Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 9


Ìpín 9

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Oliver Cowdery, ní Harmony, Pennsylvania, ní Oṣù Kẹ́rin 1829. Oliver ni a kìlọ̀ fún láti ní sùúrù a sì rọ̀ ọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn lati kọ̀wé, fún ìgbà kannáà, sí àpèkọ ẹnití ó ntúmọ̀, dípò pé kí ó gbìdánwò láti túmọ̀.

1–6: Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ mìíràn ni a kò tíì túmọ̀; 7–14, Ìwé Ti Mọ́mọ́nì ni a túmọ̀ pẹ̀lú àṣàrò àti pẹ̀lú ìfìdímúlẹ̀ ti ẹ̀mí.

1 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, ọmọ mi, pé nítorí tí ìwọ kò túmọ̀ gẹ́gẹ́bí èyíinì tí ìwọ fẹ́ lati ọ̀dọ̀ mi, àti bí o ṣe tún bẹ̀rẹ̀ láti máa kọ̀wé fún ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àní bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yíò fẹ́ kí o tẹ̀ síwájú títí ìwọ yíò fi parí àkọsílẹ̀ náà, èyí tí mo ti fi lé e lọ́wọ́.

2 Àti nígbànáà, kíyèsíi, àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn ni mo ní, tí èmi yíò fún ọ ní agbára pé kí ìwọ le ṣe àtìlẹ́hìn lati túmọ̀.

3 Ṣe sùúrù, ọmọ mi, nítorí ó jẹ́ ọgbọ́n ní inú mi, àti pé kò tọ́nà pé kí o túmọ̀ ní àkókò yìí.

4 Kíyèsíi, iṣẹ́ tí a pè ọ́ láti ṣe ni láti kọ ìwé fún ìránṣẹ́ mi Joseph.

5 Àti, kíyèsíi, nítorípé ìwọ kò tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́bí o ṣe bẹ̀rẹ̀, nígbàtí o dáwọ́lé lati máa túmọ̀, ni mo ṣe gba ànfàní yìí kúrò ní ọwọ́ rẹ.

6 Má ṣe kùn sínú, ọmọ mi, nítorí ó jẹ́ ọgbọ́n nínú mi pé mo ti hùwà sí ọ ní ọ̀nà yìí.

7 Kíyèsíi, kò tíì yé ọ; ìwọ ti ní èrò pé èmi yíò fi í fún ọ, nígbàtí ìwọ kò ní èrò inú bíkòṣe pé kí o beèrè lọ́wọ́ mi.

8 Ṣùgbọ́n, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe àsàrò rẹ̀ nínú iyè rẹ; lẹ́hìnnáà ìwọ gbọ́dọ̀ bèerè lọ́wọ́ mi bóyá ó tọ́, bí ó bá sì tọ́, èmi yíò mú kí oókan àyà rẹ kí ó gbóná nínú rẹ; nítorínáà, ìwọ yíò mọ̀ lára pé ó tọ́.

9 Ṣùgbọ́n bí kò bá tọ́ ìwọ kì yíò ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀, ṣugbọ́n ìwọ yíò ní ìraníyè ti ìrònú èyí tí yíò mú kí o gbàgbé ohun tí ó jẹ́ àìtọ́; nítorínáà, ìwọ kò leè kọ ohun náà tí ó jẹ́ mímọ́ bíkòṣe pé a bá fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ mi.

10 Nísisìyí, bí ìwọ bá ti mọ èyí ìwọ ìba ti túmọ; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò tọ̀nà pé kí o túmọ̀ nísisìyí.

11 Kíyèsíi, ó tọ̀nà nígbàtí o bẹ̀rẹ̀; ṣùgbọ́n ìwọ bẹ̀rù, àti pé àkókò náà ti kọjá, kò sì tọ̀nà mọ́ nísisìyí;

12 Nítorí, njẹ́ ìwọ kò kíyèsíi pé mo ti fun ìránṣẹ mi Joseph ní ànító okun, nípa èyí tí àlàfo náà dí? Kò sì sí ọ̀kankan nínú yin tí mo dá lẹ́bi.

13 Ṣe ohun yìí èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ, ìwọ yíò sì ṣe rere. Jẹ́ olõtọ́, kí o má sì ṣe gba ìdánwò láàyè.

14 Dúró ṣinṣin nínú iṣẹ́ náà èyí tí mo ti pè ọ́ sí, àti pé irun orí rẹ kan kì yíò sọnù, a ó sì gbé ọ sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Amin.