Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 49


Ìpín 49

Ìfihàn tí a fifúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Sydney Rigdon, Parley P. Pratt, àti Leman Copley, ní Kirtland, Ohio, 7 Oṣù Karũn 1831. Leman Copley ti tẹ́wọ́gba ìhìnrere ṣùgbọ́n síbẹ̀ òun tún dìmọ́ díẹ̀ nínú àwọn ìlànà ẹ̀kọ́ ti Shakers (United Society of Believers in Christ’s Second Appearing), nínú èyí tí òun ti wà tẹ́lẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn ohun ìgbàgbọ́ ti àwọn Shakers náà ni pé Bíbọ̀ Krístì Ẹ̀kejì ti wáyé àti pé Ó fi ara hàn ní ẹ̀yà obìnrin, Ann Lee. Wọn kò ka ìrìbọmi nípa omi sí pàtàkì. Wọ́n kọ ìgbeyàwó sílẹ̀ wọ́n sì gbàgbọ́ nínú ìgbé ayé àìgbéyàwó àti àìsí ìbálòpọ̀ rárá takọtabo. Àwọn Shakers kan bákannáà ka ẹran jíjẹ sí èèwọ̀. Ní kíkọ ọ̀rọ̀ ìṣaájú sí ìfihàn yìí, ìtàn ti Joseph Smith sọ pé, “Kí á lè ní àgbọ́yé [kan] ti ó péye síi nípa kókó ọ̀rọ̀ náà, mo béèrè lọ́wọ́ Olúwa, mo sì gba àtẹ̀lé yìí.” Ìfihàn náà tako díẹ̀ lára àwọn ìpìlẹ̀ èrò àwọn ẹgbẹ́ Shakers. Àwọn arákùnrin tí a ti dárúkọ ṣíwájú mú ẹ̀dà ìfihàn náà lọ sí àwùjọ àwọn Shakers (nítòsí Cleveland, Ohio) wọ́n sì kàá fún wọn pátápátá, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ ọ́.

1–7, Ọjọ́ àti wákàtí tíi bíbọ̀ Krístì yíò jẹ́ àìmọ̀ títí tí Òun yíò fi dé; 8–14, Àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà, kí wọ́n gba ìhìnrere gbọ́, kí wọ́n ó sì gbọ́ràn sí àwọn ìlànà láti jèrè ìgbàlà; 15–16, Ìgbéyàwó jẹ́ ohun tí Ọlọ́run ti yàn; 17–21, Ẹran jíjẹ jẹ́ ohun tí a fi àṣẹ sí; 22–28, Síónì yíò gbilẹ̀ àti pé àwọn ará Lámánì yíò tanná bí òdòdó ṣaájú Bíbọ̀ Ẹ̀kejì.

1 Ẹ fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi Sidney, àti Parley, àti Leman; nítorí kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé mo fún yín ní òfin kan pé ẹ̀yin yíó lọ wàásù ìhìnrere mi èyí tí ẹ̀yin ti gbà, àní bí ẹ̀yin ṣe gbà á, sí àwọn Shakers.

2 Ẹ kíyèsíi, mo wí fún yín, pé wọ́n fẹ́ láti mọ òtítọ́ ní apákan, ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo rẹ̀, nítorí wọn kìí ṣe olõtọ́ níwájú mi wọ́n sì gbọdọ̀ fi dandan ronúpìwàdà.

3 Nítorínáà, èmi rán yín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi Sidney àti Parley, láti wàásù ìhìnrere sí wọn.

4 A ó sì yàn ìránṣẹ́ mi Leman fún iṣẹ́ yìí, kí òun ó lè ṣe àṣàrò pẹ̀lú wọn, kìí ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òun ti gbà lati ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí èyí tí a ó kọ́ ọ láti ọwọ́ yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi; àti nípa ṣíṣe èyí èmi yíò bùkún fún un, bí bẹ́ẹ̀kọ́ òun kì yíò ṣe rere.

5 Báyìí ni Olúwa wí; nítorí èmi ni Ọlọ́run, mo sì ti rán Ọmọ Bíbí mi Kan Ṣoṣo wá sínú ayé fún ìràpadà aráyé, mo sì ti pàṣẹ pé ẹni tí ó bá gbà á ni a ó gbàlà, àti pé ẹni tí kò bá gbà á ni a ó dá lẹ́bi—

6 Wọ́n sì ti ṣe sí Ọmọ Ènìyàn àní bí wọ́n ṣe fẹ́; Òun sì ti mú agbára rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ògo rẹ̀, àti pé nísisìyí Ó njọba nínú àwọn ọ̀run, òun ó sì máa jọba títí tí yíò fi sọ̀kalẹ̀ sí orí ilẹ̀ ayé láti fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀, àkókò èyí tí ó ti súnmọ́ itòsí—

7 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, ti sọ ọ́; ṣùgbọ́n wákàtí náà àti ọjọ́ náà ẹnikẹ́ni kò mọ̀, bóyá àwọn ángẹ́lì ní ọ̀run, bẹ́ẹ̀ni wọn kì yíò mọ̀ títí tí òun yíò fi dé.

8 Nítorínáà, èmi fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ó ronúpìwàdà, nítorí gbogbo ènìyàn wà ní abẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, bíkòṣe àwọn tí èmi ti pa mọ́ fún ara mi, àwọn ẹni mímọ́ tí ẹ̀yin kò mọ̀.

9 Nitori-èyí, mo wí fún yín pé èmi ti fi májẹ̀mú mi ayérayé ránṣẹ́ sí yín, àní èyíinì tí ó ti wà lati àtètèkọ́ṣe.

10 Àti èyíinì tí mo ti ṣe ìlérí èmi ti múu ṣẹ bẹ́ẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè ayé yíò sì fi orí balẹ̀ fún un; àti, bí kò bá ṣe àwọn tìkára wọn, wọn yíò sọ̀kalẹ́ wá, nítorí èyí tí ó ti gbé ara rẹ̀ ga nísisìyí ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú agbára.

11 Nítorínáà, èmi fi òfin kan fún yín pé kí ẹ lọ lààrin àwọn ènìyàn yí, kí ẹ sì sọ fún wọn, gẹ́gẹ́bí àpóstélì mi ìgbàanì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Pétérù:

12 Ẹ gbàgbọ́ nínú orúkọ Olúwa Jésù, ẹni tí ó wá sí ayé, àti tí yíò wá, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin;

13 Ẹ ronúpìwàdà kí á sì rì yín bọmi ní orúkọ Jésù Krístì, gẹ́gẹ́bí òfin mímọ́, fún ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀;

14 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí yíò gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, nípasẹ̀ ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà ìjọ.

15 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kàá lééwọ̀ láti ṣe ìgbéyàwó kìí ṣe ẹnití Ọlọ́run yàn, nítorí ìgbéyàwó jẹ́ ohun tí Ọlọ́run yàn fún ènìyàn.

16 Nítorínáà, ó bá òfin mu pé kí òun ní ìyàwó kan, àwọn méjèèjì yíò sì di ara kan, àti gbogbo èyí kí ilẹ̀ ayé ó lè dáhùn òpin ìṣẹ̀dá rẹ̀;

17 Àti pé kí ó le kún fún ìwọ̀n àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́bí ìṣẹ̀dá rẹ̀ kí á tó ṣe ẹ̀dá ayé.

18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kàá léèwọ̀ lati fà sẹ́hìn fún àwọn ẹran jíjẹ, pé ènìyàn kì yíò jẹ irú ẹran kannáà, kìí ṣe ẹnití Ọlọrun yàn;

19 Nítorí, ẹ kíyèsíi, àwọn ẹranko inú ìgbẹ́ àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àti àwọn tí wọ́n wà ní orì ilẹ̀ ayé, ni a yàn fún lílò àwọn ènìyàn fún oúnjẹ àti fún bíbora, àti kí òun lè ní wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

20 Ṣùgbọ́n a kò fi fúnni pé kí ẹnikan ní èyíinì tí ó ju ti ẹlòmíràn, nítorínáà ayé wà nínú ẹ̀ṣẹ̀.

21 Ègbé sì ni fún ẹni náà tí ó ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ tàbí tí ó fi ẹran ṣòfò tí òun kò sì nílò rẹ̀.

22 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé Ọmọ Ènìyàn kò wá ní ẹ̀yà obìnrin, tàbí gẹ́gẹ́bí ọkùnrin arìnrìnàjò ní orí ilẹ̀ ayé.

23 Nítorínáà, kí á má tàn yín jẹ, ṣùgbọ́n kí ẹ tẹ̀síwájú ní ìdúróṣinṣin, ní wíwo ọ̀nà fún kí á mú àwọn ọ̀run mì tìtì, àti kí ilẹ̀ ayé wárìrì kí ó sì ta gbọ̃ngbọ̃n síhĩn sọ́hũn bíi ọ̀mùtí ènìyàn, àti fún àwọn àfonífojì lati di gbígbé sókè, àti awọn òkè lati rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, àti àwọn ibi pàlàpálá lati sọ di títẹ́jú—àti gbogbo ìwọ̀nyí nígbàtí ángẹ́lì náà bá fun ìpè rẹ̀.

24 Ṣùgbọ́n kí ọjọ́ nlá Olúwa náà tó dé, Jákọ́bù yíò gbilẹ̀ nínú agìnjù, àwọn ará Lámánì yíò sì ní ìtànná bíi òdòdó.

25 Síónì yíò gbilẹ̀ ní orí àwọn òkè kékèké yíò sì yọ̀ ní orí àwọn òkè nlá, a ó sì kó o jọ sí ibi náà tí èmi ti yàn.

26 Kíyèsíi, mo wí fún yín, ẹ jade lọ bí èmi ti pàṣẹ fún yín; ẹ ronúpìwàdà gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín; ẹ béèrè ẹ ó sì rí gbà; ẹ kàn kùn a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín.

27 Kíyèsíi, èmi yíò lọ ní wájú yín àti pé èmi yíò tì yín lẹ́hìn; àti pé èmi yíò wà ní ààrin yín, àti pé a kì yíò sì dààmú yín.

28 Kíyèsíi, èmi ni Jésù Krístì, èmi sì nbọ̀ kankan. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.