Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 95


Ìpín 95

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 1 Oṣù Kẹfà 1833. Ìfihàn yìí jẹ́ ìtẹ̀síwájú ti àwọn ìdarí àtọ̀runwá láti kọ́ ilé kan fún ìjọ́sìn àti ìtọ́sọ́nà, ilé Olúwa (wo ìpín 88:119–136).

1–6, Àwọn Ẹni Mímọ́ ni a báwí fún ìkùnà wọn láti kọ́ ilé Olúwa; 7–10, Olúwa ní ìfẹ́ láti lo ilé Rẹ̀ láti bùn àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní ẹ̀bùn agbára lati òkè wá; 11–17, Ilé náà yíó jẹ́ yíyà sí mímọ́ bí ibi ìjọ́sìn àti fún ilé ẹ̀kọ́ ti àwọn Àpóstélì.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún yín ẹ̀yin ẹnití èmi ní ìfẹ́ sí, àti ẹnití èmi ní ìfẹ́ sí ni èmi sì báwí bákannáà, kí á lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì, nítorí pẹ̀lú ìbáwí náà èmi pèsè ọ̀nà kan fún ìtúsílẹ̀ wọn nínú ohun gbogbo kúrò nínú ìdánwò, èmi sì ti ní ìfẹ́ yín—

2 Nísisìyí, ẹ̀yin gbọdọ̀ jẹ́ bíbáwí kí ẹ sì dúró ní fífibú ní iwájú mi;

3 Nítorí ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan sí mi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bani nínú jẹ́ gidi, nítorí ẹ̀ kò ṣe àyẹ̀wò òfin nlá náà nínú ohun gbogbo, tí èmi ti fi fún yín nípa ti kíkọ́ ilé tèmi;

4 Nítorí ìmúrasílẹ̀ nípa èyítí èmi ní èrò láti pèsè àwọn àpóstélì mi láti pa ẹ̀ka ọgbà ajarà mi fún ìgbà ìkẹ́hìn, pé kí èmi ó lè mú ìṣe àjèjì mi wá sí ìmúṣẹ, pé kí èmi ó lè tú Ẹ̀mi mi jade sí orí gbogbo ẹran ara—

5 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ti ṣe ìlànà fún ní ààrin yín, ẹnití èmi ti pè ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ni a yàn.

6 Àwọn tí a kò yàn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan tí ó bani nínújẹ́ gidi, nítorípé wọn nrìn nínú òkùnkùn ní ọ̀sán gangan.

7 Àti nítorí èyí èmi fi òfin kan fún yín pé kí ẹ̀yin ó pe àpéjọ ọ̀wọ̀ yín, pé kí àwọn ààwẹ̀ yín àti ṣíṣe ọ̀fọ̀ yín ó lè gòkè wá sí etí Olúwa ti Sábáótì, èyítí í ṣe nípa ìtúmọ̀, ẹlẹ́dàá ọjọ́ kìnní, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin.

8 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi fún yín ni òfin kan pé kí ẹ̀yin ó kọ́ ilé kan, nínú ilé èyítí èmi ní èrò lati fi agbára láti òkè wá fún àwọn wọnnì tí èmi ti yàn;

9 Nítorí èyí ni ìlérí Bàbá sí yín; nítorínáà mo pàṣẹ fún yín láti dúró pẹ́, àní bíi àwọn àpóstélì mi ní Jérúsálẹ́mù.

10 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ mi dá ẹ́ṣẹ̀ kan ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bani nínújẹ́ gidi; àwọn ìjà sì dìde ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn Wòlíì; èyí tí ó jẹ́ ohun tí ó bani nínújẹ́ gidi sí mi, ni Olúwa yín wí; nítorínáà èmi rán wọn jáde lati gba ìbáwí.

11 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí ẹ̀yín kọ́ ilé kan. Bí ẹ̀yín bá pa àwọn òfin mi mọ́ ẹ̀yin yíò ní agbára láti kọ́ ọ.

12 Bí ẹ̀yin kò bá pa àwọn òfin mi mọ́, ìfẹ́ ti Bàbá kì yíò tẹ̀síwájú pẹ̀lú yín, nítorínáà ẹ̀yin yíò máa rìn nínú òkùnkùn.

13 Nísisìyí ọgbọ́n nìyí, àti èrò inú Olúwa—ẹ jẹ́kí ilé náà ó jẹ́ kíkọ́, kìí ṣe ní ọ̀nà ti ayé, nítorí èmi kò fi fún yín pé kí ẹ̀yin gbé ìgbé ayé ní ọ̀nà ti ayé;

14 Nítorínáà, ẹ jẹ́kí á kọ́ ọ ní ọ̀nà náà èyítí èmi yíò fi hàn fún ẹni mẹ́ta nínú yín, ẹnití ẹ̀yin yíò yàn àti yà sọ́tọ̀ sí agbára yìí.

15 Àti pé ìwọ̀n rẹ̀ yíò jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà márũn lé láàdọ́ta ní fífẹ̀, ẹ sì jẹ́kí ó jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà márũn lé lọ́gọ́ta ní gígùn, ní àgbàlá ti inú rẹ̀ lọ́hũn.

16 Ẹ sì jẹ́kí apá ìsàlẹ̀ àgbàlá ti inú lọ́hũn náà ó jẹ́ yíyà sí mímọ́ sí mi fún ẹbọ-ọrẹ àmì májẹ̀mú yín, àti ti wíwàásù yín, àti ààwẹ̀ yín, àti àdúrà gbígbà yín, àti ẹbọ-ọrẹ ìfẹ́ inú mímọ́ yín jùlọ sí mi, ní Olúwa yín wí.

17 Ẹ sì jẹ́kí apá òkè àgbàlá ti inú lọ́hũn ó jẹ́ yíyà sí mímọ́ sí mi fún ilé ẹ̀kọ́ àwọn àpóstélì mi, ni Ahman Ọmọ wí; tàbí, ní ọ̀nà míràn, Álfus; tàbí, ní ọ̀nà míràn, Òmégus; àní Jésù Krístì Olúwa yín. Amìn.