Ìpín 64
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí àwọn alàgbà ìjọ ní Kirtland, Ohio, 11 Oṣù Kẹsãn 1831. Wòlíì ngbaradì láti kó lọ sí Hiram, Ohio, láti padà lọ́tun sí iṣẹ́ rẹ̀ ní orí ìtùmọ̀ Bíbélì, èyítí òun ti gbé sí ẹ̀gbẹ́ kan nígbàtí ó ti wà ní Missouri. Ọ̀wọ́ àwọn arákùnrin tí a ti pàṣẹ fún láti rin ìrìnàjò lọ sí Síónì (Missouri) nfi ìtara dáwọ́lé ṣíṣe àwọn ìgbáradì láti gbéra ní Oṣù Kẹwã. Ní àkókò tí ọwọ́ dí púpọ̀ yìí, a gba ìfihàn náà.
1–11, Àwọn Ẹni Mímọ́ ni a pàṣẹ fún lati dári ji ara wọn, bí bẹ́ẹ̀kọ́ nínú wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tóbi jù yío wà; 12–22, Àwọn aláìronúpìwàdà ní a ó mú wá sí iwájú ìjọ; 23–25, Ẹni tí ó bá san ìdámẹ́wàá kì yíò jóná ní ìpadàbọ̀ Olúwa; 26–32, Àwọn Ẹni Mímọ́ ni a kìlọ̀ fún nípa gbèsè; 33–36, Àwọn aṣọ̀tẹ̀ ni a ó ké kúrò lára Síónì; 37–40, Ìjọ Ọlọ́run yíò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè; 41–43, Síónì yíò gbilẹ̀.
1 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run yín wí fún yín, Áà ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi, ẹ fetísílẹ̀ kí ẹ sì gbọ́, àti pé kí ẹ gba ìfẹ́ inú mi nípa yín.
2 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó borí ayé; nítorínáà èmi yíò ní ìyọ́nú síi yín.
3 Àwọn kan wà láàrin yín tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n lõtọ́ ni mo wí, fún ẹ̀ẹ̀kan yìí, nítorí ògo èmi tìkara mi, àti nítorí ìgbàlà àwọn ọkàn, èmi ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.
4 Èmi yíò ṣàánú fún yín, nítorí èmi ti fi ìjọ̀ba náà fún yín.
5 Àti àwọn kọ́kọ́rọ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọ̀ba náà kì yíò jẹ́ gbígbà kúrò ní ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, nípasẹ̀ ọ̀nà tí èmi ti yàn, níwọ̀n ìgba tí òun bá wà láàyè, níwọ̀nbí òun bá gbọ́ràn sí àwọn ìlànà mi.
6 Àwọn kan tilẹ̀ wà tí wọ́n nwá ọ̀nà láti kọlù ú láìnídìí;
7 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, òun ti dẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi, Olúwa, dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn wọnnì tí wọ́n bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn níwájú mi tí wọ́n sì béèrè fún ìdáríjì, ẹnití kò dẹ́ṣẹ̀ sí ikú.
8 Àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, ní ọjọ́ wọnnì, wá ọ̀nà láti kọlù ara wọn wọn kò sì dárí ji ara wọn nínú ọkàn wọn; àti nítorí ibi yìí a pọ́n wọn lójú a sì bá wọn wí gidigidi.
9 Nítorínáà, mo wí fún yín, pé ó yẹ kí ẹ dárí ji ara yín; nítorí ẹnití kò bá dárí àìṣedéédé arákùnrin rẹ̀ jì dúró fún ìdálẹ́bi níwájú Olúwa; nítorí nínú òun gan an ní ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tóbijù wà.
10 Èmi, Olúwa, yíò dáríji ẹnití èmi yíò dáríjì, ṣùgbọ́n ní tiyín ó jẹ́ dandan lati dáríji gbogbo ènìyàn.
11 Ó sì yẹ kí ẹ̀yin ó lè sọ nínú ọkàn yín pé—jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ lààrin èmi àti ìwọ, kí òun sì pín èrè fún ọ gẹ́gẹ́bí àwọn ìṣe rẹ.
12 Àti ẹni náà tí kò ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí kò sì jẹ́wọ́ wọn, ẹ̀yin yíò mú un wá sí iwájú ìjọ, ẹ̀yin yíò sì ṣe fún un bí ìwé mímọ́ ṣe wí fún yín, bóyá nípa àṣẹ tàbí nípa ìfihàn.
13 Èyí ni ẹ̀yin yíò sì ṣe kí á lè fi ògo fún Ọlọ́run—kìí ṣe nítorí pé ẹ̀yin kò dáríjì, pé ẹ̀yin kò ní ìyọ́nú, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin ó lè ní ìdáláre lójú òfin, kí ẹ̀yin ó má baà ṣẹ̀ sí ẹni náà tí ó nfún yín ní òfin—
14 Lõtọ́ ni mo wí, nítorí ìdí èyí ni ẹ̀yin yíò ṣe àwọn ohun wọ̀nyí.
15 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, bínú sí i, ẹnití ó ti jẹ́ ìránṣẹ́ mi tẹ́lẹ̀rí Ezra Booth, àti pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Isaac Morley, nítorí wọn kò pa òfin náà mọ́, tàbí àṣẹ náà;
16 Wọ́n lépa ibi nínú ọkàn wọn, àti pé èmi, Olúwa, fa Ẹ̀mí mi sẹ́hìn. Wọ́n dálẹ́bi bíi ibi ohun náà nínú èyíti kò sí ibi; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ èmi ti dáríji ìránṣẹ́ mi Isaac Morley.
17 Àti bákannáà ìránṣẹ́ mi Edward Partridge, kíyèsíi, òun ti dẹ́ṣẹ̀, Sátánì sì nwá ọ̀nà láti pa ẹ̀mí rẹ̀ run; ṣùgbọ́n nígbàtí a bá sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ fún wọn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà nínú ìwà ibi náà, a ó dáríjì wọ́n.
18 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí pé ó tọ́ ní ojú mi pé kí ìránṣẹ́ mi Sidney Gilbert, lẹ́hìn àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ó padà sí orí ìṣẹ́ òwò rẹ̀, àti sí ìṣojú rẹ̀ ní ilẹ̀ Síónì;
19 Àti èyíinì tí òun ti rí àti tí ó ti gbọ́ kí ó lè di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, kí wọn ó má baà parun. Àti fún ìdí èyí ni èmi ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí.
20 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, pé ìránṣẹ́ mi Isaac Morley ni a kì yíò dán wò ju èyítí òun le gbà, àti kí òun fúnni ní ìmọ̀ràn òdì sí ìpalára yín, èmi fi àṣẹ kan funni pé kí a ta ilẹ̀ oko rẹ̀.
21 Èmi kì yíò fẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Frederick G. Williams ó ta oko rẹ̀, nítorí èmi, Olúwa, fẹ́ pé kí á ní ibi agbára kan ní ilẹ̀ Kirtland, fún àlàfo bíi ọdún márũn, nínú èyí tí èmi kì yíò bi àwọn ènìyàn búburú ṣubú, pé nípa bẹ́ẹ̀ kí èmi lè gba àwọn díẹ̀ là.
22 Àti lẹ́hìn ọjọ́ náà, èmi, Olúwa, kì yíò mú ẹnikẹ́ni pé ó jẹ̀bi tí ó bá lọ sí ilẹ̀ Síónì pẹ̀lú ọkàn mímọ́; nítorí èmi, Olúwa, nbéèrè ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn.
23 Kíyèsíi, ìsisìyí ni a npè ní òní títí di àkókò bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn, àti pé lõtọ́ èyí jẹ́ ìgbà ẹbọ rírú, àti ìgbà fún ìdámẹ́wã àwọn ènìyàn mi; nítorí ẹni tí ó bá san ìdámẹ́wàá kì yíò jóná ní bíbọ̀ rẹ̀.
24 Nítorí lẹ́hìn òní ní ìjóná yíò dé—èyí ni sísọ ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà ti Olúwa—nítorí lõtọ́ ni mo wí, ní ọ̀la ni gbogbo àwọn agbéraga àti àwọn olùṣe búburú yíò dàbí àkékù koríko; èmi yíò sì jó wọn ní iná kanlẹ̀, nítorí èmi ni Olúwa Àwọn Ọmọ Ogun; èmi kì yíò dá ẹnìkan sí nínú àwọn tí wọ́n wà ní Bábílónì.
25 Nítorínáà, bí ẹ̀yin bá gbà mí gbọ́, ẹ̀yin yíò ṣiṣẹ́ nígbàtí a pè ní òní.
26 Kò sì tọ́ pé kí àwọn ìránṣẹ́ mi, Newel K. Whitney àti Sidney Gilbert ó ta ilé ìtajà àti àwọn ohun ìní wọn ní ìhín; nítorí èyí kìí ṣe ọgbọ́n títí tí ìyókù ìjọ, tí wọ́n wà ní ìhín, yíò fi gòkè lọ sí ilẹ̀ Síónì.
27 Kíyèsíi, a ti sọ nínú àwọn òfin mi, tàbí a ti kàá sí èèwọ̀, láti wọ inú gbèsè sí ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá yín;
28 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, a kò sọ ọ́ ní ìgbà kankan rí pé Olúwa kò le múni nígbà tí ó bá wù ú, àti kí òun san bí ó ti dára ní ojú rẹ̀.
29 Nísisìyí, bí ẹ̀yin ṣe jẹ́ aṣojú, ẹ̀yin njẹ́ iṣẹ́ fún Olúwa; àti pé ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́bíi ìfẹ́ inú Olúwa jẹ́ iṣẹ́ ti Olúwa.
30 Òun sì ti yàn yín lati pèsè fún àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn wọ̀nyí, kí wọn ó lè gbà ogún ìní kan ni ilẹ̀ Síónì.
31 Sì kíyèsíi, èmi, Olúwa, kéde fún yín, àwọn ọ̀rọ̀ mi sì dájú wọn kò sì le kùnà, pé wọn yíó gbà á.
32 Ṣùgbọ́n ohun gbogbo gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ ní àkókò wọn.
33 Nísisìyí, ẹ máṣe kãrẹ̀ nínú ṣíṣe rere, nítorí ẹ̀yin nfi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ títóbi kan lélẹ̀. Àti pé nínú àwọn ohun kékeré ni èyíinì tí ó tóbi yíò ti jade wá.
34 Kíyèsíi, Olúwa nbéèrè ọkàn àti ẹ̀mí tí ó nfẹ́; àti pé ẹnití ó nfẹ́ àti olùgbọ́ràn ni wọn yíò jẹ ire ilẹ̀ Síónì ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn wọ̀nyí.
35 Àti pé àwọn aṣọ̀tẹ̀ ni a ó ké kúrò ni ilẹ̀ Síónì, a ó sì lé wọn kúrò, wọn kì yíò sì jogún ilẹ̀ náà.
36 Nítorí, lõtọ́ ni mo wí pé àwọn aṣọ̀tẹ̀ kìí ṣe ẹ̀jẹ̀ ti Efráímù, nítorínáà a ó fà wọ́n tu kúrò.
37 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, ti ṣe ìjọ mi ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí onídajọ́ tí ó jókòó ní orí òkè, tàbí ní ibi gíga kan, láti ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.
38 Nítorí yíò sì ṣe pé àwọn olùgbé Síónì yíò ṣe ìdájọ́ ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti Síónì.
39 Àti àwọn òpùrọ́ àti àwọn àgàbàgebè ni a ó fi hàn lati ọwọ́ wọn, àti àwọn tí kìí ṣe àpóstélì àti Wòlíì ni a ó mọ̀.
40 Àti àní bíṣọ́pù, ẹni tí ó jẹ́ onídajọ́, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, bí wọn kò bá jẹ́ olõtọ́ nínú iṣẹ́ ìríjú wọn ni a ó dálẹ́bi, àwọn ẹlòmíràn ni a ó sì fi rọ́pò wọn.
41 Nítorí, kíyèsíi, mo wí fún yín pé Síónì yíò gbilẹ̀, ògo Olúwa yíò sì wà ní orí rẹ̀;
42 Òun yíò sì jé ọ̀págun fún àwọn ènìyàn, wọn yíò sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti olúkúlùkù àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run.
43 Ọjọ́ náà yío sì dé nígbàtí àwọn orílẹ̀-èdè ayé yíò wárìrì nítorí rẹ̀, tí wọn yíò sì bẹ̀rù nítorí àwọn ẹni abanilẹ́rù rẹ̀. Olúwa ti sọ ọ́. Àmín.