Ìpín 6
Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith àti Oliver Cowdery, ní Harmony, Pennsylvania, ní oṣù kẹrin ọdún 1829. Oliver Cowdery bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí akọ̀wé nínú títúmọ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì, Ọjọ́ keje oṣù kẹrin 1829. Oun ti gba ìṣípayá àtọ̀runwá tẹ́lẹ̀ nípa jíjẹ́ òtítọ́ ẹ̀rí ti Wòlíì, nípa àwọn àwo-àkọsílẹ̀ ní orí èyí tí a fín àkọsílẹ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì sí. Wolíì náà béèrè lọ́wọ́ Olúwa nípasẹ̀ Urimù àti Tumimu òun sì gbà ìdáhùn yìí.
1–6, Àwọn òṣìṣẹ́ nínú oko Olúwa jẹ èrè ìgbàlà; 7–13, Kò sí ẹ̀bùn kan tí ó tóbi ju ẹ̀bùn ìgbàlà lọ; 14–27, Ẹ̀rí ti òtítọ́ máa njáde nípa agbára ti Ẹ̀mí; 28–37, Máa wo ọ̀dọ̀ Krísti, kí o sì máa ṣe rere láì dáwọ́ dúró.
1 Iṣẹ́ títóbi ati yíyanilẹ́nu kan ti fẹ́ jáde wá sí àwọn ọmọ ènìyàn.
2 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run; ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ mi, èyítí ó yè tí ó sì ní agbára, ó mú ju idà olójú méjì lọ, fún pípín sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àwọn oríkẽ àti mùdùnmúdùn; nítorínáà ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.
3 Kíyèsíi, oko náà ti funfun tán fún ìkórè; nítorínáà ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kórè, ẹ jẹ́ kí ó fi dòjé rẹ̀ pẹ̀lú ipá rẹ̀, àti kí ó kórè ní ojú ọjọ́, kí ó lè kó ìgbàlà àìlópin pamọ́ fún ọkàn rẹ̀ nínú ìjọba Ọlọ́run.
4 Bẹ́ẹ̀ni, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dòjé rẹ̀ tí ó sì kórè, òun náà ni Ọlọ́run pè.
5 Nítorínáà, bí ìwọ bá béèrè ní ọwọ́ mi, ìwọ yíò rí gbà; bí ìwọ bá kan ìlẹ̀kùn, a ó ṣí i fún ọ.
6 Nísisìyí, nítorítí ìwọ ti béèrè, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì lépa lati mú iṣẹ́ Síónì jáde wá ati lati fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
7 Ma ṣe lépa fún ọrọ̀ ṣugbọ́n fún ọgbọ́n, àti kíyèsíi, àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run ni a ó ṣí fún ọ, àti nígbànáà ni a ó sọ ìwọ di ọlọ́rọ̀. Kíyèsíi, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìyè ayérayé ni ọlọ́rọ̀.
8 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, gẹ́gẹ́bí ìwọ ṣe fẹ́ lati ọwọ́ mi bẹ́ẹ̀ ni yíò rí fún ọ; àti bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ yíó jẹ́ ohun èlò tí ṣíṣe rere púpọ̀ ní ìran yìí.
9 Ma ṣe sọ ohunkohun bíkòṣe ironúpìwàdà fún ìran yìí; pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì ṣe àtìlẹ́hìn lati mú iṣẹ́ mi jáde wá; ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin mi, ìwọ yíò sì di alábùkúnfún.
10 Kíyèsíi, ìwọ ní ẹ̀bùn, àti pé alábùkúnfún ni ìwọ nítorí ẹ̀bùn rẹ. Rántí pé ó jẹ́ mímọ́ ó sì wá láti òkè—
11 Àti pé bí ìwọ bá béèrè, ìwọ yíò mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ títóbi àti yíyanilẹ́nu; nítorínáà ìwọ yíò lo ẹ̀bùn rẹ, kí ìwọ lè wá àwọn ohun ìjìnlẹ̀ rí, kí ìwọ lè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí ìmọ̀ ti òtítọ́ náà, bẹ́ẹ̀ni, ní yíyí wọn lọ́kàn padà nínú àṣìṣe àwọn ọ̀nà wọn.
12 Máṣe sọ ẹ̀bùn rẹ di mímọ̀ fún ẹnikẹ́ni bíkòṣe àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ kannáà pẹ̀lúù rẹ. Maṣe ka àwọn ohun mímọ́ sí yẹpẹrẹ.
13 Bí ìwọ bá ṣe rere, bẹ́ẹ̀ni, tí ìwọ sì jẹ́ olõtọ́ títí dé òpin, a ó gbà ọ́ là ní ìjọba Ọlọ́run, èyí tí ó tóbi jùlọ nínú gbogbo awọn ẹ̀bùn Ọlọ́run; nítorí kò sí ẹ̀bùn kan tí ó tóbi ju ẹ̀bun ìgbàlà lọ.
14 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, alábùkúnfún ni ìwọ fún ohun tí ìwọ ti ṣe; nítorí ìwọ ti béèrè lọ́wọ́ mi, àti kíyèsíi, ní gbogbo ìgbà púpọ̀ tí ìwọ ti béèrè ìwọ ti gba ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí mi. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ kì bá tí wá sí ibi tí ìwọ wà ní àkókò yìí.
15 Kíyèsíi, ìwọ mọ̀ pé ìwọ ti béèrè lọ́wọ́ mi èmi sì fi òye yé ọkàn rẹ; àti pé nísisìyí èmi sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún ọ kí ìwọ lè mọ̀ pé ati fi òye yé ọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí òtítọ́;
16 Bẹ́ẹ̀ni, mo wí fún ọ, kí ìwọ ó le mọ̀ pé kò sí ẹlòmíràn bíkòṣe Ọlọ́run tí ó mọ àwọn èrò àti àwọn èròngbà ọkàn rẹ.
17 Mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún ọ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ọ—pé àwọn ọ̀rọ̀ tàbí iṣẹ́ èyítí o ti nkọ jẹ́ òtítọ́.
18 Nítorínáà jẹ́ alãpọn; dúró ti ìránṣẹ́ mi Joseph, pẹ̀lú òtítọ́, nínú èyíkéyí ipò ìsòro tí òun lè wà nítorí ọ̀rọ̀ náà.
19 Kìlọ̀ fún un nínú àwọn àṣìṣe rẹ̀, àti bákannáà gba ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Jẹ́ onísùúrù; máa ronújinlẹ̀; wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì; ní sùúrù, ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́.
20 Kíyèsíi, ìwọ ni Oliver, mo sì ti bá ọ sọ̀rọ̀ nítorí àwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ; nítorínáà fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pamọ́ sínú ọkàn rẹ. Jẹ́ olõtọ́ àti alãpọn ní pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, èmi yíò sì yí ọ ká pẹ̀lú apá ìfẹ́ mi.
21 Kíyèsíi, èmi ni Jésu Krísti, Ọmọ Ọlọ́run. Èmi yìí kannáà ni ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn tèmi, àwọn tèmi kò sì gbà mí. Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó ntan nínú òkùnkùn, tí òkùnkùn náà kò sì borí rẹ̀.
22 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, bí ìwọ bá fẹ́ ẹ̀rí síwájú síi, mú ọkàn rẹ lọ sí òru ọjọ́ tí o kígbe pè mí nínú ọkàn rẹ, pé kí ìwọ le mọ̀ nípa òtítọ́ àwọn nkan wọ̀nyí.
23 Njẹ́ èmi kò ha sọ̀rọ̀ àlãfíà sí ọkàn rẹ nípa ohun náà? Irú ẹ̀rí títóbi wo ni o tún lè ní ju láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lọ?
24 Àti nísisìyí, kíyèsíi, ìwọ ti gba ẹ̀rí kan; nítorí bí èmi bá ti sọ àwọn ohun tí ènìyàn kankan kò mọ̀, ìwọ kò ha ti gba ẹ̀rí kan bí?
25 Àti pé, kíyèsíi, mo ti fi ẹ̀bùn kan fún ọ, bí ìwọ bá fẹ́ láti ọ̀dọ̀ mi, láti lè túmọ̀, àní bíi ti ìránṣẹ mi Joseph.
26 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé àwọn àkọsílẹ̀ wà èyítí ó ní púpọ̀ lára àwọn ìhìnrere mi nínú, èyí tí a ti pamọ́ sẹ́hìn nítorí ìwà búbúrú àwọn ènìyàn.
27 Àti nísisìyí mo pàṣẹ fún ọ, pé bí o bá ní àwọn ìfẹ́ rere—ìfẹ́ láti to ìṣura jọ fún ara rẹ ní ọ̀run—nígbànáà ni ìwọ yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ ní mímú wá sí ìmọ́lẹ̀, pẹ̀lú ẹ̀bùn rẹ, àwọn abala wọnnì lára àwọn ìwé mímọ́ mi tí a ti fipamọ́ nítorí àìṣedédé.
28 Àti nísisìyí, kíyèsíi, èmi fi fún ọ, àti bákannáà fún ìránṣẹ́ mi Joseph, àwọn kọ́kọ́rọ́ ẹ̀bùn yìí, èyí tí yíò mú iṣẹ́ ìranṣẹ́ yìí wá sí ìmọ́lẹ̀; àti pé ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fi ìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.
29 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, bí wọ́n bá kọ àwọn ọ̀rọ̀ mi, àti apákan ìhìnrere mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí, alábùkúnfún ni ẹ̀yin, nítorí wọn kò le ṣe síi yín mọ́ ju sí mi lọ.
30 Àní bí wọn bá sì ṣe síi yín, aní bí wọn ti ṣe sí èmi, alábùkúnfún ni ẹ̀yin, nítorí ẹ̀yin yíò gbé pẹ̀lú mi nínú ògo.
31 Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ àwọn ọ̀rọ̀ mi, èyí tí a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ẹ̀rí èyí tí a ó fi fúnni, alábùkúnfún ni àwọn, àti nígbànáà ni ẹ̀yin yíò ní ayọ̀ nínú èso àwọn iṣẹ́ yín.
32 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, gẹ́gẹ́bí mo ti wí fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, níbi tí ẹni méjì tàbi mẹ́ta bá kó ara wọn jọ ní orúkọ mi, nípa ohun kan, kíyèsíi, níbẹ̀ ni èmi yíò wà lààrin wọn—àní bẹ́ẹ̀ni èmi ṣe wà lààrin yin.
33 Ẹ má ṣe bẹ̀rù láti ṣe rere, ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí ohunkohun tí ẹ̀yin bá fúrúgbìn, èyìínì náà ni ẹ̀yin yíò kórè; nítorínáà, bí ẹ̀yin bá fúrúgbìn rere ẹ̀yin yíò kórè rere gẹ́gẹ́bí èrè yín.
34 Nítorínáà, ẹ má bẹ̀rù, agbo kékeré, ẹ ṣe rere; ẹ jẹ́ kí ayé àti ọ̀run àpáàdì parapọ̀ ṣe òdì sí yín, nítorí bí a bá kọ́ọ yín lé orí àpáta mi, wọn kì yíò lè borí.
35 Kíyèsíi, èmi kò dá yín lẹ́bi; ẹ máa lọ ní àwọn ọ̀nà yín ẹ má sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́; ẹ ṣe àwọn iṣẹ́ tí mo pa láṣẹ fún yín pẹ̀lú àròjinlẹ̀.
36 Ẹ máa wo ọ̀dọ̀ mi nínú gbogbo èrò inú, ẹ má ṣe iyè méjì, ẹ má bẹ̀rù.
37 Ẹ kíyèsí àwọn ọgbẹ́ tí wọn gún ìhà mi, àti bákannáà àwọn àpá ìṣó tí ó wà ní awọn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi; ẹ jẹ́ olõtọ́, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́, ẹ̀yin yíò sì jogún ìjọba ọ̀run. Amin.