn án pẹ̀lú agbára Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó wà nínú ẹnití ó yàn án.

61 Onírúurú àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ ti ìjọ Krístì yìí yíò máa ní ìpádé nínú àpéjọpọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan láàrin oṣù mẹ́ta, tàbí láti àkókò dé àkókò bí àpéjọpọ̀ náà bá ṣe darí tàbí fi ọwọ́ sí;

62 Àti pé àwọn àpéjọpọ̀ tí a sọ yìí ni yíò máa ṣe èyíkéyìí iṣẹ́ ìjọ tí ó bá yẹ ní ṣíṣe ní ìgbà náà.

63 Àwọn alàgbà nílati gba àwọn ìwé àṣẹ wọn ní ọwọ́ àwọn alàgbà míràn, nípa ìbò àwọn ọmọ ìjọ èyí tí wọ́n wà, tàbí nínú àwọn àpéjọpọ̀.

64 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àlùfáà, olùkọ́ni, tàbí díakonì, ẹnití a yàn láti ọwọ́ àlùfáà, lè gba ìwé ẹ̀rí lọ́wọ́ rẹ̀ ní àkókò náà, ìwé ẹ̀rí èyítí ó jẹ́ pé, bí a bá fún alàgbà kan, yíò kà òun yẹ fún ìwé àṣẹ, tí yíò fi àṣẹ fún un láti ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó rọ̀ mọ́ ìpè rẹ̀, tàbí òun lè gbà á nínú ìpádé àpéjọpọ̀ kan.

65 A kò gbọdọ̀ yan ẹnikẹ́ni sí ipò kankan nínú ìjọ yìí, níbití àkójọ ẹ̀ka dáradára ti ìkannáà wà, láì sí ìbò ìjọ náà;

66 Ṣùgbọ́n àwọn alàgbà tí wọ́n nṣe olórí, àwọn bíṣọpù tí wọn nrin ìrìnàjò, àwọn ọmọ àjọ ìgbìmọ̀ gíga, àwọn àlùfáà gíga, àti àwọn alàgbà, lè ní ànfàní yíyanni, ní ibití kò bá sí ẹ̀ka ìjọ tí a lè ti pe ìbò.

67 Ààrẹ kọ̀ọ̀kan nínú oyè àlùfáà gìga (tàbí alàgbà tí ó nṣe olórí), bíṣọ́ọ̀pù, ọmọ àjọ ìgbìmọ̀ gíga, àti àlùfáà gíga, ni a ó yàn lábẹ́ ìdarí àjọ ìgbìmọ̀ gíga tàbí nínú ìpàdé àpéjọpọ̀ gbogbogbòò.

68 Ojúṣe àwọn ọmọ ìjọ lẹ́hìn tí a ti gbà wọ́n wọlé nípa ìrìbọmi—Àwọn alàgbà tàbí àwọn àlùfáà nílati ní ànító àkókò lati sọ àsọyé ohun gbogbo nípa ìjọ ti Krístì sí òye wọn, ṣaájú kí wọ́n ó tó jẹ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, àti kí a tó fi ìdí wọn múlẹ̀ nípa gbígbé ọwọ́ léni ní orí láti ọwọ́ àwọn alàgbà, kí á lè ṣe ohun gbogbo pẹ̀lú ètò.

69 Àti pé àwọn ọmọ ìjọ yíò fihàn ní iwájú ìjọ, àti bákannáà níwájú àwọn alàgbà, nípa ìrìn bí Ọlọ́run àti ìsọ̀rọ̀, pé wọ́n yẹ fún un, pé kí àwọn iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ lè wà ní ìbámu sí àwọn ìwé mímọ́—rírìn ní mímọ́ níwájú Olúwa.

70 Olúkúlùkù ọmọ ìjọ ti Krístì tí ó bá ní ọmọ wẹ́wẹ́ ni ó níláti mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà níwáju ìjọ, àwọn tí wọn yíò gbé ọwọ́ lé wọn ní orí ní orúkọ Jésù Krístì, tí wọn yíò sì súre fún wọn ní orúkọ rẹ̀.

71 A kò lè gba ẹnikẹ́ni sínú ìjọ ti Krístì bíkòṣe pé òun ti dàgbà dé awọn ọdún ṣíṣe ìjíhìn níwáju Ọlọ́run, àti tí ó ti lè ṣe ìrònúpìwàdà.

72 Ìrìbọmi ni a nílati ṣe àkóso rẹ̀ ní ọ̀nà tí a là sílẹ̀ yìí fún gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ronúpìwàdà—

73 Ẹni náà tí Ọlọ́run pè tí ó sì ní àṣẹ láti ọdọ̀ Jésù Krístì láti rìbọmi, yíò sọkalẹ̀ lọ sínú omi pẹ̀lú ẹni náà tí ó ti fa ara rẹ̀ kalẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin fún ìrìbọmi, òun yíò sì sọ pé, ní pípe ẹni náà lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin ní orúkọ rẹ̀: Nítorí tí a ti fi àṣẹ fúnmi lati ọ̀dọ̀ Jésù Krístì, mo rì ọ́ bọmi ní orúkọ ti Bàbá, àti ní ti Ọmọ, àti ní ti Ẹ̀mí Mímọ́. Àmín.

74 Nígbànáà ni òun yíò ri ẹni náà lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin bọ inú omi, yíò sì tún mú un jade wá láti inú omi náà.

75 O ṣe ànfààní pé kí ìjọ máa pàdé papọ̀ lóòrèkóòrè láti ṣe àbápín ti àkàrà àti wáìnì ní ìrántì Olúwa Jésù;

76 Àti pé alàgbà tàbí àlùfáà yíò ṣe ìpínfúnni rẹ̀; ní ọ̀nà yìí ni òun yíò sì ṣe ìpínfúnni rẹ̀—òun yíò kúnlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọ yíò sì ké pe Bàbá nínú àdúrà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wipe:

77 Áà Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àwa béèrè lọ́dọ̀ rẹ ní orúkọ Ọmọ rẹ, Jésù Krístì, láti súre àti lati yà àkàrà yìí sí mímọ́ sí ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹnití ó ní ìpín nínú rẹ̀, kí wọ́n lè jẹ ní ìrántí ti ara Ọmọ rẹ, àti kí wọ́n jẹ́rìí sí ọ, Áà Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, pé wọ́n fẹ́ láti gba orúkọ Ọmọ rẹ sí órí wọn, àti láti rántí rẹ̀ nígbàgbogbo àti láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ èyítí ó ti fi fún wọn; pé kí wọn lè ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn nígbàgbogbo. Àmín.

78 Ọ̀nà tí a fi nṣe ìpínfúnni wáìnì—òun yíò mú ago náà pẹ̀lú, yíò sì wipe:

79 Áà Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àwa béèrè lọ́dọ̀ rẹ ní orúkọ Ọmọ rẹ, Jésù Krístì, láti súre àti lati ya wáìnì yìí sí mímọ́ sí ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹnití ó mu nínú rẹ̀, pé kí wọ́n lè ṣeé ní ìrántí ti ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ, èyítí a ta sílẹ̀ fún wọn; pé kí wọ́n lè jẹrìí sí ọ, Áà Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, pé wọ́n nrántí rẹ̀ nígbàgbogbo, pé kí wọn lè ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn. Àmín.

80 Èyíkéyìí ọmọ ìjọ ti Krístì tí ó bá nṣe ìrékọjá, tàbí tí a bá mú nínú ìṣubú kan, ni a ó ṣe sí gẹ́gẹ́bí àwọn ìwé mímọ́ ṣe darí.

81 Yíò jẹ́ ojúṣe onírúurú awọn ìjọ, tí àpapọ̀ wọ́n jẹ́ ìjọ ti Krístì, láti rán ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn olùkọ́ wọn láti wà ní ibi onírúurú àwọn àpéjọpọ̀ síṣe lati ọwọ́ àwọn alàgbà ìjọ,

82 Pẹ̀lú títò lẹ́sẹẹsẹ àwọn orúkọ ti onírúurú àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n ti ṣe ara wọn ní ọ̀kan pẹ̀lú ìjọ lẹ́hìn àpéjọpọ̀ tí ó kẹ́hìn; tàbí fífi ránṣẹ́ láti ọwọ́ àwọn àlùfáà kan; kí títò lẹ́sẹẹsẹ dáradára kan ti gbogbo awọn orúkọ inú ìjọ pátápátá baà le wà ní pípamọ́ nínú ìwé kan lati ọwọ́ ọ̀kan nínú àwọn alàgbà, ẹnikẹ́ni tí àwọn alàgbà yókù lè yàn láti àkókò dé àkókò;

83 Àti bákannáà, bí a bá ti lé ẹnikẹ́ni kúrò nínú ìjọ, kí á lè pa orúkọ wọn rẹ́ nínú ìwé àkọsílẹ̀ awọn orúkọ gbogbogbòò ti ìjọ.

84 Gbogbo ọmọ ìjọ tí wọ́n bá nkúrò nínú ìjọ ní ibití wọ́n ngbé, tí wọ́n bá nlọ sí ìjọ tí a kò ti mọ̀ wọ́n, wọ́n lè gba ìwé ṣíṣe ẹ̀rí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ dáradára ati tí ó nṣe déédé, ìwé ẹ̀rí èyítí ó lè ní ìfọwọ́sí èyíkéyìí alàgbà tàbí àlùfáà kan, bí ọmọ ìjọ tí ó fẹ́ gba ìwé ẹ̀rí náà bá jẹ́ ẹni mímọ̀ fún alàgbà tàbí àlùfáà náà, tàbí kí àwọn olùkọ́ni tàbí àwọn díakonì ìjọ fi ọwọ́ sí i.