Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 27


Ìpín 27

Ìfihàn tí a fún Wòlíì Joseph Smith, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù Kẹ́jọ 1830. Ní ìmúrasílẹ̀ fún ìsìn àwọn olùfọkànsìn níbití a ó ti pín oúnjẹ alẹ́ Olúwa ti àkàrà àti wáínì fúnni, Joseph jade lọ láti wá wáínì. Ìránṣẹ́ ọ̀run kan pàdé rẹ̀ ó sì gba ìfihàn yìí, apákan èyítí a kọ ní àkókò náà àti ìyókù ni a kọ nínú Oṣù Kẹsãn tí ó tẹ̀lé e. Omi ni a nlò nísisìyí dípò ọtí wáínì nínú ìsìn ara Olúwa nínú Ìjọ.

1–4, Àwọn àmì tí a ó máa lò ní ṣíṣe àbápín nínú ara Olúwa ni a gbé kalẹ̀; 5–14 Krístì pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ láti gbogbo àwọn ìgbà ìríjú níláti bápín nínú ara Olúwa; 15–18, Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀.

1 Ẹ tẹ́tí sí ohùn Jésù Krístì, Olúwa yín, Ọlọ́run yín, àti Olùràpadà yín, ẹnití ọ̀rọ̀ rẹ̀ yè tí ó sì ní agbára.

2 Nítorí, ẹ kíyèsíi, mo wí fún yín, pé kò já mọ́ nkan ohun tí ẹ̀yin yíò jẹ tàbí mu nígbàti ẹ̀yin bá jẹ ounjẹ alẹ́ Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin ṣeé pẹ̀lú fífi ojú sí ògo ti èmi nìkan—ní síṣe ìrántí nínú Bàbá ara mi èyítí a fi lélẹ̀ fún yín, àti ẹ̀jẹ̀ mi èyítí a ta sílẹ̀ fún ìmúkúrò ẹṣẹ̀ yín.

3 Nítorínáà, òfin kan ni mo fi fún yín, pé ẹ̀yin kì yíò ra ọtí wáìnì tàbí ohun mímu líle lati ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá yín;

4 Nítorínáà, ẹ̀yin kì yíò bá pín nínú èyíkéyìí bí kò ṣepé a sọọ́ di titun ní ààrin yín; bẹ́ẹ̀ni, nínú ìjọba Bàbá mi yìí èyítí a ó kọ́ sí orí ilẹ̀ ayé.

5 Kíyèsíi, èyí jẹ́ ọgbọ́n inú mi; nítorínáà, ẹ máṣe jẹ́ kí ó yà yín lẹ́nu, nítorí wákàtí náà dé tán tí èmi yíò mu nínú èso àjàrà náà pẹ̀lú yín ní orí ilẹ̀ ayé, àti pẹ̀lú Mórónì, ẹnití èmi ti rán sí yín láti fi Ìwé ti Mọ́mọ́nì hàn, tí ó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ayérayé mi nínú, fún ẹnití èmi ti kó àwọn kọ́kọ́rọ́ àkọsílẹ̀ ti ẹ̀ka Efraimu;

6 Àti bákannáà pẹ̀lú Elíasì, ẹnití èmi ti kó àwọn kọ́kọ́rọ́ tí mímúwá sí ìmúṣẹ ti ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo fún, èyítí a ti sọ lati ẹnu gbogbo àwọn Wòlíì mímọ́, láti ìgbàtí ayé ti bẹ̀rẹ̀, nípa àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn.

7 Àti bákannáà Johánnù ọmọkùnrin Sakariah, Sakariah èyítí òun (Elíasì) bẹ̀wò tí ó sì ṣe ìlérí fún pé òun yíò bí ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ yíò sì jẹ́ Jòhannù, àti pé ọmọ náà yíò kún fún ẹ̀mí Elíásì;

8 Jòhánnù èyítí èmi ti rán sí yín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi, Joseph Smith Kékeré, àti Oliver Cowdery, láti yàn yín sí ipò oyè àlùfáà àkọ́kọ́ èyítí ẹ̀yin ti gbà, kí a lè pè yín kí a sì yàn yín àní bíi ti Áarónì;

9 Àti bákannáà Elijah, sí ọwọ́ ẹnití èmi fi àwọn kọ́kọ́rọ́ agbára lé láti yí ọ̀kàn àwọn baba sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baba, kí gbogbo ayé má baà gba ìkọ̀lù ègún;

10 Àti bákannáà pẹ̀lú Josẹfù àti Jakọbù, àti Isakì, àti Ábrahamù, àwọn bàbánlá yín, nípasẹ̀ àwọn tí àwọn ìléri wọ̀nyí dúró;

11 Àti bákannáà pẹ̀lú Mikaẹlì, tàbí Adamù, bàbá gbogbo ènìyàn, ọmọ aládé fún gbogbo ènìyàn, arúgbó ọjọ́.

12 Àti bákannáà pẹ̀lú Péterù, Jákọ́bù, àti Johannù, àwọn tí mo ti rán sí yín, nípasẹ̀ àwọn tí mo ti yàn yín tí mo sì ti fi ìdì yín múlẹ̀ láti di àpóstélì, àti ẹlẹ́rìí pàtàkì ti orúkọ mi, ti wọ́n sì mú kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín lọ́wọ́ ati awọn ohun kannáà èyíti mo ti fi hàn fún wọn;

13 Àwọn ẹnití mo ti fi àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba mi fún, àti ìgbà ìríjú ìhìnrere kan fún àwọn àkókò ìkẹhìn; àti fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò náà, nínú èyí tí èmi yíò kó ohun gbogbo jọ pọ̀ sí ọ̀nà kan, àti èyí tí ó nbẹ ní ọ̀run, àti àwọn tí wọ́n wà ní ayé;

14 Àti bákannáà pẹ̀lú gbogbo àwọn wọnnì tí Bàbá mi ti fi fún mi láti inú ayé wá.

15 Nítorínáà, ẹ gbé ọkàn yín sókè kí ẹ sì yọ̀, àti kí ẹ di àmùrè yín, kí ẹ sì gbé gbogbo ìhámọ́ra mi wọ̀, kí ẹ̀yin baà lè dojúkọ ọjọ́ ibi, nígbàtí ẹ̀yin bá ti ṣe ohun gbogbo, kí ẹ̀yin baà lè dúró.

16 Ẹ dúró, nítorínáà, lẹ́hìn tí ẹ ti fi àmùrè di ẹ̀gbẹ́ yín pẹ̀lú òtítọ́, tí ẹ sì ti di àwo-ìgbàyà ti òdodo, ti ẹ sì ti wọ ẹsẹ̀ yin ní bàtà pẹ̀lú ìmúra ìhìnrere àlãfíà, èyítí mo ti rán àwọn ángẹ́lì mi láti fi fún yín;

17 Ẹ mú asà ìgbàgbọ́ nípa èyítí ẹ̀yin yío lè pa iná gbogbo àwọn ọfà iná ẹni ibi nì;

18 Ẹ gbé àṣíborí ìgbàlà, àti idà Ẹ̀mí mi, èyítí èmi yíò tú jade sí orí yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi hàn fún yín, àti pé kí ẹ fi ẹnu kò nípa ohun gbogbo tí ẹ̀yin bá béèrè ní ọwọ́ mi, àti pé kí ẹ̀yin ó jẹ́ olódodo títí èmi yíò fi dé, àti pé a ó gbà yín sókè, pé ní ibití emi gbé wà kí ẹ̀yin lè wà bákannáà.