Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 124


Ìpín 124

Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith, ní Nauvoo, Illinois, 19 Oṣù Kínní 1841. Nítorí ti inúnibíni tí ó npọ̀ síi àti ìgbésẹ̀ àwọn àìbófinmu ní ìtakò wọ́n láti ọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni a fi agbára mú láti fi Missouri sílẹ̀. Àṣẹ ìpanirun náà tí ó jade lati ọwọ́ Lilburn W. Boggs, gómìnà ti Missouri, ní ònkà ọjọ́ 27 Oṣù Kẹ̀wã 1838, kò fi ààyè yíyàn kankan sílẹ̀. Ní 1841, nígbàtí à fúnni ní ìfihàn yìí, ìlu nlá Nauvoo, tí ó wà ní orí ilẹ̀ ìletò ti Commerce, Illinois, ni àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti kọ́, níbẹ̀ ni wọ́n sì ti fi olú ilé iṣẹ́ ti Ìjọ kalẹ̀ sí.

1–14, Joseph Smith ni a pàṣẹ fún láti ṣe ìkéde ìhìnrere kan pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí ààrẹ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àwọn gómìnà, àti àwọn aláṣẹ ti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; 15–21, Hyrum Smith, David W. Patten, Joseph Smith Àgbà, àti àwọn míràn láàrin àwọn tí wọ́n wà láàyè àti àwọn tí wọ́n ti kú ni a bùkúnfún fún ìṣòtítọ́ pátápátá àti ìwà rere wọn; 22–28, Àwọn Ẹni Mímọ́ ni a pàṣẹ fún láti kọ́ ilé kan fún ìtọ́jú àwọn àjèjì àti tẹ́mpìlì kan ní Nauvoo; 29–36, Àwọn ìrìbọmi fún àwọn òkú níláti jẹ́ ṣíṣe nínú àwọn tẹ́mpìlì; 37–44, Àwọn ènìyàn Olúwa máa nfi ìgbà gbogbo kọ́ àwọn tẹ́mpìlì fún ṣíṣe àwọn ìlànà mímọ́; 45–55, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni a fi ààyè gbà láti máṣe kọ́ tẹ́mpìlì ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson nítorí ti ìfìyàjẹni ti àwọn ọ̀tá wọn; 56–83, Àwọn ìtọ́nisọ́nà ni a fi fúnni fún kíkọ́ Ilé Nauvoo náà; 84–96, Hyrum Smith ni a pè láti jẹ́ pátríákì kan, láti gba àwọn kọ́kọ́rọ́, àti láti dúró ní ààyè Oliver Cowdery; 97–122, William Law àti àwọn míràn ní a fún ní ìmọ̀ràn nínú àwọn lãlã wọn; 123–145, Àwọn òṣìṣẹ́ gbogbogbò àti àwọn òṣìṣẹ́ ti àdúgbò ni a dárúkọ, pẹ̀lú àwọn ojúṣe wọn àti iyejú ìgbìmọ̀ tí wọn so mọ́.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, inú mi dùn gidigidi pẹ̀lú ẹbọ-ọrẹ rẹ àti jijẹ́wọ́ ìmọ̀ rẹ, èyítí ìwọ̀ ti ṣe nítorí fún ìdí yìí ni mo gbé ọ dìde, kí èmi ó lè fi ọgbọ́n mi hàn jade nípasẹ̀ àwọn ohun aláìlágbára ti ilẹ̀ ayé.

2 Àwọn àdúrà rẹ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú mi; àti ní ìdáhùn sí wọn mo wí fún ọ, pé nísisìyí a pè ọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti ṣe ìkéde ìhìnrere mi pẹ̀lú ọ̀wọ̀, àti ti èèkàn yìí tí èmi ti fi lọ́lẹ̀ láti jẹ́ òkúta igun ilé ti Síónì, èyítí a ó dán pẹ̀lú ìdánmọ́rán èyítí yíó dàbí àfijọ ti ààfin kan.

3 Ìkéde yìí ni a ó ṣe sí gbogbo àwọn ọba ayé, sí orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ibẹ̀, sí ọlọ́lá ààrẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, àti àwọn onípò gígá gómìnà ti orílẹ̀-èdè nínú èyítí ìwọ ngbé, àti sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé tí ó fọ́nká kiri.

4 Jẹ́ kí ó wà ní kíkọ̀ nínú ọkàn tutu àti nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí yíò wà nínú rẹ ni àkókò kíkọ ti òun kannáà;

5 Nítorí a ó fi fún ọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti mọ ìfẹ́ inú mi nípa àwọn ọbà wọnnì àti àwọn aláṣẹ, àní ohun tí yíò débá wọn ní ìgbà kan tí ó nbọ̀.

6 Nítorí, kíyèsíi, èmi ti fẹ́rẹ̀ pè wọ́n láti fi iyè sí ìmọ́lẹ̀ àti ògo Síónì, nítorí àkókò náà tí a dá ti dé tán láti ṣe ojúrere sí i.

7 Nítorínáà, ké pè wọ́n pẹ̀lú ìkéde ní ohùnrara, àti pẹ̀lu ẹ̀rí rẹ, láìbẹ̀rù wọn, nítorí wọ́n dàbíi koríko, àti gbogbo ògo wọn bí òdòdó ti ibẹ̀ tí yíò rẹ̀ dànù láìpẹ́, kí wọ́n lè wà bákannáà láì ní àwáwí—

8 Àti pé kí èmi lè bẹ̀ wọ́n wò ní ọjọ́ ìbẹ̀wò, nígbàtí èmi yíò ká ìbòjú ti bíbò ojú mi, láti yàn ìpín ti aninilára láàrin àwọn àgàbàgebè, níbití ìpahínkeke gbé wà, bí wọ́n bá kọ àwọn ìránṣẹ mi àti ẹ̀rí mi èyítí mo ti fi hàn sí wọn.

9 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi yíò bẹ̀ wọ́n wò èmi ó sì mú ọkàn wọn rọ̀, púpọ̀ nínú wọn fún ire rẹ, kí ìwọ ó lè rí ore ọ̀fẹ́ ní ojú wọn, kí wọ́n kí ó lè wá sí ìmọ́lẹ̀ ti òtítọ́, àti àwọn Kèfèrí sí ìgbéga tàbí gbígbé Síónì sókè.

10 Nítorí ọjọ́ ìbẹ̀wò mi náà nbọ̀ kánkán, ní wákàtí nígbàtí ẹ̀yin kò lérò; àti níbo ní àbò àwọn ènìyàn mi yíò wà, àti ibi ìsádi fún àwọn wọnnì tí yíó ṣẹ́kù nínú wọn?

11 Ẹ jí, ẹ̀yin Ọba ilẹ̀ ayé! Ẹ wá, ẹ wá, pẹ̀lú wúrà yín àti fàdákà yín, sí ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn mi, sí ilé àwọn ọmọbìnrin Síónì.

12 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Robert B. Thompson ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ ìkéde yìí, nítorí inú mi dùn síi gidigidi, àti pé kí òun wà pẹ̀lú rẹ;

13 Jẹ́ kí òun, nítorínáà, fetísílẹ̀ sí ìmọ̀ràn rẹ, àti pé èmi yíò bùkún fún un pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìlọpo àwọn ìbùkún; kí òun jẹ́ olódodo àti olõtọ́ nínú ohun gbogbo láti ìsisìyí lọ, òun yíò sì di nlá ní ojú mi;

14 Ṣùgbọ́n kí òun rantí pé iṣẹ́ ìríjú rẹ̀ ni èmi yíò beerè ní ọwọ́ rẹ̀.

15 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ìbùkún ni fún ìránṣẹ́ mi Hyrum Smith; nítorí èmi, Olúwa, fẹ́ràn rẹ̀ nítorí ìṣòtítọ́ ti ọkàn rẹ̀, àti nítorítí ó fẹ́ràn èyítí ó jẹ́ òtítọ́ ní iwájú mi, ni Olúwa wí.

16 Lẹ́ẹ̀kansíi, kí ìránṣẹ́ mi John C. Bennett ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú lãlã rẹ ní rírán ọ̀rọ̀ mi sí àwọn ọba àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé, kí ó sì dúró tì ọ́, àní ìwọ ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, ní ìgbà ìpọ́njú; èrè rẹ̀ kì yíò sì kùnà bí òun bá gba ìmọ̀ràn.

17 Àti fún ìfẹ́ rẹ̀ òun yíò di nlá, nítorí òun yíò jẹ́ tèmi bí òun bá ṣe èyí, ní Olúwa wí. Èmi ti rí iṣẹ́ tí òun ti ṣe, èyítí èmi tẹ́wọ́gbà bí òun bá tẹ̀síwájú, èmi yíò sì dé e ní adé pẹ̀lú àwọn ìbùkún àti ògo nlá.

18 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún ọ pé ìfẹ́ inú mi ni pé kí ìránṣẹ́ mi Lyman Wight ó tẹ̀síwájú ní wíwàásù fún Síónì, nínú ọkàn tutu, ní jíjẹ́wọ́ mi níwájú aráyé; èmi yíò sì rù ú sókè bíi ní oríi àwọn apá idì; òun yíò sì ní ògo àti ọlá sí ara rẹ̀ àti sí orúkọ mi.

19 Pé nígbàtí òun bá parí iṣẹ́ rẹ̀ kí èmi kí ó lè gbà á sí ọ̀dọ̀ èmi tìkárãmi, àní bí mo ti ṣe ìránṣẹ́ mi David Patten, ẹnití ó wà pẹ́lù mi ní àkókò yìí, àti pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Edward Partrídge, àti pẹ̀lú arúgbó ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Àgbà, ẹnití ó jókòó pẹ̀lú Abráhámù ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, alábùkúnfún àti mímọ́ sì ni òun, nítorí òun jẹ́ tèmi.

20 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi George Miller wà láìní ẹ̀tàn; a lè fi ọkàn tán an nítorí ìwà òtítọ́ ọkàn rẹ̀; àti fún ìfẹ́ èyítí òun ní sí ẹ̀rí mi èmi, Olúwa, fẹ́ràn rẹ̀.

21 Nítorínáà mo wí fún ọ, èmi fi èdídí dì ìpò iṣẹ́ àjọ bíṣọ́pù sí orí rẹ̀, gẹ́gẹ́bí sí ìránṣẹ́ mi Edward Partridge, pé kí òun ó lè gba èto ìyàsímímọ́ ti ilé mi, pé kí òun ó lè fi àwọn ìbùkún sí orí àwọn tálákà nínú àwọn ènìyàn mi, ni Olúwa wí. Kí ẹnikẹ́ni máṣe pẹ̀gàn ìránṣẹ́ mi George, nítorí òun yíò bu ọlá fún mi.

22 Kí ìránṣẹ́ mi George, àti ìránṣẹ́ mi Lyman, àti ìránṣẹ́ mi John Snider, àti àwọn yókù, ó kọ́ ilé kan sí orúkọ mi, irú ọ̀kan bí èyítí ìránṣẹ́ mi Joseph yíò fi hàn sí wọ́n, ní orí ibi náà èyítí òun yíò fi hàn sí wọn bákannáà.

23 Òun yíò sì wà fún ilè ìpèsè ibùgbé, ilé kan tí àwọn àlejò lè wá láti ọ̀nà jíjìn láti gbé inú rẹ̀; nítorínáà kí ó jẹ́ ilé tí ó dára, tí ó yẹ fún gbogbo ìtẹ́wọ́gbà, kí arìnrìnàjò tí ó ti rẹ̀ ó lè rí ìlera àti ààbò nígbàtí òun bá jíròrò nípa ọ̀rọ̀ Olúwa; òkúta igun ilé náà ni èmi sì ti yàn fún Síónì.

24 Ilé yìí yíò jẹ́ ibùgbé àlãfíà bí ó bá jẹ́ kíkọ́ sí orúkọ mi, àti bí gómìnà èyítí a ó yàn sí i kò bá gba ìbàjẹ́ kankan láàyè lati wá sí orí rẹ̀. Òun yíò jẹ́ mímọ́, tàbí Olúwa Ọlọ́run rẹ kì yíò gbé nínú rẹ̀.

25 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, jẹ́kí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ mi ó wá láti ọ̀nà jíjìn.

26 Kí ẹ sì rán àwọn onṣẹ́ tí wọ́n yára, bẹ́ẹ̀ni, àwọn àsàyàn onṣẹ́, ẹ sì wí fún wọn: Ẹ wá, pẹ̀lú gbogbo wúrà yín, àti fàdákà yín, àti àwọn òkúta oníyebíye yín, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun àtijọ́ yín; àti pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀ àwọn ohun àtijọ́, tí wọn fẹ́ wá, lè wá, kí wọn ó sì mú igi ọgbà náà wá, àti igi fírì, àti igi pínì, lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn igi oníyebíye ti ilẹ̀ ayé;

27 Àti pẹ̀lú irin, pẹ̀lú bàbà, àti pẹ̀lú idẹ, àti pẹ̀lú irin tánganran, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn nkan yín oníyebíye ti ilẹ̀ ayé; kí ẹ sì kọ́ ilé kan sí orúkọ mi, fún Ẹni Gíga jùlọ láti gbé nínú rẹ̀.

28 Nítorí kò sí ibi kan tí a rí ní ilẹ̀ ayé tí òun lè wá sí kí ó sì mú padà bọ̀sípò lẹ́ẹ̀kansíi èyíinì tí ó ti sọnù sí yín, tàbí èyítí òun ti gbà lọ, àní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oyè àlùfáà.

29 Nítorí àwo omi ìrìbọmi kan kò sí ní orí ilẹ̀ ayé, pé kí wọn, àwọn ènìyàn mímọ́ mi, lè ṣe ìrìbọmi fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti kú—

30 Nítorí ìlànà yìí jẹ́ ti ilé mi, kò sì le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sími, bíkòṣe ní àwọn ọjọ́ àìní yín, nínú èyí tí ẹ kò lè kọ́ ilé kan sí mi.

31 Ṣùgbọ́n mo pàṣẹ̀ fún yín, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mímọ́ mi, láti kọ́ ilé kan sí mi; mo sì fi ààyè tí ó tó sílẹ̀ fún yín láti kọ́ ilé kan sí mi; àti láàrin àkókò yìí àwọn ìrìbọmi yín yíò ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí mi.

32 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, ní òpin ààyè yìí àwọn ìrìbọmi yín fún àwọn òkú yín kì yíò ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí mi; bí ẹ̀yin kò bá sì ṣe àwọn ohun wọ̀nyìí ní òpin ààyè yìí a ó kọ̀ yín sílẹ̀ bí ìjọ, pẹ̀lú àwọn òkú yín, ní Olúwa Ọlọ́run yín wí.

33 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé lẹ́hìn tí ẹ́ bá ti ní àkókò tí ó tó láti kọ́ ilé kan sí mi, níbití ìlànà ṣíṣe ìrìbọmi fún àwọn òkú ti dára, àti fún èyíti ìkannáà jẹ́ fífi lélẹ̀ láti ìṣaájú ìpìlẹ̀ ayé, àwọn ìrìbọmi yín fún àwọn òkú yín kò lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí mi;

34 Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti yan àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mímọ́, kí ẹ̀yin ó lè gba ọlá àti ògo.

35 Àti lẹ́hìn àkókò yìí, àwọn ìrìbọmi yín fún àwọn òkú, nípa àwọn tí a fọ́nká kiri, kì yíò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí mi, ni Olúwa wí.

36 Nítorí a ti yàn án pé ní Síónì, àti ní àwọn èèkàn rẹ̀, àti ní Jérusálẹ́mù, àwọn ibi wọnnì tí èmi ti yàn fún ìsádi, ni yíò jẹ́ àwọn ibi fún àwọn ìrìbọmi yín fún àwọn òkú yín.

37 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, báwo ni àwọn ìwẹ̀númọ́ yín yíò ṣe jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí mi, bíkòṣe pé ẹ̀yin ṣe wọ́n nínú ilé kan èyítí ẹ̀yin ti kọ́ sí orúkọ mi?

38 Nítorí, fún ìdí èyi ni mo pàṣẹ fún Mósè pé kí òun kọ́ àgọ́ kan, pé kí wọ́n ó gbé e pẹ̀lú wọn nínú aginjù, àti láti kọ́ ilé kan ní ilẹ̀ ilérí, pé kí àwọn ìlànà wọnnì lè di fífihàn àwọn èyítí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà síwájú kí ayé tó wà.

39 Nítorínáà, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé àwọn àmì òróró yín, àti àwọn ìwẹ̀númọ́ yín, àti àwọn ìrìbọmi yín fún àwọn òkú, àti àwọn àpéjọ ọ̀wọ̀ yín, àti àwọn ìrántí yín fún àwọn ẹbọ yín láti ọwọ́ àwọn ọmọ Lefì, àti fún àwọn ọ̀rọ̀ ìfihàn yín ní àwọn ibi mímọ́ jùlọ níbití ẹ̀yin ti ngba àwọn ìbásọ̀rọ̀, àti àwọn òfin àti àwọn ìdájọ́ yín, fún ìbẹ̀rẹ̀ ti àwọn ìfihàn àti ìpìlẹ̀ Síónì, àti fún ògo, ọlá, àti ìbùkún ti gbogbo àwọn agbègbè rẹ̀, ni a yàn nípa ìlànà ti ilé mímọ́ mi, èyítí a nfi gbogbo ìgbà pàṣẹ fún àwọn ènìyàn mi láti kọ́ sí orúkọ mímọ́ mi.

40 Àti lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí ilé yìí di kíkọ́ sí orúkọ mi, kí èmi ó lè fi àwọn ìlànà mi ti inú rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn mi;

41 Nítorí mo rò pé ó tọ̀nà láti fi hàn sí ìjọ mi àwọn ohun èyítí a ti pamọ́ sí ìfipamọ́ láti ìgbà ṣaájú ìpilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí wọ́n ní ṣe sí ìgbà ìríjú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti àwọn àkókò.

42 Èmi yíò sì fi hàn sí ìránṣẹ́ mi Joseph gbogbo àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ilé yìí, àti oyè àlùfáà ti ibẹ̀, àti ibi náà ní orí èyítí a ó kọ́ ọ sí.

43 Ẹ̀yin yíò sì kọ́ ọ sí orí ibi èyítí ẹ̀yin ti ronú kíkọ́ rẹ̀ sí, nítorí èyíinì ni ọ̀gangan ibití èmi ti yàn fún yín láti kọ́ ọ sí.

44 Bí ẹ̀yin bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo ipá yín, èmi yíò ya ọ̀gangan ibẹ̀ sí mímọ́ kí á lè sọ ọ́ di mímọ́.

45 Bí àwọn ènìyàn mi bá sì fetísílẹ̀ sí ohùn mi, àti sí ohùn àwọn ìránṣẹ́ mi àwọn ẹnití èmi ti yàn láti darí àwọn ènìyàn mi, kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, a kì yíò ṣí wọn nípò kúrò ní ààyè wọn.

46 Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá fetísílẹ̀ sí ohùn mi, tàbí sí ohùn àwọn ènìyàn wọ̀nyìí àwọn ẹnití èmi ti yàn, wọn kì yíò di alábùkúnfún, nítorítí wọ́n sọ àwọn ilẹ̀ mímọ́ mi di àìmọ́, àti àwọn ìlànà mímọ́ tèmi, àti àwọn ìwé àdéhùn, àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ mi èyítí mo fi fún wọn.

47 Yíò sì ṣe pé bí ẹ̀yin bá kọ́ ilé kan sí orúkọ mi, tí ẹ̀yin kò sì ṣe àwọn ohun náà tí èmi wí, èmi kì yíò mú ìbúra ṣẹ èyítí mo ṣe síi yín, tàbí mú àwọn ìlérí ṣẹ èyítí ẹ̀yin nretí ni ọwọ́ mi, ni Olúwa wí.

48 Nítorí dípò àwọn ìbùkún, ẹ̀yin, nípa àwọn iṣẹ́ yín, mú àwọn ègún wá, ìbínú, ìrunú, àti àwọn ìdájọ́ sí orí ara yín, nípa àìmòye yín, àti nípa gbogbo àwọn ohun ìríra yín, èyítí ẹ̀ nṣe níwájú mi, ni Olúwa wí.

49 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wi fún yín, pé nigbàtí èmi bá fi òfin kan fún ẹ̀nikẹ́ni nínú àwọn ọmọ ènìyàn láti ṣe iṣẹ́ kan sí orúkọ mi, àti tí àwọn ọmọ ènìyàn wọnnì lọ pẹ̀lú gbogbo ipá àti pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní láti ṣe iṣẹ́ náà, tí wọn kò sì dáwọ́ aápọn wọn dúró, àti tí àwọn ọ̀tá wọn bá wá kọlù wọ́n tí wọ́n sì dí wọn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà, kíyèsíi, ó jẹ́ ìpinnu mi láti máṣe béèrè iṣẹ́ náà mọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ènìyàn wọnnì, ṣùgbọ́n láti tẹ́wọ́gba àwọn ẹbọ-ọrẹ wọn.

50 Àti ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá ti àwọn òfin mímọ́ àti àwọn àṣẹ mi ni èmi yíò bẹ̀wò ní orí àwọn ẹnití wọ́n dí iṣẹ́ mi lọ́wọ́, sí ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin, níwọ̀n bí wọn kò bá ronúpìwàdà, àti tí wọ́n kóríra mi, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

51 Nítorínáà, fún ìdí èyí ni mo tẹ́wọ́gba àwọn ẹbọ-ọrẹ ti àwọn wọnnì tí mo pàṣẹ fún láti kọ́ ìlú nlá kan àti ilé kan sí orúkọ mi, ní ìjọba ìbílẹ̀ Jackson, Missouri, àti tí àwọn ọ̀tá wọn dí wọn lọ́wọ́, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí.

52 Èmi yíò sì dáhùn ìdájọ́, ìbínú, àti ìrúnú, ìpohùnréré ẹkún, àti àròkàn, àti ìpahínkeke sí orí wọn, sí ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin, níwọ̀n bí wọn kò bá ronúpìwàdà, àti tí wọ́n kóríra mi, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí.

53 Èyí ni èmi sì fi ṣe àpẹ̀rẹ sí yín, fún ìtùnú yín nípa gbogbo àwọn wọnnì tí a pàṣẹ fún láti ṣe iṣẹ́ kan àti tí a sì dí wọn lọ́wọ́ nípa ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, àti nípa ìninilára, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí.

54 Nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, èmi yíò sì gba gbogbo àwọn arákùnrin yín wọnnì là tí ọkan wọn mọ́, àti tí wọ́n ti pa ní ilẹ̀ Missouri, ni Olúwa wí.

55 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, mo pàṣẹ fún yín lẹ́ẹ̀kansíi láti kọ́ ilé kan sí orúkọ mi, àní ní ibí yìí, kí ẹ̀yin ó le fi ara yín dá mi lójú pé ẹ̀yin jẹ́ olõtọ́ nínú ohun gbogbo èyíkéyìí tí èmi bá pàṣẹ fún yín, kí èmi ó lè bùkún yín, kí nsì dée yín ládé pẹ̀lú ọlá, ara àìkú, àti ìyè àìnípẹ̀kun.

56 Àti nísìsìyìí mo wí fún yín, nípa ti ilé ìpèsè ibùgbé mi èyítí mo pàṣẹ fún yín láti kọ́ fún ìpèsè ibùgbé fún àwọn àlejò, ẹ jẹ́kí ó jẹ́ kíkọ́ sí orúkọ mi, ẹ sì jẹ́kí orúkọ mi kí ó wà ní orí rẹ̀, àti pé ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Joseph àti ilé rẹ̀ kí ó ní ààyè nínú rẹ̀, láti ìran dé ìran.

57 Nítorí àmì òróró yìí tí mo fi sí orí rẹ̀, pé ìbùkún rẹ̀ yíò wà pẹ̀lú ní orí irú àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀.

58 Àti bí mo ṣe wí fún Ábráhámù nípa àwọn ìbátan ilẹ̀ ayé, àní bẹ́ẹ̀ni mo wí fún ìránṣẹ́ mi Joseph: Nínú rẹ àti nínú irú ọmọ rẹ ni ìbátan ilẹ̀ ayé yíò di alábùkúnfún.

59 Nítorínáà, kí ìránṣẹ́ mi Joseph àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀ kí ó ní ààyè nínú ilé náà, láti ìran dé ìran, láé àti títí láéláé, ni Olúwa wí.

60 Ẹ sì jẹ́kí a pe orúkọ ilé náà ní Ilé Nauvoo; ẹ sì jẹ́kí ó jẹ́ ibùgbé aláyọ̀ kan fún ènìyàn, àti ibi ìsinmi kan fún arìrìnàjò tí ó ti rẹ̀, kí òun ó lè ronú ògo Síónì, àti ògo ti èyí, òkúta igun ilé ibẹ̀;

61 Kí òun kí ó lè gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn ẹnití mo ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ bíi àwọn irúgbìn òkìkí, àti bíi àwọn olùṣọ́ ní orí àwọn ògiri rẹ̀.

62 Kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, kí ìránṣẹ́ mi George Miller, àti ìránṣẹ́ mi Lyman Wight, àti ìránṣẹ́ mi John Snider, àti ìránṣẹ́ mi Peter Haws, ṣe ètò ara wọn, kí wọn ó sì yan ẹnìkan nínú wọn láti jẹ́ ààrẹ ní orí iyejú wọn fún èrò ti kíkọ́ ilé náà.

63 Wọn yíò sì gbé ìwé òfin kan kalẹ̀, nípa èyítí wọn yíò le gba ìpín ìdókòwò fún kíkọ́ ilé náà.

64 Wọn kì yíò sì gbà dín ní àádọta owó dọ́là fún ìpín ìdókòwò kan nínú ilé náà, àti pé a ó gbà wọ́n láàyè láti gba ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún owó dọ́là láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni kan fún ìpín ìdókòwò nínú ilé náà.

65 Ṣùgbọ́n a kì yíò gbà wọ́n láàyè láti gba owó tí ó pọ̀ ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún dọ́là lọ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni kan.

66 A kì yíò sì gba wọ́n láàyè láti gbà dín ní àádọ́ta owo dọ́là fún ìpín ìdókòwò kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni kan nínú ilé náà.

67 A kì yíò sì gbà wọ́n láàyè láti gba ènìyàn kan, bíi ẹnití ó fi owó dókòwò nínú ilé yìí, bíkòṣe pé ẹni yìí kannáà san owó ìdókòwò sí ọwọ́ wọn ní àkókò tí ó gba ìpín ìdókòwò;

68 Àti ní òsùnwọ̀n sí iye owó ìdókòwò tí o bá san sí ọwọ́ wọn ni òun yíò gba ìpín ìdókòwò nínú ilé náà; ṣùgbọ́n bí óun kò bá san ohunkóhun sí ọwọ́ wọn òun kì yíò gba ìpín ìdókòwò nínú ilé náà.

69 Àti pé bí ẹnikẹ́ni bá san ìdókòwò sí ọwọ́ wọn èyí yíò wà fún ìpín ìdókòwò nínú ilé náà, fún ara rẹ̀, àti fún ìran lẹ́hìn rẹ̀, láti ìran dé ìran, níwọ̀nbí òun àti àwọn ajogún rẹ̀ yíò di okòwò náà mú, àti tí wọn kì yíò tàá tàbí mú ìdókòwò náà lọ kúrò ní ọwọ́ wọn nípa ìfẹ́ inú àti ìṣe wọn, bí ẹ̀yin bá ṣe ìfẹ́ mi, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí.

70 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí ìránṣẹ́ mi George Miller, àti ìránṣẹ́ mi Lyman Wight, àti ìránṣẹ́ mi John Snider, àti ìránṣẹ́ mi Peter Haws, bá gba ìdókòwò kankan sí ọwọ́ ara wọn, ní àwọn owó, tàbí ní àwọn ohun ìní nínú èyítí wọn gba iye àwọn owó náà ní tòótọ́, wọn kì yíò lo èyíkéyìí apákan ìdókòwò náà fún ohun míràn, bíkòṣe nínú ilé náà nìkan.

71 Bí wọ́n bá sì lo èyíkéyìí lára ìdókòwò náà sí ibòmíràn, nínú ilé náà nìkan, láì gba ìfọwọ́sí ti olùdókòwò, àti tí wọn kò san padà ní ilọ́po mẹ́rin fún ìdókòwò náà èyítí wọ́n ti lò ní ìbòmíràn, nínú ilé náà nìkan, wọn yíò di ẹni ìfibú, wọn ó sì di mímú kúrò ní ààyè wọ́n, ni Olúwa Ọlọ́run wí; nítorí èmi, Olúwa, ni Ọlọ́run, èmi kò sì le dí kíkẹ́gàn nínú èyíkéyìí àwọn ohun wọ̀nyí.

72 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, kí ìránṣẹ́ mi Joseph ó san ìdókòwò sí ọwọ́ wọn fún kíkọ́ ilé náà, bí ó bá ṣe tọ́ ní ojú rẹ̀; ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ mi Joseph kì yìò lè san ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún owó dọ́là ìdókòwò nínú ilé náà, tàbí kéré ju àádọ́ta owó dọ́là, bẹ́ẹ̀ni kì yíò sí ẹnikẹ́ni míràn, ni Olúwa wí.

73 Àwọn míràn sì wà bákannáà tí wọ́n fẹ́ láti mọ ìfẹ́ inú mi nípa wọn, nítorí wọ́n ti béèrè rẹ̀ ní ọwọ́ mi.

74 Nítorínáà, mo wí fún yín nípa ìránṣẹ́ mi Vinson Knight, bí òun yíò bá ṣe ìfẹ́ inú mi kí òun fi ìdókòwò sínú ilé náà fún ara rẹ̀, àti fún ìran rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀, láti ìran dé ìran.

75 Ẹ sì jẹ́kí òun gbé ohùn rẹ̀ sókè pẹ́ àti ní aríwo, láàrin àwọn ènìyàn náà, láti bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn tálákà àti aláìní; àti kí òun máṣe kùnà, tàbí kí ọkàn rẹ̀ kãrẹ̀; èmi yíò sì tẹ́wọ́gba àwọn ẹbọ-ọrẹ rẹ̀, nítorí wọn kì yíò dàbí àwọn ẹbọ Kaínì sí mi, nítorí òun yíò jẹ́ tèmi, ní Olúwa wí.

76 Ẹ jẹ́kí ẹbí rẹ̀ ó yọ̀ kí wọn ó sì yí ọkàn wọn kúrò nínú ìpọ́njú; nítorí mo ti yan òun mo sì ti fi àmì òróró sí orí rẹ̀, a ó sì bu ọlá fún un láàrin ilé rẹ̀, nítorí èmi yíò dárí gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì, ní Olúwa wí. Àmín.

77 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Hyrum fi ìdókòwò sí inú ilé náà bí ó bá ṣe tọ́ ní ojú rẹ̀, fún ara rẹ̀ àti ìran rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀, láti ìran dé ìran.

78 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Isaac Galland ó fi ìdókòwò sí inú ilé náà; nítorí èmi, Olúwa, fẹ́ràn rẹ̀ fún iṣẹ́ tí ó ti ṣe, èmi ó sì dárí gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì; nítorínáà, ẹ jẹ́kí á rantí rẹ̀ fún ẹ̀tọ́ kan ní inú ilé náà láti ìran dé ìran.

79 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Isaac Galland ó jẹ́ yíyàn láàrin yín, kí á sì yàn án nípa ọwọ́ ìránṣẹ́ mi William Marks, kí á sì bùkún fún un láti ọwọ́ rẹ̀, láti lọ pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Hyrum láti parí iṣẹ́ èyítí ìránṣẹ́ mi Joseph yíò tọ́kasí fún wọn, a ó sì bùkún fún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀.

80 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi William Marks san ìdókòwò sí inú ilé náà, bí ó bá ṣe tọ́ ní ojú rẹ̀, fún ara rẹ̀ àti ìran rẹ̀, láti ìran dé ìran.

81 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Henry G. Sherwood ó san ìdókòwò sí inú ilé náà, bí ó bá ṣe tọ́ ní ojú rẹ̀, fún ara rẹ̀ àti fún irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀, láti ìran dé ìran.

82 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi William Law kí ó san ìdókòwò sí inú ilé náà, fún ara rẹ̀ àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀, láti ìran dé ìran.

83 Bí òun bá ṣe ìfẹ́ mi ẹ máṣe jẹ́kí òun mú mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lọ sí àwọn ilẹ̀ ìlà oòrùn, àní sí Kirtland; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi, Olúwa, yíò kọ́ Kirtland sókè, ṣùgbọ́n èmi, Olúwa, ní pàṣán kan ní pípèsè fún àwọn olùgbé ibẹ̀.

84 Àti pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Almon Babbitt, àwọn ohun púpọ̀ ni ó wà èyítí inú mi kò dùn sí; kíyèsíi, òun nlépa láti gbé ìmọ̀ràn tirẹ̀ kalẹ̀ dípò ìmọ̀ràn èyítí èmi ti yàn, àní èyíinì tí i ṣe ti Àjọ Ààrẹ ti Ìjọ mi; òun sì gbé ère wúrà kan ti ẹgbọ̀rọ̀ màlũ kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi láti sìn.

85 Ẹ máṣe jẹ́kí ẹnikankan ó lọ kúrò ní ibíyìí ẹnití ó ti wá sí ìhín ní títiraka láti pa àwọn òfin mi mọ́.

86 Bí wọ́n bá gbé ní ìhín ẹ jẹ́ kí wọn ó gbé sí mi; àti bí wọn bá sì kú ẹ jẹ́ kí wọ́n ó kú sí mi; nítorí wọn yíò sìnmi kúrò nínú gbogbo lãlã wọn ní ìhín, wọn yíò sì tẹ̀síwájú nínú àwọn iṣẹ́ wọn.

87 Nitorínáà, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi William kí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú mi, kí ó sì dẹ́kun láti bẹ̀rù nípa ẹbí rẹ̀, nítorí ti àìsàn ilẹ̀ náà. Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́; àwọn àìsàn ilẹ̀ náà yíò sì yọrí sí ògo yín.

88 Ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi William ó lọ kí ó sì kéde ìhìnrere àìlópin mi pẹ̀lú ohùn rara, àti pẹ̀lú ayọ̀ nlá, bí òun yíò ṣe ní ìmọlára nípa Ẹ̀mí mi, sí àwọn olùgbé Warsaw, àti pẹ̀lú sí àwọn olùgbé Carthage, àti pẹ̀lú sí àwọn olùgbé Burlington, àti pẹ̀lú sí àwọn olùgbé Madison, kí òun sì dúró pẹ̀lú sùúrù àti aápọn fún àwọn ìtọ́sọ́nà síwájú síi ní ibi ìpàdé gbogbogbò mi, ni Olúwa wí.

89 Bí òun bá ṣe ìfẹ́ mi ẹ jẹ́kí òun láti ìsisìyí lọ, fetísílẹ̀ sí ìmọ̀ràn ti ìránṣẹ́ mi Joseph, àti pẹ̀lú ẹ̀tọ́ rẹ̀ kí ó ṣe àtìlẹhìn fún ọ̀rọ̀ àwọn aláìní, kí ó sì tẹ ìtumọ̀ tuntun ti ọ̀rọ̀ mímọ́ mi jade sí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.

90 Bí òun bá sì ṣe èyí èmi yíò bùkún fún un pẹ̀lú ìlọ́po àwọn ìbúkún, pé a kì yíò kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tàbí kí a rí irú ọmọ rẹ̀ ní títọrọ oúnjẹ.

91 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ mi William jẹ́ yíyàn, ṣíṣe ìlànà fún, àti fífi àmi òróró yàn, bí olùdámọ̀ràn sí ìránṣẹ́ mi Joseph, nínú yàrá ti ìránṣẹ́ mi Hyrum, kí ìránṣẹ́ mi Hyrum ó lè gba ipò iṣẹ́ ti Oyè-Àlùfáà àti Pátríákì, èyítí a yàn òun sí láti ọwọ́ bàbá rẹ̀, nípa ìbùkún àti bákannáà nípa ẹ̀tọ́;

92 Pé láti ìsisìyí lọ òun yíò ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ti àwọn ìbùkún pátríákì sí orí gbogbo àwọn ènìyàn mi,

93 Pé ẹnikẹ́ni tí òun bá bùkún yíò di alábùkúnfún, àti ẹnikẹ́ni tí òun bá fi bú yíò di ìfibú; pé ohunkóhun tí òun bá dè ní ilẹ̀ ayé yíò jẹ́ dídè ní ọ̀run; àti pé ohunkóhun tí òun bá tú ní ilẹ̀ ayé ní yíò di títú ní ọ̀run.

94 Àti láti àkókò yìí lọ mo yàn fún òun pé kí ó lè jẹ́ wòlíì, àti aríran, àti olùfihàn sí ìjọ mi, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Joseph;

95 Pé kí òun ó lè ṣe ní ìfìmọ̀ṣọ̀kan bákannáà pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Joseph; àti pé òùn yíò gba ìmọ̀ràn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph, ẹnití yíò fi àwọn kọ́kọ́rọ́ hàn síi nípa èyítí òun lè béèrè kí ó sì rí gbà, kí á sì dé e ní adé pẹ̀lú irú ìbùkún kannáà, àti ògo, àti ọlá, àti oyè-àlùfáà, àti àwọn ẹ̀bùn ti oyè àlùfáà, tí a ti fi sí òun ní orí nígbà kan rí tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ mi Olíver Cowdery;

96 Kí ìránṣẹ́ mi Hyrum kí ó lè jẹ́rĩ àwọn ohun tí èmi yíò fi hàn sí i, kí orúkọ rẹ̀ ó lè wà ní ìrántí ọlọ́lá láti ìran dé ìran, láé ati títí láéláé.

97 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi William Law pẹ̀lú gba àwọn kọ́kọ́rọ́ nípa èyítí òun lè béèrè kí ó sì rí àwọn ìbùkún gbà; kí òun ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ níwájú mi, kí ó sì wà láìní ẹ̀tàn, òun yíò sì gba níti Ẹ̀mí mi, àní Olùtùnú náà, èyítí yíò fi òtítọ́ ohun gbogbo hàn sí i, àti tí yíò fi fún un, ní wákàtí náà gan an, ohun tí òun yíò wí.

98 Àwọn àmì wọ̀nyìí ni yíò sì tẹ̀lé e—òun yíò wo aláìsàn, òun yíò lé àwọn ẹ̀mí èṣù jade, a ó sì kóo yọ lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n lè fẹ́ lo májèlé olóró fún un;

99 A ó sì ṣíwájú rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà níbití ejò olóró kì yíò lè paá ní gìgísẹ̀, òun yíò sì gòkè nínú àwọn èrò inú ọkan rẹ̀ bíi ní orí ìyẹ́ ápá idì.

100 Àti kínní ṣe bí èmi bá fẹ́ kí òun jí òkú dìde, kí ó máṣe dá ohùn rẹ̀ dúró.

101 Nítorínáà, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi William kí ó kígbe ní ohùn rara kí ó má sì ṣe dásí, pẹ̀lú ayọ̀ àti ní inú dídùn, àti pẹ̀lú àwọn hòsánnà sí èni náà tí ó jókòó ní orí ìtẹ́ láé ati títí láéláé, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí.

102 Kíyèsíi, mo wí fún yín, mo ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ kan ní ìpamọ́ fún ìránṣẹ́ mi William, àti ìránṣẹ́ mi Hyrum, àti fún àwọn nìkan; ẹ sì jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Joseph kí ó dúró ní ilé, nítorí a nílò rẹ̀. Èyí tí ó kù ni èmi yíò fi hàn sí yín lẹ́hìnwá. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.

103 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí ìránṣẹ́ mi Sidney bá sìn mí tí òun sì jẹ́ olùdámọ̀ràn sí ìránṣẹ́ mi Joseph, ẹ jẹ́kí ó dìde kí ó sì gòkè wá kí òun sì dúró ní ipò iṣẹ́ ìpè rẹ̀, kí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi.

104 Àti bí òun yíò bá rú ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà kan sí mi, àti àwọn ìjẹ́wọ́, tí òun sì dúró pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi, kíyèsíi, èmi, Olúwa Ọlọ́run yín, yíò wò sàn tí òun yíò jẹ́ wíwòsàn; òun yíò sì gbé ohùn rẹ̀ sókè lẹ́ẹ̀kansíi ní orí àwọn òkè, yíó sì jẹ́ agbẹnusọ kan níwájú mi.

105 Ẹ jẹ́ kí òun ó wá kí ó sì fi ẹbí rẹ̀ sí àdúgbò náà níbi tí ìránṣẹ́ mi Joseph ngbé.

106 Àti nínú gbogbo àwọn ìrìnàjò rẹ̀, ẹ́ jẹ́ kí òun ó gbé ohùn rẹ̀ sókè bíi pẹ̀lú ìró fèrè kan, kí òun sì kìlọ̀ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé lati sá fún ìbínú tí yíó wá.

107 Ẹ jẹ́kí òun ó ṣe àtìlẹ́hìn fún ìránṣẹ́ mi Joseph, àti bákannáà ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi William Law ṣe àtìlẹ́hìn fún ìránṣẹ́ mi Joseph, ní ṣíṣé ìkéde tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kan sí àwọn ọba ilẹ̀ ayé, ànì bí mo ṣe sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.

108 Bí ìránṣẹ́ mi Sidney yíò bá ṣe ìfẹ́ mi, jẹ́kí òun kí ó máṣe mú ẹbí rẹ̀ kúrò lọ sí àwọn ilẹ̀ ìlà oòrùn, ṣùgbọ́n jẹ́kí òun yí ìbùgbé wọn padà, àní bí mo ti sọ.

109 Kíyèsíi, kìí ṣe ìfẹ́ inú mi pé kí òun lépa láti rí ibi ààbò àti ibi ìsádi kúrò nínú ìlú nlá náà èyítí mo ti yàn fún yín, àní ìlú nlá ti Nauvoo.

110 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, àní nísisìyí, bí òun bá fetísílẹ̀ sí ohùn mi, yíò dára fún un. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.

111 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Amos Davies san owó ìdókòwò sí ọwọ́ àwọn ẹnití èmi ti yàn láti kọ́ ilé kan fún ìpèsè ibùgbé, àní Ilé Nauvoo náà.

112 Èyí ni ẹ jẹ́kí òun ṣe bí òun yíò bá ní ìpín kan; ẹ sì jẹ́kí òun fetísílẹ̀ sí ìmọ̀ràn ìránṣẹ́ mi Joseph, àti kí òun ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ kí ó lè gba ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ènìyàn.

113 Àti nígbàtí ó bá fi ara rẹ̀ hàn bí olõtọ́ nínú ohun gbogbo tí a ó fi sí ìtọ́jú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, àní àwọn ohun díẹ̀, a ó fi òun ṣe alákòóso ní orí ohun púpọ̀;

114 Ẹ jẹ́kí òun nítorínáà, rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kí á lè gbé é ga. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.

115 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí ìránṣẹ́ mi Robert D. Foster yíò bá gbọ́ràn sí ohùn mi, ẹ́ jẹ́kí ó kọ́ ilé kan fún ìránṣẹ́ mi Joseph, gẹ́gẹ́bí àdéhùn èyítí òun ti ṣe pẹ̀lú rẹ̀, bí ìlẹ̀kùn yíò ṣe ṣí sílẹ̀ fún un láti àkókò dé àkókò.

116 Kí òun kí ó sì ronúpìwàdà gbogbo àìmòye rẹ̀, kí ó sì wọ ara rẹ̀ ní aṣọ pẹ̀lú ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́; àti kí ó dẹ́kun láti ṣe búburú, kí ó sì gbé àwọn ọ̀rọ̀ líle rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan;

117 Àti kí ó san ìdókòwò bákannáà sí ọwọ́ iyejú ti Ilé Nauvoo náà, fún ara rẹ̀ àti fún ìran rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀, láti ìran dé ìran;

118 Àti kí ó fetísílẹ̀ sí ìmọ̀ràn àwọn ìránṣẹ́ mi Joseph, àti Hyrum, àti William Law, àti sí àwọn aláṣẹ èyítí mo ti pè láti fi ìpìlẹ̀ Síónì lélẹ̀; yíò sì dára fún un láé ati títí láéláé. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.

119 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ máṣe jẹ́kí ẹnikẹ́ni ó san ìdókòwò fún iyejú ti Ilé Nauvoo náà bíkòṣe pé òun jẹ́ onígbàgbọ́ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti àwọn ìfihàn tí mo ti fi fún yín, ní Olúwa Ọlọ́run yín wí;

120 Nítorí èyíinì tí ó bá jù tàbí kéré sí èyí wá láti inú ibi, yíò sì ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ègún tí kìíṣe àwọn ìbùkún, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.

121 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́kí iyejú Ilé Nauvoo náà ó gba owó ọ̀yà tí ó tọ́ fún gbogbo iṣẹ́ wọn èyítí wọn nṣe ní kíkọ́ Ilé Nauvoo náà; ẹ sì jẹ́kí owó ọ̀ya wọn ó jẹ́ bí wọn yío ti fi ẹnu kò láàrin ara wọn, bí ó ṣe jẹ mọ́ iye owó níbẹ̀.

122 Ẹ sì jẹ́kí olúkúlùkù ènìyàn tí ó san ìdókòwò kí ó faradà apákan owó ọ̀ya wọn, bí ó bá ní láti rí bẹ́ẹ̀, fún àtìlẹ́hìn wọn, ni Olúwa wí; bíbẹ́ẹ̀kọ́, àwọn lãlã wọn ni a ó kà fún wọn bíi ìdókòwò nínú ilé náà. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.

123 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi nísisìyí fún yín ní àwọn olóyè tí wọ́n jẹ́ ti Oyè-Àlùfáà mi, pé kí ẹ̀yin ó lè ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ibẹ̀, àní Oyè-Àlùfáà èyítí ó jẹ́ nípa ètò ti Melkisédékì, èyítí ó jẹ́ nípa ètò ti Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo.

124 Ní àkọ́kọ́, mo fún yín ní Hyrum Smith láti jẹ́ pátríákì kan sí yín, láti ní àwọn ìbùkún fífi èdídí dì ti ìjọ, àní Ẹ̀mí Mímọ́ ti ìlérí náà, nípa èyítí a fi èdídí dì yín títí di ọjọ́ ìràpadà, pé kí ẹ̀yin má lè ṣubú bí ó tilè wù kí wákàtí ìdánwò wá sí orí yin tó.

125 Èmi fi ìránṣẹ́ mi Joseph fún yín láti jẹ́ alàgbà olùdarí kan ní orí gbogbo ìjọ mi, láti jẹ́ olùtúmọ̀ kan, olùfihàn kan, aríran kan, àti wòlíì.

126 Èmi fifún òun bíi àwọn olùdámọ̀ràn ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon àti ìránṣẹ́ mi William Law, pé kí àwọn wọ̀nyìí ó lè parapọ̀ jẹ́ iyejú kan àti Àjọ Ààrẹ Ìkínní, láti gba àwọn ìfihàn fún ìjọ lápapọ̀.

127 Èmi fi ìránṣẹ́ mi Brigham Young fún yín láti jẹ́ ààrẹ ní orí ìgbìmọ̀ àwọn Méjìlá tí wọ́n nrìnrìnàjò;

128 Àwọn Méjìlá èyítí ó ni àwọn kọ́kọ́rọ́ láti ṣí àṣẹ ìjọba mi ní orí igun mẹ́rẹ̃rin ilẹ̀ ayé, àti lẹ́hìn èyí láti rán ọ̀rọ̀ mi sí olúkúlùkù ẹ̀dá.

129 Àwọn ni Heber C. Kimball, Parley P. Pratt, Orson Pratt, Orson Hyde, William Smith, John Taylor, John E. Page, Wilford Woodruff, Willard Richards, George A. Smith;

130 David Patten ni èmi ti mú sí ọ̀dọ̀ ara mi; kíyèsíi, oyè àlùfáà rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le gbà lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n, lõtọ́ ni mo wí fún yín, a lè yan ẹlòmíràn sí ìpè kan náà.

131 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, èmi fi ìgbìmọ̀ gíga kan fún yín, fún òkúta igun ilé náà ti Síónì—

132 Orúkọ wọ̀nyí, Samuel Bent, Henry G. Sherwood, George W. Harris, Charles C. Rich, Thomas Grover, Newel Knight, David Dort, Dunbar Wilson—Seymour Brunson ni èmi ti mú sí ọ̀dọ̀ ara mi; ẹnikẹ́ni kò lè gba oyè àlùfáà rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ni a lè yàn sí oyè àlùfáà kannáà ní ipò rẹ̀; àti pé lootọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ mi Aaron Johnson ó jẹ́ yíyàn sí ipò yìí dípò rẹ̀—David Fullmer, Alpheus Cutler, William Huntington.

133 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo fi Don C. Smith fún yín láti jẹ́ ààrẹ ní orí iyejú ti àwọn àlùfáà gíga;

134 Ìlàna èyítí a gbé kalẹ̀ fún èrò mímú kún ojú òsùnwọ̀n àwọn wọnnì tí a ó yàn bí ààrẹ dídúró pẹ́ tàbí àwọn ìránṣẹ́ ní orí onírúurú àwọn èèkàn tí wọ́n fọ́n káàkiri ilẹ̀ òkèrè;

135 Àti pé wọ́n lè rin ìrìnàjò bákannáà bí wọ́n bá yàn, ṣùgbọ́n kí á kuku yàn wọ́n fún àwọn ààrẹ dídúró pẹ́; èyí ni ipò iṣẹ́ ti ìpè wọn, ni Oúwa Ọlọ́run yín wí.

136 Èmi fún òun ní Amasa Lyman àti Noah Packard fún àwọn olùdámọ̀ràn, kí wọn ó lè ṣe àkóso ní orí iyejú ti àwọn àlùfáà gígá ti ìjọ mi, ni Olúwa wí.

137 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, èmi fún yín ní John A. Hicks, Samuel Williams, àti Jesse Baker, oyè-àlùfáà èyítí yíó ṣe àkóso ní orí iyejú ti àwọn alagbà, iyejú èyítí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ dídúró pẹ́, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ wọn lè rín ìrìnàjò, síbẹ̀ a yàn wọ́n láti jẹ́ ìránṣẹ́ dídúró pẹ́ sí ìjọ mi, ni Olúwa wí.

138 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi fún yín ní Joseph Young, Josiah Butterfield, Daniel Miles, Henry Herriman, Zera Pulsipher, Levi Hancock, James Foster, láti ṣe àkóso ní orí iyejú ti àwọn àádọ́rin;

139 Iyejú èyítí a gbékalẹ̀ fún àwọn alàgbà tí nrin ìrìnàjò láti jẹ́rìí orúkọ mi ní gbogbo ayé, ní ibikíbi tí ìgbìmọ̀ gíga tí nrìn ìrìnàjò, àwọn àpóstélì mi, yíò rán wọn lọ láti pèsè ọ̀nà kan níwájú mi.

140 Ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin iyéjú yìí àti iyéjú ti àwọn alàgbà ni pé ọ̀kan níláti rìn ìrìnàjò léraléra, àti pé ọ̀kan yìókù nílati ṣe àkóso ní orí àwọn ìjọ láti àkókò dé àkókò; ọ̀kan ní ojúṣe ti ṣíṣe àkóso láti àkókò dé àkókò, àti pé ọ̀kan yìókù kì yíò ní ojúṣe ti ṣíṣe àkóso, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí.

141 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, èmi fún yín ní Vinson Knight, Samuel H. Smith, àti Shadrach Roundy, bí òun yíò bá gbà á, láti ṣe àkóso ní orí àjọ bíṣọ́pù; ìmọ̀ nípa àjọ bíṣọ́pù tí a wí yìí ni a fi fún yín nínú ìwé Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú.

142 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, Samuel Rolfe àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ fún àwọn àlùfáà, àti alákóso ti àwọn olùkọ́ àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, àti alákóso ti àwọn déákónì àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, àti bákannáà alákóso ti èèkàn àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀.

143 Àwọn ipò iṣẹ́ tí wọ́n wà lókè yí ni mo ti fifún yín, àti àwọn kọ́kọ́rọ́ ibẹ̀, fún àwọn ìrànlọ́wọ́ àti fún àwọn ìjọba, fún iṣẹ́ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ìsọdipípé ti àwọn ènìyàn mímọ́ mi.

144 Òfin kan ni mo sì fifún yín, pé kí ẹ dí àwọn ààyè ipò iṣẹ́ wọ̀nyìí kí ẹ sì fi ọwọ́ si àwọn orúkọ wọnnì èyítí mo ti sọ, bíbẹ́ẹ̀kọ́, ẹ kọ̀ lati fi ọwọ́ sí wọn ní ìpàdé gbogbogbò mi;

145 Àti pé ẹ̀yin yíò pèsè àwọn yàrá fún gbogbo àwọn ipò iṣẹ́ wọ̀nyìí nínú ilé mi nigbàtí ẹ bá kọ́ ọ sí orúkọ mi, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.