Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 76


Ìpín 76

Ìṣípayá tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith àti Sidney Rigdon, ní Hiram, Ohio, 16 Oṣù Kejì 1832. Ní kíkọ ọ̀rọ̀ ìṣaájú sí àkọsílẹ̀ fún ìṣípayá yìí, ìtàn ti Joseph Smith sọ pé: “Lẹ́hìn ìpadabọ̀ mi láti ìpàdé àpéjọpọ̀ ní Amherst, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ àwọn Ìwé Mímọ́ lẹ́ẹ̀kansíi. Nínú onírúurú àwọn ìfihàn tí a ti gbà, ó hàn kedere pé àwọn kókó pàtàkì tí ó nííṣe pẹ̀lú ìgbàlà ènìyàn ni a ti mú kúrò nínú Bíbélì, tàbí pé wọ́n ti sọnù kí a tó ṣe àkójọpọ̀ rẹ̀. Ó tún fi ara hàn gbangba láti inú àwọn òtítọ́ tí ó ṣẹ́kù, pé bí Ọlọ́run bá fún ẹnikọ̀ọ̀kan ní èrè iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe nínú ara ‘Ọ̀run,’ bí a ṣe pèrò rẹ̀ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́’ ilé ayérayé, gbọ́dọ̀ ní àwọn ìjọ̀ba ju ọ̀kan lọ nínú. Bẹ́ẹ̀gẹ́gẹ́, … bí a ṣe ntúmọ̀ Ìhìnrere ti Jòhánnù, èmi àti Alagbà Rigdon rí ìṣípayá tí ó tẹ̀lé yìí.” Ní àkókò tí a fi ìṣípayá yìí fúnni, Wòlíì ntúmọ̀ Jòhánnù 5:29.

1–4, Olúwa ni Ọlọ́run; 5–10, Àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọba náà ni a ó fi hàn fún gbogbo àwọn olõtọ́; 11–17, Gbogbo ènìyàn ni yíò jí dìde ní àjínde àwọn olõtọ́ tàbí aláìṣõtọ́; 18–24, Àwọn olùgbé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ayé jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì; 25–29, Ángẹ́lì Ọlọ́run kan subú òun sì di èṣù; 30–49, Àwọn ọmọ ègbé jìyà ìdálẹ́bi ayérayé; gbogbo àwọn míràn jẹ èrè ìwọ̀n díẹ̀ ti ìgbàlà; 50–70, Ògo àti èrè àwọn ẹni ìgbéga ní ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà ní a ṣe àpéjúwe wọn; 71–80, Awọn wọnnì tí wọn yíò jogún ìjọba ti Tẹrẹstría ni a ṣe àpèjúwe; 81–113, Ipò tí àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní àwọn ògo tẹ̀lẹ́stía, tẹ̀rẹ́stríá, àti sẹ̀lẹ́stía ni a ṣe àlàyé; 114–119, Àwọn olõtọ́ lè ríi kí wọ́n sì le ní òye àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọba Ọlọ́run nípa agbára Ẹmí Mímọ́.

1 Ẹ gbọ́, Áà ẹ̀yin ọ̀run, é sì fi etí sílẹ̀, Áà ìwọ ilẹ̀ ayé, ẹ sì yọ̀ ẹ̀yin olùgbé ibẹ̀, nítorí Olúwa ní Ọlọ́run, àti lẹ́hìn rẹ̀ kò sí Olùgbàlà kankan.

2 Títóbi ni ọgbọ́n rẹ̀, ìyanu sì ni àwọn ọ̀nà rẹ̀, ìwọ̀n àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ àwámárídìí fún ẹnikẹ́ni.

3 Àwọn èrò rẹ̀ kìí kùnà, bẹ́ẹ̀ni kò sí ẹni tí ó lè dá ọwọ́ rẹ̀ dúró.

4 Láti ayérayé dé ayérayé bákanáà ni òun, àwọn ọdún rẹ̀ kò sì kùnà láé.

5 Nítorí báyìí ni Olúwa wí—èmi, Olúwa, èmi jẹ́ alàánú àti olóore-ọ̀fẹ́ sí àwọn tí wọ́n bẹ̀rù mi, mo sì ní inú dídùn láti bu ọlá fún àwọn tí wọn nsìn mí ní òdodo àti ní òtítọ́ títí dé òpin.

6 Títóbi ni èrè wọn yíò jẹ́ àti ògo wọn yíò sì jẹ́ títí ayérayé.

7 Àti sí wọn ni èmi yíò fi gbogbo àwọn ohun ìjìnlẹ hàn, bẹ́ẹ̀ni, gbogbo àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba mi tí ó ti farasin láti àwọn ọjọ́ ìgbàanì, àti fún àwọn ìgbà tí ó nbọ̀, ni èmi yíò sọ di mímọ̀ fún wọn rere idùnnú ìfẹ́ inú mi nípa gbogbo àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ìjọba mi.

8 Bẹ́ẹ̀ni, àní àwọn ìyanu ti ayérayé ni wọn yíò mọ̀, àti àwọn ohun tí ó nbọ̀ ni èmi yíò fi hàn wọn, àní àwọn ohun ti ìran púpọ̀.

9 Ọgbọ́n wọn yíò sì pọ̀, òye wọn yíò sì dé ọ̀run; àti níwájú wọn ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n yíò ṣègbé, àti òye àwọn amòye ni yíò sì di asán.

10 Nítorí nípa Ẹ̀mí mi ni èmi yíò fi òye yé wọn, àti nípa agbára mi ni èmi yíò fi àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ nípa ìfẹ́ mi hàn fún wọ́n—bẹ́ẹ̀ni, àní àwọn ohun wọnnì tí ojú kò tíì rí, tàbí tí etí kò tíì gbọ́, tàbí tí kò tíì wọ inú ọkàn ènìyàn.

11 Àwa, Joseph Smith Kékeré, àti Sidney Rigdon, nítorí tí a wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kejì, nínú ọdún Olúwa wa ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rũn mẹ́jọ ati méjìlé-lọ́gbọ̀n—

12 Nípa agbára Ẹ̀mi ní ojú wa là àti òye wa sì mọ́lẹ̀ síi, bẹ́ẹ̀ kí a le rí àti kí a mọ̀ àwọn ohun ti Ọlọ́run—

13 Àní àwọn ohun wọnnì tí wọ́n ti wà láti àtètèkọ́ṣe kí ayé tó wà, èyí tí Baba ti yàn, nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí rẹ̀ Kanṣoṣo, ẹni tí ó wà ní oókan àyà Baba, àní láti àtètèkọ́ṣe;

14 Nípa Ẹni tí àwa jẹ́rìí; àti ẹ̀rí tí a jẹ́ náà ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì, ẹni tí í ṣe Ọmọ, ẹni tí àwa rí àti tí a bá sọ̀rọ̀ nínú ìṣípayá ti ọ̀run.

15 Nítorí nígbàtí à nṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀, èyí tí Olúwa ti yàn fún wa, a dé ẹsẹ ìkọkàndínlọ́gbọ̀n orí ìwé karũn Jòhánnù, èyí tí a fi fúnwa bíi àtẹ̀lé yìí—

16 Ní sísọ̀rọ̀ ti àjínde àwọn òkú, nípa àwọn wọnnì tí wọn yíò gbọ́ ohun Ọmọ Ènìyàn:

17 Tí wọn yíò sì jade wá; àwọn tí wọ́n ti ṣe rere, ní àjínde àwọn olõtọ́; àti àwọn tí wọn ti ṣe búbubrú, ní àjínde àwọn aláìṣõtọ́.

18 Nísisìyí èyí mú kí a kún fún ìyàlẹ́nu, nítorí a fi fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí.

19 Àti bí a ti nṣe àsàrò ní orí àwọn nkan wọ̀nyí, Olúwa fi ọwọ́ tọ́ ojú àgbọ́yé wa wọ́n sì là, ìtànsán ògo Olúwa sì tàn yíká.

20 A sì rí ògo Ọmọ, ní ọwọ́ ọ̀tún Bàbá, tí a sì gba nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ògo rẹ̀;

21 A sì rí àwọn ángẹ́lì mímọ́, àti àwọn wọnnì tí a yà sí mímọ́ níwájú ìtẹ́ rẹ̀, ní sísin Ọlọ́run, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, ẹnití ó nsìn ín láé àti títí láéláé.

22 Àti nísisìyí, lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀rí èyí tí a ti jẹ́ nípa rẹ̀, èyí sì ni ẹ̀rí náà, tí ó jẹ́ ìkẹ́hìn gbogbo rẹ̀, èyí tí a jẹ́ nípa rẹ̀: Pé ó wà láàyè!

23 Nítorí àwa rí i, àní ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run; a sì gbọ́ ohùn náà tí ó njẹ́rìí pé òun ni Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba—

24 Pé lati ọwọ́ rẹ̀, àti nípasẹ̀ rẹ̀, àti lati ara rẹ̀, ni àwọn aye wà ni a sì dá wọn, àti àwọn olùgbé inú wọn jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

25 Àti èyí ni àwa rí bákannáà, a sì jẹ́rìí, pé ángẹ́lì Ọlọ́run ẹnití ó wà ní ipò àṣẹ níwájú Ọlọ́run, ẹnití ó ṣọ̀tẹ̀ tako Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ẹnití Bàbá fẹ́ràn àti tí ó wà ní oókan àyà Bàbá, ni a jù sí ìsàlẹ̀ kúrò níwájú Ọlọ́run àti Ọmọ.

26 A sì pè é ní Ègbé, nítorí àwọn ọ̀run sunkún nítorí rẹ̀—òun ni Lúsíférì, ọmọ òwúrọ̀.

27 A sì rí i, sì wòó, òun ti ṣubú! ó ṣubú, àní ọmọ òwúrọ̀ náà!

28 Bí a sì ṣe wà nínú Ẹ̀mí síbẹ̀, Olúwa pàṣẹ fún wa pé kí á ṣe àkọ̀sílẹ̀ ìran náà; nítorí a rí Sátánì, ejò àtijọ́ nnì, àní èṣù náà, ẹnití ó ṣọ̀tẹ̀ tako Ọlọ́run, àti tí ó wá ọ̀nà láti gba ìjọba Ọlọ́run wa àti ti Krístì rẹ̀—

29 Nítorínáà, òun gbé ogun ti àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run, òun sì nyí wọn po káàkiri.

30 A sì rí ìran kan ti ìjìyà àwọn wọnnì tí òun ti gbógun tì, tí òun sì ṣẹ́gun, nítorí báyìí ni ohùn Olúwa tọ̀wá wá:

31 Báyìí ni Olúwa wí nípa gbogbo àwọn tí wọ́n mọ agbára mi, tí a sì ti mú wọ́n jẹ́ alábápín nínú rẹ̀, àti tí wọ́n ti gba ara wọn láàyè nípasẹ̀ agbára èṣù láti jẹ́kí a borí wọn, àti lati sẹ́ òtítọ́, tí wọ́n sì pe agbára mi níjà—

32 Àwọn ni àwọ́n tí wọ́n jẹ́ ọmọ ègbé, ní ti àwọn tí èmi wí pé ìbá sàn fún wọn kí a má bí wọn rárá;

33 Nítorí wọ́n jẹ́ ohun èlò ìbínú, tí wọ́n ti ní àyànmọ́ lati jìyà ìbínú Ọlọ́run, pẹ̀lú èṣù àti àwọn ángẹ́lì rẹ̀ ní ayérayé;

34 Nípa àwọn ẹnití èmi ti wí pé kò sí ìdáríjì ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ó nbọ̀—

35 Ní sísẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ lẹ́hìn tí wọ́n ti gbà á, àti ní sísẹ́ Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Bàbá, lẹ́hìn ti wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébũ fún ara wọn tí wọ́n sì ti dójú tì í ní gbangba.

36 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí yíò lọ kúrò sí inú adágún iná àti imí ọjọ́, pẹ̀lú èṣù àti àwọn ángẹ́lì rẹ̀—

37 Àti àwọn nìkan ní orí ẹnití ikú ẹ̀ẹ̀kejì yíò ní èyíkéyìí agbára;

38 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́, àwọn nìkan tí a kì yíò rà padà ní ìgbà tí ó yẹ lójú Olúwa, lẹ́hìn àwọn ìjìyà ti ìbínú rẹ̀.

39 Nítorí gbogbo àwọn tí ó kù ni a ó mú jade wá nípa àjínde àwọn òkú, nípasẹ̀ ìṣẹ́gun àti ògo ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn, ẹni tí a pa, ẹni tí ó wà ní oókan àyà Baba ṣaájú àwọn ayé.

40 Èyí sì ni ìhìnrere náà, àwọn ìhìn ayọ̀, èyí tí ohùn náà jáde láti àwọn ọ̀run jẹ́rìí rẹ̀ fún wa—

41 Pé ó wá sí ayé, àní Jésù, lati jẹ́ kíkàn mọ́ àgbélébũ fún aráyé, àti láti ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé, àti láti ya ayé sí mímọ́, àti láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo;

42 Pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí gbogbo ènìyàn lè di gbígbàlà àwọn tí Bàbá ti fi sínú agbára rẹ̀ àti tí a dá nípa ọwọ́ rẹ̀;

43 Ẹnití ó nyin Baba lógo, tí ó sì gba gbogbo àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ là, bíkòṣe àwọn ọmọ ègbé wọnnì tí wọ́n sẹ́ Ọmọ lẹ́hìn tí Baba ti fi í hàn.

44 Nítorínáà, òun gba gbogbo ẹ̀dá là bíkòṣe pé àwọn—wọn yíò lọ kúrò sínú ìyà àìlópin, èyí tí ó jẹ́ ìyà tí kò nípẹ̀kun, èyí tí ṣe ìyà ayérayé, lati jọba pẹ̀lú èṣù àti àwọn ángẹ́lì rẹ̀ ní ayérayé, níbi tí kòkòrò wọn kìí kú, àti tí a kìí pa iná, èyí tí ó jẹ́ oró wọn—

45 Àti pé òpin rẹ̀, tàbí ibẹ̀ náà, tàbí irú ìdálóro wọn, kò sí ẹnití ó mọ̀;

46 Bẹ́ẹ̀ni a kò tíì fi hàn rí, bẹ́ẹni a kò fihàn, bẹ́ẹ̀ni a kì yío fi hàn ẹnikan, bíkòṣe àwọn tí wọ́n mú kí wọ́n jẹ́ alábápín nínú rẹ̀;

47 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi, Olúwa, fi í hàn nípa ìran sí ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n lójúkannáà tún pa á dé lẹ́ẹ̀kansíi;

48 Nítorínáà, òpin rẹ̀, fífẹ̀ rẹ̀, gíga rẹ̀, jíjìn rẹ̀, àti ipò òṣì ibẹ̀, kò yé wọn, tàbí ẹnikẹ́ni bíkòṣe àwọn tí a yàn sínú ìdálẹ́bi yìí.

49 A sì gbọ́ ohùn náà, tí ó wí pé: Kọ ìran náà, nitorí wòó, èyí ni òpin ìran àwọn ìjìyà àwọn ẹni aláìwà bí Ọlọ́run.

50 Àti lẹ́ẹ̀kansíi a jẹ́rìí—nítorí a rí a sì gbọ́, èyí sì ni ẹ̀rí ti ìhìnrere Krístì nípa àwọn ẹnití yíò jade wá ní àjínde àwọn olõtọ́—

51 Àwọn ni àwọn tí wọ́n ti gba ẹ̀rí Jésù, ati tí wọ́n gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ tí a sì rì wọ́n bọmi ní títẹ̀lé àpẹrẹ ìsìnkú rẹ̀, ní rírì wọ́n bọmi ní orúkọ rẹ̀, àti èyí gẹ́gẹ́bí òfin èyítí òun ti fi fún wọn—

52 Pé nípa pípa àwọn òfin mọ́ kí á lè fọ̀ wọ́n, kí a sì wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n ó sì lè gba Ẹ̀mí Mímọ́ nípa ìgbọ́wọ́lé ti ẹni náà tí a ti yàn tí a sì ti fi èdídí dì sí inú agbára yìí;

53 Àti ẹnití ó ti ṣẹ́gun nípa ìgbàgbọ́, tí a sì ti fi èdídí dì nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ìlérí, èyí tí Bàbá tú jáde sí orí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ olõtọ́ àti olódodo.

54 Àwọn ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjọ Àkọ́bí náà.

55 Àwọn ni àwọn lọ́wọ́ ẹnití Baba ti fi ohun gbogbo lé—

56 Àwọn ni àwọn tí wọ́n jẹ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọba, tí wọ́n ti gba lára ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀, àti lára ògo rẹ̀;

57 Wọ́n sì jẹ́ àwọn àlùfáà ti Ọ̀gá Ògo, ní títẹ̀lé àpẹrẹ ètò ti Melkísédékì, èyí tí ó tẹ̀lé ètò ti Enókù, èyí tí ó tẹ̀lé ètò ti Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo.

58 Nítorínáà, bí a ṣe kọọ́, wọ́n jẹ́ ọlọ́run, àní àwọn ọmọ Ọlọ́run—

59 Nítorínáà, gbogbo nkan jẹ́ tiwọn, bóyá ní yíyè tàbí ní kíkú, tàbí àwọn ohun tí ó wà nísisìyí, tàbí awọn ohun tí ó nbọ̀, gbogbo rẹ̀ jẹ́ tiwọn àwọn sì jẹ́ ti Krístì, Krístì sì jẹ́ ti Ọlọ́run.

60 Wọn yíò sì borí ohun gbogbo.

61 Nítorínáà, kí ẹnikẹ́ni máṣe ṣògo nínú ènìyàn, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí òun ṣògo nínú Ọlọ́run, ẹnití yíò fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.

62 Àwọn wọ̀nyí yíò gbé níwájú Ọlọ́run àti Krístì rẹ̀ láé ati títí láéláé.

63 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí òun yíò mú wá pẹ̀lú rẹ̀, nígbàtí òun yíò dé ní àwọsánmọ̀ ti ọ̀run láti jọba ní ilẹ̀ ayé ní orí àwọn ènìyàn rẹ̀.

64 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọn yíò ní ipa nínú àjínde èkínní.

65 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọn yíò jade wá ni àjínde àwọn olõtọ́.

66 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọn ti wá sí Òkè Síónì, àti sí ìlú nlá Ọlọ́run alààyè, ibi ti ọ̀run náà, tí ó jẹ́ mímọ́ jù ibi gbogbo lọ.

67 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n ti wá sí inú àìníye ẹgbẹ́ ti àwọn ángẹ́lì, sí ìpéjọpọ̀ gbogbogbòò àti ìjọ ti Enọkù, àti ti Àkọ́bí náà.

68 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn ní ọ̀run, níbi tí Ọlọ́run àti Krístì ti jẹ́ onídajọ́ gbogbo ènìyàn.

69 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n jẹ́ olõtọ́ ènìyàn tí a sọ di pipe nípasẹ̀ Jésù onílàjà ti májẹ̀mú titun, ẹni tí ó ṣe àṣetán ètùtù pípé yìí nípasẹ̀ títa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.

70 Àwọ̀n wọ̀nyí ni àwọn tí ara wọ́n jẹ́ ti sẹlẹ́stíà, tí ògo wọ́n jẹ́ ti oòrùn, àní ògo ti Ọlọ́run, tí ó ga ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹnití ògo rẹ̀ ati ti oòrùn ní òfuurufú ni a kọ pé wọ́n rí bákannáà.

71 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, a rí ayé Tẹ̀rẹ́stríà, àti kíyèsíi sì wòó, àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ti Tẹ̀rẹ́stríà, àwọn tí ògo wọ́n yàtọ̀ sí ti ìjọ Àkọ́bí àwọn tí wọ́n ti gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lati ọ̀dọ̀ Baba, àní bí ti òṣùpá ṣe yàtọ̀ sí ti oòrùn ni òfuurufú.

72 Kíyèsíi, àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n kú láìsí òfin;

73 Àti bákannáà àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀mí ènìyàn tí a fi pamọ́ nínú túbú, ẹnití Ọmọ bẹ̀wò, àti tí òun wàásù ìhìnrere fún wọn, pé kí wọ́n ó lè gba ìdájọ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn nínú ẹran ara;

74 Àwọn tí kò gba ẹ̀rí Jésù nínú ẹran ara, ṣùgbọ́n tí wọ́n gbà á nígbẹ̀hìn.

75 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọlọ́lá ní orí ilẹ̀ ayé, àwọn tí a fọ́ lójú nípa àrékérekè àwọn ènìyàn.

76 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n gba lára ògo rẹ̀, ṣùgbọ́n kìí ṣe lára ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀.

77 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n gbà nínú wíwà ní ọ̀dọ̀ Ọmọ, ṣùgbọ́n kìí ṣe nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ogo ti Baba.

78 Nítorínáà, àwọn ní tẹ̀rẹ́stríà ara, àti pé wọn kìí ṣe sẹ̀lẹ́stíà ara, wọ́n sì yàtọ̀ ní ògo bí òṣùpá ṣe yàtọ̀ sí oòrùn.

79 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọn kò ní ìgboyà nínú ẹ̀rí Jésù; nítorínáà, wọn kò gba adé náà ní orí ìjọba Ọlọ́run wa.

80 Àti nísisìyí èyí ni òpin ìran náà èyítí a rí nípa ti Tẹ̀rẹ́stríà, tí Olúwa pàṣẹ fún wa láti kọ nígbàtí a sì wà nínú Ẹ̀mí.

81 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, a rí ògo tí tẹ̀lẹ́stíà, èyí tí ògo rẹ̀ jẹ́ kékeré jùlọ, àní bí ògo àwọn ìràwọ̀ ṣe yàtọ̀ sí ògo ti òṣùpá ní òfurufú.

82 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n kò gba ìhìnrere Krístì, tàbí ẹ̀rí Jésù.

83 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ̀n kò sẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

84 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí a jù sísàlẹ̀ sí ọ̀run àpáàdì.

85 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí a kì yíò rà padà lọ́wọ́ èṣù títí di àjínde ìkẹ́hìn, títí tí Olúwa, àní Krístì Ọ̀dọ́ Agùntàn náà, yíò fi parí iṣẹ́ rẹ̀.

86 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọn kò gba lára ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ ní ayé ti ayérayé, ṣùgbọ́n lára ti Ẹ̀mí Mímọ́ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Tẹ̀rẹ́stríà;

87 Àti Tẹ̀rẹ́stríà nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Sẹ̀lẹ́stíà.

88 Àti bákannáà tẹ̀lẹ́stíà náà gbà á nípa ìpínfúnni ti àwọn ángẹ́lì tí a yàn láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn, tàbí àwọn ẹnití a yàn láti máa ṣe íṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ẹ̀mí fún wọn; nítorí wọn yíò jẹ́ ajogún ìgbàlà.

89 Àti báyìí ni a rí, nínú ìran ọ̀run náà, ògo ti tẹ̀lẹ́stíà, èyí tí ó kọjá òye gbogbo;

90 Kò sì sí ẹnikan tí ó mọ̀ ọ́ bíkòṣe òun ẹ̀nití Ọlọ́run ti fi hàn.

91 Àti báyìí ni a rí ògo ti tẹ̀rẹ́stríà èyí tí ó tayọ nínú ohun gbogbo ògo ti Tẹ̀lẹ́stíà, àní ní ògo, àti ní agbára, àti ní ipá, àti ní ìjọba.

92 Àti báyìí ni a rí ògo ti Sẹ̀lẹ́stíà, èyi tí ó tayọ nínú ohun gbogbo—níbi tí Ọlọ́run, àní Baba, ti njọba ní orí ìtẹ́ rẹ̀ láé ati títí láéláé;

93 Níwájú ìtẹ́ ẹni tí ohun gbogbo ntẹríba ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀, tí wọ́n sì nfi ògo fún un láé ati títí láéláé.

94 Àwọn tí wọ́n ngbé ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn ọ̀mọ ìjọ Àkọ́bí; wọ́n sì rí bí a ṣe rí wọn, àti pé wọ́n mọ bí a ṣe mọ̀ wón, nítorí wọ́n ti gba lára ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ àti lára ore-ọ̀fẹ́ rẹ̀;

95 Òun sì mú wọn dọ́gba ní agbára, àti ní ipá, àti ní ìjọba.

96 Ògo tí sẹ̀lẹ́stíà sì jẹ́ ọ̀kan, àní bí ògo ti oòrun ṣe jẹ́ ọ̀kan.

97 Ògo ti tẹ̀rẹ́stríà sì jẹ́ ọ̀kan, àní bí ògo ti òṣùpá ṣe jẹ́ ọ̀kan.

98 Ògo ti Tẹ̀lẹ́stíà sì jẹ́ ọ̀kan, àní bí ògo ti àwọn ìràwọ̀ ṣe jẹ́ ọ̀kan; nítorí bí ìràwọ̀ kan ṣe yàtọ̀ sí ìràwọ̀ míràn ní ògo, àní bẹ́ẹ̀ni ọ̀kan yàtọ̀ sí òmíràn ní ògo ní ayé ti Tẹ̀lẹ́stíà;

99 Nítorí àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ti Paulù, àti ti Àpóllò, àti ti Kéfà.

100 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn díẹ̀ jẹ́ ti ẹnìkan àti pé àwọn díẹ̀ jẹ́ ti ẹlòmíràn—àwọn díẹ̀ jẹ́ ti Krístì àti àwọn díẹ̀ jẹ́ ti Jòhannù, àti àwọn díẹ̀ jẹ́ ti Mósè, àti àwọn díẹ̀ jẹ́ ti Elíasì, àti àwọn díẹ̀ jẹ́ ti Esiah, àti àwọn díẹ̀ jẹ́ ti Isaiah, àti pé àwọn díẹ̀ jẹ́ ti Enọ́kù;

101 Ṣùgbọ́n wọn kò gba ìhìnrere, tàbí ẹ̀rí Jésù, tàbí àwọn wòlíì, tàbí májẹ̀mú ayérayé náà.

102 Èyí tí ó kẹ́hìn gbogbo rẹ̀, gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí a kì yíò kójọpọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́, tí a ó gbà sínú ìjọ Àkọ́bí, tí a ó sì gbà sínú àwọsánmọ̀.

103 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n jẹ́ òpùrọ́, àti oṣó, àti panságà, àti alágbéèrè, àti ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn tí ó sì npa irọ́.

104 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n jìyà ìbínú Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé.

105 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n jìyà ẹ̀san iná ayérayé.

106 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí a sọ sílẹ̀ sí ọ̀run àpáàdì àti tí wọ́n jìyà ìbínú Ọlọ́run Alágbára Jùlọ, títí di ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò, nígbàtí Krístì yíò fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ àtẹlẹsẹ̀ rẹ̀, àti tí Òun yíò ṣe àṣepé iṣẹ́ rẹ̀;

107 Nígbàtí òun yíò gbé ìjọba náà kalẹ̀, tí yíò sì gbé e fún Baba, ní àìlábàwọ́n, wípé: èmi ti borí mo sì ti nìkan tẹ ohun èlò ìfúntí wáínì, àní ìfúntí wáìnì ti gbígbóná ìbínú Ọlọ́run Alágbára Jùlọ.

108 Nígbànáà ni a ó dé e ní adé pẹ̀lú adé ògo rẹ̀, láti jókòó ní orí ìtẹ́ agbára rẹ̀ láti jọba láé ati títí láéláé.

109 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, sì wòó, a rí ògo ti àwọn olùgbé ayé tẹ̀lẹ́stíà, pé wọ́n jẹ́ àìlónkà bíi àwọn ìràwọ̀ ní òfuurufú ojú ọ̀run, tàbí bíi ìyanrìn ní etí òkun;

110 A sì gbọ́ ohùn Olúwa tí ó wípé: Gbogbo àwọn wọ̀nyí yíò tẹ eékún wọn ba, àti olúkúlùkù ahọ́n yíò jẹ́wọ́ fún un ẹni tí ó jókòó ní orí ìtẹ́ láé ati títí láéláé;

111 Nítorí a ó ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ wọn, olúkúlùkù ènìyàn yíò sì gbà gẹ́gẹ́bí awọn iṣẹ́ tirẹ̀, ìjọba tirẹ̀, nínú awọn ibùgbé èyítí a ti pèsè;

112 Wọn yíò sì jẹ́ ìránṣẹ́ ti Ọ̀gá Ògo Jùlọ; ṣùgbọ́n níbi tí Ọlọ́run àti Krístì ngbé wọn kì yíò lè wá síbẹ̀, ayé àìnípẹ̀kun.

113 Èyí ni òpin ìran náà èyí tí a rí, èyí tí a pàṣẹ fún wa láti kọ bí a ṣe wà nínú Ẹ̀mí síbẹ̀.

114 Ṣùgbọ́n títóbi ati yíyanilẹ́nu ni àwọn iṣẹ́ Olúwa, àti àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba rẹ̀ èyí tí òun fi hàn sí wa, èyi tí ó rékọjá gbogbo òye ní ògo, àti ní ipá, àti ní ìjọba;

115 Èyítí Òun pàṣẹ fún wa pé kí a má kọ bí a ṣe wà nínú Ẹ̀mí síbẹ̀, tí kò sì bá òfin mu fún ènìyàn láti wí jade;

116 Bẹ́ẹ̀ni kò sí ènìyàn tí ó ní agbára láti sọ wọ́n di mímọ̀, nítorí a lè rí wọn tàbí kí òye wọn ó yé wa nipa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ nìkan, èyí tí Ọlọ́run fi fùn àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ti sọ ara wọn di mímọ́ níwájú rẹ̀;

117 Sí ẹni tí òun fún ní ànfàní yìí ti rírí àti mímọ̀ fún ara wọn;

118 Pé nípasẹ̀ agbára àti ìṣípayá ti Ẹ̀mí, ní wíwà nínú ẹran ara síbẹ̀, wọ́n lè ní agbàra láti farada wíwà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ayé ògo.

119 Àti sí Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ògo, ọlá, àti ìjọba láé ati títí láéláé. Amín.