Ìpín 62
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní etí bèbè Odò Missouri ní Chariton, Missouri, 13 Oṣù Kẹjọ 1831. Ní ọjọ́ yìí Wòlíì náà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọn wà ní ojú ọnà wọn láti Independence sí Kirtland, pàdé ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà tí wọ́n wà ní ojú ọnà wọ́n sí ilẹ̀ Síónì, àti, lẹ́hìn kíkí ara ẹni pẹ̀lú ayọ̀, ó gba ìfihan yìí.
1–3, Àwọn ẹ̀rí wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀run; 4–9, Àwọn alàgbà níláti rìn ìrìnàjò kí wọ́n ó sì wàásù gẹ́gẹ́bí ìdájọ́ àti bí Ẹ̀mí bá ṣe darí.
1 Ẹ kíyèsíi, kí ẹ sì fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin alàgbà ijọ mi, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí, àní Jésù Krístì, alágbàwí yín, ẹnití ó mọ àìlera ènìyàn àti ọ̀nà láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún irú àwọn tí a dánwò.
2 Àti lõtọ́ ojú mi wà lára àwọn wọnnì tí wọn kò tíì gòkè lọ sí ilẹ̀ Síónì síbẹ̀; nítorínáà iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín kò tíì kún tó.
3 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, alábùkúnfún ni ẹ̀yin, nítorí ẹ̀rí tí ẹ jẹ́ ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀run fún àwọn ángẹ́lì láti bojúwò; wọ́n sì yọ̀ nítorí yín, a sì ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.
4 Àti nísisìyí ẹ tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò yín. Ẹ kó ara yín jọ pọ̀ ní orí ilẹ̀ Síónì; kí ẹ sì ṣe ìpádé kan kí ẹ sì jọ yọ̀ papọ̀, kí ẹ sì rú ẹbọ àmì májẹ̀mú sí Ọ̀gá Ògo.
5 Àti nígbànáà ẹ̀yin lè padà láti jẹ́rìí, bẹ́ẹ̀ni, àní lápapọ̀, tàbí ní méjì méjì, bí ó bá ṣe dára ní ojú yín, kò ṣe pàtàkì sí mi; kìkì pé kí ẹ̀yin jẹ́ olõtọ́, kí ẹ sì kéde ìhìn ayọ̀ sí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, tàbí lààrin ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn búburú.
6 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, ti kó yín papọ̀ kí ìlérí le wá sí ìmúṣẹ, kí á lè pa àwọn tí ó jẹ́ olõtọ́ nínú yín mọ́ àti kí wọ́n ó lè yọ̀ papọ̀ ní orí ilẹ̀ Missouri. Èmi, Olúwa, ṣe ìlérí fún àwọn olõtọ́ èmi kì yíò sì ṣèké.
7 Èmi, Olúwa, nfẹ́, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá fẹ́ láti gun ẹṣin, tàbí ìbákasíẹ, tàbí kẹ̀kẹ́, òun yíò gba ìbùkún yìí, bí òun bá gbà á láti ọwọ́ Olúwa, pẹ̀lú ọkàn tí ó kún fún ọpẹ́ nínú ohun gbogbo.
8 Àwọn nkan wọ̀nyí wà pẹ̀lú yín láti ṣe gẹ́gẹ́bí ìdájọ́ àti àwọn ìdárí ti Ẹ̀mí.
9 Kíyèsíi, tiyín ni ìjọba náà. Àti kíyèsíi, sì wòó, èmi wà pẹ̀lú àwọn olódodo nígbà gbogbo. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.