Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 67


Ìpín 67

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, ní ìbẹ̀rẹ̀ Oṣù Kọ́kànlá 1831. Àkókò náà jẹ́ ìgbà ìpàdé àpéjọpọ̀ pàtàkì kan, àti tí títẹ̀jáde àwọn ìfihàn tí a ti gbà láti ọwọ́ Olúwa nípasẹ̀ Wòlíì jẹ́ gbígbé yẹ̀wò tí a sì gbé ìgbésẹ̀ lé ní orí (wo àkọlé sí ìpín 1). William W. Phelps ti ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àgbékalẹ̀ ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé ní Independence, Missouri. Ìpàdé àpapọ̀ ṣe ìpinnu láti tẹ àwọn ìfihàn jade bíi Book of Commandments (Ìwé àwọn Òfin) àti láti tẹ 10,000 àwọn ẹ̀dà (èyítí, nítorí àwọn ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀, ó dínkù sí 3,000 àwọn ẹ̀dà). Púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jẹ́rìí pé àwọn ìfihàn tí a kójọ fún títẹ̀jade nígbànáà jẹ́ òtítọ́ ní tòótọ́, bí a ti ṣe ẹ̀rí rẹ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a tú sí orí wọn. Ìtàn ti Joseph Smith ṣe àkọsílẹ̀ pé lẹ́hìn tí a ti gba ìfihàn tí a mọ̀ sí ìpín 1, àwọn ọ̀rọ̀ kan jẹ jáde nípa èdè tí a lò nínú àwọn ìfihàn náà. Ìfihàn eléyìí tẹ̀lée.

1–3, Olúwa ngbọ́ àwọn àdúrà ti Ó sì nṣe àmójútó ní orí àwọn alàgbà Rẹ̀; 4–9, Ó npe ọlọgbọ́n jùlọ ènìyàn níjà láti ṣe ẹ̀dà èyítí ó kéré jùlọ nínú àwọn ìfihàn Rẹ̀; 10–14, Àwọn alàgbà olõtọ́ ni a ó ta jí láti ọwọ́ Ẹ̀mí, wọn yíò sì rí ojú Ọlọ́run.

1 Ẹ kíyèsíi kí ẹ sì fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi, ẹ̀yin tí ẹ ti kó ara yín jọ papọ̀, ẹ̀yin tí mo ti gbọ́ àdúrà yín, àti ọkàn ẹ̀yin ẹnití èmi mọ̀, àti ẹ̀yin ẹnití ìfẹ́ inú yín ti gòkè wá sí iwájú mi.

2 Ẹ kíyèsíi kí ẹ sì wòó, ojú mi wà lára yín, àti pé àwọn ọ̀run àti ilé ayé wà ní ọwọ́ mi, àwọn ọrọ̀ ayérayé sì jẹ́ tèmi láti fi fúnni.

3 Ẹ̀yin gbìyànjú láti gbàgbọ́ pé ẹ nílati gba ìbùkún tí a fi lélẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín àwọn ìbẹ̀rù wà ní ọkàn yín, àti lõtọ́ èyí ni ìdí tí ẹ̀yin kò fi rí gbà.

4 Àti nísisìyí èmi, Olúwa, fún yín ní ẹ̀rí òtítọ́ kan nípa àwọn òfin wọ̀nyí tí wọ́n wà níwájú yín.

5 Ojú yín ti wà lára ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, èdè rẹ̀ ni ẹ̀yin sì ti mọ̀, àti àwọn àbùkù rẹ̀ ni ẹ̀yin ti mọ̀; àti pé ẹ̀yin ti wá ìmọ̀ nínú ọkàn yín pé kí ẹ̀yin ó lè sọ̀rọ̀ kọjá èdè rẹ̀; èyí ni ẹ̀yin mọ̀ bákannáà.

6 Nísisìyí, ẹ wáa nínú Ìwé àwọn Òfin, àní èyí tí ó kéré jùlọ tí ó wà láàrin wọn, kí ẹ̀yin ó sì yàn ẹni náà tí ó gbọ́n jùlọ láàrin yín.

7 Tàbí, bí a bá rí ẹnìkan ní ààrin yín tí yíò ṣe ọ̀kan tí ó dàbí rẹ̀, nígbànáà ẹ̀yin ní ìdáláre ní sísọ́ pé ẹ kò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ òtítọ́;

8 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá lè ṣe ọ̀kan tí ó dàbí rẹ̀, ẹ̀yin wà nínú ìdálẹ́bi bí ẹ kò bá jẹ́rìí pé wọ́n jẹ́ òtítọ́.

9 Nítorí ẹ̀yin mọ̀ pé kò sí àìṣòdodo nínú wọn, àti èyíinì tí ó jẹ́ òdodo sọ̀kalẹ̀ wá láti òke, láti ọ̀dọ̀ Bàbá àwọn ìmọ́lẹ̀.

10 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín pé ànfàní yín ni, àti ìlérí kan tí mo fún yín tí a ti yàn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí, pé níwọ̀nbí ẹ̀yin bá ti lè gba ara yin kúrò lọ́wọ owú jíjẹ àti ẹ̀rù, tí ẹ sì rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú mi, nítorí ẹ̀yin kò ní ìrẹ̀lẹ̀ tó, a ó fa aṣọ ìkéle ya ẹ̀yin yíò sì rí mi ẹ ó sì mọ̀ pé èmi ni—kìí ṣe nípa ti ara tàbi ọ̀kan àdánidá, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ti ẹ̀mí.

11 Nítorí kò sí ènìyàn kan tí ó rí Ọlọ́run nigbà kan rí nínú ẹran ara, bíkòṣe pé a ta á jí nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run.

12 Tàbí kí èniyàn ẹlẹ́ran ara kankan ó le gbé níwájú Ọlọ́run, tàbí nínú ọkàn ara.

13 Ẹ̀yin kì yíò le gbé níwájú Ọlọ́run nísisìyí, tàbí ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì; nítorínáà, tẹ̀síwájú nínú sùúrù títí tí a ó fi sọ yín di pípé.

14 Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín padà sẹ́hìn, nígbàtí ẹ̀yin bá sì yẹ, ní àkokò tí ó tọ́ ní ojú mi, ẹ̀yin yíò rí ẹ ó sì mọ̀ èyí tí a fi fún yín láti ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré. Amin.