Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 38


Ìpín 38

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ni Fayette, New York, 2 Oṣù Kínní 1831. Àkókò yìí jẹ́ ti ìpàdé àpéjọpọ̀ tí Ìjọ.

1–6, Krístì dá ohun gbogbo; 7–8, Òun wà ní ààrin àwọn Èniyàn Mímọ́ Rẹ̀, tí wọn yíò ríi láìpẹ́; 9–12, Gbogbo ẹran ara ni wọ́n ti díbàjẹ́ níwájú Rẹ̀; 13–22, Òun ti fi ilẹ̀ ìlérí kan pamọ́ fún àwọn Ẹ̀ni Mímọ́ Rẹ̀ ní àkókò yìí àti ní ayérayé; 23–27, A pàṣẹ fún àwọn Ẹni Mímọ́ láti wà ní ọ̀kan àti kí wọn ó sì ka ara wọn sí bíi arákùnrin; 28–29, A sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ogun; 30–33, Àwọn Ẹni Mímọ́ ni a ó fún ní agbára láti òkè wá àti lati jáde lọ lààrin àwọn orílẹ̀-èdè; 34–42, A pàṣẹ fún Ijọ lati ṣe ìtọ́jú àwọn tálákà àti aláìní àti lati lépa àwọn ọrọ̀ ti ayérayé.

1 Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí, àní Jésù Krístì, Èmi Ni Nlá náà, Alfà àti Omégà, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, ẹni kannáà tí ó bojúwo fífẹ̀ pẹ́ títí ti ayérayé, àti gbogbo àwọn ogun ọ̀run ti séràfù, kí á tó ṣe ẹ̀dá ayé;

2 Ẹni kannáà tí ó mọ ohun gbogbo, nítorí ohun gbogbo wà ní iwájú mi;

3 Èmi ni ẹni kannáà tí ó sọ̀rọ, tí a sì ṣe ẹ̀dá ayé, àti pé ohun gbogbo wá nípa mi.

4 Èmi ni ẹni kannáà tí ó ti gba Síónì ti Énọkù sí oókan àyà mi; àti lõtọ́, ni mo wí, àní iye àwọn tí wọn ti gbàgbọ́ nínú orúkọ mi, nítorí èmi ni Krístì, àti ní orúkọ mi, nípa agbára ẹ̀jẹ̀ náà èyí tí mo ti ta sílẹ̀, ni èmi ti bẹ̀bẹ̀ níwájú Baba fún wọn.

5 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, ìyókù àwọn ènìyàn búburú ni èmi ti fi pamọ́ nínú àwọn ẹ̀wọ̀n òkùnkùn títí di ìdàjọ́ ọjọ́ nlá náà, èyítí yíò wá ní òpin ilé ayé;

6 Àti bẹ́ẹ̀ni èmi yíò mú kí àwọn ènìyàn búburú ó wà ní ìpamọ́, tí wọn kò gbọ́ ohùn mi ṣùgbọ́n tí wọ́n sé ayà wọn le, àti pé ègbé, ègbé, ègbé, ni ìparun wọn.

7 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín pé ojú mi wà ní ara yín. Èmi wà lààrin yín ẹ̀yin kò sì lè rí mi;

8 Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà dé tán tí ẹ̀yin yíò rí mi, tí ẹ ó sì mọ̀ pé èmi ni; nítorí a ó fa ìbòjú òkùnkùn ya láìpẹ́, àti pé ẹnikẹ́ni tí a kò bá sọ di mímọ́ kì yíò lè dúró ní ọjọ́ náà.

9 Nitorí-èyí, ẹ di àmùrè yín kí ẹ sì múra sílẹ̀. Kíyèsíi, tiyín ni ìjọba náà, ọ̀tá kì yío sì borí.

10 Lõtọ́ ni èmi wí fún yín, ẹ̀yin mọ́, ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo yín; kò sì tún sí ẹlòmíràn mọ́ tí inú mi dùn sí gidigidi.

11 Nítorí gbogbo ẹran ara ni ó ti díbàjẹ́ ní iwájú mi; agbára òkùnkùn sì borí ní orí ilẹ̀ ayé, ní ààrin àwọn ọmọ ènìyàn, ní iwájú gbogbo àwọn ogun ọ̀run—

12 Èyítí ó mú kí ìdákẹ́rọ́rọ́ ó jọba, gbogbo ayérayé sì ní ìrora, àwọn ángẹ́lì sì ndúró fún àṣẹ nlá láti kórè ayé lulẹ̀, láti kó àwọn èpò jọ pé kí a lè jó wọn; àti, kíyèsíi, àwọn ọ̀tá ti parapọ̀.

13 Àti nísisìyí èmi fi ohun ìjìnlẹ̀ kan hàn yín, ohun kan tí a ní nínú àwọn ìyàrá ìkọ̀kọ̀, láti mú wá sí ìmúṣẹ àní ìparun yín ni àkókò tí ó tọ́, ẹ̀yin kò sì mọ̀ ọ́;

14 Ṣùgbọ́n nísisìyí èmi sọ ọ́ fún yín, àti pé ìbùkún ni fún yín, kìí ṣe nítorí àìṣedéédé yín, tàbí ọkàn àìgbàgbọ́ yín; nítorí lõtọ́ díẹ̀ nínú yín ti jẹ̀bi ní iwájú mi, ṣùgbọ́n èmi yíò jẹ́ alàánú sí àìní agbára yín.

15 Nítorínáà, ẹ jẹ́ alágbára láti ìgbà yìí lọ; ẹ máṣe bẹ̀rù, nítorí tiyín ni ìjọba náà.

16 Àti fún ìgbàlà yín ni èmi fi òfin kan fún yín, nítorí èmi ti gbọ́ àwọn àdúrà yín, àwọn tálákà sì ti ráhùn ní iwájú mi, àti pé àwọn ọlọ́rọ̀ ni èmi ti dá, gbogbo ẹran ara sì jẹ́ ti èmi, àti pé èmi kìí ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni.

17 Àti pé èmi ti mú kí ilẹ̀ ayé ní ọrọ̀, sì kíyèsíi ó jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi, nítorínáà, lẹ́ẹ̀kansíi èmi yíò dúró ní orí rẹ̀.

18 Àti pé èmi nawọ́ jáde mo sì fi àánú fún yín ní àwọn ọrọ̀ tí ó tóbi, àní ilẹ̀ ìlérí kan, ilẹ̀ tí ó nsàn fún wàrà àti oyin, ní orí èyítí kì yíò sí ègún nígbàtí Olúwa yíò wá.

19 Àti pé èmi yíò fi fún yín bíi ilẹ̀ ìní yín, bí ẹ̀yin bá lépa rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín.

20 Àti pé èyí yíò jẹ́ májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, ẹ̀yin yíò ní i fún ilẹ̀ ìní yín, àti fún ìní àwọn ọmọ yín títí láéláé, níwọ̀n ìgbàtí ayé yíò wà, ìwọ yíò sì tún ní i lẹ́ẹ̀kansíi ní ayérayé, tí kì yíò kọjá lọ mọ́.

21 Ṣùgbọ́n, lõtọ́ ni mo wí fún yín pé ní àkókò kan, ẹ̀yin kì yíò ní ọba tàbí aláṣẹ, nítorí èmi yíò jẹ́ Ọba yín àti olùṣọ́ fún yín.

22 Nítorínáà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí ẹ sì tẹ̀lé mi, ẹ̀yin yíò sì di òmìnira ènìyàn, àti pé ẹ̀yin kì yíò ní àwọn òfin ṣùgbọ́n àwọn òfin ti èmi nígbàtí mo bá padà dé, nítorí èmi ni yíò máa ṣe òfin fún yín, àti pé kínni ó lè dá ọwọ́ mi dúró?

23 Ṣùgbọ́n, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ máa kọ́ ara yín ní ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́bí ipò èyítí èmi ti yàn yín sí;

24 Àti pé jẹ́ kí olúkúlùkù ó ka arákùnrin rẹ̀ sí gẹ́gẹ́bí ara rẹ̀, kí wọ́n ó sì hu ìwà rere àti mímọ́ ní iwájú mi.

25 Àti lẹ́ẹ̀kansíi mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù ó ka arákùnrin rẹ̀ sí gẹ́gẹ́bí ara rẹ̀.

26 Nítorí taani nínú yín tí yíò ní àwọn ọmọkùnrin méjìlá, tí òun kì yíò fi ọ̀wọ̀ fúwọn, tí wọ́n sì nṣiṣẹ́ fún un pẹ̀lú ìgbọràn, àti tí òun yíò sì sọ fún ọ̀kan: Wọ aṣọ dáradára kí o sì jókòó ní ìhín yìí; Àti sí òmíràn: Wọ àkísà kí o sì jókòó sí ọ̀hún—àti kí òun sì wo àwọn ọmọ náà kí ó wí pé mo ṣe òdodo?

27 Kíyèsíi, èyí ni mo ti fún yín bí òwe, ó sì jẹ́ àní bí èmi ti rí. Mo wí fún yín, ẹ jẹ́ ọ̀kan; bí ẹ̀yin kò bá sì jẹ́ ọ̀kan ẹ̀yin kìí ṣe tèmi.

28 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín pé ọ̀tá náà tí ó wà nínú àwọn ìyàrá ìkọ̀kọ̀ nlépa àwọn ẹ̀mí yín.

29 Ẹ̀yin ngbúro ogun ní àwọn orílẹ̀-èdè jíjìnà, ẹ̀yin sì wí pé àwọn ogun nlá yíò bẹ́ sílẹ̀ láìpẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè jíjìnà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ ọkàn àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ tiyín.

30 Èmi sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún yín nítorí àwọn àdúrà yín; nítorínáà, ẹ fi ọgbọ́n sí ìṣúra nínú oókan àyà yín, bí bẹ́ẹ̀kọ́ ìwà búburú àwọn ènìyàn yíò fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn fún un yín nípa ìwà búburú wọn, ní ọ̀nà tí yíò sọ̀rọ̀ sí etí yín pẹ̀lú ohùn tí ó pariwo ju èyí tí yíó mi ilẹ̀ ayé lọ; ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá múrasílẹ̀ ẹ̀yin kì yíò bẹ̀rù.

31 Àti pé kí ẹ̀yin lè bọ́ lọ́wọ́ agbára ọ̀tá, kí a sì kó yín jọ sí ọ̀dọ̀ mi bíi olódodo ènìyàn, láìní àbùkù àti tí kò ní ẹ̀bi—

32 Nítorínáà, fún ìdí yìí ni èmi ṣe fi òfin kan fún yín pé kí ẹ lọ sí Ohio; àti níbẹ̀ ni èmi yíò fún yín ní òfin mi; níbẹ̀ ni a ó sì bùn yín ní ẹ̀bùn agbára láti òkè wá;

33 Àti pé láti ibẹ̀ lọ, ẹnikẹ́ni tí èmi bá fẹ́ yíò jade lọ lààrin àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo, a ó sì sọ fún wọn ohun tí wọn yíò ṣe; nítorí mo ní iṣẹ́ nlá kan tí mo tò jọ ní ibi ìpamọ́, nítorí a ó gbà Isráẹlì là, èmi yíò sì ṣe amọ̀nà wọn sí ibikíbi tí mo fẹ́, kò sì sí agbára tí yíò lè dá ọwọ́ mi dúró.

34 Àti nísisìyí, èmi fi òfin kan fún ìjọ ní àwọn agbègbè wọ̀nyí, pé àwọn ènìyàn kan láàrin wọn ni a ó yàn, a ó sì yàn wọ́n nípa ohùn ìjọ;

35 Àti pé wọn yíò kíyèsí àwọn tálákà àti aláìní, wọn yíò sì ṣe àmójútó ìrọ̀rùn wọn pé kí wọn má baà jìyà; kí á sì rán wọn jáde lọ sí ibi tí mo ti pàṣẹ fún wọn;

36 Èyí ni yíò sì jẹ́ iṣẹ́ wọn, láti ṣe àkóso àwọn ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ ohun ìní ìjọ yìí.

37 Àti pé àwọn tí wọ́n bá ní àwọn oko tí a kò lè tà, ẹ jẹ́kí wọ́n fi í sílẹ̀ tàbí kí wọn ó fi yá bí ó bá ṣe dára lójú wọn.

38 Ẹ ríi pé a pa ohun gbogbo mọ́; àti nígbàtí a bá bùn àwọn ènìyàn ní ẹ̀bùn agbára láti òkè wá, tí a sì rán wọn jade, gbogbo ohun wọ̀nyí ni a ó kó jọ sí oókan àyà ti ìjọ.

39 Àti pé bí ẹ̀yin bá lépa àwọn ọrọ̀ èyí tí ó jẹ́ ìfẹ́ Baba láti fi fún yín, ẹ̀yin yíò jẹ́ ọlọ́rọ̀ júlọ lààrin àwọn ènìyàn, nitorí ẹ̀yin yíò ní àwọn ọrọ̀ ti ayérayé; ó sì gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀ pé àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi láti fi fúnni; ṣùgbọ́n ẹ sọ́ra fún ìgbéraga, bí bẹ́ẹ̀kọ́ ẹ̀yin ó dàbíi àwọn ara Néfì ìgbàanì.

40 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, èmi fún yín ní òfin kan, pé olúkúlùkù ènìyàn, àti alàgbà, àlùfáà, olùkọ́ni, àti bákannáà ọmọ ìjọ, kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú agbára rẹ̀, pẹ̀lú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, láti múra àti láti ṣe àṣeyọrí àwọn ohun tí mo ti pa láṣẹ.

41 Ẹ sì jẹ́kí ìwàásù yín ó jẹ́ ohùn ìkìlọ̀, olúkúlùkù sí aládùúgbò rẹ̀, ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti ní ọkàn tutu.

42 Kí ẹ sì jade lọ kúrò lààrin àwọn ènìyàn búburú. Ẹ gba ara yín là. Ẹ jẹ́ aláìlẽrí tí ó ngbé ohun èlò Olúwa. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.