Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 35


Ìpín 35

Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith àti Sidney Rigdon ní tàbí ní ẹ̀bá Fayette, New York, 7 Oṣù Kejìlá 1830. Ní àkókò yìí, Wòlíì nṣiṣẹ́ ní ojojúmọ́ nípa títúmọ̀ Bíbélì. Ìṣẹ́ ìtumọ̀ yìí ti tètè bẹ̀rẹ̀ ní oṣù Kẹfà 1830, Oliver Cowdery àti John Whitmer sì ti ṣiṣẹ́ bíi akọ̀wé. Níwọ̀n ìgbàtí a ti pè wọ́n nísìsìyí sí àwọn iṣẹ́ míràn, Sidney Rigdon ni a pè nípasẹ̀ ìgbanisíṣẹ́ àtọ̀runwá láti ṣe iṣẹ́ akọ̀wé Wòlíì nínu iṣẹ́ yìí (wo ẹsẹ 20). Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ ìsaájú sí àkọsílẹ̀ fún ìfihàn yìí, ìtàn ti Joseph Smith sọ pé: “Ní Oṣù Kejìlá Sidney Rigdon wá (láti Ohio) láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa, àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Edward Partridge…Ní kété lẹ́hìn dídée àwọn arákùnrin méjì wọ̀nyí, báyìí ni Olúwa sọ.”

1–2 Bí àwọn ènìyàn ṣe lè di ọmọ Ọlọ́run; 3–7, Sidney Rigdon ni a pè láti ṣe ìrìbọmi àti láti fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ fúnni; 8–12, Àwọn àmi àti iṣẹ́ ìyanu ṣeéṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́; 13–16, Àwọn ìránṣẹ́ Olúwa yíò yà àwọn orílẹ̀-èdè sọ́tọ̀ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́; 17–19, Joseph Smith ní àwọn kọ́kọ́rọ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀; 20–21, Àwọn àyànfẹ́ yíò dúró de ọjọ́ bíbọ̀ Olúwa; 22–27, Israẹlì yíò di gbígbàlà.

1 Ẹ tẹ́tí sí ohùn Olúwa Ọlọ́run yín, àní Alfà àti Òmégà, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, ẹnití ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà yípo ayérayé, ọ̀kannáà lónìí bíi lánàá, àti títí láéláe.

2 Èmi ni Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ẹnití a kàn mọ́ àgbélẽbu fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé, àní iye àwọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú orúkọ mi, pé kí wọ́n ó lè di ọmọ Ọlọ́run, àní ọ̀kan ṣoṣo nínú mi gẹ́gẹ́bí èmi ṣe jẹ́ ọ̀kan nínú Bàbá, bí Bàbá ṣe jẹ́ ọ̀kan nínú mi, kí á lè jẹ́ ọ̀kan náà.

3 Kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ìránṣẹ́ mi Sydney, èmi ti bojúwò ọ́ àti àwọn iṣẹ́ rẹ. Èmi ti gbọ́ àwọn àdúrà rẹ, èmi sì ti pèsè rẹ sílẹ̀ fún iṣẹ́ nlá kan.

4 Ìbùkún ni fún ọ, nítorí ìwọ yíò ṣe àwọn nkan nlá. Kíyèsíi a rán ọ jade, àní bíi Johannù, láti pèsè ọ̀nà sílẹ̀ níwájú mi, àti níwájú Èlíjah ẹ̀nití yíò wá, tí ìwọ kò sì mọ̀ ọ́.

5 Ìwọ ti rìbọmi nípa omi sí ironúpìwàdà, ṣùgbọ́n wọn kò gba Ẹ̀mí Mímọ́;

6 Ṣùgbọ́n nísisìyí èmi fi òfin kan fún ọ, pé ìwọ yío rìbọmi nípa omi, wọn yíò sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ nípa ìgbọ́wọ́lé ní orí, àní gẹ́gẹ́bí àwọn àpóstélì ìgbàanì.

7 Àti pé yíò sì ṣe tí iṣẹ́ nlá kan yíò wà ní ilẹ̀ náà, àní lààrin àwọn Kèfèrí, nítorí àìmọ̀ wọn àti àwọn ohun ìríra wọn ni a ó fi hàn ní ojú gbogbo ènìyàn.

8 Nítorí èmi ni Ọlọ́run, ọwọ́ mi kò sì kúrú; èmi yíò sì fi àwọn iṣẹ́ ìyanu, àwọn àmì, àti àwọn ìyanu hàn sí gbogbo àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú orúkọ mi.

9 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè ní orúkọ mi pẹ̀lú ìgbàgbọ́, wọn yíò lé àwọn ẹ̀mí èṣù jade; wọn yíò mú aláìsàn lára dá; wọn yíò mú kí àwọn afọ́jú gba ìríran wọn, àti àwọn adití kí wọ́n ó gbọràn, àti àwọn odi kí wọn ó sọ̀rọ̀, àti àwọn arọ kí wọn ó rìn.

10 Àti pé àkókò náà yára dé kánkán tí a ó fi àwọn ohun nlá hàn jáde fún àwọn ọmọ ènìyàn;

11 Ṣùgbọ́n láì sí ìgbàgbọ́ ni a kì yíò fi ohunkóhun hàn jáde bíkòṣe ìsọdahoro ní orí Babilónì, ọ̀kannáà èyítí ó ti mú kí gbogbo orílẹ̀-ède ó mu nínú ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀.

12 Àti pé kò sí ẹnití ó nṣe rere bíkòṣe kìkì àwọn tí wọ́n ti ṣetán láti gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi, èyítí èmi ti rán jáde sí ìran yìí.

13 Nítorínáà, mo pe àwọn ohun aláìlágbára ayé, àwọn wọnnì tí kò ní ìmọ̀ àti tí a kórĩra, láti ṣe ìyàsọ́tọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè nípa agbára Ẹ̀mí mi;

14 Àti apá wọn yíò jẹ́ apá mi, èmi yíò sì jẹ́ apata àti asà wọn; èmi yíò sì dì àmùrè sí ẹ̀gbẹ́ wọ́n, àwọn yíò sì ja bíi akọni fún mi; àti àwọn ọ̀tá wọn yíò wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ wọn; èmi yíò sì jẹ́ kí idà ó wá sílẹ̀ nítorí wọn, àti nípa iná irunú mi ni èmi yíò pa wọ́n mọ́.

15 Àti pé a ó wàásù ìhìnrere sí àwọn òtòsì àti àwọn ọlọ́kàn tutu, wọn yíò sì máa fi ojú sọ́nà fún àkókò bíbọ̀ mi, nítorí ó ti súnmọ́ itòsí—

16 Àti pé wọn yíò kọ́ ẹ̀kọ́ nínú òwe igi ọ̀pọ̀tọ́, nítorí àní nísisìyí àkókò ẹ̀rùn ti súnmọ́ ìtosí.

17 Àti pé èmi ti rán ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi jade lati ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph; àti nínú àìní agbára ni èmi ti bùkún fún un.

18 Àti pé èmi ti fún un ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjìnlẹ̀ àwọn ohun wọnnì èyítí a ti fi èdìdí dì, àní àwọn ohun tí wọn ti wà láti ìpilẹ̀sẹ̀ ayé, àti àwọn ohun tí wọn yíò wá láti àkókò yìí títí di àkókò bíbọ̀ mi, bí òun bá dúró nínú mi, bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ẹlòmíràn ni èmi yíó fi sí ipò rẹ̀.

19 Nítorínáà, máa ṣe àmójútó rẹ̀ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ó má baà kùnà, a ó sì fi fúnni láti ọwọ́ Olùtùnú, Ẹ̀mí Mímọ̀ náà, ẹnití ó mọ ohun gbogbo.

20 Àti pé òfin kan ni mo fi fún ọ—pé kí ìwọ kọ ìwé fún un; a ó sì fi àwọn ìwé mímọ́ fúnni, àní bí wọ́n ṣe wà ní oókan àyà mi, fún ìgbàlà àwọn àyànfẹ́ mi;

21 Nítorí wọn yíò gbọ́ ohùn mi, wọn yíò sì rí mi, wọn kì yíò sì sùn, àti pé wọn yíò dúró de ọjọ́ bíbọ̀ mi; nítorí a ó sọ wọ́n di mímọ́, àní bí èmi náà ṣe jẹ́ mímọ́.

22 Àti nísisìyí mo wí fún ọ, dúró tì í, òun yíò sì rìn ìrìnàjò pẹ̀lú rẹ; má ṣe fi í sílẹ̀, àti dájúdájú gbogbo ohun wọ̀nyí ni yíò wá sí ìmúṣẹ.

23 Àti pé níwọ̀nbí ìwọ kò bá kọ ìwé, kíyèsíi, a ó fi fún un láti sọ àsọtẹ́lẹ̀; àti pé ìwọ yíò wàásù ìhìnrere mi ìwọ yíò sì pe àwọn wòlíì mímọ́ láti fi ìdí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀, gẹ́gẹ́bí a ó ṣe fi fún un.

24 Ẹ pa gbogbo àwọn òfin àti májẹmú mi mọ́ nípa èyí tí ẹ̀yin ní ojúṣe; èmi yíò sì mú kí àwọn ọ̀run ó mì fún rere yín, àti Sátánì yíò sì wárìrì, Síónì yíò sì yọ̀ ní orí àwọn òkè yíò sì gbilẹ̀;

25 Àti pé a ó gba Israẹlì là nigbàtí àkókò bá tó ní ojú mi; àti nípa àwọn kọ́kọ́rọ́ èyítí mo ti fi fúnni ni a ó darí wọn, a kì yíò sì dà wọ́n láàmú mọ́ rárá.

26 Ẹ gbé ọkàn yín sókè kí ẹ sì yọ̀, ìràpadà yín ti súnmọ́ itòsí.

27 Ẹ máṣe bẹ̀rù, agbo kékeré, ìjọba jẹ́ tiyín títí tí èmi yíò fi dé. Kíyèsíi, èmi nbọ̀ kánkan. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.